Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jíjàre ní Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

Jíjàre ní Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

Jíjàre ní Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn

WỌ́N dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Jámánì láre lọ́nà tó kàmàmà ní Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, nílùú Karlsruhe. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì láti jẹ́ káwọn èèyàn rí wọn gẹ́gẹ́ bí àjọ kan tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin.

Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù nílẹ̀ Jámánì. Wọ́n ti kojú inúnibíni líle koko lábẹ́ àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ méjì tó ṣèjọba ní ọ̀rúndún ogún—ìyẹn ni ìjọba Násì àti ti Kọ́múníìsì. Láti ọdún 1990 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wá ọ̀nà láti jẹ́ káwọn èèyàn rí wọn gẹ́gẹ́ bí àjọ kan tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ méjì ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre, tí òmíràn sì wá dá wọn lẹ́bi, wọ́n wá pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, tó kéde ìdájọ́ rẹ̀ ní December 19, 2000.

Ẹnu Àwọn Adájọ́ Ṣọ̀kan Nínú Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn adájọ́ méjèèje tó wà ní kóòtù náà ló dá àwọn Ẹlẹ́rìí láre. Àwọn adájọ́ náà fagi lé ìdájọ́ kan tí Kóòtù Tí Ń Mú Òfin Ìjọba Àpapọ̀ Ṣẹ ṣe ní 1997, wọ́n sì pàṣẹ pé kí ilé ẹjọ́ náà tún ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí gbé yẹ̀ wò.

Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn wá fi àkókò yẹn sọ̀rọ̀ lórí àjọṣe tó wà láàárín Orílẹ̀-Èdè àti àwọn ẹlẹ́sìn. Ní ti gidi, ohun tí a fi ń mọ bí ẹ̀sìn kan ṣe jẹ́ “kì í ṣe ìgbàgbọ́ rẹ̀, bí kò ṣe ìhùwàsí rẹ̀.”

Kóòtù náà tún ṣàlàyé pé, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá sọ pé “gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àwọn kì í dá sí tọ̀túntòsì,” wọn “ò tako ìlànà ìjọba tiwa-n-tiwa,” wọn ò sì “gbìyànjú láti fi oríṣi ìjọba mìíràn rọ́pò ìjọba tiwa-n-tiwa.” Nítorí náà, kò yẹ kí wọ́n torí àìdásí ọ̀ràn ìṣèlú kọ̀ láti fìdí ètò àwọn Ẹlẹ́rìí múlẹ̀ lábẹ́ òfin.—Jòhánù 18:36; Róòmù 13:1.

Kóòtù náà tún sọ pé onígbàgbọ́ kan—yálà ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tàbí ẹlẹ́sìn mìíràn—lè bá ara rẹ̀ nínú ipò tí ohun tí Orílẹ̀-Èdè ń béèrè àti ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ ń béèrè ti tako ara wọn. Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ní kó ṣe nípa “ṣíṣègbọràn sí ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ sọ dípò ohun tí òfin wí,” Orílẹ̀-Èdè lè ka èyí sí ohun tí ó tọ̀nà, tí ó sì wà lára òmìnira ìsìn.—Ìṣe 5:29.

Ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ló fi ohun tí kóòtù náà sọ ṣe àkọlé ìròyìn. Bóyá la fi rí ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Jámánì tí kò sọ̀rọ̀ nípa àbájáde ẹjọ́ náà. Gbogbo ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n pàtàkì àti àwọn ilé iṣẹ́ rédíò ló gbé àwọn ìròyìn tàbí àwọn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò nípa rẹ̀ jáde. Kò tíì sígbà tí wọ́n polongo orúkọ Jèhófà tó báyẹn rí nílẹ̀ Jámánì.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Fọ́tò AP/Daniel Maurer