Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Gba Ohun Tó Wù Ẹ́ Gbọ́

O Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Gba Ohun Tó Wù Ẹ́ Gbọ́

O Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Gba Ohun Tó Wù Ẹ́ Gbọ́

Inú ẹ á dùn pé o lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù ẹ́ gbọ́. Ṣàṣà lẹni tó máa fẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀tọ́ yẹn du òun. Nítorí ẹ̀tọ́ yìí, onírúurú nǹkan, tó jẹ́ ọ̀kan-kò-jọ̀kan, làwọn èèyàn tí ó tó bílíọ̀nù mẹ́fà tó ń gbé orí ilẹ̀ ayé lónìí gbà gbọ́. Gẹ́gẹ́ bí onírúurú àwọ̀, ìrísí, ẹ̀yà aṣọ, ìtọ́wò, òórùn, àti ìró tí ń bẹ nínú ìṣẹ̀dá, bẹ́ẹ̀ náà ni oríṣiríṣi èròǹgbà máa ń jẹ́ ká rí nǹkan tuntun gbọ́, kí orí wa wú, ká sì gbádùn ìgbésí ayé. Ká sòótọ́, irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí ń bẹ lóríṣiríṣi ń máyé dùn.—Sáàmù 104:24.

ÀMỌ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Yàtọ̀ sí pé àwọn ìgbàgbọ́ kan wà lóríṣiríṣi, wọ́n tún léwu. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, àwọn èèyàn kan gbà gbọ́ pé àwọn Júù àtàwọn Ẹgbẹ́ Ògbóni ń pètepèrò láti “da ètò àwọn Kristẹni rú, kí wọ́n sì dá orílẹ̀-èdè àgbáyé sílẹ̀, èyí tí wọ́n á jùmọ̀ máa ṣàkóso.” Ọ̀kan lára ibi tí èròǹgbà yìí ti jẹ yọ ni nínú ìwé ìléwọ́ táwọn aṣòdì-sí-Júù kọ, tí wọ́n pè ní Protocols of the Learned Elders of Zion. Ìwé ìléwọ́ náà sọ pé lára ìpètepèrò náà ni fífi owó orí àsan-àn-san-tán fá àwọn èèyàn lórí, ṣíṣe ohun ìjà tìrìgàngàn, dídá àwọn iléeṣẹ́ okòwò ńláńlá sílẹ̀, èyí tó máa mú káwọn iléeṣẹ́ yòókù kógbá sílé, kí ‘gbogbo ọrọ̀ Kèfèrí lè wọmi lọ́sàn-án kan òru kan.’ Ẹ̀sùn náà tún kan yíyí ètò ẹ̀kọ́ padà láti lè ‘sọ àwọn Kèfèrí di ẹranko aláìnírònú,’ àní ó tún kan ṣíṣe ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ tí yóò dé gbogbo olú ìlú, kí ọwọ́ àwọn àgbààgbà Júù lè ‘tẹ gbogbo àwọn alátakò, kí wọ́n sì rẹ́yìn wọn.’

Bẹ́ẹ̀, irọ́ ni gbogbo ẹ̀—wọ́n kàn fẹ́ káwọn èèyàn kórìíra àwọn Júù ni. Mark Jones, tó ń ṣiṣẹ́ ní British Museum sọ pé: ‘Ìtàn èké yìí tàn dé òkè òkun láti ilẹ̀ Rọ́ṣíà,’ níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ gbé e jáde nínú ìwé ìròyìn kan lọ́dún 1903. Ó jáde nínú ìwé ìròyìn The Times ti London ní May 8, 1920. Ní ohun tó lé lọ́dún kan lẹ́yìn náà, ìwé ìròyìn The Times kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ pé ayédèrú ni ìwé ìléwọ́ náà. Àmọ́, ẹ̀pa ò bóró mọ́. Jones sọ pé: ‘Irú irọ́ báwọ̀nyí a máa ṣòroó gbà lẹ́nu àwọn èèyàn.’ Gbàrà táwọn èèyàn bá ti gbà wọ́n sóòótọ́, wọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn ní àwọn ìgbàgbọ́ tó kún fún ẹ̀tanú, tó ń gbin ìkórìíra síni lọ́kàn, tó sì léwu—irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kì í sì í bímọ re, gẹ́gẹ́ bí ìtàn ọ̀rúndún ogún ti fi hàn.—Òwe 6:16-19.

Ìyàtọ̀ Wà Láàárín Ìgbàgbọ́ àti Òtítọ́

Àmọ́ ṣá o, èèyàn lè gba ohun tó lòdì gbọ́, kódà láìjẹ́ pé wọ́n purọ́ tan onítọ̀hún jẹ. Nígbà míì, ó lè jẹ́ nítorí àṣìlóye. Mélòó la fẹ́ kà lára àwọn tó ti rí ikú àìtọ́jọ́ he, bí wọ́n ti ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó tọ̀nà? Bákan náà, a máa ń gba nǹkan kan gbọ́ kìkì nítorí pé a fẹ́ gbà á gbọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ pàápàá “máa ń ka àbá tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ sí nǹkan bàbàrà.” Ohun tó wà lọ́kàn wọn máa ń jẹ́ kí èrò wọn pọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Fún ìdí yìí, wọ́n lè fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn máa ṣe wàhálà àṣedànù, láti lè rí nǹkan fi kín àwọn èròǹgbà tí kò tọ̀nà lẹ́yìn.—Jeremáyà 17:9.

Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn—níbi tí ìtakora ti pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. (1 Tímótì 4:1; 2 Tímótì 4:3, 4) Ẹnì kan lè sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ jíjinlẹ̀ nínú Ọlọ́run. Kí ẹlòmíràn sì sọ pé ìgbàgbọ́ ọ̀hún ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Onítibí lè sọ pé èèyàn ní àìleèkú ọkàn tí ń la ikú já. Kí onítọ̀hún gbà gbọ́ pé téèyàn bá kú, kò sí níbì kankan mọ́ rárá, ó ti ṣaláìsí nìyẹn. Dájúdájú, gbogbo ìgbàgbọ́ tó takora wọ̀nyí kò lè jẹ́ òótọ́. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu, nígbà náà, láti rí i dájú pé òótọ́ lohun tóo gbà gbọ́, pé kì í kàn-án ṣe ohun tó wù ẹ́ láti gbà gbọ́? (Òwe 1:5) Báwo lo ṣe lè ṣèyẹn? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò gbé kókó yìí yẹ̀ wò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àpilẹ̀kọ ọdún 1921 náà tó gbé ìtàn “Protocols of the Learned Elders of Zion” jáde