Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Táa Lè Rí Kọ́ Lára Igi Ọ̀pẹ

Ẹ̀kọ́ Táa Lè Rí Kọ́ Lára Igi Ọ̀pẹ

Ẹ̀kọ́ Táa Lè Rí Kọ́ Lára Igi Ọ̀pẹ

“ẸWÀ títayọ.” Báyẹn ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì kan ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀yà ọ̀pẹ tí ń so èso déètì. Ní àkókò táa kọ Bíbélì àti lóde òní pàápàá, àwọn ọ̀pẹ tí ń so èso déètì ló jẹ́ kí Àfonífojì Odò Náílì tó wà ní Íjíbítì lẹ́wà, wọ́n sì tún jẹ́ ibòji ní àwọn ibi àbàtà tó wà ní Aṣálẹ̀ Négébù.

Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀yà ọ̀pẹ, ńṣe ni ọ̀pẹ tí ń so èso déètì máa ń dúró ní òró gangan. Àwọn míì máa ń ga tó ọgbọ̀n mítà, wọ́n sì máa ń so èso fún àádọ́jọ [150] ọdún. Àní sẹ́, ẹ̀yà ọ̀pẹ tí ń so èso déètì lẹ́wà gan-an, ó tún máa ń so jìngbìnnì. Ọdọọdún ló máa ń so ọ̀pọ̀ òṣùṣù èso déètì. Òṣùṣù kan ṣoṣo lè ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún èso déètì lára. Òǹṣèwé kan sọ nípa èso déètì pé: “Àwọn tó jẹ́ pé . . . kìkì ẹ̀gbẹ èso déètì tí a ń tà lọ́jà nìkan ni wọ́n mọ̀, kò lè mọ bí èso yìí ti dùn tó ní tútù.”

Abájọ tí Bíbélì fi fàwọn èèyàn kan wé igi ọ̀pẹ. Láti lè múnú Ọlọ́run dùn, èèyàn gbọ́dọ̀ níwà rere, kí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sì máa so èso rere, bíi ti igi ọ̀pẹ eléso jìngbìnnì. (Mátíù 7:17-20) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi fàwòrán igi ọ̀pẹ ṣọ̀ṣọ́ sára tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì àti tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. (1 Àwọn Ọba 6:29, 32, 35; Ìsíkíẹ́lì 40:14-16, 20, 22) Nítorí náà, kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn èèyàn, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ní irú àwọn ànímọ́ fífani mọ́ra tí ọ̀pẹ tí ń so èso déètì ní. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ.”—Sáàmù 92:12.