Máa Dúpẹ́ Kóo sì Máa Yọ̀
Máa Dúpẹ́ Kóo sì Máa Yọ̀
“ÌWÉ ìròyìn Kánádà kan táa ń pè ní Calgary Herald, sọ pé: “Mímọ ọpẹ́ẹ́ dá jẹ́ ànímọ́ àdánidá.” Ìwé ìròyìn Herald náà fa ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tí wọ́n ń lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yọ, àwọn tí olùkọ́ wọn sọ pé kí wọ́n kọ̀wé nípa gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ dúpẹ́ fún. Ọmọ kan sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ ìdílé òun ‘torí pé wọ́n tọ́jú òun.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọmọdébìnrin mìíràn dúpẹ́ nítorí ìdílé rẹ̀, ó ní: “Wọ́n ń dáàbò bò mí, wọn ò fi ìlera mi ṣeré, wọ́n ń tọ́jú mi, wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n ń bọ́ mi, bí kì í bá sì í ṣe tàwọn òbí mi ni, mi ò ní sí láyé yìí.”
Yíya abaraá-móore-jẹ máa ń jẹ́ kéèyàn máa ráhùn ṣáá ni. Gẹ́gẹ́ bí J. I. Packer, tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, ti wí, “a dá wa láti gbára lé Ọlọ́run, ká sì gbára lé ara wa lẹ́nì kìíní kejì.” Èyí rán wa létí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Bíbélì gbà wá ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, pé: “Ẹ . . . fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Fífi ìdúpẹ́ àti ìmoore àtọkànwá hàn fáwọn ẹlòmíràn máa ń jẹ́ ká mú àjọṣe onífẹ̀ẹ́ dàgbà.
Síwájú sí i, nípa mímọrírì àti mímọyì ara wa lẹ́nì kìíní kejì, a tún ń fi hàn pé a ń moore Jèhófà, ó sì ń kíyè sí èyí. Bíbélì sọ pé: “Ojú [Jèhófà] ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé òun ò jẹ́ gbàgbé ìfẹ́ táwọn èèyàn ń fi hàn fún orúkọ òun, òun sì mọrírì rẹ̀. (Hébérù 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, a ní ìdí gúnmọ́ láti jẹ́ ẹni tó mọ ọpẹ́ẹ́ dá, nítorí pé táa bá ń fi ànímọ́ rere yìí hàn lójoojúmọ́, inú Jèhófà yóò máa dùn, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò sì máa fi kún ayọ̀ wa. Gẹ́gẹ́ bí Òwe 15:13 ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú máa ń ní ipa rere lórí ìrísí.”