Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ́lẹ̀ Tẹ̀mí Ti Tàn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé

Ìmọ́lẹ̀ Tẹ̀mí Ti Tàn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìmọ́lẹ̀ Tẹ̀mí Ti Tàn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé

GẸ́GẸ́ BÍ NAJIB SALEM ṢE SỌ Ọ́

Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn láti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, ó sì mọ́lẹ̀ dé àwọn ibi jíjìnnàréré lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. Láàárín ọ̀rúndún ogún, ìmọ́lẹ̀ yẹn tún padà wá tàn sí apá ibẹ̀ yẹn lórí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kan sí i. Ẹ jẹ́ kí n sọ bọ́rọ̀ ṣe rí bẹ́ẹ̀ fún yín.

ỌDÚN 1913 ni wọ́n bí mi ní ìlú Amioun tó wà ní àríwá Lẹ́bánónì. Ọdún yẹn ni ìwọ̀nba àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà lórí ilẹ̀ ayé kẹ́yìn, nítorí pé ọdún tó tẹ̀ lé e ni Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀. Nígbà tí ogun náà parí ní 1918, Lẹ́bánónì, táa mọ̀ sí péálì Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé nígbà yẹn, wá di èyí tí ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú rẹ̀ forí ṣánpọ́n.

Nígbà tó di ọdún 1920, tí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìfìwéránṣẹ́ tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Lẹ́bánónì, a bẹ̀rẹ̀ sí rí ìwé gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Lẹ́bánónì tó ń gbé lókè òkun. Abdullah àti George Ghantous tí wọ́n jẹ́ arákùnrin màmá mi wà lára wọn. Wọ́n kọ lẹ́tà sí Habib Ghantous, baba wọn, ìyẹn baba mi àgbà, wọ́n sì sọ fún un nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Kìkì ohun táwọn ọmọ kọ sínú lẹ́tà lásán ni baba àgbà sọ fáwọn ará ìlú rẹ̀ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe ẹlẹ́yà. Àwọn ará ìlú wá bẹ̀rẹ̀ sí tan ọ̀rọ̀ àhesọ náà kálẹ̀ pé àwọn ọmọ Habib ń gba baba wọn níyànjú pé kó ta ilẹ̀ rẹ̀, kó ra kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kó sì máa wàásù kiri.

Ìgbà Tí Ìmọ́lẹ̀ Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tàn

Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn 1921, Michel Aboud, tó ń gbé Brooklyn, New York, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, padà wá sí Tripoli, Lẹ́bánónì. Ó ti di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ Arákùnrin Aboud ni kò fara mọ́ ìhìn Bíbélì, síbẹ̀ àwọn méjì tó gbajúmọ̀ gan-an ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ibrahim Atiyeh, àti oníṣègùn eyín kan tó ń jẹ́ Hanna Shammas. Àní, Dókítà Shammas tiẹ̀ yọ̀ǹda pé kí wọ́n máa lo ilé òun àti ilé ìwòsàn òun fún àwọn ìpàdé Kristẹni.

Mo ṣì kéré nígbà tí Arákùnrin Aboud àti Arákùnrin Shammas ṣèbẹ̀wò sí Amioun, níbi tí mò ń gbé. Ìbẹ̀wò wọn nípa lórí mi gan-an, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Arákùnrin Aboud jáde òde ẹ̀rí. Ogójì ọdún gbáko làwa méjèèjì fi jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó tó di pé Arákùnrin Aboud kú ní 1963.

Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bíbélì tàn kálẹ̀ gan-an ní ọ̀pọ̀ abúlé tó wà ní àríwá Lẹ́bánónì láàárín 1922 sí 1925. Àwọn èèyàn bí ogún sí ọgbọ̀n ló ń pàdé pọ̀ láti jíròrò Bíbélì láwọn ilé àdáni, báa ti ń ṣe nínú ilé tiwa ní Amioun. Àwọn àlùfáà ní káwọn ọmọdé máa lu agolo, kí wọ́n sì máa pariwo ká má bàa gbọ́ ohun táa ń sọ láwọn ìpàdé wa, ìdí nìyẹn táa fi máa ń pàdé nínú igbó nígbà mìíràn.

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìtara tí mo ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́—àti fún lílọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni—ni wọ́n fi ń pè mí ní Tímótì. Olùdarí ilé ẹ̀kọ́ pa á láṣẹ pé n ò gbọ́dọ̀ lọ sí ohun tó pè ní “àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn” mọ́. Nígbà tí mo kọ̀, wọ́n lé mi jáde nílé ìwé.

Jíjẹ́rìí Láwọn Ilẹ̀ Tí Wọ́n Ti Kọ Bíbélì

Kété lẹ́yìn tí mo ṣe batisí ní 1933 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń pe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kéré níye nígbà yẹn, kì í ṣe pé a wàásù ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn abúlé tó wà ní apá àríwá Lẹ́bánónì nìkan ni, àmọ́ a tún dé Beirut àtàwọn eréko rẹ̀ títí dé gúúsù Lẹ́bánónì. Láwọn ọdún táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, ẹsẹ̀ la fi máa ń rìnrìn àjò tàbí ká gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bí Jésù Kristi àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní ti ṣe.

Ní 1936, Yousef Rahhal, Ẹlẹ́rìí ọmọ ilẹ̀ Lẹ́bánónì tó ti wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fún ọ̀pọ̀ ọdún, padà wá bẹ Lẹ́bánónì wò. Ó gbé ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti àwọn ẹ̀rọ giramafóònù méjì bọ̀. A so àwọn ohun èlò wọ̀nyí mọ́ ọkọ̀ Ford kan tí wọ́n ṣe ní 1931, a sì rin ìrìn àjò jákèjádò Lẹ́bánónì àti Síríà, táa ń mú ìhìn Ìjọba náà lọ sáwọn àgbègbè àdádó. Àwọn èèyàn máa ń gbọ́ dídún ohun èlò yìí ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́wàá síbi táa bá wà. Àwọn èèyàn máa ń gòkè lọ sí orí òrùlé ilé wọn, kí wọ́n lè gbọ́ ohun tí wọ́n pè ní ohùn tó ń wá láti ọ̀run. Àwọn tó wà nínú oko máa ń fiṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n a sì sún mọ́ tòsí láti wá gbọ́.

Ọ̀kan lára ìrìn àjò tí mo bá Yousef Rahhal rìn kẹ́yìn ni èyí táa fi lọ sí Aleppo, ní Síríà, nígbà òtútù 1937. A tún jọ rìnrìn àjò lọ sí Palẹ́sìnì, kó tó di pé ó padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ibẹ̀ la ti ṣèbẹ̀wò sí ìlú ńlá Haifa àti Jerúsálẹ́mù, títí kan àwọn abúlé tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Ọ̀kan lára àwọn táa bá pàdé ni Ibrahim Shehadi, ẹni tí èmi pẹ̀lú rẹ̀ ti máa ń kọ lẹ́tà síra wa tẹ́lẹ̀. Ibrahim ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìmọ̀ Bíbélì débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí bá wa jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé nígbà táa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀.—Ìṣe 20:20.

Mo tún ń hára gàgà láti rí Ọ̀jọ̀gbọ́n Khalil Kobrossi, tó jẹ́ Kátólíìkì kan tí kò fi ẹ̀sìn rẹ̀ ṣeré rárá, àmọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ. Báwo ló ṣe rí àdírẹ́sì àwa Ẹlẹ́rìí ní Lẹ́bánónì gbà? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, òǹtajà tó wà ní ilé ìtajà kan ní Haifa ló fi bébà tí wọ́n ya lára ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà di àwọn nǹkan tí Khalil wá rà fún un. Àdírẹ́sì wa sì wà lára bébà ọ̀hún. A jọ gbádùn ara wa gan-an lásìkò ìbẹ̀wò yẹn, nígbà tó yá, ní ọdún 1939, ó wá sí Tripoli láti ṣe batisí.

Ní 1937, Petros Lagakos àti aya rẹ̀ dé sí Tripoli. Láàárín ọdún díẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kárí apá tó pọ̀ jù lọ ní Lẹ́bánónì àti Síríà, táa ń mú ìhìn Ìjọba náà tọ àwọn èèyàn lọ nínú ilé wọn. Nígbà tí Arákùnrin Lagakos kú ní 1943, àwa Ẹlẹ́rìí ti mú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí lọ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìlú ńlá àtàwọn abúlé tó wà ní Lẹ́bánónì, Síríà, àti Palẹ́sìnì. Ìgbà mìíràn, nǹkan bí aago mẹ́ta òru ni àwa bí ọgbọ̀n máa gbéra nínú ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí bọ́ọ̀sì, ká lè dé àwọn àgbègbè àdádó.

Láwọn ọdún 1940, Ibrahim Atiyeh ń túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí èdè Lárúbáwá. Lẹ́yìn náà, máa fi ọwọ́ da ẹ̀dà bíi mẹ́rin ìwé ìròyìn náà kọ, máa sì fi ránṣẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Palẹ́sìnì, Síríà, àti Íjíbítì. Láyé ọjọ́un, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń jà lọ́wọ́, àtakò tí wọ́n ń ṣe sí iṣẹ́ ìwàásù wa ga gan-an, àmọ́ a ò ṣíwọ́ kíkàn sí gbogbo àwọn olùfẹ́ òtítọ́ Bíbélì tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Mo dìídì ya àwòrán ilẹ̀ àwọn ìlú ńlá àtàwọn abúlé tó yí wọn ká, a sì rí i dájú pé a mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ wọn.

Ní 1944, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń jà lọ́wọ́, mo fẹ́ Evelyn, ọmọ Michel Aboud, táa jọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a bí ọmọ mẹ́ta, ọmọbìnrin kan àti ọmọkùnrin méjì.

Bíbá Àwọn Míṣọ́nnárì Ṣiṣẹ́

Kété lẹ́yìn tí ogun parí ni àwọn tó kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà fún àwọn míṣọ́nnárì dé sí Lẹ́bánónì. Nítorí náà, a dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní Lẹ́bánónì, wọ́n sì fi mí ṣe ìránṣẹ́ ẹgbẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ní 1947, Nathan H. Knorr àti akọ̀wé rẹ̀, Milton G. Henschel, wá sí Lẹ́bánónì, wọ́n sì fún àwọn ará níṣìírí. Láìpẹ́, àwọn míṣọ́nnárì púpọ̀ sí i tún dé, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti ṣètò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti láti darí àwọn ìpàdé ìjọ.

Nígbà kan táa lọ sí àgbègbè àdádó kan ní Síríà, bíṣọ́ọ̀bù ibẹ̀ gbé àtakò dìde sí wa. Ó fi ẹ̀sùn kàn wá pé a ń pín ohun tó pè ní àwọn ìtẹ̀jáde Ẹgbẹ́ Síónì kiri. Kẹ́ẹ sì wá wò ó, “Kọ́múníìsì” ni àwọn àlùfáà sábà máa ń pè wá ṣáájú 1948. Lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n mú wa, wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò fún wákàtí méjì, àwa náà wá lo àkókò yẹn láti jẹ́rìí fún wọn kúnnákúnná.

Níkẹyìn, adájọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ wa sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fi bíṣọ́ọ̀bù tó fẹ̀sùn kàn yín bú, mo tún ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó jẹ́ kí n ní àǹfààní láti rí yín, kí n sì gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín.” Ó wá bẹ̀ wá pé ká máà bínú gbogbo wàhálà tí wọ́n kó wa sí.

Nígbà tí mo wà nínú bọ́ọ̀sì kan tó ń lọ sí Beirut ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá ọkùnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi sọ̀rọ̀, onímọ̀ ẹ̀rọ iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọkùnrin náà. Lẹ́yìn tó fetí sí ìgbàgbọ́ wa fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, ó ní òun ti gbọ́ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ lẹ́nu ọ̀rẹ́ òun kan ní Síríà. Ta ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀hún? Adájọ́ tó gbọ́ ẹjọ́ wa ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni!

Láwọn ọdún 1950, mo bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Iraq wò, mo sì bá wọn kópa nínú ìjẹ́rìí láti ilé-dé-ilé. Mo tún rin ọ̀pọ̀ ìrìn àjò lọ sí Jọ́dánì àti àgbègbè West Bank. Ní 1951, mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin tó lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ibẹ̀ la ti ṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn, gbogbo àwọn tó wá fún àṣeyẹ náà ló ti wọ bọ́ọ̀sì lọ sí Odò Jọ́dánì, níbi tí àwọn méjìlélógún ti ṣe batisí láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà hàn. Ìgbàkigbà tí wọ́n bá ti gbé àtakò dìde sí wa ní àgbègbè yẹn, a máa ń sọ fún wọn pé: “Ohun táa wá sọ fún yín ni pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú yín ló máa di Ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé! Kí ló wá ń bí yín nínú? Ńṣe ló yẹ kẹ́ẹ máa yọ̀!”

Wíwàásù Nínú Ìṣòro

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ló jẹ́ ọlọ́kàn rere, onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì láájò àlejò. Ọ̀pọ̀ ló ń fetí sí ìhìn Ìjọba Ọlọ́run tìfẹ́tìfẹ́. Ká sọ tòótọ́, kò sí ohun tó fini lọ́kàn balẹ̀ tó mímọ̀ pé láìpẹ́ ìlérí Bíbélì yìí yóò ní ìmúṣẹ pé: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò . . . wà pẹ̀lú [àwọn ènìyàn rẹ̀]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Mo ti wá rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń takò iṣẹ́ wa ni kò lóye iṣẹ́ wa ní ti gidi àti ìhìn tí a ń wàásù rẹ̀. Kò sí itú tí àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù kò tíì pa láti lè fi wá gbojúbi! Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí fi kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro nígbà ogun abẹ́lé tó bẹ̀rẹ̀ ní Lẹ́bánónì lọ́dún 1975, tó sì jà fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

Ìgbà kan wà tí mo ń bá ìdílé kan tó máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì bí àwọn àlùfáà nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, ní alẹ́ ọjọ́ kan, ẹgbẹ́ onísìn kan ládùúgbò ní kí àwọn mẹ́ńbà òun lọ ba ṣọ́ọ̀bù ìdílé náà jẹ́, wọ́n sì dáná sun ọjà tí ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ó kéré tán. Alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà ni wọ́n wá fipá gbé mi. Àmọ́, ó ṣeé ṣe fún mi láti bá aṣáájú wọn fèròwérò. Mo ṣàlàyé fún un pé bí wọ́n bá jẹ́ Kristẹni ní tòótọ́, wọn ò ní máa hu irú ìwà ẹhànnà yẹn. Nígbà tó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó pàṣẹ pé kí ọkọ̀ náà dúró, ó sì ní kí n máa lọ.

Ní àkókò mìíràn, àwọn mẹ́rin tó jẹ́ ológun jí mi gbé. Lẹ́yìn tí wọ́n halẹ̀ mọ́ mi ní àìmọye ìgbà, lójijì ni ọ̀gá wọn, tó ti sọ pé òun máa yìnbọn pa mí yí èrò rẹ̀ padà, wọ́n sì ní kí n máa lọ. Méjì lára àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wà lẹ́wọ̀n báyìí, lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti olè jíjà, wọ́n sì ti pa àwọn méjì tó kù.

Àwọn Àǹfààní Mìíràn Láti Jẹ́rìí

Mo sábà máa ń láǹfààní láti wọkọ̀ òfuurufú láti orílẹ̀-èdè kan lọ sí òmíràn. Nígbà kan tí mo wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tó ń ti Beirut lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, mo jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Charles Malek, tó jẹ́ mínísítà nípa ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè fún Lẹ́bánónì tẹ́lẹ̀. Ó tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́, ó sì mọrírì gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí mo kà fún un. Níkẹyìn, ó sọ pé òun ti lọ sí ilé ìwé kan ní Tripoli, níbi tí Ibrahim Atiyeh ti jẹ́ olùkọ́ òun, ìyẹn ni ọkùnrin tó tipasẹ̀ baba ìyàwó mi mọ òtítọ́ Bíbélì! Ọ̀gbẹ́ni Malek sọ pé Ibrahim ti kọ́ òun láti máa bọ̀wọ̀ fún Bíbélì.

Nígbà ìrìn àjò mìíràn, mo jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣojú àwọn ará Palẹ́sìnì sí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Mo láǹfààní láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún un. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó mú mi mọ ìdílé àbúrò rẹ̀ tó wà ní New York, mo sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn níbẹ̀. Mo tún ní mọ̀lẹ́bí kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó wà ní New York. Ìbẹ̀wò kan tí mo ṣe sí ọ́fíìsì rẹ̀ lọ́jọ́ kan gba odindi wákàtí mẹ́ta, tó sì ṣeé ṣe fún mi láti fi àkókò yẹn jẹ́rìí fún un nípa Ìjọba Ọlọ́run.

Mo ti di ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] báyìí, mo ṣì ń kópa déédéé nínú bíbójútó àwọn ẹrù iṣẹ́ ìjọ. Evelyn, aya mi náà ṣì ń sin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú mi. Ọmọbìnrin wa fẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ kan ní Beirut báyìí. Ẹlẹ́rìí ni ọmọbìnrin wọn pẹ̀lú. Ẹlẹ́rìí ni ọmọkùnrin wa tó kéré jù lọ àti aya rẹ̀, ọmọbìnrin àwọn náà sì wà nínú òtítọ́ pẹ̀lú. Ní ti ọmọkùnrin wa àgbà, a gbin ìgbàgbọ́ Kristẹni sí i lọ́kàn, mo sì nírètí pé bí àkókò ti ń lọ, yóò tẹ́wọ́ gbà á.

Ní ọdún 1933, wọ́n yàn mí láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà—àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Mi ò rò pé ohunkóhun mìíràn wà tó tún lè dára ju bí mo ṣe fi ìgbésí ayé mi sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní gbogbo ọdún méjìdínláàádọ́rin wọ̀nyí. Mo sì ti pinnu láti máa bá a lọ láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó pèsè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Najib ní 1935

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ táa so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ ní àwọn Òkè Ńlá Lẹ́bánónì, 1940

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Lókè, láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún; Najib, Evelyn, ọmọbìnrin wọn, Arákùnrin Aboud àti ọmọkùnrin tí Najib kọ́kọ́ bí, 1952

Nísàlẹ̀, (ní ìlà iwájú): Arákùnrin Shammas, Knorr, Aboud, àti Henschel ní ilé Najib, ní Tripoli, 1952

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Najib àti Evelyn, aya rẹ̀