Ohun Tóo Gbà Gbọ́—Kí Nìdí Tóo Fi Gbà Á Gbọ́?
Ohun Tóo Gbà Gbọ́—Kí Nìdí Tóo Fi Gbà Á Gbọ́?
Láti gba nǹkan gbọ́ túmọ̀ sí láti gbà pé òótọ́, ojúlówó, tàbí òdodo, ni nǹkan ọ̀hún. Ìwé Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé, tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, kéde pé olúkúlùkù ló ní “ẹ̀tọ́ sí òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn, àti ẹ̀sìn.” Ẹ̀tọ́ yìí kan òmìnira “láti yí ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́ ẹni padà,” béèyàn bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
ÀMỌ́, kí ló lè sún èèyàn yí ẹ̀sìn tàbí ìgbàgbọ́ rẹ̀ padà? Ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ni pé, “Mo ní ìgbàgbọ́ tèmi, ó sì tẹ́ mi lọ́rùn.” Ọ̀pọ̀ gbà pé, kódà béèyàn bá ní ìgbàgbọ́ òdì pàápàá, ìwọ̀nba ni ìpalára tíyẹn lè ṣe fún un. Fún àpẹẹrẹ, ẹni tó gbà gbọ́ pé ńṣe ni ayé tẹ́ pẹrẹsẹ, kò lè fìyẹn pa ara rẹ̀ tàbí ẹlòmíràn lára. Àwọn kan a sọ pé, “Ká fi kálukú sílẹ̀ pẹ̀lú ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló tọ́.” Ǹjẹ́ èyí sábà máa ń mọ́gbọ́n dání? Ṣé dókítà kan á sọ pé ká sáà fi kálukú sílẹ̀ pẹ̀lú ohun tó gbà gbọ́, bí ọ̀kan lára àwọn dókítà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá ranrí pé kò sóhun tó burú nínú gbígbéra níbi tóun ti lọ fọwọ́ ba òkú nílé ìgbókùú-sí, kóun sì lọ tààrà sínú yàrá ilé ìwòsàn láti lọ tọ́jú àwọn aláìsàn?
Bó bá dọ̀ràn ẹ̀sìn, ìtàn fi yé wa pé àwọn ìgbàgbọ́ òdì ti dá rúgúdù ńlá sílẹ̀. Ronú nípa àwọn nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn “kó sí àwọn Kristẹni agbawèrèmẹ́sìn nínú, tí wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa hu ìwà ipá tó burú jáì,” nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn ń ja Ogun Mímọ́ ní sànmánì Ojú Dúdú. Tàbí kẹ̀, ronú nípa àwọn “Kristẹni” oníbọn lóde òní, tí wọ́n ń ja ogun abẹ́lé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tí wọn “kò yàtọ̀ rárá sí àwọn jagunjagun sànmánì ojú dúdú tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹni mímọ́ sára èèkù idà wọn, tí wọ́n lẹ àwọn àwòrán Màríà Wúńdíá mọ́ ìdí ìbọn wọn.” Gbogbo àwọn agbawèrèmẹ́sìn wọ̀nyí ló gbà gbọ́ pé ohun táwọn ń ṣe dáa. Ṣùgbọ́n, àwa náà mọ̀ pé gbogbo ogun wọ̀nyí àti rògbòdìyàn àti tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun yòókù tí ẹ̀sìn dá sílẹ̀ ló burú, tó tún bògìrì.
Èé ṣe tí ìdàrúdàpọ̀ àti ìforígbárí fi pọ̀ tó báyìí? Ìdáhùn Bíbélì ni pé Sátánì Èṣù “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9; 2 Kọ́ríńtì 4:4; 11:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé, ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbé ọ̀ràn ẹ̀sìn karí ni wọ́n “forí lé ìparun” nítorí pé Sátánì ti tàn wọ́n jẹ, nípa “ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àrà tó fi ń tanni jẹ.” Pọ́ọ̀lù sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò “tilẹ̀kùn èrò inú wọn sí ìfẹ́ òtítọ́ tí ì bá gbà wọ́n là,” wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni ‘táa ṣì lọ́nà láti máa gba irọ́ gbọ́.’ (2 Tẹsalóníkà 2:9-12, The New Testament, látọwọ́ William Barclay) Báwo lo ṣe lè yẹra fún gbígba irọ́ gbọ́? Àní sẹ́, ohun tóo gbà gbọ́, kí nìdí rẹ̀ gan-an tóo fi gbà á gbọ́?
Ṣé Ohun Tí Wọ́n Fi Kọ́ Ẹ Láti Kékeré Ni?
Bóyá ohun tí ìdílé rẹ gbà gbọ́ ni wọ́n fi tọ́ ẹ dàgbà. Ó lè máà sóhun tó burú nínú ìyẹn. Ọlọ́run fẹ́ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:4-9; 11:18-21) Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́kùnrin náà Tímótì, jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú fífetí sí ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà. (2 Tímótì 1:5; 3:14, 15) Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká máa fi ojú pàtàkì wo ohun táwọn òbí wa gbà gbọ́. (Òwe 1:8; Éfésù 6:1) Ṣùgbọ́n ṣé ohun tí Ẹlẹ́dàá rẹ fẹ́ fún ọ ni pé kóo kàn gba nǹkan kan gbọ́, kìkì nítorí pé àwọn òbí rẹ̀ gbà á gbọ́? Kéèyàn kàn wonkoko mọ́ ohun táwọn ìran àtẹ̀yìnwá gbà gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe láìronú lé e lórí, léwu o.—Sáàmù 78:8; Ámósì 2:4.
Ẹ̀sìn àwọn ará Samáríà lobìnrin ará Samáríà kan tó bá Jésù Kristi pàdé ti ń ṣe láti kékeré. (Jòhánù 4:20) Jésù gbà pé ó lómìnira láti gba ohun tó bá wù ú gbọ́, àmọ́ ó sọ fún un pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀.” Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ lára ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ gbà gbọ́ ni kò tọ̀nà, Jésù sì sọ fún un pé ó pọndandan pé kó yí ìgbàgbọ́ rẹ̀ padà bó bá fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà—“ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Dípò wíwonkoko mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ tó dájú pé ó ń gbé gẹ̀gẹ̀, yóò di dandan, nígbà tó bá yá, kí obìnrin yìí àtàwọn mìíràn bíi tirẹ̀, di “onígbọràn sí ìgbàgbọ́” táa ṣí payá nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Jòhánù 4:21-24, 39-41; Ìṣe 6:7.
Ṣé Ohun Táwọn Ògbógi Fi Kọ́ Ẹ Ni?
Ọ̀pọ̀ olùkọ́ àtàwọn ògbógi tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ kan yẹ lẹ́ni à ń bọ̀wọ̀ fún gidigidi. Ṣùgbọ́n ìtàn kún fún àpẹẹrẹ àwọn gbajúgbajà olùkọ́ tí wọ́n ṣìnà pátápátá. Fún àpẹẹrẹ, òpìtàn nì, Bertrand Russell sọ nípa ìwé méjì tí ọ̀mọ̀ràn ará Gíríìkì náà, Aristotle kọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì pé “bóyá la fi lè rí odindi gbólóhùn kan nínú ìwé méjèèjì tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní mu.” Kódà àwọn ògbógi òde òní sábà máa ń gbé e gbági pátápátá. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Alàgbà Kelvin, là á mọ́lẹ̀ lọ́dún 1895 pé: “Àwọn ẹ̀rọ tó wúwo ju afẹ́fẹ́ lọ, táá sì máa fò, kò tiẹ̀ ṣeé ṣe ni.” Nítorí náà, ẹni tó bá gbọ́n, kò kàn ní gbà gbọ́ pé òótọ́ ni nǹkan kan, kìkì nítorí pé olùkọ́ kan tó jẹ́ ògbógi ti sọ pé òótọ́ ni.—Sáàmù 146:3.
A ń béèrè irú ìṣọ́ra kan náà nínú ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn fi ń kọ́ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pegedé nínú ẹ̀kọ́ tí àwọn olùkọ́ni ní ọ̀ràn ẹ̀sìn fi kọ́ ọ, ó sì “jẹ́ onítara púpọ̀púpọ̀ jù fún àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn bàbá” rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìtara tó ní fún àwọn ìgbàgbọ́ àbáláyé tó gbà lọ́wọ́ àwọn baba ńlá rẹ̀, kó o sí wàhálà. Ó jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí “ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run, tí [ó] sì ń pa á run.” (Gálátíà 1:13, 14; Jòhánù 16:2, 3) Kò fi mọ síbẹ̀ o, fún àkókò pípẹ́ ni Pọ́ọ̀lù tún ń bá a nìṣó “ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́,” ìyẹn ni pé ó ń tako ohun tí ì bá jẹ́ kó gba Jésù Kristi gbọ́. Ìgbà tí Jésù alára dìídì dá sọ́ràn náà ni Pọ́ọ̀lù tó yí ìgbàgbọ́ rẹ̀ padà.—Ìṣe 9:1-6; 26:14.
Ṣé Àwọn Iléeṣẹ́ Ìròyìn Ló Ń Nípa Lórí Rẹ Ni?
Ó lè jẹ́ pé àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ti nípa lórí ìgbàgbọ́ rẹ gan-an. Inú ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dùn pé àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, èyí tó ń jẹ́ kí ìsọfúnni tó wúlò wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n, àwọn agbára kan wà tó lè darí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn, tó sì ń darí wọn. Wọ́n máa ń gbé ìsọfúnni tó pọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tó sì lè jin ìrònú rẹ lẹ́sẹ̀ jáde.
Aísáyà 5:20; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Láfikún sí i, kí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn lè fa ojú ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́ra, àwọn ìròyìn tó lè tètè ru ìmọ̀lára sókè, àtàwọn ìròyìn kàyéfì ni wọ́n sábà máa ń gbé jáde. Ohun tí kò ṣeé sọ jáde tàbí tí kò ṣeé tẹ̀ jáde fún mùtúmùwà ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni wọ́n wá ń gbé jáde fún tajátẹran báyìí. Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ bí ìgbà tí ikán ń jẹlé ni ìwà ọmọlúwàbí rọra ń yìnrìn. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìrònú àwọn èèyàn ń dìdàkudà. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́ pé “ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.”—Gbígbé Ìgbàgbọ́ Rẹ Ka Ìpìlẹ̀ Tó Dúró Sán-ún
Ẹni tó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ka àwọn èròǹgbà àti ọgbọ́n orí èèyàn kò yàtọ̀ sẹ́ni tó kọ́lé rẹ̀ sórí iyanrìn. (Mátíù 7:26; 1 Kọ́ríńtì 1:19, 20) Kí lo wá lè gbé ìgbàgbọ́ rẹ kà, tí ọkàn rẹ sì máa balẹ̀? Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fún ọ ní làákàyè láti fi yẹ àwọn ohun tó yí ọ ká wò, kí o sì béèrè ìbéèrè nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí, ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú, pé Ọlọ́run yóò pèsè ọ̀nà tóo fi lè rí ìdáhùn tó gún régé sáwọn ìbéèrè rẹ? (1 Jòhánù 5:20) Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé Ọlọ́run yóò pèsè ọ̀nà yẹn! Àmọ́, báwo lo ṣe lè mọ ẹ̀sìn tòótọ́, tó jẹ́ ojúlówó, tàbí tó jẹ́ òdodo? Pẹ̀lú ìdánilójú la fi sọ pé Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nìkan ló lè tọ́ wa sọ́nà láti mọ̀ ọ́n.—Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17.
Ẹnì kan lè wá sọ pé: “Àmọ́ dúró ná, ṣé kì í ṣe àwọn tó ní Bíbélì ọ̀hún lọ́wọ́ ló dá gbogbo ìforígbárí àti ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láyé yìí ni?” Tóò, òótọ́ ni pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé Bíbélì ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ tó kún fún ìdàrúdàpọ̀, tó sì takora jáde. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé wọn kò gbé ìgbàgbọ́ wọn karí Bíbélì. Àpọ́sítélì Pétérù pè wọ́n ní “wòlíì èké” àti “olùkọ́ èké” tí yóò dá “àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run” sílẹ̀. Pétérù sọ pé nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn, “ọ̀nà òtítọ́ yóò . . . di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” (2 Pétérù 2:1, 2) Pétérù tún kọ̀wé pé, “a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a túbọ̀ mú dáni lójú; ẹ sì ń ṣe dáadáa ní fífún un ní àfiyèsí gẹ́gẹ́ bí fún fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn.”—2 Pétérù 1:19; Sáàmù 119:105.
Bíbélì rọ̀ wá pé ká gbé ìgbàgbọ́ wa karí ohun tí òun ń fi kọ́ni. (1 Jòhánù 4:1) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn yìí lè jẹ́rìí sí i pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn lójú, kí ó sì tòrò. Nítorí náà, fìwà jọ àwọn ọlọ́kàn rere ará Bèróà. ‘Máa fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́’ kóo tó pinnu ohun tóo máa gbà gbọ́. (Ìṣe 17:11) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Bó ti wù kó rí, ìwọ lo máa pinnu ohun tóo fẹ́ gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni láti rí i dájú pé kì í ṣe ọgbọ́n àti ìfẹ́ ènìyàn ló pinnu àwọn ohun tóo gbà gbọ́, bí kò ṣe Ọ̀rọ̀ òtítọ́ tí Ọlọ́run ṣí payá.—1 Tẹsalóníkà 2:13; 5:21.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
O lè gbé àwọn ohun tóo gbà gbọ́ karí Bíbélì láìfòyà