Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Ní Ṣíṣe Ohun Tó Dára

Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Ní Ṣíṣe Ohun Tó Dára

Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Ní Ṣíṣe Ohun Tó Dára

“Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—GÁLÁTÍÀ 6:9.

1, 2. (a) Èé ṣe táa fi nílò ìfaradà ká tó lè sin Ọlọ́run? (b) Báwo ni Ábúráhámù ṣe lo ìfaradà, kí sì ni ó ràn án lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

 GẸ́GẸ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tayọ̀tayọ̀ la fi ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. A tún ń rí ìtura nínú gbígbé “àjàgà” tó wé mọ́ jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 11:29) Ṣùgbọ́n, dídarapọ̀ mọ́ Kristi láti sin Jèhófà kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú èyí ṣe kedere nígbà tó rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.” (Hébérù 10:36) A nílò ìfaradà nítorí pé sísin Ọlọ́run kò gba ojú bọ̀rọ̀.

2 Ìgbé ayé Ábúráhámù fi èyí hàn kedere. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló dojú kọ òkè ìṣòro tó sún un kan ògiri, láìmọ èwo ni ṣíṣe. Àṣé gbogbo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni nígbà táa pàṣẹ fún un pé kó jáde kúrò ní ìlú Úrì tó ti ń gbé ìgbé ayé ìdẹ̀ra. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ìyàn dé, ìyẹn lọ tàìlọ làwọn ará àdúgbò tún gbógun tì í, ló tún di pé díẹ̀ ló kù kí wọ́n gba aya rẹ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́, àwọn ẹbí kan tún ń ṣe kèéta sí i, ẹ̀yìn ìyẹn ni hílàhílo ogun tún kó ìdààmú bá a. Síbẹ̀, àwọn àdánwò gbankọgbì ṣì ń bẹ níwájú o. Àmọ́, Ábúráhámù kò juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tó dára. Èyí sì jẹ́ ohun ìyanu, àgàgà táa bá rántí pé kò ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lódindi lọ́wọ́, báa ti ní in lónìí. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé ó mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́, tí Ọlọ́run sọ, pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipasẹ̀ Ábúráhámù ni Irú Ọmọ yẹn yóò gbà wá, láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, Sátánì yóò jẹ́ ọ̀tá gidi fún Ábúráhámù. Ó dájú pé lílóye tí Ábúráhámù lóye kókó yìí ló ràn án lọ́wọ́ láti fi tayọ̀tayọ̀ fara da àwọn àdánwò tó dé bá a.

3. (a) Èé ṣe tó fi yẹ káwọn èèyàn Jèhófà òde òní máa retí ìpọ́njú? (b) Ìṣírí wo ni Gálátíà 6:9 fún wa?

3 Àwa èèyàn Jèhófà lónìí pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa retí ìpọ́njú. (1 Pétérù 1:6, 7) Ó ṣe tán, Ìṣípayá 12:17 kìlọ̀ fún wa pé Sátánì ń bá ìyókù àwọn ẹni àmì òróró “ja ogun.” Bẹ́ẹ̀ ni “àwọn àgùntàn mìíràn” náà tún ń rí ìbínú Sátánì nítorí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ tí wọ́n ń ní pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró. (Jòhánù 10:16) Yàtọ̀ sí àtakò táwọn Kristẹni ń dojú kọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún gbogbo èèyàn, àwọn ìṣòro kan tún wà tí wọ́n ń rún mọ́ra lábẹ́lẹ̀. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:9) Àní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ti pinnu pé òun fẹ́ ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa, a gbọ́dọ̀ mú ìdúró wa lòdì sí i, ká dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. (1 Pétérù 5:8, 9) Kí ni ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ lè yọrí sí? Jákọ́bù 1:2, 3 ṣàlàyé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.”

Gbígbé Ìjà Kò Wá Ní Tààràtà

4. Báwo ni Sátánì ṣe ń gbéjà kò wá ní tààràtà láti fi ba ìwà títọ́ àwa èèyàn Ọlọ́run jẹ́?

4 Dájúdájú, ìgbésí ayé Ábúráhámù jẹ́ àpẹẹrẹ “onírúurú àdánwò” tí Kristẹni kan lè dojú kọ lónìí. Fún àpẹẹrẹ, ó di dandan kó wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn àwọn agbóguntini tó wá láti Ṣínárì. (Jẹ́nẹ́sísì 14:11-16) Kò yani lẹ́nu pé Sátánì ń gbéjà kò wá ní tààràtà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti fi ṣe inúnibíni sí wa. Látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ni ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Ìwé 2001 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ròyìn ìwà ìkà táwọn ọ̀tá hù sáwọn Kristẹni tó wà ní Àǹgólà. Àwọn ará wa tó wà nírú orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ti fi gbogbo rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, wọ́n sì dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀! Kàkà kí wọ́n máa wá ọ̀nà láti foró yaró tàbí kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fọgbọ́n bá iṣẹ́ ìwàásù wọn nìṣó.—Mátíù 24:14.

5. Báwo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ṣe ń fojú winá inúnibíni níléèwé?

5 Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni inúnibíni ń ní ìwà ìkà nínú. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a fi ọmọkùnrin méjì jíǹkí Ábúráhámù—ìyẹn Íṣímáẹ́lì àti Ísákì. Jẹ́nẹ́sísì 21:8-12 sọ fún wa pé ní àkókò kan Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì “dá àpárá.” Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Gálátíà, ó fi hàn pé èyí kọjá erémọdé lásán, nítorí ó sọ pé ńṣe ni Íṣímáẹ́lì ń ṣe inúnibíni sí Ísákì! (Gálátíà 4:29) Fún ìdí yìí, ó tọ́ láti pe yẹ̀yẹ́ táwọn ọmọléèwé ẹlẹgbẹ́ ẹni bá ń fini ṣe, tàbí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé táwọn alátakò bá ń sọ sí wa ní inúnibíni. Kristẹni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Ryan ròyìn bí àwọn ọmọ kíláàsì òun ṣe ń han òun léèmọ̀, ó ní: “Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún táa fi jọ ń wọ bọ́ọ̀sì lọ sí iléèwé ní àlọ-àtàbọ̀ á wá dà bí ọ̀pọ̀ wákàtí nígbà táwọn ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú wọ̀nyẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹnu lé mi lórí. Wọ́n á mú àwọn ẹ̀mú táa fi ń mú bébà, èyí tó ti gbóná yoyo, torí pé wọ́n ti tì í bọnú ihò tí wọ́n fi ń tanná ran sìgá, wọ́n á wá máa fi jó mi lára.” Èrèdí gbogbo ìwà ìkà yìí? “Kìkì nítorí pé ẹ̀kọ́ tí ètò Ọlọ́run kọ́ mi jẹ́ kí n yàtọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ yòókù níléèwé wa.” Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú ìtìlẹyìn àwọn òbí Ryan, ó fara dà á láìjuwọ́ sílẹ̀. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, yẹ̀yẹ́ táwọn ojúgbà yín ń fi yín ṣe ha ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá yín bí? Tóò, ẹ má juwọ́ sílẹ̀ o! Bí ẹ bá fara dà á láìjuwọ́ sílẹ̀, ọ̀rọ̀ Jésù yóò ṣẹ sí yín lára, pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.”—Mátíù 5:11.

Àníyàn Ojoojúmọ́

6. Kí làwọn nǹkan tó lè da àárín àwọn Kristẹni rú lóde òní?

6 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àdánwò táa ń rí lónìí wé mọ́ àníyàn ojoojúmọ́ tí kálukú wa ń bá yí. Ábúráhámù alára ní láti fara da wàhálà tó dìde láàárín àwọn darandaran tirẹ̀ àti ti Lọ́ọ̀tì ọmọ arákùnrin rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 13:5-7) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, èdèkòyédè àti owú jíjẹ lè da àárín àwọn ará rú, àní kí ó tilẹ̀ dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ. “Nítorí níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà.” (Jákọ́bù 3:16) Ẹ má ṣe jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀ o, ṣùgbọ́n bí Ábúráhámù ti ṣe, ẹ jẹ́ kí a máa wá àlàáfíà dípò gbígbéra ẹni ga, ká sì máa wá ire àwọn ẹlòmíràn!—1 Kọ́ríńtì 13:5; Jákọ́bù 3:17.

7. (a) Kí ló yẹ ní ṣíṣe, bí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni bá ṣe ohun tó dunni? (b) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú rírí i pé àjọṣe àárín òun àtàwọn ẹlòmíì ò bà jẹ́?

7 Ó lè nira láti pa àlàáfíà mọ́ nígbà táa bá ronú pé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ti ṣe wá láìdáa. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Ọ̀rọ̀ àìnírònú lè múni lọ́kàn gbọgbẹ́, kódà bí onítọ̀hún tilẹ̀ sọ pé òun kàn fi ń ṣeré ni. Àròdùn náà tilẹ̀ lè wá légbá kan, báa bá ronú pé wọ́n ti fọ̀rọ̀ èké bà wá jẹ́ tàbí pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ wa láìdáa lẹ́yìn. (Sáàmù 6:6, 7) Àmọ́ Kristẹni kan kò lè sọ pé wọ́n ṣe nǹkan tó dun òun kó wá torí ìyẹn juwọ́ sílẹ̀ o! Bóo bá wà nínú irú ipò yẹn, gbé ìgbésẹ̀ láti mú nǹkan tọ́ nípa fífi ohùn pẹ̀lẹ́ bá ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ sọ̀rọ̀. (Mátíù 5:23, 24; Éfésù 4:26) Gbìyànjú láti dárí ji onítọ̀hún. (Kólósè 3:13) Báa bá bomi sùúrù mu, ọ̀ràn náà yóò tán lọ́kàn wa, àjọṣe àárín àwa àti arákùnrin wa ò sì ní bà jẹ́. Ábúráhámù kò takú pé ohun tí Lọ́ọ̀tì ṣe kò ní tán nínú òun láé. Ṣebí Ábúráhámù ló tún sáré lọ gba Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ sílẹ̀!—Jẹ́nẹ́sísì 14:12-16.

Àdánwò Àfọwọ́fà

8. (a) Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè ‘fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri’? (b) Èé ṣe tí Ábúráhámù fi ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa àwọn nǹkan tara?

8 Táa bá fẹ́ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, a óò gbà pé àwọn àdánwò kan wà tó jẹ́ àfọwọ́fà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè.” (Mátíù 6:19) Àmọ́, àwọn ará kan a máa “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri,” nígbà tí wọ́n bá fi ìlépa àwọn nǹkan tara ṣíwájú ire Ìjọba náà. (1 Tímótì 6:9, 10) Ábúráhámù ṣe tán láti fi àwọn nǹkan ìdẹ̀ra du ara rẹ̀ kí ó bàa lè rí ojú rere Ọlọ́run. “Nípa ìgbàgbọ́ ni ó ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí bí ní ilẹ̀ òkèèrè, ó sì gbé nínú àwọn àgọ́ pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí tí ó ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 11:9, 10) Ìgbàgbọ́ tí Ábúráhámù ní nínú “ìlú ńlá” náà, èyíinì ni ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ wá, ràn án lọ́wọ́ láti má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀. Ǹjẹ́ ohun kan náà kọ́ ló bọ́gbọ́n mu pé kí á ṣe?

9, 10. (a) Báwo ni ìfẹ́ láti yọrí ọlá ṣe lè jẹ́ àdánwò? (b) Báwo ni arákùnrin kan lónìí ṣe lè hùwà bí “ẹni tí ó kéré jù”?

9 Ẹ jẹ́ ká gbé apá mìíràn yẹ̀ wò. Bíbélì pèsè ìtọ́ni tó ṣe ṣàkó yìí: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” (Gálátíà 6:3) Síwájú sí i, a rọ̀ wá pé ká má ṣe “ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” (Fílípì 2:3) Àwọn kan ti kó ara wọn sínú àdánwò, nígbà tí wọ́n bá kọ̀ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí. Nígbà tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ láti yọrí ọlá ni wọ́n ń lé kiri, dípò kí ó jẹ́ ìfẹ́ láti ṣe “iṣẹ́ àtàtà,” ńṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì á wá dé bá wọn, tí wọ́n á sì máa kanrí mọ́nú kiri tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò nawọ́ àwọn àǹfààní kan sí wọn nínú ìjọ.—1 Tímótì 3:1.

10 Ábúráhámù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti pé kò “ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù 12:3) Nígbà tí Ábúráhámù bá Melikisédékì pàdé, kò sọ pé torí pé òun wà nípò ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run kó wá máa ṣe ìṣe àwa-la-wà-ńbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé Melikisédékì tí í ṣe àlùfáà lọ́lá ju òun lọ, ìyẹn ló jẹ́ kó san ìdámẹ́wàá fún un. (Hébérù 7:4-7) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó yẹ káwọn Kristẹni lónìí múra tán láti hùwà “bí ẹni tí ó kéré jù,” kí wọ́n má sì máa dupò ọlá. (Lúùkù 9:48) Bó bá dà bíi pé àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ kò nawọ́ àwọn àǹfààní kan sí ọ, lọ tún ara rẹ yẹ̀ wò dáadáa, kí o lè mọ ibi tí ọ̀ràn ara rẹ kù sí, kóo ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ní ṣíṣe nínú ìwà rẹ àti ọ̀nà tóo gbà ń ṣe nǹkan. Kàkà tí o ó fi máa fapá jánú nítorí pé o ò ní àwọn àǹfààní kan, kúkú máa lo àwọn àǹfààní tóo lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́—èyíinì ni àǹfààní ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà. Àní sẹ́, “ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.”—1 Pétérù 5:6.

Gbígba Ohun Tí A Kò Lè Rí Gbọ́

11, 12. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó sún àwọn kan nínú ìjọ láti dẹwọ́? (b) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa gbígbé ìgbésí ayé rẹ̀ ka ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run?

11 Àdánwò míì ni bí ó ti dà bíi pé òpin ètò búburú àwọn nǹkan yìí ti ń pẹ́ jù. Gẹ́gẹ́ bí 2 Pétérù 3:12 ti wí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa dúró “de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.” Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ló ti ń fi ọ̀pọ̀ ọdún, àní àwọn míì ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, retí pé kí “ọjọ́” yìí dé. Fún ìdí yìí, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn kan, wọ́n sì ti dẹwọ́.

12 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ jẹ́ ká tún gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. Ó gbé gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ka ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí bí ìmúṣẹ gbogbo ìlérí náà ṣe lè ṣojú rẹ̀. Òótọ́ ni pé ó gbó, ó tọ́, dépò pé Ísákì ọmọ rẹ̀ dàgbà di géńdé lójú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣì máa kọjá ká tó lè fi àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù wé “àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run” tàbí “àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Àmọ́ Ábúráhámù ò tìtorí ìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí fapá jánú tàbí kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa Ábúráhámù àtàwọn baba ńlá yòókù pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.”—Hébérù 11:13.

13. (a) Báwo làwọn Kristẹni òde òní ṣe dà bí “olùgbé fún ìgbà díẹ̀”? (b) Èé ṣe tí Jèhófà yóò mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan yìí?

13 Bí Ábúráhámù bá lè gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ka àwọn ìlérí tí ìmúṣẹ wọn ṣì wà “lókèèrè réré,” mélòómélòó ló yẹ kí àwa ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí, àwa táa ń gbé ní àkókò tí ìmúṣẹ nǹkan wọ̀nyí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán! Bíi ti Ábúráhámù, a gbọ́dọ̀ máa wo ara wa gẹ́gẹ́ bí “olùgbé fún ìgbà díẹ̀” nínú ètò Sátánì, àkókò kọ́ yìí láti máa gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì. A mọ̀ pé ohun tí ì bá wù wá ni pé kí “òpin ohun gbogbo” yìí ti dé kíákíá, kì í ṣe ká kàn máa sọ pé ó ti sún mọ́lé. (1 Pétérù 4:7) Ó lè jẹ́ nítorí pé àìsàn kò-gbóògùn ń bá wa jà. Ó sì lè jẹ́ pé ìṣòro ìṣúnná owó ń hàn wá léèmọ̀. Àmọ́ o, ẹ jẹ́ ká rántí pé ìdí tí Jèhófà yóò fi mú òpin wá kì í ṣe kìkì nítorí àtigbà wá lọ́wọ́ àwọn ipò tí kò bára dé, ṣùgbọ́n láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ pẹ̀lú. (Ìsíkíẹ́lì 36:23; Mátíù 6:9, 10) Ó lè máà jẹ́ àkókò táa fẹ́ kí òpin dé ni yóò dé, àmọ́ yóò dé ní àkókò tó bá ète Jèhófà mu wẹ́kú.

14. Báwo ni sùúrù Ọlọ́run ṣe ṣàǹfààní fáwọn Kristẹni lóde òní?

14 Ká má sì gbàgbé o, pé “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Kíyè sí i pé Ọlọ́run “ń mú sùúrù fún yín”—ìyẹn àwa mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wa ṣì nílò àkókò púpọ̀ sí i láti ṣe àwọn ìyípadà àti àtúnṣe kan kí a lè bá wa “nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pétérù 3:14) Ǹjẹ́ kò wá yẹ ká máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run ń mú sùúrù fún wa?

Níní Ayọ̀ Láìfi Àwọn Ohun Ìdènà Pè

15. Báwo ni Jésù ò ṣe pàdánù ayọ̀ rẹ̀ lójú àdánwò, báwo sì ni fífara wé e ṣe lè ṣàǹfààní fún àwa Kristẹni òde òní?

15 Ìgbésí ayé Ábúráhámù kọ́ àwa Kristẹni òde òní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́. Kì í ṣe ìgbàgbọ́ nìkan ló ní, ó tún ní sùúrù, ọgbọ́n, ìgboyà, àti ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan. Ó fi ìjọsìn Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n o, á dáa ká rántí pé Jésù Kristi ló fi àpẹẹrẹ títayọ jù lọ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. Òun náà dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò àti ìpọ́njú, ṣùgbọ́n kò pàdánù ayọ̀ rẹ̀ nínú gbogbo ìṣòro wọ̀nyí. Èé ṣe? Nítorí pé ìrètí tí ń bẹ níwájú ló gbájú mọ́. (Hébérù 12:2, 3) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gbàdúrà pé: “Wàyí o, kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.” (Róòmù 15:5) Báa bá ní ẹ̀mí tó dáa, a lè ní ayọ̀ láìfi àwọn ohun ìdènà tí Sátánì ń gbé kò wá pè.

16. Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé iná ti jó dóríi kókó?

16 Nígbà tó bá dà bíi pé iná ti jó dóríi kókó, máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Ábúráhámù. Ó fẹ́ kí o ṣàṣeyọrí. (Fílípì 1:6) Gbé gbogbo ọkàn rẹ lé Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé ‘kì yóò jẹ́ kí a dẹ ọ́ wò ré kọjá ohun tí o lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí o lè fara dà á.’ (1 Kọ́ríńtì 10:13) Sọ kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ dàṣà. (Sáàmù 1:2) Má sinmi àdúrà gbígbà, máa bẹ Jèhófà kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara dà á. (Fílípì 4:6) Òun “yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Lo àwọn nǹkan tí Jèhófà ti pèsè láti mẹ́sẹ̀ rẹ dúró nípa tẹ̀mí, àwọn nǹkan bí ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì. Kò tán síbẹ̀ o, máa ní ìfararora pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará. (1 Pétérù 2:17) Máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, torí pé ibẹ̀ ni wàá ti rí ìṣírí tóo nílò, kí o bàa lè fara dà á. (Hébérù 10:24, 25) Máa yọ̀ nínú ìdánilójú náà pé ìfaradà rẹ yóò jẹ́ kóo wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run àti pé ìṣòtítọ́ rẹ ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀!—Òwe 27:11; Róòmù 5:3-5.

17. Èé ṣe táwọn Kristẹni kì í fi í sọ̀rètí nù?

17 Ọlọ́run fẹ́ràn Ábúráhámù nítorí “ọ̀rẹ́” rẹ̀ ni. (Jákọ́bù 2:23) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé Ábúráhámù kún fún hílàhílo àti ìpọ́njú. Nítorí náà, àwọn Kristẹni lè retí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ní “ọjọ́ ìkẹyìn” búburú wọ̀nyí. Bíbélì tilẹ̀ kìlọ̀ fún wa pé “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tímótì 3:1, 13) Dípò tí wàá fi sọ̀rètí nù, mọ̀ dájú pé àwọn pákáǹleke táa ń dojú kọ wọ̀nyí ló fi hàn pé òpin ètò búburú Sátánì ti dé tán. Àmọ́ Jésù rán wa létí pé “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Nítorí náà, ‘má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀!’ Máa fara wé Ábúráhámù, kí o sì wà lára “àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—Hébérù 6:12.

Ǹjẹ́ O Ṣàkíyèsí?

• Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn Jèhófà òde òní máa retí àdánwò àti ìpọ́njú?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà gbéjà kò wá ní tààràtà?

• Báwo la ṣe lè yanjú èdèkòyédè láàárín àwọn Kristẹni?

• Báwo ni ìgbéraga àti ìgbéra ẹni lárugẹ ṣe lè fa àdánwò?

• Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti dídúró de ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀dọ́ ló ń fojú winá inúnibíni, ní ti pé àwọn ojúgbà wọ́n ń fi wọ́n ṣẹ̀sín

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Nígbà ayé Ábúráhámù, ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣì ń bẹ “lókèèrè réré,” síbẹ̀ ó gbé gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ lé wọn