Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kólósè 1:16 sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run pé “gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.” Lọ́nà wo la gbà dá ohun gbogbo “fún” Jésù, Ọmọ Ọlọ́run?

Jèhófà fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo ṣe àgbà òṣìṣẹ́ nínú dídá gbogbo ohun yòókù, èyíinì ni, ohun gbogbo yàtọ̀ sí Jésù alára. (Òwe 8:27-30; Jòhánù 1:3) Ó tọ́ kí iṣẹ́ wọ̀nyí mú inú Ọmọ náà dùn, táa bá sì wò ó lọ́nà yìí, wọ́n wà “fún” un.

A mọ̀ pé inú àwọn òbí sábà máa ń dùn sí àwọn ọmọ tí wọ́n bí. Ìdí nìyẹn tí òwe Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa “ọmọ tí [bàbá rẹ̀] dunnú sí.” (Òwe 3:12; 29:17) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí Ísírẹ́lì nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́. (Sáàmù 44:3; 119:108; 147:11) Bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòtítọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin ń fún un láyọ̀ títí di àkókò táa wà yìí pàápàá.—Òwe 12:22; Hébérù 10:38.

Nípa báyìí, ó bá a mu pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn Jésù, rí ìdùnnú nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Àní Òwe 8:31 sọ pé Ọmọ ‘ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ sí ilẹ̀ eléso ilẹ̀ ayé rẹ̀, àwọn ohun tí ó sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.’ Lọ́nà yìí ni Kólósè 1:16 fi sọ pé: “Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.”