Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Tí Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Àwọn Ọ̀dọ́ Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí

Ìwé Tí Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Àwọn Ọ̀dọ́ Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí

Ìwé Tí Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Àwọn Ọ̀dọ́ Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí

“BÁWO ni mo ṣe fẹ́ mọ̀ bóyá Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́? Kì í ṣe ìwé tí mo nífẹ̀ẹ́ sí rárá,” ohun tí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Beate sọ nìyẹn.

Ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀dọ́ ló ní irú èrò kan náà nílẹ̀ Jámánì, tí Beate ń gbé; ìdí nìyẹn tí wọn kò fi ka Bíbélì kíkà sí pàtàkì. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe níbẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, nǹkan bí ìpín kan nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ ló ń ká Bíbélì déédéé, ìpín méjì ló ń kà á lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìpín mọ́kàndínlógún ló jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń kà á, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgọ́rin tí kò tiẹ̀ kà á rí. Ó ṣeé ṣe kí ìṣirò yìí rí bákan náà láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, bóyá títí kan ibi tí ìwọ alára ń gbé. Ní kedere, Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ kò nífẹ̀ẹ́ sí.

Abájọ, tí àwọn ọ̀dọ́ tí kò mọ ohunkóhun nínú Bíbélì fi pọ̀ lọ jàra. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, ìwé ìròyìn Lausitzer Rundschau gbé ìròyìn kan jáde lórí ìwádìí kan tó fi iye ènìyàn tó mọ̀ nípa Òfin Mẹ́wàá tí wọ́n sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí atọ́nà nínú ìgbésí ayé wọn hàn. Ní ti àwọn tó ti lé ní ẹni ọgọ́ta ọdún, ìpín mẹ́tàdínláàádọ́rin nínú wọn ló mọ àwọn òfin náà tó sì ń tọ́ wọn sọ́nà; ní ti àwọn tí kò tíì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, iye wọn kò ju ìpín méjìdínlọ́gbọ̀n lọ. Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ohun kan tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kò mọ̀ nípa rẹ̀ rárá.

Àwọn Kan Ní Èrò Tó Yàtọ̀

Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, káàkiri àgbáyé la ti rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ohun kan tó ṣeyebíye gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Alexander, ó sì máa ń ka Bíbélì láràárọ̀ kó tó lọ síbi iṣẹ́. Ó sọ pé: “Mi ò rò pé ọ̀nà mìíràn wà tó dára ju èyí lọ láti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.” Sandra ti sọ ọ́ di àṣà láti máa ka Bíbélì lálaalẹ́. Ó ṣàlàyé pé: “Ó ti di ara ìgbòkègbodò mi ojoojúmọ́.” Julia pẹ̀lú, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ti sọ ọ́ di àṣà láti máa ka ó kéré tán orí kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì kó tó sùn lálẹ́. Ó sọ pé: “Mo ń gbádùn rẹ̀ gan-an ni, á sì wù mí kí n máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”

Èrò wo ló tọ̀nà tó sì mọ́gbọ́n dání? Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ yẹ ní kíkà? Ṣé ìwé tó níye lórí, tó sì ṣe pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́ ni? Kí lèrò ẹ?