Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àpéjọpọ̀—Àkókò Aláyọ̀ Tó Ń Fi Hàn Dájú Pé A Ní Ẹgbẹ́ Àwọn Ará

Àwọn Àpéjọpọ̀—Àkókò Aláyọ̀ Tó Ń Fi Hàn Dájú Pé A Ní Ẹgbẹ́ Àwọn Ará

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

Àwọn Àpéjọpọ̀—Àkókò Aláyọ̀ Tó Ń Fi Hàn Dájú Pé A Ní Ẹgbẹ́ Àwọn Ará

JOSEPH F. RUTHERFORD, ẹni àádọ́ta ọdún, tó di aláìlera lẹ́yìn tó lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi èrú jù ú sí, ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣèránṣẹ́ fáwọn àlejò. Ó ń fi tokunratokunra gbé àwọn àpótí ẹrù, ó sì ń mú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sí inú yàrá òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ṣètò fún wọn. Méjì lára àwọn tí wọ́n jọ ṣẹ̀wọ̀n—tí wọ́n jẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi tirẹ̀—ń ṣètò yàrá fún ọ̀pọ̀ èrò tó ń retí àtimọ ibi táa fẹ́ fi wọ́n wọ̀ sí. Gbogbo ìgbòkègbodò náà ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ńṣe ni gbogbo wọn ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ tínú wọn sì ń dùn ṣìnkìn. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn ná?

Ọdún 1919 ni, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (táa mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí) ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ́ lọ́wọ́ sáà inúnibíni líle koko tí wọ́n gbé dìde sí wọn ni. Láti mú ẹgbẹ́ ará wọn sọjí padà, wọ́n ṣe àpéjọpọ̀ kan ní Cedar Point, Ohio, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, láti September 1 sí 8, 1919. Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ènìyàn ló tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí gba àwọn tó pé jọ pọ̀ náà níyànjú pé: “Ẹ̀yin ni ikọ̀ fún Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa, tó ń kéde . . . ìjọba ológo ti Olúwa wa fún àwọn ènìyàn.”

Láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà, àpéjọpọ̀ jẹ́ ohun tí wọ́n ti ń ṣe láti àkókò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Ẹ́kísódù 23:14-17; Lúùkù 2:41-43) Irú àwọn àpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ àkókò aláyọ̀, tó ń ran gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ láti pa ọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bákan náà ni àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní máa ń dá lórí ire tẹ̀mí. Lójú àwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń wòran wọn, irú àpéjọpọ̀ aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ń fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé ìdè lílágbára ti ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni ló so àwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ ṣọ̀kan.

Ìsapá Láti Wá Síbẹ̀

Àwọn Kristẹni òde òní mọ̀ pé àwọn àpéjọpọ̀ wọn jẹ́ àkókò fún ìtura àti ìtọ́ni tẹ̀mí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ka àwọn ìpàdé ńlá wọ̀nyí sí àwọn ọ̀nà pàtàkì kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ‘dúró lọ́nà pípè pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.’ (Kólósè 4:12) Abájọ táwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi tọkàntọkàn kọ́wọ́ ti àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí lẹ́yìn, tí wọ́n máa ń sapá gidigidi láti wá sí àpéjọpọ̀ náà.

Fún àwọn kan, wíwà ní irú àwọn àpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ béèrè pé kí wọ́n lo ìgbàgbọ́, kí wọ́n sì borí ọ̀pọ̀ òkè ìṣòro. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn àgbàlagbà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Austria yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àrùn àtọ̀gbẹ, tó sì ní láti máa gba abẹ́rẹ́ insulin lójoojúmọ́, ó rí i dájú pé òun lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n fi ṣe é lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Ní Íńdíà, ìdílé ńlá kan tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n wà nípò òṣì paraku, rí i pé ó máa nira gan-an láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan. Ọ̀kan lára mẹ́ńbà ìdílé ọ̀hún ló yanjú ìṣòro náà. Ó sọ pé: “Kí a bàa lè lọ sí àpéjọpọ̀ náà, mo ta yẹtí oníwúrà tí mo ní, ká lè rówó táa nílò fún ìrìn àjò náà. Ìnáwó yìí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àti àwọn ohun táa rí níbẹ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lókun.”

Ní Papua New Guinea, àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn kan tí kò tíì ṣe batisí pinnu láti wá sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ní olú ìlú wọn. Wọ́n lọ bá ọkùnrin kan tó ní ọkọ̀ èrò ní abúlé wọn, wọ́n sì béèrè iye tó máa gbà láti gbé wọn débi àpéjọpọ̀ náà. Nígbà tí wọ́n rí i pé iye tó fẹ́ gbà kọjá agbára àwọn, wọ́n ṣètò láti ṣiṣẹ́ nílé ọkùnrin náà, wọ́n bá a tún ilé ìdáná rẹ̀ kọ́. Ọgbọ́n tí wọ́n dá tí wọ́n fi lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè náà nìyẹn o, tí wọ́n sì jàǹfààní fífetí sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Ọ̀nà jíjìn kì í ṣe ìṣòro tí kò ṣeé borí fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá fẹ́ lọ sí àpéjọpọ̀. Ní 1978, ọ̀dọ́kùnrin kan tó wá láti Poland fi kẹ̀kẹ́ rin ìrìn àjò ẹgbẹ̀fà [1,200] kìlómítà fún ọjọ́ mẹ́fà gbáko, láti dé ibi àpéjọpọ̀ kan tí wọ́n ṣe ní Lille, ilẹ̀ Faransé. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1997, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì láti Mongolia rin ìrìn àjò ẹgbẹ̀fà [1,200] kìlómítà kí wọ́n lè wà níbi àpéjọpọ̀ Kristẹni tí wọ́n ṣe ní Irkutsk, Rọ́ṣíà.

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Ní Ti Gidi

Ìṣọ̀kan àti ẹ̀mí ará táwọn Ẹlẹ́rìí ń fi hàn láwọn àpéjọpọ̀ wọn hàn kedere sí àwọn òǹwòran tí kò ní ẹ̀tanú. Ó ti wú ọ̀pọ̀ ènìyàn lórí pé kò sí ojúsàájú láàárín àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ náà, kódà ojúlówó ọ̀yàyà wà láàárín àwọn tó bára wọn pàdé fún ìgbà àkọ́kọ́ pàápàá.

Ní àkókò àpéjọpọ̀ àgbáyé kan ní Ọsirélíà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, afinimọ̀nà tó lo ọ̀sẹ̀ kan pẹ̀lú àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ tí wọ́n tún fẹ́ mọ̀lú lọ, fẹ́ túbọ̀ dúró tì wọ́n fúngbà díẹ̀ sí i, kó lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wọn. Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn wú u lórí gan-an, ó sì yà á lẹ́nu pé wọ́n ń bára wọn ṣe nǹkan pọ̀ báyẹn, nígbà tó jẹ́ pé wọn ò mọra rí. Nígbà tó fẹ́ máa lọ, ó lóun fẹ́ bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀. Ó pè wọ́n ní “arákùnrin àti arábìnrin,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, àmọ́ kò lè parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó tó di pé ẹkún ń gbọ̀n ọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

Ní 1997, Sri Lanka ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè elédè mẹ́ta rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ibi ìṣeré ìdárayá ńlá kan. Gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni wọ́n ṣe nígbà kan náà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè Sinhalese, àti Tamil. Nínú ayé tí pákáǹleke ẹlẹ́yàmẹ̀yà ti túbọ̀ ń pọ̀ sí i yìí, kò sí bi irú àpéjọpọ̀ elédè mẹ́ta bẹ́ẹ̀ kò ṣe ní gba àfiyèsí. Ọlọ́pàá kan bi arákùnrin kan pé: “Ta ló ń darí àpéjọpọ̀ yìí, ṣé àwọn Sinhalese ni, àbí àwọn Tamil, tàbí àwọn Gẹ̀ẹ́sì?” Arákùnrin náà fèsì pé: “Kò sí èyí tó ń darí rẹ̀ nínú wọn. Gbogbo wa la jọ ń ṣe é pa pọ̀.” Ohun tí ọlọ́pàá náà gbọ́ yà á lẹ́nu. Nígbà tí àwọn tó ń sọ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà jùmọ̀ gba àdúrà ìparí pa pọ̀, tí “Àmín” tí gbogbo wọn jùmọ̀ ṣe sì dún jákèjádò ibi ìṣeré ìdárayá náà, ńṣe làwọn tó pé jọ pọ̀ náà kàn bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́. Bóyá la fi rí ẹnì kan tí kò da omi lójú nínú wọn. Dájúdájú, àwọn àpéjọpọ̀ jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó ń fi hàn dájú pé a ní ẹgbẹ́ àwọn ará ní tòótọ́.—Sáàmù 133:1 a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ojú ìwé 66 sí 77, àti 254 sí 282 nínú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.