Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Dúpẹ́ Fáwọn Ìrírí Mánigbàgbé Tí Mo Ní!

Mo Dúpẹ́ Fáwọn Ìrírí Mánigbàgbé Tí Mo Ní!

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Dúpẹ́ Fáwọn Ìrírí Mánigbàgbé Tí Mo Ní!

GẸ́GẸ́ BÍ DRUSILLA CAINE ṢE SỌ Ọ́

Ọdún 1933 ni, Zanoah Caine sì ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ mi ni. Àwa méjèèjì jẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ńṣe ni inú mi ń dùn ṣìnkìn, bí mo ti ń múra àtilọ bá ọkọ mi níbi táa yàn án sí. Àmọ́ kí n tó lọ, mo gbọ́dọ̀ ní kẹ̀kẹ́—kì í sì í ṣe nǹkan tí apá mi lè ká nígbà yẹn nítorí nǹkan le gan-an nígbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀. Kí ni mo wá lè ṣe báyìí o?

NÍGBÀ táwọn àbúrò ọkọ mi gbọ́ nípa ìṣòro mi, wọ́n wá àwọn ògbólógbòó ẹ̀yà ara kẹ̀kẹ́ lọ sórí ààtàn, kí wọ́n lè fi ṣe kẹ̀kẹ́ fún mi. Wọ́n tò ó pọ̀, ló bá di kẹ̀kẹ́ ológeere! Gbàrà tí mo mọ̀ ọ́n gùn lèmi àti Zanoah mú ọ̀nà wa pọ̀n, táa ń fi tayọ̀tayọ̀ gun kẹ̀kẹ́ jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń pè ní Worcester àti Hereford, táa ń jẹ́rìí fún gbogbo àwọn táa bá pàdé.

Mi ò tètè mọ̀ pé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tí mo gbé wẹ́rẹ́ yìí yóò jẹ́ kí ìgbésí ayé mi kún fún àwọn ìrírí wíwúnilórí. Àmọ́ o, àwọn òbí mi ọ̀wọ́n ló fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àwọn nǹkan tẹ̀mí láti àárọ̀ ọjọ́.

Ojú Rí, Láwọn Ọdún Ogun Ńlá Náà

December 1909 ni wọ́n bí mi. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni màmá mi gba ẹ̀dà ìwé náà The Divine Plan of the Ages, nígbà tó sì di 1914, àwọn òbí mi mú mi lọ wo “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá], ní àdúgbò Oldham, ní ẹkùn ilẹ̀ Lancashire. (Àwọn táa mọ̀ sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ló ṣe méjèèjì jáde.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, mo rántí dáadáa pé ńṣe ni mo ń fò sókè tí mo ń yọ̀ ṣìnkìn nígbà táa ń lọ sílé nítorí ohun tí mo rí! Lẹ́yìn náà ni Frank Heeley bẹ̀rẹ̀ àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ní àdúgbò Rochdale tí à ń gbé. Lílọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́.

Ṣe ni Ogun Ńlá náà—tí à ń pè ní Ogun Àgbáyé Kìíní nísinsìnyí, fọ́ ìgbésí ayé wa tó tòrò minimini yángá lọ́dún kan náà. Wọ́n fẹ́ fagbára mú bàbá mi wọnú iṣẹ́ ológun, àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀, ó lóun ò ní dá sí tọ̀túntòsì. Ní ilé ẹjọ́, wọ́n pe bàbá mi ní “ẹni iyì,” lẹ́tà sì wá lóríṣiríṣi látọ̀dọ̀ “àwọn ọmọlúwàbí èèyàn tó sọ pé àwọn gbà gbọ́ pé tinútinú ni kò fi fẹ́ wọnú iṣẹ́ ológun,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn àdúgbò náà ṣe wí.

Àmọ́, kàkà tí wọn ì bá fi yọ̀ǹda bàbá mi pátápátá, wọ́n kàn forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ pé “Ojú Ogun nìkan ni kò ní lọ.” Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n tún ń fi èmi àti màmá mi ṣe yẹ̀yẹ́ pẹ̀lú. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n tún ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, wọ́n sì yanṣẹ́ àgbẹ̀ fún un, ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí mú un sìn, láìsanwó tó jọjú fún un, tàbí láìtilẹ̀ fún un ní kọ́bọ̀. Láti lè gbọ́ bùkátà ìdílé, màmá mi lọ ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó—nítorí àtirí tọ́rọ́ kọ́bọ̀ gbà—ní iléeṣẹ́ aṣọ fífọ̀ tí ẹnì kan dá sílẹ̀. Síbẹ̀ náà, mo wá rí i bí ìyà tó jẹ mí nígbà tí mo wà ní kékeré ṣe fún mi lókun tó; ó jẹ́ kí n mọ ìjẹ́pàtàkì àwọn nǹkan tẹ̀mí.

Ibi Kékeré Ló Ti Bẹ̀rẹ̀

Láìpẹ́ ni Daniel Hughes, tó fẹ́ràn fífara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dara pọ̀ mọ́ wa. Ó jẹ́ awakùsà ní abúlé Ruabon, tó jẹ́ nǹkan bí ogún kìlómítà sí Oswestry, níbi táa kó lọ. Ẹ̀gbọ́n Dan, bí mo ṣe máa ń pè é, kì í jìnnà sí ìdílé wa. Gbogbo ìgbà tó bá sì wá sọ́dọ̀ wa, ọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ ló sábà máa ń sọ. Kò ráyè ká kàn máa tàkúrọ̀sọ. A bẹ̀rẹ̀ kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Oswestry ní 1920, Ẹ̀gbọ́n Dan sì fún mi ní ẹ̀dà ìwé Duru Ọlọrun ní 1921. Bíi góòlù ni ìwé yìí rí lójú mi nítorí pé ó jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Ẹlòmíràn tún ni Pryce Hughes, a tó di òjíṣẹ́ alábòójútó ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní London lẹ́yìn náà. Itòsí wa lòun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé nílùú Bronygarth, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà ilẹ̀ Wales, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Cissie, sì di ọ̀rẹ́ màmá mi tímọ́tímọ́.

Mo rántí bí orí wa ṣe wú lọ́dún 1922 nígbà tí ìpè náà dún, pé ká ‘fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.’ Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì wà níléèwé, pẹ̀lú ìháragàgà ni mo fi bá wọn pín àwọn àkànṣe àṣàrò kúkúrú náà, pàápàá jù lọ Ecclesiastics Indicted ní 1924. Nígbà tí mo bá rántí ẹ̀wádún yẹn, ẹ wo àǹfààní ńlá tó jẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin olóòótọ́ tó pọ̀ tóyẹn—àwọn bí Arábìnrin Maud Clark b àti ẹnì kejì rẹ̀ Mary Grant, c Edgar Clay, d Robert Hadlington, Katy Roberts, Edwin Skinner, e àti Percy Chapman àti Jack Nathan, f tí àwọn méjèèjì lọ sí Kánádà láti lọ kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn níbẹ̀.

Àsọyé náà táa gbé ka Bíbélì, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé,” jẹ́ ẹ̀rí tó bákòókò mu wẹ́kú ní ìpínlẹ̀ wa gbígbòòrò. Ní May 14, 1922, Stanley Rogers, tó jẹ́ ìbátan Pryce Hughes, wá láti Liverpool láti wá sọ àsọyé yìí ní abúlé Chirk, tó wà ní àríwá ìlú wa, lẹ́yìn náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn ó sọ àsọyé kan náà ní Ilé Eré Sinimá tó wà ní Oswestry. Mo ṣì ní ọ̀kan lára ìwé ìléwọ́ táa dìídì tẹ̀ fún àsọyé yẹn lọ́wọ́. Ní gbogbo àkókò yìí, àwùjọ kékeré wa túbọ̀ ń gba agbára kún agbára nípasẹ̀ ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mẹ́ta—àwọn táa ń pè ní arìnrìn-àjò onísìn láyé ọjọ́un—àwọn ni Herbert Senior, Albert Lloyd, àti John Blaney.

Àkókò Ìpinnu

Lọ́dún 1929, mo pinnu pé mo fẹ́ ṣe batisí. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mí, ìgbà yẹn ni mo sì kọ́kọ́ dojú kọ ìdánwò gidi. Mo bá ọ̀dọ́mọkùnrin kan pàdé tí bàbá rẹ̀ jẹ́ olóṣèlú. Ó wù mí, èmi náà sì wù ú. Ó wá lóun fẹ́ẹ́ fẹ́ mi. Ọdún tó ṣáájú ìyẹn ni ìwé náà Government jáde, mo sì fún un ní ẹ̀dà kan. Àmọ́ kò pẹ́ tó fi ṣe kedere pé kò nífẹ̀ẹ́ sí ìjọba ọ̀run, tí í ṣe ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwé yìí. Ara ohun tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ ni pé a pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìjelòó pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn aláìgbàgbọ́ dána, mo sì mọ̀ pé ìlànà yìí kan àwa Kristẹni. Nítorí náà, mo sọ fún un pé mi ò ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòroó sọ.—Diutarónómì 7:3; 2 Kọ́ríńtì 6:14.

Mo rí ìṣírí nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:9) Ẹ̀gbọ́n Dan, ẹni ọ̀wọ́n, tún ràn mí lọ́wọ́ nígbà tó kọ̀wé pé: “Nínú àdánwò kékeré àti ńlá, má gbàgbé ìwé Róòmù 8, ẹsẹ 28,” tó kà pé: “Wàyí o, a mọ̀ pé Ọlọ́run ń mú kí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí í ṣe àwọn tí a pè ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀.” Kò rọrùn, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ìpinnu tó tọ́ ni mo ṣe yẹn. Ọdún yẹn ni mo di apínwèé-ìsìn-kiri.

Kíkojú Ìpèníjà Náà

Ní ọdún 1931, a gba orúkọ wa tuntun náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì pín ìwé pẹlẹbẹ Ijọba Na, Ireti Aiye káàkiri lọ́dún yẹn. Gbogbo olóṣèlú, àlùfáà, àti oníṣòwò la fún ní ẹ̀dà ìwé náà. Ìpínlẹ̀ mi nasẹ̀ láti Oswestry dé Wrexham, tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n níhà àríwá. Kò rọrùn rárá láti kárí gbogbo ìpínlẹ̀ náà.

Ní àpéjọpọ̀ kan ní Birmingham lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n béèrè fún olùyọ̀ǹda ara ẹni mẹ́rìnlélógún. Pẹ̀lú ìháragàgà ni àwa mẹ́rìnlélógún fi kọ orúkọ wa sílẹ̀ fún irú iṣẹ́ kan tó jẹ́ tuntun, a ò tíì mọ irú iṣẹ́ tó jẹ́. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa nígbà tí wọ́n pín wa ní méjìméjì, tí wọ́n ní ká lọ máa pín ìwé pẹlẹbẹ kan náà, Ijọba Na, Ireti Aiye, pẹ̀lú ìsọfúnni fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ táa gbé kọ́rùn táa fi ń polongo Ìjọba náà.

Àyíká ṣọ́ọ̀ṣì gàgàrà kan la ti lọ ṣiṣẹ́, ojú sì bẹ̀rẹ̀ sí tì mí, ṣùgbọ́n mo tu ara mi nínú pé kò kúkú sẹ́ni tó mọ̀ mí ní ìlú ńlá yìí. Ṣùgbọ́n ẹni àkọ́kọ́ tó wá bá mi ni ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ táa jọ lọ síléèwé. Ó wò mí sùn-ùn, ó ní: “Èwo ló dé, tó wá sún ẹ gbé eléyìí kọ́rùn?” Ìrírí yẹn ló wá mú gbogbo ìbẹ̀rù èèyàn kúrò lọ́kàn mi pátá!

Mo Túbọ̀ Wọnú Pápá Lọ

Lọ́dún 1933, mo fẹ́ Zanoah tí ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ ti kú, tó sì fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n jù mí lọ. Ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara, Zanoah sì ń fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó lẹ́yìn ikú aya rẹ̀. Láìpẹ́ la ṣí kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ sí ìpínlẹ̀ wa tuntun ní Àríwá Wales, tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́jọ [145] síbi táa wà tẹ́lẹ̀. Ńṣe la to àwọn páálí, àpótí, àtàwọn nǹkan iyebíye yòókù gàgàgúgú sọ́rùn ọwọ́ kẹ̀kẹ́, àti sára ọ̀pá tó lọ síbi ìjókòó, táa tún to ẹrù gúdugùdu sẹ́yìn kẹ̀kẹ́, àmọ́ a gúnlẹ̀ láyọ̀! Kòṣeémánìí ni àwọn kẹ̀kẹ́ wa jẹ́ ní ìpínlẹ̀ yẹn—àwọn là ń gùn lọ síbi gbogbo, títí dé ẹ̀bá ṣóńṣó òkè Cader Idris, ní Wales, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] mítà. Ohun ìwúrí ńláǹlà ló jẹ́ láti rí àwọn èèyàn tí ń hára gàgà láti gbọ́ “ìhìn rere ìjọba yìí.”—Mátíù 24:14.

Kò tíì pẹ́ táa débẹ̀ làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wa pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tom Pryce ti ń wàásù fáwọn, bí àwa náà ti ń ṣe. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a fojú gán-ánní Tom tó ń gbé ní Long Mountain, nítòsí Welshpool—háà sì ṣe wá! Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí jáde òde ẹ̀rí ni mo fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Ìlàjà. Ó dá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó kọ̀wé sí London pé kí wọ́n fi ìwé púpọ̀ sí i ránṣẹ́ sóun, látìgbà yẹn ló sì ti ń fi tìtara-tìtara wàásù nípa ìgbàgbọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí. A gbádùn ọ̀pọ̀ wákàtí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ aláyọ̀, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sábà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ láti fún ara wa níṣìírí.

Ìjábá Kan Yọrí sí Ìbùkún

Ní 1934, wọ́n ní kí gbogbo àwa apínwèé-ìsìn-kiri tí ń bẹ nítòsí Àríwá Wales lọ sílùú Wrexham láti lọ pín ìwé pẹlẹbẹ Righteous Ruler níbẹ̀. Ìjábá kan ṣẹlẹ̀ kárí orílẹ̀-èdè náà nígbà tó ku ọ̀la tí a ó bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò àkànṣe yìí. Kiní kan bú gbàù níbi ìwakùsà Gresford, tó wà ní kìlómítà mẹ́ta sí ìhà àríwá Wrexham, ó sì pa mẹ́rìndínláàádọ́rin lé rúgba [266] àwọn awakùsà. Àwọn ọmọ tó lé ní igba ló di aláìníbaba, ọgọ́jọ [160] obìnrin sì di opó.

A ṣètò láti ní orúkọ gbogbo àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lọ́wọ́, ká bẹ̀ wọ́n wò, ká sì fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ náà. Ọ̀kan lára àwọn orúkọ tí wọ́n fún mi jẹ́ ti Ìyáàfin Chadwick, tí ọmọkùnrin rẹ̀ ẹni ọdún mọ́kàndínlógún bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Nígbà tí mo débẹ̀, mo bá Jack, ọmọ rẹ̀ àgbà níbẹ̀ tó wá bẹ màmá rẹ̀ wò láti tù ú nínú. Ọ̀dọ́mọkùnrin yìí dá mi mọ̀, ṣùgbọ́n kò sọ fún mi. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó ka ìwé pẹlẹbẹ náà, ó sì wá ìwé pẹlẹbẹ náà The Final War kàn, èyí tí mo fún un ní ọdún mélòó kan ṣáájú.

Jack àti May, aya rẹ̀ wá ibi tí mò ń gbé kàn, wọ́n sì wá gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i. Ní 1936, wọ́n gbà láti máa ṣe ìpàdé nínú ilé wọn ní Wrexham. Lẹ́yìn ìbẹ̀wò Albert Lloyd ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, a dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀, Jack Chadwick sì di alábòójútó olùṣalága ìjọ náà. Ìjọ mẹ́ta ló wà ní Wrexham báyìí.

Ìgbésí Ayé Nínú Ọkọ̀ Àfiṣelé Ti Àwọn Gypsy

Títí di àkókò yìí, ibikíbi táa bá rí là ń wọ̀ sí báa ti ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíràn, ṣùgbọ́n Zanoah pinnu pé ó ti tó àkókò kí àwa náà ní ilé tiwa, ilé tí á ṣeé fà kiri. Káfíńtà tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ ni ọkọ mi, ẹ̀yà Gypsy sì ni. Ọkọ̀ àfiṣelé irú ti àwọn Gypsy ló sì kọ́ fún wa. Èlísábẹ́tì, orúkọ kan látinú Bíbélì tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Oníbú Ọrẹ,” la ń pe ilé náà.

Mo rántí ibì kan pàtó táa dó sí—nínú oko igi eléso lẹ́bàá odò kan. Lójú tèmi, bíi Párádísè gẹ́ẹ́ ló rí! Kò sí nǹkan kan tó ba ayọ̀ wa jẹ́ ní gbogbo ọdún táa fi jọ ń gbé inú ọkọ̀ àfiṣelé yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó há. Nígbà tí ojú ọjọ́ bá tutù, ńṣe ni aṣọ táa tẹ́ sórí ibùsùn máa ń gan mọ́ ara ògiri, omi á sì máa kán. Ọ̀nà jíjìn la sì ti lọ máa ń pọnmi nígbà míì, àmọ́ a jùmọ̀ borí ìṣòro wọ̀nyí.

Nígbà ọ̀gìnnìtìn kan ara mi ò yá, oúnjẹ táa ní nílé ò tó nǹkan, kò sì sí kọ́bọ̀ lápò. Zanoah jókòó sórí ibùsùn, ó di ọwọ́ mi mú, ó sì ka Sáàmù 37:25 sétígbọ̀ọ́ mi, pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” Ó wò mí lójú, ó ní: “Bí nǹkan ò bá yí padà, a ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ṣagbe, àmọ́ Ọlọ́run ò ní jẹ́!” Bó ṣe jáde lọ wàásù fáwọn aládùúgbò wa nìyẹn.

Nígbà tí Zanoah padà dé ní ọjọ́ kanrí láti wá ṣètò nǹkan mímu fún mi, àpòòwé kan ti wà nílẹ̀ tó ń dúró dè é. Àádọ́ta owó pọ́n-ùn la bá nínú rẹ̀, tí bàbá rẹ̀ fi ránṣẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n fẹ̀sùn èké kan Zanoah pé ó kówó jẹ, ṣùgbọ́n wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i kedere pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ni. Ẹ̀bùn yẹn jẹ́ owó gbà-máà-bínú. Gẹ́gẹ́ ló ṣe!

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n

Nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọdún ká tó lóye ohun tí wọ́n ń kọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ: Kí n tó kúrò ní iléèwé lọ́dún 1927, gbogbo ọmọ kíláàsì àtàwọn tíṣà mi ni mo jẹ́rìí fún—àfi Lavinia Fairclough nìkan. Níwọ̀n bí kò ti sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe, tí èmi àti Omidan Fairclough ò sì kúkú rẹ́ lọ títí, mo pinnu pé mi ò ní jẹ́rìí fún un. Fojú inú wo bó ṣe yà mí lẹ́nu tó—tí inú mi sì ti dùn tó—ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí màmá mi sọ fún mi pé tíṣà yìí ti padà wá bá gbogbo ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ àtijọ́, tó ń sọ fún wọn pé òun ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà!

Nígbà táa pàdé, mo ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi sọ fún un nípa ẹ̀sìn mi àtohun tí mo fẹ́ fi ìgbésí ayé mi ṣe. Ó baralẹ̀ gbọ́ mi, ó sì sọ pé: “Ọjọ́ ti pẹ́ tí mo ti ń wá òtítọ́. Òun ni mo ti ń fi gbogbo ọjọ́ ayé mi wá kiri!” Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ni ìrírí yìí jẹ́ fún mi—láti má ṣe kùnà láti jẹ́rìí fún gbogbo èèyàn tí mo bá ń bá pàdé, kí n má sì ní èrò òdì nípa ẹnikẹ́ni.

Ogun Mìíràn—Àtohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Náà

Òjò ogun tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣú dẹ̀dẹ̀ bí àwọn ọdún 1930 ṣe ń parí lọ. Wọ́n sọ fún Dennis, àbúrò mi ọkùnrin tí mo gba ọdún mẹ́wàá lọ́wọ́ rẹ̀, pé àwọn ò ní mú un wọṣẹ́ ológun bó bá gbà láti máa bá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ nìṣó. Kò fẹ̀ẹ̀kàn fẹ́ràn òtítọ́ lọ títí, nítorí náà èmi àti ọkọ mi bẹ Rupert Bradbury àti David àbúrò rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, pé kí wọ́n jọ̀wọ́ máa bá wa bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Dennis ṣe batisí lọ́dún 1942, ó wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn náà, wọ́n yàn án ṣe alábòójútó arìnrìn-àjò ní 1957.

A bí Elizabeth ọmọbìnrin wa ní 1938, ká sì lè kojú àìní ìdílé wa, Zanoah mú ọkọ̀ àfiṣelé wa gbòòrò sí i. Nígbà táa bí Eunice, ọmọbìnrin wa kejì ní 1942, ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti wá ilé gidi tí a óò máa gbé. Ìyẹn ló fà á tí Zanoah fi ṣíwọ́ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọdún díẹ̀, a sì kó lọ sínú ilé kékeré kan nítòsí Wrexham. Lẹ́yìn náà, a kó lọ sílùú Middlewich, tó wà ní ẹkùn ilẹ̀ Cheshire, tó wà nítòsí. Ibẹ̀ ni ọkọ mi ọwọ̀n ti kú ní 1956.

Àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì di ajíhìnrere alákòókò kíkún, wọ́n sì ń gbádùn ilé ọkọ wọn. Eunice àti ọkọ rẹ̀, tó jẹ́ alàgbà, ṣì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní London. Ọkọ Elizabeth pẹ̀lú jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, nǹkan ayọ̀ ló sì jẹ́ fún mi, pé àwọn, àtàwọn ọmọ wọn, àtàwọn àtọmọdọ́mọ mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń gbé nítòsí mi ní Preston, Lancashire.

Mo dúpẹ́ pé mo lè rìn láti ẹnu ọ̀nà àbájáde ilé mi dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ń bẹ ní ìsọdá títì. Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwùjọ tí ń sọ èdè Gujarati tó ń pàdé níbẹ̀, ni mo ń dara pọ̀ mọ́. Èdè náà kò rọrùn-ún gbọ́ nítorí pé n kì í fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ mọ́ báyìí. Kì í sábàá rọrùn fún mi láti mọ̀yàtọ̀ àwọn ìró ohùn tó jọra gan-an nínú èdè náà, bó ti máa ń rọrùn fáwọn ọ̀dọ́. Ṣùgbọ́n ìpèníjà tó fani lọ́kàn mọ́ra ni.

Mo ṣì lè wàásù láti ilé dé ilé, kí n sì darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé mi pẹ̀lú. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ bá wá kí mi, inú mi máa ń dùn gan-an láti sọ àwọn kan lára ìrírí mi ìgbà àtijọ́ fún wọn. Mo dúpẹ́ gan-an fáwọn ìrírí mánigbàgbé tí mo ní, pàápàá àwọn ìbùkún tí mo ti rí gbà bí mo ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rùn-ún ọdún báyìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Inú àpilẹ̀kọ náà “In Step With the Faithful Organization,” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́, April 1, 1963, lédè Gẹ̀ẹ́sì, ni ìtàn ìgbésí ayé Pryce Hughes wà.

b Ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ti jáde tipẹ́ nínú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì.

c Ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ti jáde tipẹ́ nínú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì.

d Ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ti jáde tipẹ́ nínú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì.

e Ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ti jáde tipẹ́ nínú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì.

f Ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyí ti jáde tipẹ́ nínú àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ìwé ìléwọ́ táa fi polongo àsọyé Bíbélì náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé,” èyí tí mo gbọ́ ní May 14, 1922

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Zanoah kété lẹ́yìn ìgbéyàwó wa ní 1933

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Mo dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ “Èlísábẹ́tì,” ìyẹn ọkọ̀ àfiṣelé wa tí ọkọ mi kàn