Bóo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání
Bóo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání
ÒMÌNIRA láti ṣe ohun tó wù wá jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Láìsí òmìnira yìí, bóyá la fi máa yàtọ̀ sí ẹ̀rọ lásán, tí kò lè dánú rò. Àmọ́ òmìnira yìí tún ní ìpèníjà tirẹ̀. Níní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá máa ń jẹ́ kó di dandan fún wa láti ṣe àwọn ìpinnu nínú ìgbésí ayé.
A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìpinnu ni kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n àwọn ìpinnu míì, gẹ́gẹ́ bí irú iṣẹ́ táa fẹ́ ṣe, àti bóyá a ó ṣègbéyàwó tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, lè nípa lórí gbogbo ọjọ́ ọ̀la wa. Àwọn ìpinnu míì tún wà tó máa ń kan àwọn ẹlòmíì. Àwọn ìpinnu kan táwọn òbí ń ṣe máa ń kan àwọn ọmọ wọn gbọ̀ngbọ̀n. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a ní láti jíhìn fún Ọlọ́run nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpinnu táa ṣe.—Róòmù 14:12.
A Ń Fẹ́ Ìrànlọ́wọ́
Àkọsílẹ̀ fi hàn pé àṣìṣe pọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìpinnu tọ́mọ ẹ̀dá ti ṣe. Ọ̀kan lára ìpinnu àkọ́kọ́ pàá téèyàn ṣe ló kó o sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Éfà pinnu pé òun máa jẹ lára èso tí Ọlọ́run dìídì kà léèwọ̀. Ìpinnu rẹ̀, tó dá lórí ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan, mú kí ọkọ rẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì yọrí sí ìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ fáráyé. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn ṣì ń gbé ìpinnu wọn ka ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan dípò kí wọ́n gbé e ka àwọn ìlànà títọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6-19; Jeremáyà 17:9) Nígbà táa bá sì dojú kọ àwọn ìpinnu pàtàkì, a kì í sábàá mọ èwo ni ṣíṣe.
Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń fọ̀ràn lọ àwọn ẹ̀dá tó ga ju ènìyàn lọ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tó di dandan pé kí Nebukadinésárì ṣe ìpinnu kan lójú ogun. Ọba ni lóòótọ́, àmọ́ ó “yíjú sí iṣẹ́ wíwò,” ó lọ fọ̀ràn lọ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Nítorí náà, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó mi àwọn ọfà. Ó fi ère tẹ́ráfímù béèrè; ó wo inú ẹ̀dọ̀.” (Ìsíkíẹ́lì 21:21) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ló rí lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fọ̀ràn lọ àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àti awòràwọ̀, wọ́n sì tún ń lo àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ẹ̀tàn àti ìṣìnà ló máa ń yọrí sí.—Léfítíkù 19:31.
Ẹnì kan wà tó ṣeé gbára lé pátápátá, tó sì ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu ọlọgbọ́n jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Jèhófà Ọlọ́run ni ẹni táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Fún àpẹẹrẹ, láyé ọjọ́un, Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, orílẹ̀-èdè rẹ̀, ní Úrímù àti Túmímù—tó ṣeé ṣe kó jẹ́ kèké mímọ́ tí wọ́n ń ṣẹ́ nígbà tí ọ̀ràn bá fẹ́ dojú rú ní orílẹ̀-èdè náà. Jèhófà máa ń tipasẹ̀ Úrímù àti Túmímù dáhùn àwọn ìbéèrè wọn ní tààràtà, ó sì máa ń tipasẹ̀ kèké wọ̀nyí ran àwọn alàgbà Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti rí i dájú pé ìpinnu wọn wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ òun.—Ẹ́kísódù 28:30; Léfítíkù 8:8; Númérì 27:21.
Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n ní kí Gídíónì kó àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, kó lọ bá Mídíánì jà, ó ní láti pinnu bóyá kí òun tẹ́wọ́ gba àǹfààní ńláǹlà yìí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Gídíónì fẹ́ Àwọn Onídàájọ́ 6:33-40; 7:21, 22.
mọ̀ dájú bóyá Jèhófà á ti òun lẹ́yìn, fún ìdí yìí ó béèrè fún àmì. Ó gbàdúrà pé kí ìrì sẹ̀ sára ìṣùpọ̀ irun tó gbé síta mọ́jú, àmọ́ kí ìrì má sẹ̀ sórí ilẹ̀ tó yí i ká. Ní òru ọjọ́ kejì, ó bẹ̀bẹ̀ pé kí ìrì má sẹ̀ sára ìṣùpọ̀ irun náà, ṣùgbọ́n kí ó sẹ̀ sórí ilẹ̀ tó yí i ká. Jèhófà fi inú rere pèsè àwọn àmì tí Gídíónì béèrè. Nípa báyìí, Gídíónì ṣe ìpinnu tó tọ́, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì pátápátá, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.—Lónìí Ńkọ́?
Lónìí, Jèhófà ṣì ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Lọ́nà wo? Ṣé kí àwa náà máa béèrè fún ‘iṣẹ́ ìyanu ìṣùpọ̀ irun’ ni, ìyẹn àmì látọ̀dọ̀ Jèhófà láti tọ́ wa sọ́nà? Tọkọtaya kan ń ronú nípa bóyá kí àwọn lọ sìn níbi táa ti fẹ́ kí àwọn oníwàásù Ìjọba náà túbọ̀ pọ̀ sí i. Kí ó lè rọrùn fún wọn láti ṣèpinnu, wọ́n ṣètò ìdánwò kan. Wọ́n polówó ilé wọn, pé àwọn fẹ́ tà á ní iye kan. Bí wọ́n bá rí ilé yẹn tà ní ọjọ́ báyìí-báyìí, ní iye tí wọ́n fẹ́ tà á tàbí ní iye tó jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n á kà á sí pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n lọ nìyẹn. Bí wọn ò bá rí ilé yẹn tà, wọ́n á parí èrò sí pé Ọlọ́run kò fẹ́ káwọn lọ nìyẹn.
Wọn ò rí ilé yẹn tà. Ṣé àmì pé Jèhófà kò fẹ́ kí tọkọtaya yìí lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ni? Tóò, yóò jẹ́ ìkọjá àyè ẹni láti sọ ṣàkó pé ohun báyìí ni Jèhófà ń ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tàbí pé ohun báyìí ni kì í ṣe fún wọn. A ò lè sọ pé Jèhófà kì í dá sí ọ̀ràn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí láti jẹ́ ká mọ ohun tí òun fẹ́. (Aísáyà 59:1) Àmọ́ o, a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti retí kí Ọlọ́run dá sí àwọn ìpinnu pàtàkì táa fẹ́ ṣe, kí ó wá dà bíi pé à ń ti àwọn ìpinnu tó yẹ ká ṣe sí Ọlọ́run lọ́rùn. Kódà ní ti Gídíónì, ṣebí òun ló fúnra rẹ̀ ṣe àwọn ìpinnu tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa dúró de àmì látọ̀dọ̀ Jèhófà!
Àmọ́ o, Bíbélì sọ pé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Nígbà táa bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, kò sóhun tó burú rárá nínú wíwá ọ̀nà láti rí i dájú pé àwọn ìpinnu wa wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ títayọ hàn. Lọ́nà wo? Nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí a sì jẹ́ kí ó jẹ́ ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wa, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa.’ (Sáàmù 119:105; Òwe 2:1-6) Láti ṣe èyí, a ní láti jẹ́ kí ó mọ́ wa lára láti máa gba ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì. (Kólósè 1:9, 10) Nígbà táa bá sì fẹ́ ṣe ìpinnu kan, a ní láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò gbogbo ìlànà Bíbélì tó jẹ mọ́ ọ̀ràn náà. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká mọ “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:9, 10.
Ó sì yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò gbọ́ wa. Ẹ wo bó ti ń tuni nínú tó láti ṣàlàyé ìpinnu táa fẹ́ ṣe fún Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, ká sì jẹ́ kó mọ onírúurú ìgbésẹ̀ tí à ń ronú àtigbé! Lẹ́yìn náà, a lè wá fi ìgbọ́kànlé béèrè pé kó tọ́ wa sọ́nà ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀mí mímọ́ máa ń rán wa létí àwọn ìlànà Bíbélì tó wé mọ́ ọ̀ràn náà, tàbí kí ó jẹ́ ká túbọ̀ lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tan mọ́ ipò wa.—Jákọ́bù 1:5, 6.
Jèhófà tún ń pèsè àwọn tó dàgbà dénú nínú ìjọ táa lè bá jíròrò àwọn ìpinnu wa. (Éfésù ) Àmọ́, táa bá fẹ́ fọ̀ràn lọ ẹlòmíì, kò ní dáa ká máa ṣe bíi ti àwọn tó máa ń lọ látọ̀dọ̀ ẹnì kan sọ́dọ̀ ẹlòmíì, títí wọ́n á fi rí ẹni tó máa sọ ohun tí wọ́n ń retí àtigbọ́. Wọ́n á wá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onítọ̀hún. Ó tún yẹ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rèhóbóámù kọ́ wa lọ́gbọ́n. Nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan, àwọn àgbààgbà tó ń fún bàbá rẹ̀ nímọ̀ràn gbà á nímọ̀ràn tó dáa gan-an. Ṣùgbọ́n, kàkà tí ì bá fi tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn, ó lọ bá àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jọ dàgbà. Ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn, ó ṣe ìpinnu tó burú jáì, bó ṣe pàdánù èyí tó pọ̀ jù nínú ìjọba rẹ̀ nìyẹn.— 4:11, 121 Àwọn Ọba 12:1-17.
Nígbà táa bá ń wá ìmọ̀ràn, ọ̀dọ̀ àwọn tó ní ìrírí nínú ìgbésí ayé, tí wọ́n mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, tí wọ́n sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn ìlànà òdodo ni ká wá ìmọ̀ràn lọ. (Òwe 1:5; 11:14; 13:20) Tó bá ṣeé ṣe, wá àkókò láti ṣàṣàrò lórí àwọn ìlànà tó jẹ mọ́ ọ̀ràn náà, àti lórí gbogbo ìsọfúnni tóo ti kó jọ. Bóo bá fi ojú tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi wo ọ̀ràn náà wò ó, yóò rọrùn fún ọ láti ṣe ìpinnu tó tọ́.—Fílípì 4:6, 7.
Àwọn Ìpinnu Táa Ń Ṣe
Àwọn ìpinnu kan rọrùn-ún ṣe. Nígbà tí wọ́n pàṣẹ pé káwọn àpọ́sítélì ṣíwọ́ jíjẹ́rìí, wọ́n mọ̀ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù nípa Jésù dúró, ìyẹn ló fi jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sọ ìpinnu wọn fún Sànhẹ́dírìn pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò ènìyàn. (Ìṣe 5:28, 29) Àwọn ìpinnu mìíràn lè béèrè àròjinlẹ̀ nítorí pé kò sí gbólóhùn kan pàtó lórí ọ̀ràn náà nínú Bíbélì. Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní ṣàìsí àwọn ìlànà Bíbélì tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa jù lọ. Fún àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ eré ìnàjú tó wà lónìí ni kò sí nígbà ayé Jésù, síbẹ̀ àwọn gbólóhùn kan tó ṣe kedere wà nínú Bíbélì nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Kristẹni èyíkéyìí tó bá ń lọ́wọ́ sí eré ìnàjú tó ń gbé ìwà ipá, ìṣekúṣe, tàbí ìwà ọ̀tẹ̀ lárugẹ, ti ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání.—Sáàmù 97:10; Jòhánù 3:19-21; Gálátíà 5:19-23; Éfésù 5:3-5.
Nígbà míì, ó lè jẹ́ ìpinnu méjèèjì ló tọ̀nà. Sísìn níbi tí àìní gbé pọ̀ jẹ́ àgbàyanu àǹfààní, ó sì lè yọrí sí àwọn ìbùkún ńláǹlà. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá pinnu pé òun ò ní lè lọ nítorí ìdí kan tàbí òmíràn, ó ṣì lè máa ṣe iṣẹ́ àtàtà nínú ìjọ rẹ̀ nílé. Nígbà míì, a lè fẹ́ ṣe ìpinnu tí yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fi bí ìfọkànsìn wa sí Jèhófà ti jinlẹ̀ tó hàn tàbí láti fi ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa hàn. Nípa báyìí, Jèhófà máa ń yọ̀ǹda fún wa láti lo òmìnira tó fún wa láti ṣe ohun tó wù wá, kí ó lè mọ ohun tó wà nínú ọkàn wa gan-an.
Àìmọye ìgbà ni ìpinnu wa máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, inú àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dùn pé àwọn bọ́ lọ́wọ́ Òfin tó ká wọn lọ́wọ́ kò lóríṣiríṣi ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ó túmọ̀ sí pé wọ́n lè yàn láti jẹ oúnjẹ tí Òfin sọ pé ó jẹ́ aláìmọ́ tàbí kí wọ́n máà jẹ ẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, a rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bóyá kí àwọn lo òmìnira yìí tàbí kí àwọn má lò ó. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ lórí ọ̀ràn náà kan ọ̀pọ̀ ìpinnu tí à ń ṣe lónìí, ó ní: “Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì ) Ìfẹ́ láti má ṣe mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀pọ̀ ìpinnu tó yẹ ní ṣíṣe. Ó ṣe tán, ìfẹ́ fún aládùúgbò ni àṣẹ kejì tó tóbi jù lọ.— 10:32Mátíù 22:36, 39.
Ìyọrísí Àwọn Ìpinnu Wa
Àwọn ìpinnu táa fi ẹ̀rí ọkàn rere ṣe, táa sì gbé ka àwọn ìlànà Bíbélì yóò ní àbájáde rere, bó pẹ́ bó yá. Àmọ́ ní báyìí ná, ó lè kó ìyà jẹ wá. Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì sọ fún Sànhẹ́dírìn pé ìpinnu àwọn ni láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nípa Jésù nìṣó, wọ́n nà wọ́n lọ́rẹ́ kí wọ́n tó tú wọn sílẹ̀. (Ìṣe 5:40) Nígbà táwọn Hébérù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò—pinnu pé àwọn ò ní tẹrí ba fún ère wúrà Nebukadinésárì, ńṣe ni wọ́n fi ẹ̀mí wọn wewu. Wọ́n múra tán láti dojú kọ òtítọ́ náà pé ìpinnu tí wọ́n ṣe lè mú ikú lọ́wọ́. Àmọ́ wọ́n mọ̀ pé inú Ọlọ́run yóò dùn sí wọn, yóò sì bù kún wọn.—Dáníẹ́lì 3:16-19.
Báa bá dojú kọ àwọn ìṣòro lẹ́yìn táa bá ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn wa mu, ìyẹn kì í ṣe ìdí láti wá máa rò pé ìpinnu táa ṣe lòdì. “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” lè mú kí ìpinnu tó dáa jù lọ pàápàá forí ṣánpọ́n. (Oníwàásù 9:11) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà míì Jèhófà máa ń jẹ́ kí a rí ìpọ́njú, kí ó lè dán ìdúróṣinṣin wa wò. Jékọ́bù wọ̀yá ìjà pẹ̀lú áńgẹ́lì kan láti òru mọ́jú kí áńgẹ́lì yẹn tó súre fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 32:24-26) Ó lè di dandan kí àwa náà fàyà rán ìṣòro, kódà nígbà tó jẹ́ pé ohun tó tọ́ là ń ṣe. Ṣùgbọ́n bí ìpinnu wa bá wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ìdánilójú wà pé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á, yóò sì bù kún wa nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Fún ìdí yìí, tóo bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, má ṣe gbára lé ọgbọ́n ara rẹ. Wá àwọn ìlànà tó tan mọ́ ọn kàn nínú Bíbélì. Bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Bó bá ṣeé ṣe, fọ̀ràn lọ àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú. Sì jẹ́ onígboyà. Fi làákàyè lo òmìnira tí Ọlọ́run fún ọ láti ṣe ohun tó wù ọ́. Ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kí o sì jẹ́ kí ó hàn kedere sí Jèhófà pé gbágbáágbá ni ọkàn rẹ wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kóo tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
Bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpinnu tóo fẹ́ ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
O lè bá àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpinnu pàtàkì tóo fẹ́ ṣe