Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni àkókò tí Jóòbù fi jìyà ṣe gùn tó?

Àwọn èèyàn kan rò pé àdánwò Jóòbù ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n ìwé Jóòbù kò sọ pé ìjìyà ọlọ́jọ́ pípẹ́ ni.

Apá àkọ́kọ́ nínú àdánwò Jóòbù, ìyẹn ni pípàdánù àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ àti àwọn ohun ìní rẹ̀, dà bí èyí tó wáyé láàárín àkókò kúkúrú. A kà á pé: “Wàyí o, ó wá di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọkùnrin [Jóòbù] àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ń jẹun, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé arákùnrin wọn tí í ṣe àkọ́bí.” Bí Jóòbù ṣe ń gba ìròyìn kan ni òmíràn ń tẹ̀ lé e pé ó tí pàdánù—àwọn màlúù rẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn àgùntàn rẹ̀, àwọn ràkúnmí rẹ̀, àtàwọn ìránṣẹ́ tí ń bójú tó àwọn ẹran wọ̀nyẹn. Ó jọ pé, kété lẹ́yìn náà ni Jóòbù gbọ́ nípa ikú àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ tí wọ́n “ń jẹun, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ní ilé arákùnrin wọn tí í ṣe àkọ́bí.” Ó dà bíi pé ọjọ́ kan ṣoṣo ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀.—Jóòbù 1:13-19.

Apá kejì àdánwò Jóòbù ti ní láti gba àkókò tó gùn jùyẹn lọ. Sátánì tọ Jèhófà lọ, ó sì sọ pé Jóòbù yóò kùnà bí ìyà náà bá jẹ òun fúnra rẹ̀—ìyẹn bí ó bá kàn án lára. Ìgbà yẹn ló “fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí ó gba àkókò díẹ̀ kí àìsàn yìí tó tàn ká gbogbo ara rẹ̀. Ó sì tún ní láti gba àkókò díẹ̀ kí ìròyìn “gbogbo ìyọnu àjálù yìí” tó dé etígbọ̀ọ́ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olùtùnú rẹ̀, tí wọ́n gbéra láti wá bá a.—Jóòbù 2:3-11.

Téménì tó wà ní orílẹ̀-èdè Édómù ni Élífásì ti wá, Sófárì wá láti àgbègbè kan ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Arébíà, tó túmọ̀ sí pé ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn kò jìnnà sí ibi tí Jóòbù wà ní ilẹ̀ Úsì tí ó ṣeé ṣe kó wà ní àríwá Arébíà. Àmọ́, ọmọ Ṣúáhì ni Bílídádì, a sì gbọ́ pé ẹ̀bá odò Yúfírétì làwọn èèyàn rẹ̀ ń gbé. Tó ba jẹ́ pé ilé ni Bílídádì wà lákòókò yẹn, ó ti lè gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù pàápàá kó tó gbọ́ nípa ipò tí Jóòbù wà, kí ó sì tó rin ìrìn àjò wá sí ilẹ̀ Úsì. Àmọ́ o, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tòsí ibi ti Jóòbù ń gbé ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà nígbà tí ìyà Jóòbù bẹ̀rẹ̀. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà dé, wọ́n “jókòó sórí ilẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún ọ̀sán méje àti òru méje” láìfọhùn.—Jóòbù 2:12, 13.

Ìgbà yẹn ni apá tí ó kẹ́yìn nínú àdánwò Jóòbù ṣẹ̀ṣẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀, èyí tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé rẹ̀ kún ọ̀pọ̀ orí ìwé náà. Onírúurú ọ̀rọ̀ tí àwọn tó pe ara wọn ní olùtùnú sọ, àti èsì tí Jóòbù ń fún wọn ló wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tíyẹn parí ni ọ̀dọ́kùnrin náà Élíhù bá Jóòbù wí, tí Jèhófà sí tọ́ Jóòbù sọ́nà láti ọ̀run wá.—Jóòbù 32:1-6; 38:1; 40:1-6; 42:1.

Nítorí náà, ìjìyà Jóòbù àti bó ṣe dópin ti lè gba oṣù díẹ̀, ó ṣeé ṣe kó má tiẹ̀ tó ọdún kan. A mọ̀ pé nígbà táa bá ń fojú winá àwọn àdánwò líle koko, ó lè wá dà bíi pé a ò ní bọ́ nínú ẹ̀ láé. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé wọ́n máa ń dópin, bí ti Jóòbù ṣe dópin. Bó ti wù kí àdánwò táa dojú kọ pẹ́ tó, kí á má gbàgbé pé Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn, bó ṣe wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa mí sí pé: “Bí ìpọ́njú náà tilẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì fúyẹ́, fún àwa, ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú àti síwájú sí i, tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun.” (2 Kọ́ríńtì 4:17) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tí ó pè yín sí ògo àìnípẹ̀kun rẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”—1 Pétérù 5:10.