Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà

Wọ́n Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà

Wọ́n Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà

Ọ̀PỌ̀ jù lọ àwọn tó ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà ló gba Ọlọ́run gbọ́. Ó dá wọn lójú hán-ún hán-ún pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:11) Àmọ́, bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn ibòmíràn, wọn kì í sábàá lo orúkọ rẹ̀ gan-an—ìyẹn Jèhófà.

Àwọn ará Àárín Gbùngbùn Áfíríkà àti kárí ayé máa ń tọ́ka sí orúkọ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá sọ pé, “Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ” nínú Àdúrà Olúwa. (Mátíù 6:9, Bibeli Mimọ) Ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ló ti mọ orúkọ yẹn tipẹ́. Àmọ́, bí ọdún ti ń gorí ọdún, iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìtara ṣe ti yí èrò àwọn èèyàn padà nípa lílo orúkọ Ọlọ́run. Lónìí, orúkọ náà ti di mímọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Áfíríkà, wọ́n sì ń lò ó nínú ọ̀pọ̀ èdè ilẹ̀ Áfíríkà, bíi Zulu (uJehova), Yorùbá (Jèhófà), Xhosa (uYehova) àti Swahili (Yehova). Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè wọ̀nyí ṣì ń sá fún lílo orúkọ Ọlọ́run.

Ìtumọ̀ kan tó pegedé, tó lo orúkọ Ọlọ́run ni Bíbélì èdè Zande, èdè kan tí wọ́n ń sọ láwọn àdúgbò kan ní Central African Republic, Sudan, àti ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò. Àwọn èèyàn ń lo orúkọ Ọlọ́run lágbègbè yẹn, bí wọ́n sì ṣe ń kọ ọ́ sílẹ̀ lédè wọn ni Yekova. Ọ̀nà tó wù kí wọ́n máa gbà kọ orúkọ Ọlọ́run lédè ìbílẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé à ń lò ó. Èé ṣe? Nítorí pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Róòmù 10:13.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

SUDAN

CENTRAL AFRICAN REPUBLIC

ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TI KÓŃGÒ

[Credit Line]

The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck