Títàn Bí Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ìlú Ìmọ́lẹ̀
Títàn Bí Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ìlú Ìmọ́lẹ̀
Oríkì ìlú ńlá Paris ni Fluctuat nec mergitur, tàbí “Ìgbì ń bì lù ú ṣùgbọ́n kò rì.”
NÍ OHUN tí ó ju ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn ni àìmọye àwọn àtọ̀húnrìnwá ti ń bì lu ìlú Paris, bí ẹ̀fúùfù ṣe ń bì lu ọkọ̀ okùn, tí egbìnrìn ọ̀tẹ̀ sì ń rú lọ́tùn-ún lósì láàárín ìlú ńlá náà, àmọ́ tí ìjì ayé kò gbé ìlú yìí lọ. Paris ti wá di ọ̀kan lára ìlú ńlá tó rẹwà jù lọ lágbàáyé, àwọn èèyàn sì fẹ́ràn rẹ̀ gan-an báyìí nítorí àwọn ilé mèremère tó wà níbẹ̀, àwọn òpópónà táa gbin igi sẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àtàwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyésí tó lókìkí kárí ayé. Àwọn kan gbà pé ibẹ̀ làwọn akéwì, àwọn kunlékunlé, àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí máa ń bẹ̀ wò jù lọ. Oúnjẹ aládùn tí wọ́n ń sè níbẹ̀ làwọn mìíràn ń gbádùn, wọ́n sì tún ń gbóṣùbà fún àwọn nǹkan ìṣaralóge tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ pẹ̀lú.
Nínú ìtàn, Paris jẹ́ ibi tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ gan-an. Láti igba ọdún sẹ́yìn ni Paris sì ti di ibi tí a ń pè ní Ìlú Ìmọ́lẹ̀, nítorí ipa pàtàkì tó kó nínú ìgbòkègbodò àjọ àwọn onílàákàyè ilẹ̀ Yúróòpù, èyí táa mọ̀ sí Ẹgbẹ́ Àwọn Amòye. Bóyá wọ́n mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀, ipa tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àtìgbà yẹn ní lórí àwọn ará Paris lóde òní ju èyí tí ìsìn ní lọ.
Àmọ́, ọgbọ́n ènìyàn kò tànmọ́lẹ̀ sínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe retí. Ọ̀pọ̀ ló ti ń wá ìjìnlẹ̀ òye láti orísun mìíràn lóde Fílípì 2:15) Bíi ti awakọ̀ òkun tó mọṣẹ́ dunjú, wọn ti mú ara wọn bá onírúurú ipò tó ń yí padà tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń yọjú mu kí wọ́n lè kó “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” wọnú ọkọ̀ òkun tẹ̀mí náà.—Hágáì 2:7.
òní. Fún nǹkan bí àádọ́rùn-ún ọdún báyìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti “ń tàn bí àwọn atànmọ́lẹ̀” ní Paris. (Ìlú Ńlá Kan Tó Ń Peni Níjà
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 1850, Paris jẹ́ ìlú kan tí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] èèyàn ń gbé. Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ àti àgbègbè rẹ̀ lónìí, lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án èèyàn. Irú ìbísí bẹ́ẹ̀ ti sọ Paris di ìlú tí onírúurú èèyàn pọ̀ sí jù lọ nílẹ̀ Faransé. Ó jẹ́ ibùdó ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gíga lágbàáyé, tó ní ọ̀kan lára yunifásítì tó lọ́jọ́ lórí jù lọ láyé, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga bí ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] ló sì wà níbẹ̀. Àwọn àgbègbè kan ní Paris, níbi tí àwọn ilé gígagíga wà tí ìwàkiwà kún dẹ́nu, tí àwọn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ pọ̀ lọ jàra bí ewé rúmọ̀, ló jẹ́ apá ibi tí kò fani mọ́ra ní Paris. Láìsí àní-àní, ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìmọwọ́ọ́yípadà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù ìhìn rere náà lọ́nà tó fani mọ́ra fún gbogbo onírúurú ènìyàn bẹ́ẹ̀.—1 Tímótì 4:10.
Ó lé ní ogún mílíọ̀nù arìnrìn-àjò afẹ́ tó máa ń ṣèbẹ̀wò sí Paris lọ́dọọdún. Wọ́n lè fi tayọ̀tayọ̀ gun Òkè Gogoro ti Eiffel, kí wọ́n rìn yí ká odò Seine, tàbí kí wọ́n máa fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri láwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, kí wọ́n sì máa gba atẹ́gùn àgbègbè náà sára. Síbẹ̀ kòókòó jàn-ánjàn-án táwọn ará Paris ń fara dà kò kéré. Christian, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣàlàyé pé: “Àwọn èèyàn máa ń kánjú ṣáá ni. Á ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu kí wọ́n tó tibi iṣẹ́ dé.” Kò rọrùn rárá láti bá àwọn tọ́wọ́ wọn máa ń dí wọ̀nyí sọ̀rọ̀.
Àmọ́, ọ̀kan lára ìṣòro títóbi jù lọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dojú kọ ní Paris ni ti kíkàn sí àwọn èèyàn nínú ilé wọn. Ọ̀pọ̀ ilé ló ní àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ táa lè fi bá onílé sọ̀rọ̀ látẹnu ọ̀nà. Àmọ́, nítorí ìwà ọ̀daràn tó ń pọ̀ sí i, wọ́n sábà máa ń ṣe ètò ààbò sí àbáwọlé, tó fi jẹ́ pé kò sí béèyàn ṣe lè wọlé. Èyí ló wá fà á tó fi jẹ́ pé ní àwọn àgbègbè kan, ìpín Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo péré ló wà fún egbèje [1,400] ènìyàn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù àti ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà ti wá di èyí táwọn ará túbọ̀ ń ṣe jù lọ. Ǹjẹ́ ó ti ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti jẹ́ kí ‘ìmọ́lẹ̀ wọn tàn’ láwọn ọ̀nà mìíràn?—Mátíù 5:16.
Àǹfààní wà fún wọn, bẹ́ẹ̀ làwọn ibi tí wọ́n ti lè ṣe ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà pọ̀ lọ jàra. Martine rí obìnrin kan níbi tí wọ́n ti ń wọ bọ́ọ̀sì tí ìrísí obìnrin náà fi hàn pé ó ní ìṣòro. Ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí obìnrin náà bí ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni. Martine fún un ní ìwé pẹlẹbẹ kan tó dá lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi tuni nínú nípa ìrètí àjíǹde. Lẹ́yìn náà, wọn ò tún fojú gán-án-ní ara wọn mọ́ fún oṣù bíi mélòó kan. Nígbà tí Martine tún padà rí obìnrin náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Obìnrin náà di Ẹlẹ́rìí láìfi àtakò tí ọkọ rẹ̀ gbé dìde pè.
Ìjẹ́rìí Aláìjẹ́-bí-Àṣà Tó Méso Jáde
Ètò ọkọ̀ wíwọ̀ nílùú Paris jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gbéṣẹ́ jù lọ lágbàáyé. Ọkọ̀ ojú irin tó lókìkí gan-an tó máa ń gba abẹ́ ilẹ̀ máa ń gbé mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn lójúmọ́. Ibùdó ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ ti Paris, tí wọ́n ń pè ní Châtelet-Les-Halles ló tóbi jù lọ lágbàáyé, ibẹ̀ sì ni ibùdókọ̀ tí èrò ti ń wọ́ jù lọ lágbàáyé. Àǹfààní láti kàn sí àwọn èèyàn wà níbẹ̀ dáadáa. Ọkọ̀ abẹ́lẹ̀ náà ni Alexandra máa ń wọ̀ lọ síbi iṣẹ́ lójoojúmọ́. Ní ọjọ́ kan, ó bá ọ̀dọ́kùnrin kan tó ní àrùn leukemia fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀. Alexandra fún ọkùnrin náà ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Párádísè. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò Bíbélì nìyẹn lákòókò kan náà àti níbì kan náà yẹn fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko. Nígbà tó wá di ọjọ́ kan, ọkùnrin náà kò wá mọ́. Kété lẹ́yìn náà ni ìyàwó ọkùnrin náà tẹ Alexandra láago, tó sì sọ fún un pé kó máa bọ̀ ní ọsibítù, nítorí pé àìsàn ọkọ òun ti le gan-an. Ó ṣeni láàánú pé ẹ̀pa kò bóró mọ́ nígbà tí Alexandra fi máa débẹ̀. Lẹ́yìn ikú ọkùnrin náà, aya rẹ̀ kó lọ sí Bordeaux, ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé, níbi táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò yẹn ti kàn sí i. Àgbàyanu ìròyìn ló mà jẹ́ fún Alexandra láti gbọ́ ní ọdún kan lẹ́yìn náà pé opó náà ti di Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣe batisí, pẹ̀lú ìrètí àtirí ọkọ rẹ̀ nígbà tó bá jíǹde!—Jòhánù 5:28, 29.
Kristẹni àgbàlagbà kan bá Renata sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin tó ń ti Paris lọ sí Limoges, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Faransé. Ọdún márùn-ún gbáko ni Renata fi kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì ní Poland ìlú rẹ̀, àmọ́ kò nígbàgbọ́ mọ́. Ó wá gbàdúrà sí Ọlọ́run ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta ṣáájú àkókò yìí. Renata fún ìyá yìí ní nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí arábìnrin àgbàlagbà náà ń sọ, kò sì ronú pé òun tún lè gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Àmọ́, arábìnrin náà kò dákẹ́ síbẹ̀, ó rí i dájú pé àwọn kan bẹ Renata wò kété lẹ́yìn àkókò náà. Nígbà tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Renata ronú pé, ‘Kí ni wọ́n fẹ́ kọ́ mi báyìí?’ Láìfi gbogbo ẹ̀kọ́ ìsìn tó ti kọ́ pè, òtítọ́ Bíbélì fa Renata mọ́ra. Ó ṣàlàyé pé: “Ojú ẹsẹ̀ ni mo mọ̀ pé òtítọ́ ni.” Nísinsìnyí, inú rẹ̀ ń dùn bó ṣe ń sọ ìhìn Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn.
Michèle ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ọkọ̀ wíwà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Michèle jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun kò fara mọ́ ọn rárá. Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, olùkọ́ wọn, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sylvie béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́?” Ojú ìwòye táa gbé ka Bíbélì tí Michèle ní mú inú Sylvie dùn gan-an ni. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, Sylvie sì ṣe batisí ni ọdún kan lẹ́yìn náà.
Ọ̀pọ̀ ibi ìgbafẹ́ àtàwọn ọgbà ìtura tó wà ní Paris jẹ́ ibi tó dára láti báwọn èèyàn jíròrò. Ní àkókò ìsinmi ráńpẹ́ kan, Josette lọ sí ọgbà ìtura kan, níbi tí ìyá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Aline ti ń najú. Josette ṣàlàyé àwọn ìlérí àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì fún un. Wọ́n ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tí Aline fi tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe batisí. Nísinsìnyí, tí Aline ti di ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin, ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé tí iṣẹ́ rẹ̀ ń sèso rere, tínú rẹ̀ sì ń dùn láti báwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Kristẹni.
Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
Kò pọndandan fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Paris láti rìnrìn àjò lọ sí àwọn ilẹ̀ jíjìnnà réré kí wọ́n tó gbádùn onírúurú àṣà ìbílẹ̀. Nǹkan bí ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbébẹ̀ ló wá láti ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ Kristẹni tó ń sọ èdè bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló wà níbẹ̀.
Lílo òye àti fífojú inú wo nǹkan tún pẹ̀lú ohun tó ń mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere lọ́nà àkànṣe yìí. Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ará Philippines wá ìpínlẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan fún ara rẹ̀. Ó ti ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa bíbá àwọn ará Philippines ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà tó bá lọ ra nǹkan nílé ìtajà.
Ó jẹ́ ohun tó dára gan-an láti lo ìdánúṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ní December 1996, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn gbajúmọ̀ òṣèré afarapitú kan ń bọ̀ wá ṣeré nígboro, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè òkèèrè pinnu láti kàn sí àwọn òṣèré náà. Lálẹ́ ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n parí eré, ó ṣeé ṣe fún wọn láti bá àwọn òṣèré afarapitú tó ń padà lọ sí òtẹ́ẹ̀lì wọn sọ̀rọ̀. Ìdánúṣe yìí yọrí sí fífi Bíbélì méjìdínlọ́gbọ̀n, àwọn ìwé Kristẹni mọ́kàndínlọ́gọ́ta, ìwé pẹlẹbẹ mọ́kànléláàádóje [131], àti ìwé ìròyìn igba ó lé àádọ́rùn-ún [290] sóde. Lẹ́yìn tí wọ́n ti lo ọ̀sẹ̀ mẹ́ta níbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn òṣèré afarapitú náà béèrè pé: “Báwo ni mo ṣe lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” Òmíràn sọ pé: “Màá wàásù ní orílẹ̀-èdè mi!”
Àwọn Ìṣúra Fífarasin Táa Lè Rí
Ibikíbi táwọn tó wá ṣèbẹ̀wò sí Paris bá yíjú sí ni wọ́n ti ń rí àwọn ilé rèǹtè rente tó ti wà látayébáyé. Àmọ́ àwọn ohun iyebíye púpọ̀ sí i wà tí wọ́n lè rí. Aniza tẹ̀ lé ọkọ àǹtí rẹ̀, tó jẹ́ aṣojú fún orílẹ̀-èdè rẹ̀, wá sí ilẹ̀ Faransé. Ó máa ń ka Bíbélì déédéé nínú ilé. Bó ṣe fẹ́ kánjú jáde nílé lọ́jọ́ kan ni aṣáájú ọ̀nà kan fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Idi Tí O Fi Lè Gbẹkẹle Bibeli. Wọ́n ṣètò láti tún ríra lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹbí Aniza gbé ọ̀pọ̀ àtakò dìde sí i. Ó tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ débi tó fi ṣe batisí. Ojú wo ló fi wo àǹfààní tó ní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́? Ó sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, iṣẹ́ ìwàásù náà ṣòro nítorí pé mo máa ń tijú. Síbẹ̀síbẹ̀ nígbà tí mo ka Bíbélì, ó ta mí jí. Ọkàn mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá wàásù.” Irú ẹ̀mí yẹn ni ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí tó wà ní Paris ní, wọ́n “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Òtítọ́ Bíbélì tún tàn dé ibi iṣẹ́ ìkọ́lé kan ní ẹ̀yìn odi Paris, tó tún jẹ́ ká rí “àwọn ohun iyebíye” mìíràn. Nítorí àtilọ yá àwọn kásẹ́ẹ̀tì kan ni Bruce ṣe lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí Bruce rí i pé ọ̀rẹ́ òun ń bá àwọn ojúlùmọ̀ òun kan jíròrò Bíbélì, ni òun náà bá fetí sí ìjíròrò náà. Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó ní àwọn ìṣòro kan. “Àwọn èèyàn mọ̀ mí bí ẹní mowó lágbègbè náà. Ẹ̀gbọ́n wa pátápátá máa ń jà ṣáá ni, èmi náà sì máa ń ṣètò àwọn àríyá aláriwo. Báwo làwọn èèyàn ṣe fẹ́ gbà pé lóòótọ́ ni mo ti di Ẹlẹ́rìí?” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn ń bẹ Bruce ṣáá pé kó tún máa ṣètò àríyá, síbẹ̀ ó ṣíwọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù, ó sì sọ pé: “Gbogbo àwọn tó wà lágbègbè náà ló fẹ́ mọ ìdí tí mo fi di Ẹlẹ́rìí.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló ṣe batisí. Bí àkókò ti ń lọ, ó láǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.
Wíwá ìṣúra lè gba ìsapá tí kò kéré. Àmọ́, ẹ wò bó ṣe máa ń jẹ́ ayọ̀ ńlá tó nígbà tí iṣẹ́ náà bá yọrí sí rere! Búrẹ́dì ni Jacky, Bruno, àti Damien ń ṣe ní Paris. Jacky ṣàlàyé pé: “Kò ṣeé ṣe láti rí wa bá sọ̀rọ̀ nítorí pé gbogbo ìgbà la máa ń ṣiṣẹ́, a ò sì dúró sílé rí.” Patrick tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, rí i pé àwọn yàrá kéékèèké kan wà ní òkè ilé tí wọ́n ń gbé, ó sì wá ronú pé, ó kéré tán àwọn èèyàn ń gbé inú ọ̀kan lára àwọn yàrá náà. Gbogbo ìsapá tó ṣe láti kàn sí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ so èso rere
nígbà tó di ọ̀sán ọjọ́ kan, tó jàjà rí Jacky, tó ń gbé níbẹ̀ fúngbà díẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Àwọn ọ̀rẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà di Ẹlẹ́rìí, wọ́n sì wá iṣẹ́ mìíràn tó fún wọn láyè láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.Dídẹwọ́ Ìjì Líle
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Faransé pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ẹ̀sìn wọn léwu. Ní ọdún 1996, àwọn Ẹlẹ́rìí fi tọkàntọkàn kópa nínú pípín ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ẹ̀dà ìsọfúnni àrà ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Mọ̀ Nípa Wọn. Àbájáde rẹ̀ dára gan-an ni.
Wọ́n sapá gidigidi láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn. Ọ̀pọ̀ aláṣẹ ló fi ìmọrírì wọn hàn fún àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Olùgbani-nímọ̀ràn kan ní ìlú náà kọ̀wé pé: “Pípín táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pín ìwé àṣàrò kúkúrú yìí kiri dára gan-an. Ó ti jẹ́ káyé mọ̀ pé irọ́ làwọn èèyàn ń pa mọ́ wọn.” Dókítà kan sọ pé: “Ó pẹ́ tí mo ti ń dúró de irú ìsọfúnni yìí!” Ọkùnrin kan láti àgbègbè Paris kọ̀wé pé: “Ìwé àṣàrò kúkúrú náà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ohun Tí Ó Yẹ Kí O Mọ̀ Nípa Wọn ṣèèṣì tẹ̀ mí lọ́wọ́ ni. Máa sì fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa wọn, kí n sì jàǹfààní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.” Ẹlòmíràn kọ̀wé pé: “Ẹ ṣé gan-an fún àìlábòsí yín.” Obìnrin kan tó jẹ́ Kátólíìkì sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Áà! Ẹ ti wá já irọ́ yìí ní koro níkẹyìn!”
Ohun àrà ọ̀tọ̀ tó fún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí lágbègbè Paris láyọ̀ gan-an ni iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ṣètò fún Àwọn Ọjọ́ Èwe Ti Kátólíìkì Àgbáyé ní 1997. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ooru tó mú lé ní ìwọ̀n márùndínlógójì lórí òṣùwọ̀n Celsius, nǹkan bí egbèjìlá ààbọ̀ [2,500] Ẹlẹ́rìí ló kópa. Láàárín ọjọ́ díẹ̀, wọ́n ti fi ẹgbẹ̀sán [18,000] ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn sóde fún àwọn ọ̀dọ́ láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé. Ní àfikún sí jíjẹ́rìí àtàtà sí orúkọ Jèhófà àti gbígbin irúgbìn òtítọ́, ìkéde náà tún ta àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí jí. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó dín àkókò ìsinmi rẹ̀ kù kí ó lè kópa nínú ìgbòkègbodò àrà ọ̀tọ̀ yìí dáadáa kọ̀wé pé: “Jèhófà ní àwọn èèyàn aláyọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń lo okun wọn láti yin orúkọ rẹ̀. Ọjọ́ méjì wọ̀nyí kún rẹ́rẹ́, ó sì lérè, ju gbogbo ìsinmi téèyàn lè gbà nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lọ! (Sáàmù 84:10)”
February 28, 1998 ló pé ọdún márùndínláàádọ́rin tí Hitler gbé òfin tó yọrí sí fífi òfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jámánì jáde. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Faransé lo ọjọ́ yẹn láti fi fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, tó jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìyà tó jẹ àwọn èèyàn Jèhófà, hàn láwọn gbọ̀ngàn tí wọ́n háyà. Ó lé ní mílíọ̀nù méje ìwé ìkésíni tí wọ́n pín káàkiri. Àwọn òpìtàn àtàwọn tó ti wà lágọ̀ọ́ yẹn tẹ́lẹ̀ sọ àwọn ìrírí tó wọni lákínyẹmí ara. Ní àgbègbè Paris, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] èèyàn tó wá síbẹ̀, títí kan ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.
Ọ̀pọ̀ nílẹ̀ Paris ló mọyì ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí gan-an, inú wọn sì dùn pé àwọn akéde Ìjọba náà ń tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀. Bí Jésù ṣe polongo rẹ̀ ló rí: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” (Mátíù 9:37) Ẹ̀mí ìmúratán tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, tí wọ́n fi ń borí àwọn ìpèníjà ti wíwàásù láàárín ìlú ti sọ Paris di Ìlú Ìmọ́lẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, sí ìyìn Jèhófà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Gbọ̀ngàn Ìlú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Louvre
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Opera Garnier
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Sísọ ìhìn Bíbélì fún àwọn tí ọwọ́ wọn dí níbikíbi táa bá ti lè rí wọn