Ǹjẹ́ o Lè “Fi Ìyàtọ̀ Sáàárín Ohun Tí ó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́”?
Ǹjẹ́ o Lè “Fi Ìyàtọ̀ Sáàárín Ohun Tí ó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́”?
“Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—ÉFÉSÙ 5:10.
1. Kí ló lè mú kí ìgbésí ayé pinni lẹ́mìí lóde òní, èé sì ti ṣe?
“MO MỌ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àwa tí a ń gbé ayé lóde òní gan-an ni kókó pàtàkì tí Jeremáyà sọ yìí wúlò fún jù lọ. Kí nìdí? Nítorí pé a ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ tẹlẹ̀. (2 Tímótì 3:1) Ojoojúmọ́ là ń kojú àwọn ipò tó ń pinni lẹ́mìí tó ń béèrè pé ká ṣe àwọn ìpinnu. Ì báà jẹ́ ìpinnu tó ṣe pàtàkì tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, àwọn ìpinnu wọ̀nyí lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ire wa—nípa tara, ní ti ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí.
2. Àwọn yíyàn wo la lè kà sí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, síbẹ̀ ojú wo ni àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fi ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
2 Ọ̀pọ̀ yíyàn táa ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ la lè kà sí ohun tó ti mọ́ wa lára tàbí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Fún àpẹẹrẹ, ojoojúmọ́ là ń yan aṣọ táa ń wọ̀, oúnjẹ táa ń jẹ, àwọn èèyàn táa ń rí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A ń ṣe àwọn yíyàn wọ̀nyí déédéé láìṣẹ̀ṣẹ̀ ronú lọ títí. Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni? Ní ti àwa Kristẹni táa ti ya ara wa sí mímọ́, ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ́ olórí àníyàn wa ni pé kí yíyàn táa ń ṣe nípa aṣọ àti ìrísí wa, nínú jíjẹ àti mímu wa, àti nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa máa fi gbogbo ìgbà fi hàn pé ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni wá. A rán wa létí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31; Kólósè 4:6; 1 Tímótì 2:9, 10.
3. Àwọn yíyàn wo ló gba ìrònújinlẹ̀?
3 Àmọ́, àwọn yíyàn kan tún wà tó gba ìrònú jinlẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú pé ṣíṣe ìpinnu láti gbéyàwó tàbí láti wà lápọ̀n-ọ́n jẹ́ ohun tó ń nípa tó jinlẹ̀ tó sì wà pẹ́ títí lórí ìgbésí ayé ẹnì kan. Láti rí i dájú pé a yan ẹni tó dára láti fẹ́, tó máa jẹ́ ẹnì kejì ẹni títí ayé, kì í ṣe ọ̀ràn kékeré rárá. a (Òwe 18:22) Láfikún sí i, irú àwọn ọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ táa yàn, ẹ̀kọ́ táa yàn, iṣẹ́ táa yàn, àti irú eré ìdárayá táa yàn ń kópa pàtàkì, àní tó ṣe kókó gan-an nínú ipò tẹ̀mí wa—ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kan ire wa ayérayé.—Róòmù 13:13, 14; Éfésù 5:3, 4.
4. (a) Agbára wo ló máa ṣe wá láǹfààní jù lọ? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
4 Lójú gbogbo yíyàn wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì gan-an fún wa láti lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ tàbí sáàárín ohun tó fara hàn bí èyí tí ó tọ́ àti ohun tí ó tọ́ ní ti gidi. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 14:12) Nítorí ìdí èyí, a lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé: ‘Báwo la ṣe lè mú agbára láti fìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú dàgbà? Ibo la lè yíjú sí láti rí ìtọ́sọ́nà táa nílò nínú ṣíṣe ìpinnu? Kí làwọn èèyàn ìgbàanì àtàwọn tòde òní ti ṣe lórí ọ̀ràn yìí, kí ló sì ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?’
“Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí àti Ẹ̀tàn Òfìfo” Ti Ayé
5. Irú ayé wo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbénú rẹ̀?
5 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbé nínú ayé kan tí ìlànà àti èrò àwọn Gíríìkì àti tàwọn ará Róòmù ti gbòde kan. Lọ́nà kan, ọ̀nà ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì táwọn ará Róòmù gbé wà níbẹ̀, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí ohun tó yẹ káwọn jowú. Yàtọ̀ síyẹn, àwùjọ àwọn amòye tún ń fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí Plato àti ti Aristotle ṣe fọ́rífọ́rí, àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún ní àwọn èròǹgbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú, irú bíi tàwọn Epikúréì àtàwọn Sítọ́ìkì. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sí Áténì nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Epikúréì àti ti Sítọ́ìkì kò ó lójú, ìyẹn àwọn tí wọ́n gbà pé àwọn ṣe pàtàkì ju “onírèégbè yìí,” ìyẹn Pọ́ọ̀lù.—Ìṣe 17:18.
6. (a) Kí làwọn nǹkan kan tó ń fa àwọn kan lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mọ́ra? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni?
6 Nítorí náà, kò ṣòro láti lóye ìdí tí àṣà àti ọ̀nà ìgbésí ayé ṣekárími àwọn èèyàn tó yí wọn ká fi fa àwọn kan lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mọ́ra. (2 Tímótì 4:10) Ó dà bí ẹni pé àwọn tó jẹ́ ara ètò yẹn ń gbádùn ọ̀pọ̀ àǹfààní, yíyàn tí wọ́n sì ń ṣe dà bí èyí tó dára gan-an. Ó dà bíi pé ayé ní ohun ṣíṣeyebíye láti fúnni, èyí tí ọ̀nà ìgbésí ayé oníyàsímímọ́ táwọn Kristẹni ń gbé kò lè fúnni. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” (Kólósè 2:8) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀?
7. Kí ni ọgbọ́n ayé jẹ́ ní ti gidi?
7 Pọ́ọ̀lù fún wọn ní ìkìlọ̀ yẹn nítorí ó rí i pé ewu gidi ló ń wu ìrònú àwọn tí nǹkan ayé ń fà mọ́ra wọ̀nyẹn. Lílò tí ó lo ọ̀rọ̀ náà “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo” ṣe pàtàkì gan-an ni. Ọ̀rọ̀ náà, “ìmọ̀ ọgbọ́n orí” wúlẹ̀ túmọ̀ sí “nínífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n àti lílépa rẹ̀.” Ìyẹn nínú ara rẹ̀ lè ṣeni láǹfààní. Ká sòótọ́, Bíbélì, ní pàtàkì ìwé Òwe, gbà wá níyànjú láti máa lépa ìmọ̀ àti ọgbọ́n tí ó tọ́. (Òwe 1:1-7; 3:13-18) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù so “ìmọ̀ ọgbọ́n orí” pọ̀ mọ́ “ẹ̀tàn òfìfo.” Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, Pọ́ọ̀lù ka ọgbọ́n tí ayé lè fúnni sí òfìfo àti ẹ̀tàn. Bíi fèrè táa fẹ́ afẹ́fẹ́ kún inú rẹ̀, ó dà bí nǹkan tó le, ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun nínú rẹ̀. Ó dájú pé asán ni yóò já sí, ó tiẹ̀ léwu pàápàá láti gbé ohun téèyàn kà sí ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ kárí ohun kan tí kò ní láárí tó jẹ́ “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo” ti ayé.
Àwọn Tó Ń Sọ Pé “Ohun Tí Ó Dára Burú àti Pé Ohun Tí Ó Burú Dára”
8. (a) Ọ̀dọ̀ ta làwọn èèyàn ń yíjú sí láti gba ìmọ̀ràn? (b) Irú ìmọ̀ràn wo ni wọ́n ń fúnni?
8 Àwọn nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ lóde òní. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú gbogbo ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn ni àwọn ògbóǹkangí wà. Àwọn olùgbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó àti ìdílé, àwọn akọ̀ròyìn, àwọn tó ń pe ara wọn ní oníṣègùn, àwọn awòràwọ̀, àwọn abẹ́mìílò, àtàwọn mìíràn múra tán láti gbani nímọ̀ràn—kí wọ́n sì gbowó iṣẹ́ wọn. Àmọ́ irú ìmọ̀ràn wo ni wọ́n ń fúnni? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìlànà Bíbélì lórí ìwà rere la máa ń fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ohun tí wọ́n ń pè ní ọ̀nà ìwà rere tuntun. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọba ṣe kọ̀ láti fọwọ́ sí “ìgbéyàwó àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà kan náà,” ọ̀rọ̀ olótùú nínú ìwé ìròyìn The Globe and Mail tó gbajúmọ̀ gan-an ní Kánádà sọ pé: “Nínú ọdún 2000, kò bọ́gbọ́n mu rárá láti fi ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn méjì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ti pinnu láti jọ wà fún ara wọn, dù wọ́n kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹ̀yà kan náà.” Àṣà tó lòde lónìí ni pé kéèyàn rára gba nǹkan, kì í ṣe kó máa ṣe lámèyítọ́. Wọ́n ní èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ ni gbogbo nǹkan; kò sí ìlànà àjọgbà lórí ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.—Sáàmù 10:3, 4.
9. Kí làwọn táwọn èèyàn kà sí ẹni iyì láwùjọ sábà máa ń ṣe?
9 Àwọn mìíràn ń wo àwọn tó ti kẹ́sẹ járí láàárín ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti nínú ọ̀ràn ìṣúnná owó—ìyẹn àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tó lókìkí—gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tó lókìkí sí àwọn tó yẹ ká máa bọlá fún láwùjọ, ẹnu lásán ni wọ́n fi máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà funfun bí àìlábòsí àti ìfọkàntánni. Nígbà tó bá dórí ọ̀ràn lílépa agbára àti èrè, ọ̀pọ̀ ni kò rí ohun tó burú nínú kí wọ́n gbọ̀nà ẹ̀bùrú, kí wọ́n sì fojú pa ìlànà ìwà rere rẹ́. Nítorí àtidi gbajúmọ̀ àti olókìkí, àwọn kan ti fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà àtayébáyé sẹ́yìn kí wọ́n lè máa hu ìwà tó ṣàjèjì tó sì lè múni gbọ̀n rìrì. Àbájáde rẹ̀ ni àwùjọ kan tó ń gbé èrè jíjẹ lárugẹ, tó sì gbàgbàkugbà, tó jẹ́ pé ẹ̀mí tó ń darí wọn ni, “Ohun gbogbo ló dára.” Ṣé ó wá yani lẹ́nu nígbà náà pé ọ̀ràn àwọn èèyàn kò yéra wọn rárá, tí wọn ò sì dákan mọ̀ tó bá ti di ọ̀ràn ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́?—Lúùkù 6:39.
10. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ nípa ohun rere àti ohun búburú ṣe já sí òtítọ́?
10 Gbogbo àbájáde búburú tí ìpinnu òmùgọ̀ táwọn èèyàn ń ṣe ń mú jáde nítorí àìtọ ọ̀nà tó tọ́ la ń rí láyìíká wa—àwọn ìgbéyàwó àti ìdílé tó ń tú ká, jíjẹ oògùn yó àti mímu àmupara ọtí, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ oníjàgídíjàgan, ìṣekúṣe, àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ká wulẹ̀ mẹ́nu kan díẹ̀ lára wọn. Ká sọ tòótọ́, báwo la ṣe lè retí ohun tó yàtọ̀ síyẹn nígbà táwọn èèyàn kọ gbogbo ìlànà tàbí ọ̀pá ìdiwọ̀n ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ sílẹ̀? (Róòmù 1:28-32) Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni wòlíì Aísáyà sọ ọ́, pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára, àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn, àwọn tí ń fi ohun kíkorò dípò dídùn àti ohun dídùn dípò kíkorò! Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n ní ojú ara wọn, tí wọ́n sì jẹ́ olóye àní ní iwájú àwọn fúnra wọn!”—Aísáyà 5:20, 21.
11. Èé ṣe tó fi jẹ́ èrò tí kò bọ́gbọ́n mu láti gbẹ́kẹ̀ lé ara ẹni nígbà táa bá ń pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́?
11 Pípè tí Ọlọ́run pe àwọn Júù ìgbàanì, tí wọ́n “gbọ́n ní ojú ara wọn” láti jíhìn jẹ́ kó túbọ̀ ṣe pàtàkì fún wa láti yẹra fún gbígbẹ́kẹ̀ lé ara wa láti pinnu ohun rere àti búburú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pẹ̀lú àbá táwọn èèyàn ń dá lónìí pé “ìwọ ṣáà ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ pé kóo ṣe,” tàbí “ṣe ohun tóo bá mọ̀ pé ó tọ́.” Ǹjẹ́ irú ìgbésẹ̀ yẹn bọ́gbọ́n mu? Kò bọ́gbọ́n mu, lójú ohun tí Bíbélì wí, tó sọ kedere pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Ǹjẹ́ o lè gbára lé aládàkàdekè èèyàn tàbí ẹnì kan tó ti gbékútà láti darí rẹ nígbà tóo bá fẹ́ ṣe ìpinnu? Rárá. Ká sọ tòótọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òdì kejì ohun tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ fún ọ lo máa ṣe. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rán wa létí pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.”—Òwe 3:5-7; 28:26.
Kíkọ́ Ohun Tó Ṣe Ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run
12. Èé ṣe táa fi ní láti fúnra wa ṣàwárí ohun tó jẹ́ “ìfẹ́ Ọlọ́run”?
12 Níwọ̀n bí kò ti yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n ayé, tí kò sì yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé ara wa nígbà táa bá ń pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, kí ni ká wá ṣe? Kíyè sí ìmọ̀ràn tó ṣe kedere tó sì yéni yékéyéké yìí látọ̀dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ fúnra wa ṣàwárí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́? Nínú Bíbélì, Jèhófà fún wa ní ìdí tó ṣe tààrà àmọ́ tó jẹ́ èyí tó lágbára lórí ọ̀ràn yìí, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.” (Aísáyà 55:9) Nítorí náà, dípò tí a ó fi gbẹ́kẹ̀ lé làákàyè ara wa tàbí lé ohun táa rò pé ó dáa, a ṣí wa létí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfésù 5:10.
13. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 17:3 ṣe tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti mọ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run?
13 Jésù Kristi tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Gbólóhùn náà, “gba ìmọ̀” ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an ju “mímọ̀” lásán lọ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary sọ, ó “fi ìbátan tó wà láàárín ẹni tí ó mọ nǹkan àti ohun tí ó mọ̀ hàn; nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí ó mọ̀ náà níye lórí tàbí ó ṣe pàtàkì sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, èyí sì tipa bẹ́ẹ̀ fi bí àjọṣe tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó hàn.” Ohun tí níní àjọṣe pẹ̀lú ẹnì kan túmọ̀ sí kọjá wíwulẹ̀ mọ ẹni tí onítọ̀hún jẹ́ tàbí mímọ orúkọ rẹ̀. Ó tún kan mímọ ohun tí ẹni náà fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́, kí a mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì lójú rẹ̀ àtàwọn ìlànà rẹ̀—kí a sì máa fojú ribiribi wo nǹkan wọ̀nyí.—1 Jòhánù 2:3; 4:8.
Kíkọ́ Agbára Ìrònú Wa
14. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ olórí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ìkókó nípa tẹ̀mí àti àwọn èèyàn tó dàgbà dénú?
14 Báwo wá la ṣe lè ní agbára láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́? Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù ní ọ̀rúndún kìíní fún wa ní ìdáhùn rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń mu wàrà jẹ́ aláìdojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ òdodo, nítorí tí ó jẹ́ ìkókó. Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Níhìn-ín, Pọ́ọ̀lù fi “wàrà,” tó ṣàpèjúwe nínú ẹsẹ tó ṣáájú gẹ́gẹ́ bí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run,” wé “oúnjẹ líle,” tí ó wà fún “àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú,” àwọn tí wọ́n ti “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:12-14.
15. Èé ṣe táa fi ní láti ṣe iṣẹ́ àṣekára láti jèrè ìmọ̀ pípéye ti Ọlọ́run?
15 Èyí túmọ̀ sí pé, lákọ̀ọ́kọ́ pàá, a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣekára láti jèrè ìmọ̀ tó péye nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kò dìgbà táa bá rí àkọsílẹ̀ tó pọ̀ lọ jàra, tó ń sọ pé ṣèyí má ṣèyẹn, ká tó mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe àti ohun tí kò yẹ ní ṣíṣe. Bíbélì kì í ṣe irú ìwé bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Táa bá fẹ́ jàǹfààní nínú kíkọ́ni, fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, àti bíbániwí yẹn, a gbọ́dọ̀ máa lo èrò inú àti agbára ìmòye wa. Èyí gba ìsapá, àmọ́ àǹfààní tó ń tìdí rẹ̀ yọ kò kéré rárá—èyíinì ni dídi ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—Òwe 2:3-6.
16. Kí ló túmọ̀ sí láti kọ́ agbára ìwòye ẹni lẹ́kọ̀ọ́?
16 Lẹ́yìn ìyẹn, bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, àwọn èèyàn tó dàgbà dénú ti “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” Ibí yìí la ti wá dórí kókó tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọ̀ràn náà. Ní ṣáńgílítí, gbólóhùn náà “kọ́ agbára ìwòye wọn” túmọ̀ sí “dídá àwọn ẹ̀yà ara táa fi ń mòye lẹ́kọ̀ọ́ (bíi ti eléré ìdárayá).” (Kingdom Interlinear Translation) Eléré ìdárayá kan tó ti mọ ohun èlò kan í lò dáadáa, bíi fífi okùn fò tàbí fífi igi tilẹ̀ kó si fò lọ sókè fíofío, lè di ẹni tó ń fi nǹkan èlò náà dárà tó máa dà bíi pé ó ń ṣe àwọn nǹkan tó tako òfin òòfà ilẹ̀ tàbí àwọn òfin adánidá mìíràn láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan. Ó lè ṣàkóso ẹ̀yà ara rẹ̀ bó ṣe wù ú ní gbogbo ìgbà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ kó gbé ló ń kíyè sí fínnífínní, kó lè parí eré ìdárayá lọ́nà tó gún régé. Gbogbo èyí jẹ́ àbájáde ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó lágbára àti ìdánrawò ìgbà gbogbo.
17. Ọ̀nà wo la lè gbà rí bí eléré ìdárayá?
17 Àwa náà gbọ́dọ̀ dà bí eléré ìdárayá táa dá lẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí, táa bá fẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ìpinnu wa àtàwọn yíyàn táa ń ṣe ń bọ́gbọ́n mu ní gbogbo ìgbà. A gbọ́dọ̀ máa ṣàkóso agbára ìmòye àti ẹ̀yà ara wa látòkè délẹ̀. (Mátíù 5:29, 30; Kólósè 3:5-10) Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o máa ń ṣàkóso ojú rẹ láti má ṣe wo àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìwà pálapàla tàbí etí rẹ láti má ṣe gbọ́ àwọn orinkórin tàbí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀? Òótọ́ ni pé irú àwọn nǹkan-kí-nǹkan bẹ́ẹ̀ wà yí wa ká. Àmọ́, ọwọ́ wa náà ló ṣì wà láti yàn bóyá a fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ta gbòǹgbò nínú ọkàn àti èrò inú wa. A lè fara wé onísáàmù tó sọ pé: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi. Èmi kórìíra ìgbòkègbodò àwọn tí ó ti yapa; kì í dìrọ̀ mọ́ mi. . . . Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣèké, òun kì yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní iwájú mi.”—Sáàmù 101:3, 7.
Tipasẹ̀ Lílò Kọ́ Agbára Ìwòye Rẹ
18. Kí ni gbólóhùn náà “tipasẹ̀ lílò” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nínú àlàyé tó ṣe nípa kíkọ́ agbára ìwòye ẹni fi hàn?
18 Rántí pé ‘ipasẹ̀ lílò’ la lè gbà kọ́ agbára ìwòye wa láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Lọ́rọ̀ mìíràn, gbogbo ìgbà táa bá ní ìpinnu kan láti ṣe, a gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń lo agbára ìrònú wa láti mọ àwọn ìlànà Bíbélì tó wé mọ́ ohun táa fẹ́ ṣe àti bí a ṣe fi wọ́n sílò. Sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì, tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mátíù 24:45) Àmọ́, a tún lè wá ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú. Síbẹ̀síbẹ̀, ìsapá táa bá fúnra wa ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pẹ̀lú àdúrà táa bá gbà sí Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó sì fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, yóò jẹ́ èrè ńlá fún wa ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.—Éfésù 3:14-19.
19. Àwọn ìbùkún wo ló lè jẹ́ tiwa bí a bá ń dá agbára ìwòye wa lẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé?
19 Bí a ṣe ń kọ́ agbára ìwòye wa ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ète táa fi ń ṣe é ni “kí a má bàa tún jẹ́ ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” (Éfésù 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, táa bá gbé àwọn ìpinnu wa karí ìmọ̀ àti òye wa nípa ohun tó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, a lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, lórí ohun ńlá àti kékeré, àwọn ìpinnu tí yóò ṣe wá láǹfààní, tí yóò gbé àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ró, àti lékè gbogbo rẹ̀, tí yóò mú inú Baba wa ọ̀run dùn. (Òwe 27:11) Ẹ ò rí i pé ìbùkún àti ààbò ńlá lèyí jẹ́ láwọn àkókò líle koko wọ̀nyí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Dókítà Thomas Holmes àti Dókítà Richard Rahe ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó lé ní ogójì, tó ń fa pákáǹleke nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn, ikú ọkọ tàbí aya ẹni, ìkọ̀sílẹ̀, àti ìpínyà ni ohun mẹ́ta tí wọ́n fi ṣáájú. Ṣíṣègbéyàwó ló wà ní ipò keje.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Agbára wo lá nílò láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu?
• Èé ṣe tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti yíjú sí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tàbí láti gbẹ́kẹ̀ lé èrò ti ara wa nígbà táa bá ń pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká mọ àwọn ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run dájú nígbà tí a bá ń ṣe àwọn ìpinnu, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
• Kí ló túmọ̀ sí láti ‘kọ́ agbára ìwòye wa’?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Òtúbáńtẹ́ ni kéèyàn máa wá ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn olókìkí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bíi ti eléré ìdárayá kan, a gbọ́dọ̀ máa ṣàkóso gbogbo agbára ìmòye àti àwọn ẹ̀yà ara wa