Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Èṣù Wà?

Ǹjẹ́ Èṣù Wà?

Ǹjẹ́ Èṣù Wà?

“Ìgbà kan wà nínú ìtàn, tí Ìjọ Kristẹni ka èṣù, Béélísébúbù tàbí Sátánì, baba bìlísì, sí ẹni gidi, tó wà lóòótọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tó ń dín kù sí i lónìí ṣe gbà pé ‘Ọlọ́run’ wà; àwọn Júù àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ló hùmọ̀ èṣù láti fi ṣàlàyé ìwà ẹhànnà tí wọ́n rí táwọn ọmọ adáríhurun ń hù láyìíká wọn. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn làwọn Kristẹni wá rí i pé kò sóhun tó ń jẹ́ èṣù níbì kankan, bí wọ́n ṣe rọra gbẹ́nu dákẹ́ lórí ọ̀ràn èṣù nìyẹn.”—“All in the Mind—A Farewell to God,” látọwọ́ Ludovic Kennedy.

GẸ́GẸ́ bí Ludovic Kennedy tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti oníròyìn ṣe wí, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni kò fi sí ẹnikẹ́ni nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù tó ṣiyèméjì nípa bóyá Èṣù wà lóòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Norman Cohn sọ pé ńṣe làwọn Kristẹni sábà “máa ń bẹ̀rù agbára Sátánì àti tàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.” (Europe’s Inner Demons) Ìbẹ̀rù yìí kò mọ sọ́dọ̀ àwọn gbáàtúù tó jẹ́ púrúǹtù nìkan. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Cohn tún sọ pé, ìgbàgbọ́ náà pé Èṣù gbé àwọ̀ ẹranko wọ̀, tó sì wá ń darí àwọn ààtò burúkú tó kún fún ìwàkiwà, “kò pilẹ̀ṣẹ̀ látinú ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé táwọn gbáàtúù tí kò kàwé ń sọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó pilẹ̀ṣẹ̀ látẹnu àwọn ọ̀tọ̀kùlú amòye.” Àwọn “ọ̀tọ̀kùlú amòye” wọ̀nyí—títí kan àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé—ló wà nídìí dídọdẹ àwọn àjẹ́ kiri ní ilẹ̀ Yúróòpù láti ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún sí ìkẹtàdínlógún, láàárín àkókò tí ìtàn sọ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aláṣẹ ìlú dá nǹkan bíi ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] àwọn èèyàn tí wọ́n pè ní àjẹ́ lóró, tí wọ́n sì pa wọ́n.

Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń di etí wọn sí àwọn èròǹgbà tí wọ́n gbà pé kò bọ́gbọ́n mu rárá nípa Èṣù. Lẹ́yìn lọ́hùn-ún lọ́dún 1726 pàápàá, ńṣe ni Daniel Defoe máa ń fi àwọn èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí wọ́n bá sọ pé Èṣù rí bí iwin “tó ní ìyẹ́ àdán, tó hùwo lórí, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ la pátákò, tó ní ìrù gígùn, tó ní ahọ́n aláwẹ́ méjì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.” Ó sọ pé “àwọn tó ń pe èṣù ní ẹbọra” ló ń hùmọ̀ irú “àwọn èrò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀” bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì “ń fi èṣù tí wọ́n hùmọ̀ rẹ̀ tan àwọn aláìmọ̀kan ayé jẹ.”

Ṣé èrò tìrẹ náà nìyẹn? Ṣé ìwọ náà gbà pé “èèyàn ló hùmọ̀ èṣù ní ti gidi, láti rí nǹkan fi ṣàlàyé jíjẹ́ tí èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀”? Inú ìwé náà, The Zondervan Pictorial Encyclopedia of the Bible ni gbólóhùn yẹn ti jáde, ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ló sì gbà bẹ́ẹ̀. Jeffrey Burton Russell sọ pé lápapọ̀, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ti “jánu lórí ọ̀ràn Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù báyìí, wọ́n ló ti di àgbọ̀nrín èṣí tí kò yẹ ká tún máa jẹ lọ́bẹ̀.”

Àmọ́ lójú àwọn kan, Èṣù wà ní ti gidi. Èrò tiwọn ni pé ará ọ̀run kan, tó jẹ́ olubi, ló ní láti wà nídìí ọ̀pọ̀ ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ léraléra nínú ìtàn aráyé. Russell sọ pé “àwọn nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún” jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tí “ìgbàgbọ́ nínú Èṣù fi padà wáyé, lẹ́yìn táwọn èèyàn ti dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀ tipẹ́.” Òǹkọ̀wé nì, Don Lewis, sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé lóde òní, tí wọ́n “ń tẹ́ńbẹ́lú” àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìbẹ̀rù “àwọn baba ńlá wọn aláìlajú” ló wá di ẹni tí “ìgbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà nídìí àwọn ìwà ibi tún ń gbà lọ́kàn báyìí.”—Religious Superstition Through the Ages.

Kí wá ni òótọ́ ọ̀rọ̀ gan-an? Ṣé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni pé Èṣù wà? Tàbí kẹ̀, ṣé ẹnì kan tí a kò gbọ́dọ̀ kóyán rẹ̀ kéré ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí pàápàá ni?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Gẹ́gẹ́ bí àwòrán yìí tí Gustave Doré fín ti fi hàn, àwọn ìtàn àròsọ ayé ọjọ́un fi Èṣù hàn bí apá kan èèyàn apá kan ẹranko

[Credit Line]

The Judecca—Lucifer/The Doré Illustrations For Dante’s Divine Comedy/Dover Publications Inc.