Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Akutupu Wo Ló Ń Hu Nílẹ̀ Faransé O?”

“Akutupu Wo Ló Ń Hu Nílẹ̀ Faransé O?”

“Akutupu Wo Ló Ń Hu Nílẹ̀ Faransé O?”

“Òmìnira, áà, kòṣeémánìí lòmìnira.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wá látinú orin orílẹ̀-èdè Faransé, tí wọ́n ń pè ní “La Marseillaise.” Láìsí àní-àní, ọ̀ràn òmìnira ṣe kókó. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí nílẹ̀ Faransé ti jẹ́ kí ominú bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn èèyàn pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí jin àwọn òmìnira pàtàkì lẹ́sẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní Friday, November 3, 2000, ẹgbẹẹgbẹ̀rùn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pín àròpọ̀ mílíọ̀nù méjìlá ẹ̀dà àkànṣe ìwé àṣàrò kúkúrú táa pe àkọlé rẹ̀ ní “Akutupu Wo Ló Ń Hu Nílẹ̀ Faransé O? Àbí Òmìnira Ò Sí Mọ́ Ni?”

Ó TI tó ọdún mélòó kan báyìí tí onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú àtàwọn ẹgbẹ́ tó ń gbógun ti ẹ̀ya ìsìn ti n gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé. Wọ́n ti fi ayé ni àwọn Ẹlẹ́rìí lára, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, gbogbo ìjọ lódindi, àti jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ o, ní June 23, 2000, Ìgbìmọ̀ Conseil d’État, tí í ṣe kóòtù agbófinró tó ga jù lọ nílẹ̀ Faransé, ṣe ìpinnu mánigbàgbé kan tó wà níbàámu pẹ̀lú ìpinnu tí àwọn kóòtù kéékèèké mọ́kànlélọ́gbọ̀n ti ṣe nínú àwọn ẹjọ́ tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100]. Ilé ẹjọ́ gíga náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá òfin ilẹ̀ Faransé mu látòkèdélẹ̀, àti pé gbogbo owó tí ìjọba kò bá béèrè lọ́wọ́ àwọn ètò ẹ̀sìn yòókù, kí ẹnikẹ́ni má gbà á lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn.

Àmọ́ o, ńṣe ni Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Ìjọba Ilẹ̀ Faransé Tí Ń Rí Sọ́ràn Ìṣúnná Owó fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́, tí wọ́n fàáké kọ́rí pé àwọn ò ní fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́rùn sílẹ̀, wọ́n ní àwọn Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ máa san gbogbo owó tí òfin kì í gbà lọ́wọ́ àwọn ètò ẹ̀sìn. Iléeṣẹ́ náà ní dandan ni kí àwọn máa gba ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo owó táwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ìjọ tó wà nílẹ̀ Faransé fi ń ta ìjọ lọ́rẹ. Ọ̀ràn yìí ti wà nílé ẹjọ́ báyìí.

Ète ìgbòkègbodò táa mẹ́nu kàn ṣáájú ni láti sọ fáyé gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì yìí, ká sì tẹnu mọ́ ewu tó wà nínú owó ipá tí wọ́n fẹ́ máa gbà yìí, àti ewu gbígbé àwọn àbádòfin kan jáde tó lè jin òmìnira ẹ̀sìn lẹ́sẹ̀ fún kóówá. a

Látàárọ̀ Ṣúlẹ̀ Ni

Agogo méjì òru làwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn ìjọ kan ti bẹ̀rẹ̀ sí pín ìwé náà ní àwọn ibùdókọ̀ ojú irin àti láwọn iléeṣẹ́ kan, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbọ̀nà àwọn pápákọ̀ òfuurufú lọ. Nígbà tó máa di aago mẹ́fà, ojú ti mọ́ nílùú Paris. A yan nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn síbi táwọn òṣìṣẹ́ sábà máa ń gbà lọ síbi iṣẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan sọ pé: “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe láti fìdí òmìnira ẹ̀sìn múlẹ̀ dáa. Kì í ṣe ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan lọ̀ràn yìí kàn.” Nílùú Marseilles, ó lé ní àádọ́ta dín nírínwó [350] àwọn Ẹlẹ́rìí tó pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà láwọn ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ àti lójú pópó. Láàárín wákàtí kan, àwọn rédíò ti bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn nípa ìgbòkègbodò náà kárí orílẹ̀-èdè, wọ́n ń sọ fáwọn èèyàn pé kí ó má yà wọ́n lẹ́nu bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá yọ sí wọn. Nílùú Strasbourg, tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù wà, ńṣe ni àwọn arìnrìn àjò ní ibùdókọ̀ ńlá tó wà níbẹ̀ fi sùúrù tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gba ẹ̀dà tiwọn. Lọ́yà kan sọ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ò gba ti ẹ̀sìn wa, síbẹ̀ òun ń fọkàn bá ẹjọ́ wa lọ, torí pé akitiyan wa ṣe pàtàkì, ó sì bá ìdájọ́ òdodo mu.

Nígbà tó máa di aago mẹ́jọ, láìfi wábi-wọ́sí òjò tó ń rọ̀ pè, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méje [507] àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ nílùú Grenoble olókè ti lọ yí ká gbogbo ojú pópó tàbí kí wọ́n fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà sínú àpótí táwọn èèyàn ti ń gba lẹ́tà. Àwọn dírẹ́bà tí ń wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti bọ́ọ̀sì ojú irin, tí wọ́n rí i pé nǹkan kan ń lọ lọ́wọ́, yà wá gba ìwé àṣàrò kúkúrú tiwọn. Ní ìlú Poitiers tí ń bẹ ní ìwọ̀ oòrùn, àwọn arìnrìn-àjò tó wọkọ̀ ojú irin dé láago mẹ́sàn-án ti rí ìwé àṣàrò kúkúrú tiwọn gbà níbi tí wọ́n ti ń bọ̀. Nílùú Mulhouse, tí ń bẹ nítòsí ààlà Jámánì, ọ̀kẹ́ méjì [40,000] ẹ̀dà la ti pín.

Nígbà tó máa di aago mẹ́wàá, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ti pín kọjá ìdajì ìwé àṣàrò kúkúrú tí wọ́n ní lọ́wọ́. Bó ti ń di ọwọ́ ìyálẹ̀ta, ṣàṣà làwọn tó kọ̀ láti gba ìwé náà, ọ̀pọ̀ ìjíròrò tó wúni lórí ló sì wáyé. Nílùú Besançon, tí kò ju ọgọ́rin kìlómítà sí ààlà Switzerland, ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé òun fẹ́ràn Bíbélì, ó sì béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi àyè gba ìjìyà. Ẹlẹ́rìí náà sọ pé kí àwọn máa bá ìjíròrò náà nìṣó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ń bẹ nítòsí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ẹsẹ̀ nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?

Nígbà tó máa di ọ̀sán, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló fi àkókò tí wọ́n fi ń sinmi fún oúnjẹ ọ̀sán wàásù fún wákàtí kan tàbí méjì. Jálẹ̀ gbogbo ọ̀sán là ń pín ìwé náà nìṣó, ó sì tó aago mẹ́ta tàbí mẹ́rin ọ̀sán kí ọ̀pọ̀ ìjọ tó ṣíwọ́. Nílùú Reims, àwọn kan tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí tí wọ́n ti dara pọ̀ nígbà kan rí tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Nílùú Bordeaux, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ta la bẹ̀rẹ̀. Ní ìlú kan náà, Ẹlẹ́rìí kan wọ ilé ìtajà kan láti lọ ra ìwé ìròyìn, ó sì rí òkìtì ìwé àṣàrò kúkúrú lórí káńtà. Lẹ́yìn tí òǹtajà náà, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀, gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, tó rí i pé ọ̀rọ̀ pàtàkì ló wà nínú rẹ̀, ló wá lọ ṣe ẹ̀dà rẹ̀, kí òun náà lè pín in fáwọn èèyàn.

Nílùú Le Havre, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Normandy, tí í ṣe ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, nígbà tó gbọ́ lórí rédíò pé ìjọba ń gbà lára owó ọrẹ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí gbà. Pẹ̀lú ìháragàgà ló fi gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ó sì kan sáárá sáwọn Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọ́n fìgboyà tú irú ìwà ìrẹ́nijẹ bẹ́ẹ̀ fó. Nígbà tó máa di aago méje kọjá ogún ìṣẹ́jú lálẹ́, ìròyìn àdúgbò nílé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan nílùú Lyons ti gbé ìròyìn nípa ìwé táa ń pín kiri náà, ó sọ pé: “Láàárọ̀ òní, ó rọrùn láti gba àárín àwọn ẹ̀kán òjò kọjá láìjẹ́ pé ó ta sí wa lára, ju kí á yẹra fún ìwé àṣàrò kúkúrú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Wọ́n fọ̀rọ̀ wá Ẹlẹ́rìí méjì lẹ́nu wò, wọ́n sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ń ṣe ìkéde náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́ kópa nínú iṣẹ́ náà lẹ́yìn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí pín ìwé àṣàrò kúkúrú fáwọn tó ń tibi iṣẹ́ bọ̀, wọ́n tún ń fi sínú àpótí táwọn èèyàn ti ń gba lẹ́tà. Ní àwọn ìlú bíi Brest àti Limoges—tó jẹ́ ìlú àwọn amọ̀kòkò—àwọn èèyàn tó ń jáde nílé sinimá ní aago mọ́kànlá alẹ́ wà lára àwọn tó gba ìwé náà gbẹ̀yìn lọ́jọ́ yẹn. A kó ìwé àṣàrò kúkúrú tó ṣẹ́ kù jọ, a sì pín in láàárọ̀ ọjọ́ kejì.

Ìyọrísí Rẹ̀

Ẹlẹ́rìí kan kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀tá wa rò pé àwọn tí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. Àmọ́ ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀.” Nínú àwọn ìjọ tó pọ̀ jù lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tó kópa nínú iṣẹ́ náà lọ́jọ́ yẹn lé ní ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún, àwọn kan lò tó wákàtí mẹ́wàá, méjìlá, tàbí mẹ́rìnlá pàápàá nínú ìgbòkègbodò yìí. Nílùú Hem ní àríwá ilẹ̀ Faransé, lẹ́yìn iṣẹ́ alẹ́ tí Ẹlẹ́rìí kan ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà láti aago márùn-ún àárọ̀ títí di aago mẹ́ta ọ̀sán. Nílùú Denain tó wà nítòsí ibẹ̀, tí ìjọ ti wà láti ọdún 1906, àwọn Ẹlẹ́rìí márùndínlọ́gọ́rin lo igba wákàtí láti pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ́jọ́ Friday. Àwọn ẹlòmíì pẹ̀lú pinnu láti kópa nínú iṣẹ́ náà, láìfi ọjọ́ ogbó, àìsàn, àti ojú ọjọ́ tó dágùdẹ̀ pè. Fún àpẹẹrẹ, nílùú Le Mans, àwọn obìnrin mẹ́ta kan tí wọ́n ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún lo wákàtí méjì lẹ́nu fífi ìwé àṣàrò kúkúrú náà sínú àpótí táwọn èèyàn ti ń gba lẹ́tà, Ẹlẹ́rìí kan tó wà nínú àga onítáyà sì ń pín in fúnni níwájú ibùdókọ̀ ojú irin. Ẹ sì wo bó ti fúnni níṣìírí tó láti rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti dẹwọ́ tẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àkànṣe yìí!

Láìsí àní-àní, pípín ìwé àṣàrò kúkúrú yìí kiri yọrí sí ẹ̀rí ńláǹlà. Àwọn èèyàn látinú onírúurú ipò nínú ìgbésí ayé, tí a kì í sábàá bá nílé, rí ẹ̀dà ìwé náà gbà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé kì í ṣe ire tàwọn Ẹlẹ́rìí nìkan ni ìgbòkègbodò yìí máa jà fún. Ọ̀pọ̀ rí i gẹ́gẹ́ bí gbígbèjà òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ìjọsìn fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Faransé. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti fi ti èyí lẹ́yìn, ńṣe làwọn èèyàn ń béèrè fún ẹ̀dà púpọ̀ sí i, kí àwọn náà lè pín in fún àwọn ọ̀rẹ́, ojúgbà, tàbí àwọn ẹbí wọn.

Ní tòótọ́, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Faransé dùn láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀, kí wọ́n sì gbèjà ire Ìjọba rẹ̀. (1 Pétérù 3:15) Ó jẹ́ ìfẹ́ wọn àtọkànwá pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà,” àti pé kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún sí i wá dara pọ̀ mọ́ wọn nínú yíyin Jèhófà, Baba wọn ọ̀run.—1 Tímótì 2:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú ìgbòkègbodò kan náà wáyé ní January 1999 láti fi hàn pé a ò fara mọ́ ìwà ṣíṣe kèéta ẹ̀sìn míì. Wo Ilé Ìṣọ́, August 1, 1999, ojú ìwé 9, àti 2000 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 24 sí 26.