Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́

Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́

Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́

“[Ábúráhámù ni] baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”—RÓÒMÙ 4:11.

1, 2. (a) Kí làwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní máa ń rántí nípa Ábúráhámù? (b) Èé ṣe táa fi pe Ábúráhámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́”?

 ÒUN ni baba orílẹ̀-èdè ńlá kan, wòlíì ni, oníṣòwò ni, aṣáájú sì tún ni. Síbẹ̀, ohun àkọ́kọ́ pàá táwọn Kristẹni ń rántí nípa rẹ̀ lónìí ni ànímọ́ tó mú kí Jèhófà Ọlọ́run pè é ní ọ̀rẹ́ òun—èyíinì ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23) Ábúráhámù là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì sì pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 4:11.

2 Ṣé àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì, Énọ́kù, àti Nóà tó wà ṣáájú Ábúráhámù kò ní ìgbàgbọ́ ni? Wọ́n ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n Ábúráhámù la bá dá májẹ̀mú náà pé a ó tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ìyẹn ló sọ ọ́ di baba ìṣàpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn tó bá gba Irú Ọmọ táa ṣèlérí náà gbọ́. (Gálátíà 3:8, 9) Títí dé àyè kan, a lè pe Ábúráhámù ní bàbá wa, nítorí pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ yẹ ní fífarawé. A lè ka ìgbé ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀ sí ìfihàn ìgbàgbọ́, torí ó kún fún àdánwò lọ́tùn-ún lósì. Àní, tipẹ́tipẹ́ kí Ábúráhámù tó dojú kọ èyí táa lè sọ pé ó le jù nínú gbogbo ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ̀—ìyẹn, ìgbà táa pàṣẹ pé kó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ—ni Ábúráhámù ti fi hàn pé òun nígbàgbọ́, nígbà tó ń dojú kọ àwọn àdánwò tí kò lágbára tóyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1, 2) Ẹ wá jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò mélòó kan lára àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ tó kọ́kọ́ dé bá a, ká sì wo ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú wọn lóde òní.

A Pàṣẹ fún Un Pé Kó Fi Úrì Sílẹ̀

3. Kí ni Bíbélì sọ fún wa nípa ibi tí Ábúrámù ti wá?

3 Ìgbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ Ábúrámù (táa wá mọ̀ sí Ábúráhámù lẹ́yìn náà) ni ìgbà tó sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 11:26 pé: “Térà sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún àádọ́rin ọdún, lẹ́yìn èyí tí ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.” Ábúrámù jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ṣémù olùbẹ̀rù Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 11:10-24) Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 11:31 ti wí, Ábúrámù àti ìdílé rẹ̀ ń gbé ní “Úrì ti àwọn ará Kálídíà,” ìlú aásìkí tó fìgbà kan wà ní ìlà oòrùn Odò Yúfírétì. a Fún ìdí yìí, kì í ṣe láti àárọ̀ ọjọ́ ni Ábúrámù ti di alárìnkiri tí ń gbé inú àgọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, inú ìlú ńlá tó ní àwọn ohun amáyédẹrùn ló kọ́kọ́ ń gbé. A lè rí àwọn nǹkan tí wọ́n kó wá láti ilẹ̀ òkèèrè rà ní àwọn ọjà kó-lọ-ńlẹ̀-kó-dowó tó wà ní Úrì. Téèyàn bá ń gba ojú títì kọjá, yóò rí àwọn ilé ńláńlá táa kùn lẹ́fun, tí wọ́n ní nǹkan bíi yàrá mẹ́rìnlá nínú, tí wọ́n tún ní ètò àwọn páìpù tí ń gbé omi kiri inú ilé.

4. (a) Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ àwọn tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́ ní Úrì? (b) Báwo ni Ábúrámù ṣe di ẹni tó gba Jèhófà gbọ́?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ọlọ́rọ̀ ni Úrì jẹ́, ó nira gan-an láti sin Ọlọ́run tòótọ́ níbẹ̀. Ìbọ̀rìṣà àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán pọ̀ nílùú yẹn. Àní, tẹ́ńpìlì gàgàrà aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tí wọ́n kọ́ fún Nanna, ìyẹn òrìṣà òṣùpá, ni ilé tó ga jù ní gbogbo ìlú yẹn. Láìsí àní-àní, kò sí bí àwọn èèyàn náà, títí kan àwọn kan lára àwọn ẹbí Ábúrámù pàápàá, kò ṣe ní fúngun mọ́ ọn, pé kó báwọn lọ́wọ́ sí ẹ̀sìnkẹ́sìn yìí. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu Júù kan tiẹ̀ sọ pé Térà, bàbá Ábúrámù alára ń ṣe àwọn òrìṣà. (Jóṣúà 24:2, 14, 15) Bó ti wù kó rí, Ábúrámù kì í ṣe abọgibọ̀pẹ̀. Ṣémù, baba ńlá rẹ̀ ọlọ́jọ́lórí ṣì wà láàyè, ẹ̀rí sì wà pé ó fi ohun tó mọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kọ́ wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Jèhófà ni Ábúrámù gbà gbọ́, kì í ṣe Nanna!—Gálátíà 3:6.

Ìdánwò Ìgbàgbọ́

5. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún Ábúrámù, ìlérí wo ló sì ṣe fún un nígbà tó ṣì wà ní Úrì?

5 A óò dán ìgbàgbọ́ Ábúrámù wò. Ọlọ́run yọ sí i, ó sì pàṣẹ fún un pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́; èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá; kí ìwọ fúnra rẹ sì jẹ́ ìbùkún. Èmi yóò sì súre fún àwọn tí ń súre fún ọ, ẹni tí ó sì ń pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí rẹ ni èmi yóò fi gégùn-ún, gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ yóò sì bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ rẹ.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; Ìṣe 7:2, 3.

6. Èé ṣe tí kíkúrò tí Ábúrámù kúrò ní Úrì fi gba ìgbàgbọ́ gidi?

6 Ábúrámù ti darúgbó, kò sì bímọ. Báwo ló ṣe lè di “orílẹ̀-èdè ńlá”? Ibo gan-an tiẹ̀ ni ilẹ̀ tí wọ́n ní kó kọrí sí yìí wà? Ọlọ́run kò sọ fún un nígbà yẹn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó gba ìgbàgbọ́ gidi, kí Ábúrámù tó lè kúrò ní Úrì, ìlú aásìkí, ìlú tí fàájì ti ń ṣàn. Ìwé náà, Family, Love and the Bible sọ nípa ayé ọjọ́un pé: “Ìyà tó burú jù lọ táa lè fi jẹ ẹnì kan tó dá ọ̀ràn tó burú jáì nínú ẹbí ni láti lé e dà nù, kí wọ́n fi àǹfààní jíjẹ́ ‘mẹ́ńbà’ ẹbí dù ú. . . . Ìdí nìyẹn tí ṣíṣe tí Ábúráhámù ṣègbọràn tọkàntọkàn sí Ọlọ́run, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e, nígbà tó jẹ́ ìpè Ọlọ́run, tó fi orílẹ̀-èdè rẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ pàápàá sílẹ̀, fi jẹ́ ohun mériyìírí.”

7. Báwo làwa Kristẹni òde òní ṣe lè dojú kọ irú àwọn ìdánwò tí Ábúrámù dojú kọ?

7 Àwa Kristẹni òde òní lè dojú kọ irú àdánwò bẹ́ẹ̀. Bíi ti Ábúrámù, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wá bíi pé ká fi ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ṣáájú ire Ìjọba Ọlọ́run. (1 Jòhánù 2:16) A lè dojú kọ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa tí kì í ṣe onígbàgbọ́, títí kan àwọn ẹbí táa ti yọ lẹ́gbẹ́, tí wọ́n ń fẹ́ ká máa báwọn kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. (Mátíù 10:34-36; 1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 15:33) Ábúrámù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nínú ọ̀ràn yìí. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lójú rẹ̀ ni jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà—àní ó ṣe pàtàkì ju àjọṣe òun pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀. Kò mọ ọ̀nà náà gan-an, tàbí ìgbà náà, tàbí ibi tí àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ti ní ìmúṣẹ. Síbẹ̀, ó fi ìgbésí ayé rẹ̀ jin àwọn ìlérí wọ̀nyẹn. Ẹ wo ìṣírí ńlá tí èyí jẹ́ fún wa láti máa fi Ìjọba náà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa!—Mátíù 6:33.

8. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ Ábúrámù ní lórí àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé tirẹ̀ gan-an, ẹ̀kọ́ wo sì ni àwa Kristẹni lè rí kọ́ nínú èyí?

8 Àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Ábúrámù gan-an ńkọ́? Ó jọ pé ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú Ábúrámù ní ipa tí kò kéré lórí wọn, nítorí pé Sáráì aya rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀ tó ti kú, múra tán láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, wọ́n sì fi Úrì sílẹ̀. Nígbà tó ṣe, Náhórì arákùnrin Ábúrámù àti díẹ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀ fi Úrì sílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Háránì, níbi tí wọ́n ti ń sin Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 24:1-4, 10, 31; 27:43; 29:4, 5) Kódà Térà, bàbá Ábúrámù pàápàá gbà láti bá ọmọ rẹ̀ jáde nílùú! Nítorí pé òun ni olórí ìdílé ni Bíbélì fi sọ pé òun ló ṣètò ṣíṣí lọ síhà Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31) Ǹjẹ́ àwa náà ò lè kẹ́sẹ járí táa bá fi ọgbọ́n jẹ́rìí fáwọn ẹbí wa?

9. Ìpalẹ̀mọ́ wo ló di dandan kí Ábúrámù ṣe fún ìrìn àjò rẹ̀, èé sì ti ṣe tíyẹn yóò fi wé mọ́ fífi nǹkan du ara rẹ̀?

9 Kí Ábúrámù tó mú ìrìn àjò rẹ̀ pọ̀n, iṣẹ́ ń bẹ lọ́rùn rẹ̀. Ó ní láti ta dúkìá rẹ̀ àtàwọn ẹrù rẹ̀, kí ó sì ra àgọ́, ràkúnmí, oúnjẹ, àtàwọn ohun kòṣeémánìí. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló lu ẹrù rẹ̀ tà nígbà tí gbogbo rẹ̀ ti bọ́ sí kánjúkánjú, ṣùgbọ́n tayọ̀tayọ̀ ló fi ṣègbọràn sí Jèhófà. Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà, lẹ́yìn tí Ábúrámù ti palẹ̀ mọ́ tán, tóun àtàwọn èèyàn ẹ̀ dúró sẹ́yìn odi Úrì, tí wọ́n fẹ́ mú ìrìn àjò wọn pọ̀n! Àwọn arìnrìn-àjò náà ń tọ ipadò Yúfírétì lọ, bí wọ́n ti ń rìn lọ síhà àríwá ìwọ̀ oòrùn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀, tí wọ́n ti rin nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kìlómítà, wọ́n dé ìlú ńlá kan ní àríwá Mesopotámíà tí wọ́n ń pè ní Háránì, níbi táwọn arìnrìn-àjò ti sábà máa ń tẹsẹ̀ dúró díẹ̀.

10, 11. (a) Kí ló jọ pé ó fà á tí Ábúrámù fi dúró ní Háránì fúngbà díẹ̀? (b) Ìṣírí wo la lè fún àwọn Kristẹni tó bá ń tọ́jú àwọn òbí tó ti darúgbó?

10 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí Térà, bàbá rẹ̀ tó ti darúgbó, ni Ábúrámù ṣe fìdí kalẹ̀ sí Háránì. (Léfítíkù 19:32) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹrù iṣẹ́ títọ́jú àwọn òbí tó ti darúgbó tàbí tó ti di olókùnrùn ń bẹ lọ́rùn ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí, àwọn kan tiẹ̀ ń yááfì àwọn nǹkan kan kí wọ́n lè ṣe èyí. Nígbà tíyẹn bá pọndandan, kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀ dájú pé làálàá wọn onífẹ̀ẹ́ “ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.”—1 Tímótì 5:4.

11 Ọjọ́ ò dúró dẹnì kan. “Àwọn ọjọ́ Térà sì wá jẹ́ igba ọdún ó lé márùn-ún. Lẹ́yìn náà, Térà kú ní Háránì.” Ó dájú pé ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ Ábúrámù yìí, ṣùgbọ́n gbàrà tí sáà ọ̀fọ̀ parí ló tún gbéra. “Ábúrámù sì jẹ́ ẹni àrùn-dín-lọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Háránì. Nítorí náà, Ábúrámù mú Sáráì aya rẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì ọmọkùnrin arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ẹrù tí wọ́n ti kó jọ rẹpẹtẹ àti àwọn ọkàn tí wọ́n ti ní ní Háránì, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti jáde lọ sí ilẹ̀ Kénáánì.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:32; 12:4, 5.

12. Kí ni Ábúrámù ṣe nígbà tó wà ní Háránì?

12 Ó gba àfiyèsí pé nígbà tí Ábúrámù wà ní Háránì, ó ‘kó ẹrù jọ rẹpẹtẹ.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ábúrámù fi du ara rẹ̀ kí ó lè fi Úrì sílẹ̀, síbẹ̀ ọlọ́rọ̀ ni nígbà tó kúrò ní Háránì. Ó dájú pé ìbùkún Ọlọ́run ni. (Oníwàásù 5:19) Òótọ́ ni pé Ọlọ́run kò ṣèlérí ọrọ̀ fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí, síbẹ̀ ó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun yóò pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fáwọn tó bá “fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin” nítorí Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 10:29, 30) Ábúrámù tún ‘kó ọkàn jọ rẹpẹtẹ,’ ìyẹn, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́. Ìtumọ̀ Májẹ̀mú Láéláé ti Jerúsálẹ́mù àti Ìtumọ̀ Alálàyé lédè Árámáíkì sọ pé Ábúrámù ‘yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà.’ (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ máa ń sún ẹ láti bá àwọn aládùúgbò, tàbí àwọn tẹ́ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, tàbí àwọn ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ rẹ sọ̀rọ̀? Dípò kí Ábúrámù fìdí kalẹ̀, kó sì fọwọ́ rọ́ àṣẹ Ọlọ́run sẹ́yìn, ó lo àkókò tó fi wà ní Háránì lọ́nà rere. Àmọ́ o, èyí tó ṣe níbẹ̀ ti tó. “Látàrí ìyẹn, Ábúrámù lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:4.

Ó Sọdá Odò Yúfírétì

13. Ìgbà wo ni Ábúrámù sọdá Odò Yúfírétì, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì ìgbésẹ̀ yìí?

13 Ó tún di dandan kí Ábúrámù tẹsẹ̀ bọ ìrìn. Ó fi Háránì sílẹ̀, òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ sì forí lé ìwọ̀ oòrùn, wọ́n rin ìrìn nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] kìlómítà. Ó ṣeé ṣe kí Ábúrámù tẹsẹ̀ dúró díẹ̀ lẹ́bàá Yúfírétì, kó sì sọdá rẹ̀ ní Kákémíṣì tí í ṣe ibùdó ìṣòwò láyé ìgbàanì. Ibí yìí làwọn arìnrìn-àjò ti sábà máa ń sọdá rẹ̀. b Ọjọ́ wo gan-an ni Ábúrámù àtàwọn èèyàn ẹ̀ sọdá odò yìí? Bíbélì fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀ ní irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n [430] ṣáájú ìjádelọ àwọn Júù kúrò ní Íjíbítì ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ẹ́kísódù 12:41 sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní òpin irínwó ọdún ó lé ọgbọ̀n náà, àní ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yìí gan-an pé, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Nítorí náà, ó jọ pé nígbà tí Ábúrámù ṣègbọràn, tó sọdá Yúfírétì ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, lọ́dún 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa, ni májẹ̀mú táa bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

14. (a) Kí ni Ábúrámù lè fi ojú ìgbàgbọ́ rí? (b) Lọ́nà wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí ṣe láǹfààní tó pọ̀ ju ti Ábúrámù lọ?

14 Ábúrámù ti fi ìlú aláásìkí sílẹ̀ sẹ́yìn. Àmọ́ lọ́wọ́ tó wà yìí, ó ń wo “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́,” èyíinì ni ìjọba òdodo tí yóò ṣàkóso lórí aráyé. (Hébérù 11:10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìsọfúnni tá-tà-tá ni Ábúrámù ní lọ́wọ́, ète Ọlọ́run láti ra aráyé ẹni kíkú padà ti bẹ̀rẹ̀ sí hàn sí i fírífírí. Lónìí, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé òye táa ní nípa àwọn ète Ọlọ́run jinlẹ̀ ju èyí tí Ábúrámù ní lọ fíìfíì. (Òwe 4:18) “Ìlú ńlá,” ìyẹn Ìjọba náà, tí Ábúrámù ń retí ti di òun báyìí—a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run láti ọdún 1914. Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ ká túbọ̀ fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé hàn nínú Jèhófà?

Ó Bẹ̀rẹ̀ sí Ṣe Àtìpó ní Ilẹ̀ Ìlérí

15, 16. (a) Èé ṣe tó fi béèrè ìgboyà pé kí Ábúrámù mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà? (b) Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe lè nígboyà bíi ti Ábúrámù?

15 Jẹ́nẹ́sísì 12:5, 6 sọ fún wa pé: “Níkẹyìn, wọ́n dé ilẹ̀ Kénáánì. Ábúrámù sì la ilẹ̀ náà kọjá lọ títí dé ibi tí Ṣékémù wà, nítòsí àwọn igi ńlá Mórè.” Ṣékémù jẹ́ àádọ́ta kìlómítà sí àríwá Jerúsálẹ́mù, ó sì wà ní àfonífojì ẹlẹ́tùlójú táa ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bíi “párádísè ilẹ̀ mímọ́.” Àmọ́ o, “ní àkókò yẹn, ọmọ Kénáánì . . . wà ní ilẹ̀ náà.” Níwọ̀n bí àwọn ọmọ Kénáánì ti jẹ́ oníṣekúṣe, Ábúrámù gbọ́dọ̀ sán okùn ṣòkòtò rẹ̀, kó tètè wá bó ṣe máa dáàbò bo ìdílé rẹ̀, kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn wọ́n.—Ẹ́kísódù 34:11-16.

16 Ní ìgbà kejì, “Jèhófà fara han Ábúrámù, ó sì wí pé: ‘Irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.’” Inú rẹ̀ yóò mà dùn o! Àmọ́, bí kì í bá ṣe pé Ábúrámù ní ìgbàgbọ́ ni, kò ní máa yọ̀ nínú ohun tí kìkì àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n, Ábúrámù fi ìdùnnú rẹ̀ hàn, “ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tí ó fara hàn án.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:7) Ọ̀mọ̀wé kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé: “Mímọ tó mọ pẹpẹ kan sí ilẹ̀ náà jẹ́ ọ̀nà láti fi hàn pé ilẹ̀ náà ti di tirẹ̀, nítorí ìgbàgbọ́ tó ní.” Mímọ irú pẹpẹ bẹ́ẹ̀ tún fi ìgboyà hàn. Ó dájú pé irú pẹpẹ yìí ni májẹ̀mú Òfin lànà pé kí wọ́n mọ lẹ́yìn náà, tó ní kí wọ́n fi àwọn òkúta tí a kò gbẹ́ mọ. (Ẹ́kísódù 20:24, 25) Ìrísí rẹ̀ yóò yàtọ̀ pátápátá sí pẹpẹ táwọn ọmọ Kénáánì ń lò. Ábúrámù tipa báyìí fi ara rẹ̀ hàn gbangba-gbàǹgbà pé Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ lòun ń sìn, ó sì mọ̀ pé èyí lè fa ìbínú àwọn èèyàn, kí wọ́n sì fẹ́ ṣe òun ní jàǹbá. Àwa náà ńkọ́ lónìí? Ǹjẹ́ àwọn kan nínú wa—àgàgà àwọn ọ̀dọ́—ha ń fojú pa mọ́, kí àwọn aládùúgbò tàbí ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ wa má bàa mọ̀ pé Jèhófà là ń sìn? Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ àìṣojo Ábúrámù fún gbogbo wa níṣìírí láti máa fi jíjẹ́ táa jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà yangàn!

17. Báwo ni Ábúrámù ṣe fi hàn pé òun ń wàásù orúkọ Ọlọ́run, kí sì ni èyí ń rán àwa Kristẹni létí lónìí?

17 Gbogbo ibi tí Ábúrámù lọ ló ti fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú ohun gbogbo. “Nígbà tí ó ṣe, ó ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá sí ìlà-oòrùn Bẹ́tẹ́lì, ó sì pa àgọ́ rẹ̀, tí Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀-oòrùn, tí Áì sì wà ní ìlà-oòrùn. Lẹ́yìn náà, ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:8) Gbólóhùn èdè Hébérù táa tú sí “pe orúkọ Jèhófà” tún túmọ̀ sí “polongo (wàásù) orúkọ náà.” Láìsí àní-àní, Ábúrámù fi àìṣojo polongo orúkọ Jèhófà láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí í ṣe aládùúgbò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 14:22-24) Èyí rán wa létí ojúṣe wa láti máa nípìn-ín kíkún nínú ṣíṣe “ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀” lónìí.—Hébérù 13:15; Róòmù 10:10.

18. Báwo ni àárín Ábúrámù àtàwọn ará Kénáánì ṣe rí?

18 Ábúrámù kò fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ láwọn ibi tó dé dúró wọ̀nyẹn. “Lẹ́yìn náà, Ábúrámù ṣí ibùdó, ó ń lọ láti ibùdó sí ibùdó síhà Négébù”—èyíinì ni àgbègbè tí òjò kì í ti í dunlẹ̀ tí ń bẹ ní gúúsù àwọn òkè ńlá Júdà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:9) Nípa ṣíṣí kiri àti jíjẹ́ káwọn èèyàn tó bá pàdé ní gbogbo ibi tó bá dé mọ̀ pé Jèhófà lòun ń sìn, Ábúrámù àti agboolé rẹ̀ “polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” (Hébérù 11:13) Gbogbo ìgbà ni wọ́n ń yẹra fún bíbá àwọn abọ̀rìṣà tó múlé gbè wọ́n ṣe wọlé wọ̀de. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni lónìí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Bí a tilẹ̀ ń ṣojú àánú sí àwọn aládùúgbò wa àtàwọn táa jọ ń ṣiṣẹ́, táa sì ń yẹ́ wọn sí, a máa ń yàgò fáwọn ìwà tó ń fi ẹ̀mí ayé tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run hàn.—Éfésù 2:2, 3.

19. (a) Kí nìdí tí ṣíṣí kiri kò fi lè rọ Ábúrámù àti Sáráì lọ́rùn? (b) Kí tún ni àwọn àdánwò tí ń bẹ níwájú fún Ábúrámù?

19 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé yóò nira gan-an kí kòókòó jàn-ánjàn-án ṣíṣí kiri tó lè mọ́ Ábúrámù àti Sáráì lára. Agbo ẹran wọn ni wọ́n ń jẹ, dípò jíjẹ oúnjẹ tí wọ́n lè rí rà ní àwọn ọjà Úrì tó jẹ́ pé kò sóhun téèyàn wá lọ síbẹ̀ tí kò ní rí; inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé, dípò ilé tí wọ́n kọ́ rèǹtè rente. (Hébérù 11:9) Ojoojúmọ́ ni Ábúrámù ń ṣiṣẹ́ kárakára; iṣẹ́ pọ̀ lọ́rùn rẹ̀, ó ń bójú tó agbo ẹran àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Kò sì sí àní-àní pé ọwọ́ Sáráì dí lẹ́nu iṣẹ́ táwọn obìnrin àdúgbò yẹn sábà máa ń ṣe, bíi: pípo ìyẹ̀fun, yíyan búrẹ́dì, rírànwú, ríránṣọ. (Jẹ́nẹ́sísì 18:6, 7; 2 Àwọn Ọba 23:7; Òwe 31:19; Ìsíkíẹ́lì 13:18) Àmọ́, àwọn àdánwò tuntun ṣì ń bẹ níwájú. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó máa fi ìwàláàyè Ábúrámù àti ti agboolé rẹ̀ sínú ewu máa tó ṣẹlẹ̀ o! Ṣé ìgbàgbọ́ Ábúrámù á gbé e báyìí?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún síhà ìlà oòrùn ni Odò Yúfírétì wà báyìí sí ibi tí ìlú Úrì wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé ìhà ìwọ̀ oòrùn ìlú yẹn ni odò náà wà láyé ọjọ́un. Ìyẹn ni wọ́n fi wá sọ lẹ́yìn náà pé Ábúrámù wá láti “ìhà kejì Odò [Yúfírétì].”—Jóṣúà 24:3.

b Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, ńṣe ni Aṣunásípálì Kejì, tí í ṣe ọba Ásíríà, to igi sójú Odò Yúfírétì nítòsí Kákémíṣì nígbà tó fẹ́ sọdá rẹ̀. Bíbélì ò sọ bóyá ọgbọ́n kan náà yìí ni Ábúrámù àtàwọn èèyàn rẹ̀ dá nígbà tí wọ́n fẹ́ sọdá odò náà, tàbí ṣe ni wọ́n kàn wọ́ odò náà kọjá.

Ǹjẹ́ O Ṣàkíyèsí?

• Èé ṣe táa fi pe Ábúrámù ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́”?

• Èé ṣe tó fi gba ìgbàgbọ́ pé kí Ábúrámù fi Úrì ti àwọn ará Kálídíà sílẹ̀?

• Báwo ni Ábúrámù ṣe fi hàn pé ìjọsìn Jèhófà ló wà ní góńgó ẹ̀mí òun?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌRÌN ÀJÒ ÁBÚRÁMÙ

Úrì

Háránì

Kákémíṣì

KÉNÁÁNÌ

Òkun Ńlá

[Credit Line]

A gbé e ka àwòrán kan tí Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel yọ̀ǹda fún wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ó gba ìgbàgbọ́ kí Ábúrámù tó lè fi gbogbo ohun amáyédẹrùn tí ń bẹ nílùú Úrì sílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Nípa gbígbé inú àgọ́, Ábúrámù àti agboolé rẹ̀ “polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀”