Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbùkún Jèhófà Ní í Sọ Wá Dọlọ́rọ̀

Ìbùkún Jèhófà Ní í Sọ Wá Dọlọ́rọ̀

Ìbùkún Jèhófà Ní í Sọ Wá Dọlọ́rọ̀

“Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—ÒWE 10:22.

1, 2. Èé ṣe tí ayọ̀ kò fi ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú dúkìá?

 ERÉ àtilà ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń sá kiri lónìí. Àmọ́ ǹjẹ́ àwọn nǹkan tara ń fún wọn láyọ̀? Ìwé ìròyìn The Australian Women’s Weekly sọ pé: “Mi ò rí i kí àwọn èèyàn ro ara wọn pin tó báyìí rí.” Ó wá fi kún un pé: “Kàyéfì gbáà ni. Ṣebí wọ́n sọ fún wa pé Ọsirélíà ò rí towó ṣe tó báyìí rí, ṣebí wọ́n ní ayé ò yẹ àwọn èèyàn ibẹ̀ tó báyìí rí. . . . Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà ńkọ́, ọ̀ràn ayé ọ̀hún ti sú àwọn èèyàn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin rí i pé nǹkan kan sọnù nínú ìgbésí ayé àwọn, ṣùgbọ́n ohun tí nǹkan ọ̀hún jẹ́ gan-an, wọn ò mọ̀ ọ́n.” Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ohun ìní wa kọ́ ní í fún wa láyọ̀ tàbí ìwàláàyè!—Oníwàásù 5:10; Lúùkù 12:15.

2 Bíbélì fi kọ́ wa pé ìbùkún Ọlọ́run ló ń mú ayọ̀ gíga jù lọ wá. Ìdí nìyẹn tí Òwe 10:22 fi sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Fífi ìwọra kó àwọn nǹkan tara jọ sábà máa ń yọrí sí ìrora. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.

3. Kí nìdí tí àdánwò fi ń dé bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run?

3 Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ìbùkún tí kì í fa ìrora máa ń dé bá àwọn tó “ń bá a nìṣó láti máa fetí sí ohùn Jèhófà.” (Diutarónómì 28:2) Àmọ́ o, àwọn kan lè béèrè pé, ‘Bí ìbùkún Jèhófà kì í bá mú ìrora lọ́wọ́, kí ló dé tí ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń jìyà?’ Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run kàn fàyè gba àwọn àdánwò tó ń bá wa ni. Ṣùgbọ́n ní ti gidi, Sátánì, àti ètò búburú rẹ̀, àti ẹ̀dá aláìpé táa jẹ́ ló ń fà wá sínú àdánwò. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Diutarónómì 32:4, 5; Jòhánù 15:19; Jákọ́bù 1:14, 15) Jèhófà ni orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Fún ìdí yìí, àwọn ìbùkún rẹ̀ kì í fa ìrora. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ọrẹ pípé tí ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run —Ẹ̀bùn Tí Kò Ṣeé Díye Lé Ni

4. Ìbùkún àti ẹ̀bùn aláìlẹ́gbẹ́ wo làwọn èèyàn Jèhófà ń gbádùn ní “àkókò òpin” yìí?

4 Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àkókò òpin” pé: “Ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” Àmọ́, ó fi kún un pé: “Àwọn ẹni burúkú kankan kì yóò sì lóye; ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:4, 10) Ẹ sáà rò ó wò ná! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—àgàgà àwọn àsọtẹ́lẹ̀—kún fún ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀ tí òye rẹ̀ kò fi lè yé àwọn ẹni burúkú, àmọ́ ó yé àwọn èèyàn Jèhófà. Ọmọ Ọlọ́run gbàdúrà pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Lúùkù 10:21) Ẹ wo irú ìbùkún ńlá tó jẹ́, pé a ní Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀, tí í ṣe ẹ̀bùn tí kò ṣeé díye lé, àti pé a wà lára àwọn tí Jèhófà ti fi ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí jíǹkí!—1 Kọ́ríńtì 1:21, 27, 28; 2:14, 15.

5. Kí ni ọgbọ́n jẹ́, báwo sì ni a ṣe lè ní in?

5 Ọpẹ́lọpẹ́ “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè,” láìsí i, a kò lè ní ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí. (Jákọ́bù 3:17) Ọgbọ́n jẹ́ fífi ìmọ̀ àti òye yanjú ìṣòro, kí á fi yẹra tàbí ká fi yàgò fún ewu, ká fi lé góńgó wa bá, tàbí ká fi fúnni ní ìmọ̀ràn yíyè kooro. Báwo la ṣe lè ní ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá? Òwe 2:6 sọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, báa bá ń gbàdúrà sí Jèhófà láìdábọ̀ pé kí ó fún wa ní ọgbọ́n, yóò fi ọgbọ́n jíǹkí wa, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fún Sólómọ́nì Ọba ní “ọkàn-àyà ọgbọ́n àti òye.” (1 Àwọn Ọba 3:11, 12; Jákọ́bù 1:5-8) Bí a óò bá jèrè ọgbọ́n, a gbọ́dọ̀ máa fetí sí Jèhófà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti fífi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò.

6. Èé ṣe tó fi jẹ́ ipa ọ̀nà ọgbọ́n láti fi àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé wa?

6 Àwọn àpẹẹrẹ títayọ nípa ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń bẹ nínú àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì. Ìwọ̀nyí sì ń ṣe wá láǹfààní ní gbogbo ọ̀nà—ìbáà jẹ́ nípa tara ni o, àti nípa ti èrò orí, àti nípa ti ìmí ẹ̀dùn, àti nípa tẹ̀mí. Lọ́nà tó bá a mu, onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀. Ìbẹ̀rù Jèhófà mọ́ gaara, ó wà títí láé. Àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́; òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀. Wọ́n yẹ ní fífẹ́ ju wúrà, bẹ́ẹ̀ ni, ju ọ̀pọ̀ wúrà tí a yọ́ mọ́.”—Sáàmù 19:7-10; 119:72.

7. Kí ni ṣíṣàìka ìlànà òdodo Ọlọ́run sí máa ń yọrí sí?

7 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tí kò ka ìlànà òdodo Ọlọ́run sí kì í láyọ̀, wọn kì í sí ì ní òmìnira tí wọ́n ń wá. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á rí i pé kò sẹ́ni tó lè gan Ọlọ́run kó sì mú un jẹ, torí pé ohun téèyàn bá gbìn ni yóò ká. (Gálátíà 6:7) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí kò ka ìlànà Bíbélì sí ló ń kàgbákò lóríṣiríṣi, bíi kí wọ́n lóyún ẹ̀sín, kí wọ́n kó àrùn burúkú, tàbí kí wọ́n di ẹni tí àwọn àṣàkaṣà kan ti di ara fún. Àfi bí wọ́n bá ronú pìwà dà, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí tọ ọ̀nà tó tọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ikú ni wọ́n fi ń ṣeré yẹn, ó sì lè yọrí sí ìparun pàápàá látọwọ́ Ọlọ́run.—Mátíù 7:13, 14.

8. Èé ṣe tí àwọn tó fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ń láyọ̀?

8 Ṣùgbọ́n àwọn tó bá fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi í sílò, yóò rí ìbùkún yàbùgà-yabuga nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Pẹ̀lú ìdí tó ṣe gúnmọ́, òfin Ọlọ́run ń fún wọn lómìnira, ayọ̀ kún inú wọn, wọ́n sì ń fi taratara dúró de ìgbà tí a óò dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó jẹ́ àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 8:20, 21; Jákọ́bù 1:25) Ìrètí yìí dájú, torí pé a gbé e ka ẹ̀bùn onífẹ̀ẹ́ gíga jù lọ tí Ọlọ́run fi fún aráyé—èyíinì ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23) Irú ẹ̀bùn títayọ bẹ́ẹ̀ fi hàn bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún ọmọ aráyé ti jinlẹ̀ tó, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ìbùkún aláìlópin ń dúró de gbogbo àwọn tó bá ń fetí sí Jèhófà.—Róòmù 8:32.

A Mọrírì Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

9, 10. Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà? Mú àpẹẹrẹ kan wá.

9 Ẹ̀bùn onífẹ̀ẹ́ mìíràn tí Ọlọ́run fún wa, tó yẹ ká mọrírì ni ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù rọ ogunlọ́gọ̀ àwọn tó pé jọ sí Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:38) Lóde òní, Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ń tọrọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:9-13) Láyé ọjọ́un, ipá alágbára gíga jù lọ lọ́run òun ayé—ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ tí í ṣe ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run—fún àwọn ọkùnrin àtobìnrin onígbàgbọ́ lágbára, títí kan àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. (Sekaráyà 4:6; Ìṣe 4:31) Ó lè fún àwa náà lágbára, bí àwa èèyàn Jèhófà tilẹ̀ dojú kọ àwọn ohun ìdènà tàbí òkè ìṣòro.—Jóẹ́lì 2:28, 29.

10 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Laurel yẹ̀ wò, ẹni tí àrùn rọpárọsẹ̀ ń ṣe, tó sì jẹ́ pé ẹ̀rọ ló fi ń mí fún ọdún mẹ́tàdínlógójì. a Láìka ipò ìṣòro lílé kenkà tí obìnrin yìí wà sí, ó fìtara sin Ọlọ́run títí dọjọ́ ikú rẹ̀. Ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn, ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ Jèhófà dé bá Laurel. Fún àpẹẹrẹ, ó ran èèyàn mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀rọ tó fi ń mí yẹn ló máa ń wà tọ̀sán tòru! Ọ̀ràn rẹ̀ ránni létí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́ríńtì 12:10) Dájúdájú, àṣeyọrí èyíkéyìí táa bá ní nínú wíwàásù ìhìn rere náà, kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe àti agbára wa, bí kò ṣe ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ tó máa ń fún àwọn tó bá ń fetí sí ohùn rẹ̀.—Aísáyà 40:29-31.

11. Àwọn ànímọ́ wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú kí àwọn tó ti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀ ní?

11 Báa bá ń fetí sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí elétí ọmọ, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) “Èso ti ẹ̀mí” yìí jẹ́ ara “àkópọ̀ ìwà tuntun” tí àwọn Kristẹni ń gbé wọ̀, dípò ìwà kàràǹbààní, ìwà ẹhànnà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀. (Éfésù 4:20-24; Aísáyà 11:6-9) Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú èso ti ẹ̀mí yìí ni ìfẹ́, tí í ṣe “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:14.

Ìfẹ́ Kristẹni—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Ni

12. Báwo ni Tàbítà àtàwọn Kristẹni mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní ṣe fìfẹ́ hàn?

12 Ìfẹ́ Kristẹni jẹ́ ẹ̀bùn oníbùkún mìíràn látọ̀dọ̀ Jèhófà—ẹ̀bùn yìí ṣeyebíye gan-an lójú wa. Orí ìlànà la gbé e kà, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni, àní ó jinlẹ̀ débi pé ó ń fa àwọn onígbàgbọ́ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí ju àwọn ìbátan pàápàá. (Jòhánù 15:12, 13; 1 Pétérù 1:22) Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká rántí Tàbítà, obìnrin àtàtà tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní. “Ó pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú,” pàápàá jù lọ fún àwọn opó tó wà nínú ìjọ. (Ìṣe 9:36) Ó ṣeé ṣe kí àwọn obìnrin wọ̀nyí ní ẹbí, ṣùgbọ́n Tàbítà fẹ́ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kí ó sì fún wọn níṣìírí. (1 Jòhánù 3:18) Àpẹẹrẹ tí Tàbítà fi lélẹ̀ yìí mà dáa o! Ìfẹ́ ará ló sún Pírísíkà àti Ákúílà láti “fi ọrùn ara wọn wewu” nítorí Pọ́ọ̀lù. Bákan náà, ìfẹ́ ló sún Epafírásì, Lúùkù, Ónẹ́sífórù, àtàwọn míì láti ran àpọ́sítélì náà lọ́wọ́ nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù. (Róòmù 16:3, 4; 2 Tímótì 1:16; 4:11; Fílémónì 23, 24) Dájúdájú, irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ lóde òní ‘ní ìfẹ́ láàárín ara wọn,’ èyí tí í ṣe ẹ̀bùn oníbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tó sì ń fi hàn pé àwọn ni ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù.—Jòhánù 13:34, 35.

13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni wa lọ́pọ̀lọpọ̀?

13 Ǹjẹ́ o mọyì ìfẹ́ tí ń bẹ nínú ìjọ Kristẹni? Ǹjẹ́ o mọrírì ẹgbẹ́ àwọn ará wa nípa tẹ̀mí, tó kárí ayé? Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀bùn àtọ̀runwá tí ń mú ọkàn yọ̀, tó sì ń wúni lórí. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ẹ̀bùn wọ̀nyí ṣeyebíye lójú wa? Nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run, nípa sísọ̀rọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni, àti nípa fífi ìfẹ́ àtàwọn yòókù nínú èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn.—Fílípì 1:9; Hébérù 10:24, 25.

“Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn”

14. Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ Kristẹni tó bá fẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

14 Àwọn Kristẹni ọkùnrin tó fẹ́ máa sin àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní ète rere lọ́kàn. (1 Tímótì 3:1, 8) Láti tóótun fún àǹfààní wọ̀nyí, arákùnrin kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí, tó mọ Ìwé Mímọ́ dunjú, tó sì jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. (Ìṣe 18:24; 1 Tímótì 4:15; 2 Tímótì 4:5) Ó gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kí ó sì jẹ́ onísùúrù, nítorí pé àwọn oníkùgbù àti agbéraga, àtàwọn tí ń kánjú àtidé ipò ọlá kì í rí ìbùkún Ọlọ́run gbà. (Òwe 11:2; Hébérù 6:15; 3 Jòhánù 9, 10) Bó bá ti gbéyàwó, ó ní láti jẹ́ baálé onífẹ̀ẹ́ tó ń bójú tó agboolé rẹ̀ dáadáa. (1 Tímótì 3:4, 5, 12) Nítorí pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ń fojú ribiribi wo ọrọ̀ tẹ̀mí, yóò rí ìbùkún Jèhófà gbà.—Mátíù 6:19-21.

15, 16. Àwọn wo ni “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? Mú àwọn àpẹẹrẹ wá.

15 Nígbà tí àwọn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ bá ń sa gbogbo ipá wọn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, olùṣọ́ àgùntàn, àti olùkọ́ni, wọ́n ń fún wa ní ìdí gúnmọ́ láti mọyì irú “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” bẹ́ẹ̀. (Éfésù 4:8, 11) Ó lè máà jẹ́ gbogbo ìgbà làwọn tó ń jàǹfààní iṣẹ́ ìsìn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń ṣe máa ń fi ìmọrírì hàn, ṣùgbọ́n Jèhófà rí gbogbo ohun táwọn alàgbà olóòótọ́ ń ṣe. Kò ní gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún orúkọ rẹ̀ nípa ṣíṣèránṣẹ́ fáwọn èèyàn rẹ̀.—1 Tímótì 5:17; Hébérù 6:10.

16 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń forí ṣe fọrùn ṣe. Ó lọ bẹ Kristẹni ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ ọpọlọ fún wò. Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ìdílé yẹn kọ̀wé pé: “Oníyọ̀ọ́nú ni, adúrótini lọ́jọ́ ìpọ́njú ni, ó sì láájò. Ó béèrè bóyá àá fẹ́ ká jọ gbàdúrà sí Jèhófà. Bó ti ń gbàdúrà, bàbá ọmọ náà [tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà] kàn bú sẹ́kún ni, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú gbogbo àwa táa wà nínú yàrá ọsibítù yẹn. Àdúrà alàgbà yẹn mà tù wá nínú o, ẹ sì wo bí Jèhófà ti nífẹ̀ẹ́ wa tó, tó fi rán an wá ní àkókò yẹn gan-an!” Ẹlẹ́rìí mìíràn tó ń gbàtọ́jú, sọ nípa àwọn alàgbà tó bẹ̀ ẹ́ wò pé: “Nígbà tí wọ́n ń bọ̀ nítòsí bẹ́ẹ̀dì mi ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe, mo mọ̀ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà yẹn lọ, màá lè fara dà á. Mo mí kanlẹ̀, ara sì tù mí pẹ̀sẹ̀.” Ǹjẹ́ irú aájò onífẹ̀ẹ́ yẹn ṣeé fowó rà? Láéláé! Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tó pèsè nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni.—Aísáyà 32:1, 2.

Ẹ̀bùn Ni Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá

17, 18. (a) Ẹ̀bùn iṣẹ́ ìsìn wo ni Jèhófà fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ọlọ́run ti pèsè kí a lè ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

17 Kò sí iyì tó ga tó kí ènìyàn ní àǹfààní sísin Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ. (Aísáyà 43:10; 2 Kọ́ríńtì 4:7; 1 Pétérù 2:9) Bẹ́ẹ̀, àǹfààní nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wà fún gbogbo èèyàn—tọmọdé tàgbà, tọkùnrin tobìnrin—tó bá ní ìfẹ́ àtọkànwá láti sin Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o ń lo ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye yìí? Àwọn kan lè máa lọ́ tìkọ̀ nítorí wọ́n rò pé àwọn ò tóótun, àmọ́ rántí pé Jèhófà ń fún àwọn tó ń sìn ín ní ẹ̀mí mímọ́, tó ń ràn wá lọ́wọ́ níbi táa bá ti kù díẹ̀ káàtó.—Jeremáyà 1:6-8; 20:11.

18 Jèhófà ti fi iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà síkàáwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀, kò fi síkàáwọ́ àwọn agbéraga, tó ní ẹ̀mí mo-tó-tán. (1 Kọ́ríńtì 1:20, 26-29) Àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó mọ̀wọ̀n ara wọn máa ń mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, ojú Ọlọ́run sì ni wọ́n ń wò bí wọ́n ti ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Wọ́n tún mọyì ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí ó ń pèsè nípasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú” náà.—Lúùkù 12:42-44; Òwe 22:4.

Ìgbésí Ayé Ìdílé Aláyọ̀—Ẹ̀bùn Àtàtà Ni

19. Kí làwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti tọ́ ọmọ ní àtọ́yanjú?

19 Ìgbéyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Rúùtù 1:9; Éfésù 3:14, 15) Àwọn ọmọ pẹ̀lú jẹ́ ‘ogún ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Jèhófà,’ wọ́n ń mú ayọ̀ wá bá àwọn òbí tó bá gbin ìbẹ̀rù Ọlọ́run sí wọn lọ́kàn. (Sáàmù 127:3) Bí o bá jẹ́ òbí, máa fetí sí ohùn Jèhófà nípa fífi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ àwọn ọmọ rẹ. Ó dájú pé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò rí ìtìlẹyìn Jèhófà àti ìbùkún jìngbìnnì látọ̀dọ̀ rẹ̀.—Òwe 3:5, 6; 22:6; Éfésù 6:1-4.

20. Kí ló lè ran àwọn òbí tí ọmọ wọn kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ lọ́wọ́?

20 Pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe, àwọn kan lára àwọn ọmọ wọn lè yàn láti kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ nígbà tí wọ́n bá dàgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 26:34, 35) Èyí lè kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá àwọn òbí. (Òwe 17:21, 25) Àmọ́, dípò tí wọn ó fi sọ̀rètí nù, á dáa kí wọ́n rántí àkàwé Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ yẹn fi ilé sílẹ̀, tó sì lọ yàyàkuyà, nígbà tó ṣe ó padà sílé bàbá rẹ̀, bàbá rẹ̀ sì tẹ́wọ́ gbà á tayọ̀tayọ̀ àti tìfẹ́tìfẹ́. (Lúùkù 15:11-32) Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, kí àwọn Kristẹni òbí tó jẹ́ olóòótọ́ mọ̀ dájú pé Jèhófà lóye ipò wọn, ó nífẹ̀ẹ́ wọn látọkànwá, gbágbáágbá ló sì wà lẹ́yìn wọn.—Sáàmù 145:14.

21. Ta ló yẹ ká fetí sí, èé sì ti ṣe?

21 Ǹjẹ́ kí kálukú wa mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Ṣé eré àtilà là ń sá kiri, èyí tó jẹ́ pé ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwa àti ìdílé wa? Tàbí kẹ̀, ṣé ‘àwọn ẹ̀bùn rere àti ọrẹ pípé’ tí ń wá látọ̀dọ̀ “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá” là ń lépa? (Jákọ́bù 1:17) Sátánì, “baba irọ́,” fẹ́ ká máa ṣe làálàá nítorí àtidi ọlọ́rọ̀, ká lè pàdánù ayọ̀ àti ẹ̀mí wa. (Jòhánù 8:44; Lúùkù 12:15) Àmọ́ bó ṣe máa dáa fún wa ni Jèhófà ń wá lójú méjèèjì. (Aísáyà 48:17, 18) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní fífetí sí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ká sì máa “ní inú dídùn kíkọyọyọ” nínú rẹ̀. (Sáàmù 37:4) Báa bá ń tọ ipa ọ̀nà yẹn, àwọn ẹ̀bùn Jèhófà tí kò ṣeé díye lé àti ìbùkún yàbùgà-yabuga látọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò sọ wá dọlọ́rọ̀—láìsí ìrora rárá.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, January 22, 1993, ojú ìwé 18 sí 21.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Níbo la ti lè rí ayọ̀ tó ga jù lọ?

• Kí ni díẹ̀ lára ẹ̀bùn tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀?

• Èé ṣe tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fi jẹ́ ẹ̀bùn?

• Kí làwọn òbí lè ṣe láti jèrè ìbùkún Ọlọ́run bí wọ́n ti ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ǹjẹ́ o mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Laurel Nisbet fi ìtara sin Ọlọ́run, láìka ipò líle koko tó wà sí

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bíi ti Tàbítà, àwọn èèyàn mọ àwọn Kristẹni òde òní mọ́ ìfẹ́ tí wọ́n ní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn Kristẹni alàgbà ń fìfẹ́ ṣaájò àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn