Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Nǹkan Kan Tiẹ̀ Wà Tó Lè So Aráyé Pọ̀ Ṣọ̀kan?

Ǹjẹ́ Nǹkan Kan Tiẹ̀ Wà Tó Lè So Aráyé Pọ̀ Ṣọ̀kan?

Ǹjẹ́ Nǹkan Kan Tiẹ̀ Wà Tó Lè So Aráyé Pọ̀ Ṣọ̀kan?

OHUN yòówù kóo gbà gbọ́, ó ṣeé ṣe kóo gbà pé bóyá la fi rí ẹ̀sìn kan tí kò ní àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ nínú. A lè rí àwọn tó mọyì ohun tó jẹ́ òtítọ́ gan-an, tí wọ́n sì múra tán láti wá a rí, wọ́n wà láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, àwọn Kátólíìkì, àwọn ẹlẹ́sìn Júù, àtàwọn ẹlẹ́sìn mìíràn. Síbẹ̀, ó dà bíi pé ẹ̀sìn ló ń pín aráyé níyà. Àwọn kan tiẹ̀ ń fi ẹ̀sìn bojú ṣe iṣẹ́ ibi. Ǹjẹ́ ìṣọ̀kan tiẹ̀ lè wà láé láàárín àwọn aláìlábòsí ènìyàn inú gbogbo ẹ̀sìn, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun rere àti òtítọ́? Ǹjẹ́ wọ́n lè kóra jọ pọ̀ fún ète kan náà?

Ẹ wo bó ṣe ń dani láàmú tó pé ìsìn ló túbọ̀ ń fa ìpínyà! Gbé díẹ̀ lára àwọn ìforígbárí wọ̀nyí yẹ̀ wò. Àwọn Híńdù ń bá àwọn ẹlẹ́sìn Búdà jà ní Sri Lanka. Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, Kátólíìkì, àtàwọn Júù ti tàjẹ̀ sílẹ̀ nínú onírúurú ìforígbárí. Àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ń bá àwọn Mùsùlùmí jà ní Bosnia, Chechnya, Indonesia, àti Kosovo. Ní March 2000, ọ̀ọ́dúnrún ọmọ Nàìjíríà ló kú láàárín ọjọ́ méjì tí rògbòdìyàn fi wà nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Ní ti gidi, ìkórìíra tí ẹ̀sìn dá sílẹ̀ ti dá kún ìwà òǹrorò táwọn èèyàn ń hù lákòókò àwọn ìforígbárí wọ̀nyí.

Ọ̀pọ̀ ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù lórúkọ ìsìn sábà máa ń ṣe àwọn aláìlábòsí ènìyàn ní kàyéfì. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ló gbọ̀n rìrì nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ṣì gba àwọn àlùfáà ti wọ́n ti bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe láyè láti máa báṣẹ́ wọn lọ. Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ìsìn tó pe ara wọn ní Kristẹni kò ṣe fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀ràn bí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti ìṣẹ́yún ṣì ń kótìjú bá àwọn mìíràn tó jẹ́ onígbàgbọ́. Ó ṣe kedere pé ìsìn kò tíì so aráyé pọ̀ ṣọ̀kan. Síbẹ̀, àwọn tó dìídì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wà nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn, bí a ó ṣe rí i nínú àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e.

Òùngbẹ Òtítọ́ Ń Gbẹ Wọ́n

Fidelia jẹ́ olùfọkànsìn nílé ìjọsìn Francis “Mímọ́” ti Ìjọ Kátólíìkì ní La Paz, Bolivia. Ó máa ń tẹrí ba níwájú ère Màríà, ó sì máa ń tan èyí tó dára jù lọ nínú àbẹ́là tó bá rà síwájú àgbélébùú. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń kó ọ̀pọ̀ oúnjẹ fún àlùfáà pé kó pín in fún àwọn tálákà. Àmọ́, márùn-ún nínú àwọn ọmọ Fidelia ló kú láìṣe batisí. Nígbà tí àlùfáà sọ fún un pé gbogbo wọn ló ń jìyà nínú òkùnkùn Limbo, Fidelia wá ṣe kàyéfì pé, ‘Bí Ọlọ́run bá jẹ́ onífẹ̀ẹ́, báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?’

Inú ìjọ Híńdù ní Kathmandu, ní ìlú Nepal ni wọ́n ti tọ́ Tara, tó jẹ́ oníṣègùn òyìnbó dàgbà. Ní ìbámu pẹ̀lú àṣà táwọn baba ńlá rẹ̀ ti ń bá bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, òun náà ń sin àwọn ọlọ́run rẹ̀ nínú àwọn tẹ́ńpìlì Híńdù, ó sì tún ní àwọn ère tó ń júbà fún nínú ilé ara rẹ̀. Àmọ́ Tara ń ṣe kàyéfì nípa àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Èé ṣe tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Èé ṣe táwọn èèyàn fi ń kú? Kò rí ìdáhùn kankan tó ṣe gúnmọ́ sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú ẹ̀sìn rẹ̀.

Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀sìn Búdà ni Panya ṣe dàgbà nínú ilé kan tí wọ́n kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ omi ní Bangkok, Thailand. Wọ́n kọ́ ọ pé ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn dá ní ayé àkọ́wá ló ń fa ìjìyà, àti pé kìkì ohun téèyàn fi lè bọ́ nínú rẹ̀ ni pé kó yàgò fún gbogbo afẹ́ ayé. Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Búdà tòótọ́, wọ́n kọ́ ọ pé kó ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọgbọ́n àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n máa ń wọṣọ àwọ̀kanlẹ̀ aláwọ̀ ìyeyè, tí wọ́n sì ń wá sínú ilé náà láti wá tọrọ owó tí ọ̀yẹ̀ bá ti là. Ó máa ń ṣàṣàrò, ó sì kó àwọn ère Búdà jọ pẹ̀lú èrò pé wọ́n máa ń dáàbò boni. Lẹ́yìn tí jàǹbá ọkọ̀ burúkú kan sọ Panya di ẹni tí ìbàdí rẹ̀ sísàlẹ̀ rọ, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti ìsìn Búdà náà, pẹ̀lú ìrètí pé wọn ó wo òun sàn lọ́nà ìyanu. Kò rí ìwòsàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì là á lóye nípa tẹ̀mí. Dípò ìyẹn, ọ̀nà tó máa gbà di ẹni tó ń bẹ́mìí lò ni wọ́n fi hàn án, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ́mìí lò.

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí Virgil sí, ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Black Muslims nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́ gíga. Tìtaratìtara ló fi máa ń pín àwọn ìwé wọn kiri, èyí tó kọ́ni pé Èṣù ni àwọn aláwọ̀ funfun. Wọ́n lérò pé ìyẹn ló fà á táwọn aláwọ̀ funfun fi ń hùwà ìkà sí àwọn adúláwọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkàntọkàn ni Virgil fi ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ yìí, síbẹ̀ àwọn ìbéèrè kan ṣì ń dà á láàmú, àwọn bíi: Báwo ni gbogbo àwọn aláwọ̀ funfun ṣe lè jẹ́ èèyàn burúkú? Èé sì ti ṣe tó jẹ́ pé orí owó ni gbogbo ìwàásù wọn máa ń dá lé?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ti gbilẹ̀ gan-an ní Gúúsù Amẹ́ríkà ni Charo ti dàgbà, síbẹ̀ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gidi ni. Inú rẹ̀ dùn pé òun ò bá wọn lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà tó yí i ká. Charo máa ń gbádùn lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ní gbogbo ọjọ́ Sunday láti lọ ṣe ìsìn tó máa ń kún fún ìgbónára, níbi tó ti máa ń ké “Halelúyà!” táá sì bá wọn kópa nínú orin àti ijó tó máa ń tẹ̀ lé e. Charo fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ pé òun ti rí ìgbàlà, òun sì ti di àtúnbí. Ó máa ń san ìdá mẹ́wàá owó tó ń wọlé fún un sí ṣọ́ọ̀ṣì, nígbà tí ajíhìnrere kan tó máa ń fẹ́ gbọ́ ìwàásù rẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n bá sì béèrè ọrẹ, ó máa ń fi owó ránṣẹ́ sí i láti fún àwọn ọmọ tó wà nílẹ̀ Áfíríkà. Àmọ́, nígbà tó béèrè lọ́wọ́ pásítọ̀ rẹ̀ pé kí nìdí tí Ọlọ́run ìfẹ́ fi ń dá ọkàn lóró nínú ọ̀run àpáàdì, ó wá rí i pé kò ní ìdáhùn kan tó ṣe gúnmọ́ sí ìbéèrè náà. Níkẹyìn, ó tún rí i pé wọn kò fi ọrẹ òun ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ tó wà nílẹ̀ Áfíríkà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti tọ́ àwọn márààrún wọ̀nyí dàgbà, síbẹ̀ ohun kan ni ọ̀ràn wọn fi bára mu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, wọ́n sì fi tọkàntọkàn wá ìdáhùn tòótọ́ sí àwọn ìbéèrè wọn. Àmọ́, ǹjẹ́ wọ́n lè di ẹni táa so pọ̀ ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ǹjẹ́ àwọn onírúurú èèyàn lè di ẹni táa so pọ̀ ṣọ̀kan?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

G.P.O., Jerusalem