Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “ìsinmi” táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Hébérù 4:9-11, báwo lèèyàn sì ṣe ń “wọnú ìsinmi yẹn”?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ìsinmi ti sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorí ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn.”—Hébérù 4:9-11.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run sinmi kúrò nínú iṣẹ́ Rẹ̀, ó ṣe kedere pé ohun tó ń tọ́ka sí ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:2, tó kà pé: “Ní ọjọ́ keje, Ọlọ́run dé àṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe.” Èé ṣe tí Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ sí “sinmi ní ọjọ́ keje”? Dájúdájú kì í ṣe nítorí pé ó fẹ́ sọ agbára dọ̀tun lẹ́yìn “gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe.” Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé, ó ní: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀, nítorí pé inú rẹ̀ ni ó ti ń sinmi kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí Ọlọ́run ti dá fún ète ṣíṣe.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:3; Aísáyà 40:26, 28.
“Ọjọ́ keje” yàtọ̀ sí ọjọ́ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ìṣáájú ní ti pé Ọlọ́run bù kún ọjọ́ yìí, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀, ìyẹn ni pé, ó yà á sọ́tọ̀, tàbí pé ó sọ ọ́ di mímọ́, fún ète pàtàkì kan. Kí ni ète yẹn? Ní ìṣáájú, Ọlọ́run ṣí ète rẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé payá. Ọlọ́run sọ fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá aráyé àti ilẹ̀ ayé ní pípé ní ìbẹ̀rẹ̀, yóò gba àkókò ká tó lè ṣèkáwọ́ odindi ilẹ̀ ayé, ká sì sọ ọ́ di párádísè tó kún fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn pípé, níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní “ọjọ́ keje,” Ọlọ́run sinmi, tàbí pé ó ṣíwọ́ dídá àwọn nǹkan míì sórí ilẹ̀ ayé, kí ó lè jẹ́ kí àwọn ohun tí òun ti dá ṣiṣẹ́ yọrí níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Nígbà tí “ọjọ́” náà yóò fi parí, gbogbo ohun tí Ọlọ́run pète ni yóò ti nímùúṣẹ. Báwo ni ìsinmi yẹn yóò ti gùn tó?
Táa bá padà lọ wo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Hébérù, a óò rí i pé ó tọ́ka sí i pé “ìsinmi sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run,” ó sì rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn “láti wọnú ìsinmi yẹn.” Èyí fi hàn pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, “ọjọ́ keje” ìsinmi Ọlọ́run, tó bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, ṣì ń lọ lọ́wọ́. Kó tó di pé ó dópin, gbogbo ète Ọlọ́run fún aráyé àti ilẹ̀ ayé ti gbọ́dọ̀ nímùúṣẹ pátápátá ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù Kristi, tí í ṣe “Olúwa sábáàtì.”—Mátíù 12:8; Ìṣípayá 20:1-6; 21:1-4.
Pẹ̀lú ìfojúsọ́nà àgbàyanu yẹn lọ́kàn, Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé béèyàn ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run, òun pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀.” Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ pípé ní àtètèkọ́ṣe, aráyé lódindi kò tíì wọnú ìsinmi Ọlọ́run. Ìdí ni pé Ádámù àti Éfà kò pa ìsinmi Ọlọ́run ní “ọjọ́ keje” mọ́ fún àkókò pípẹ́, nípa títẹ́wọ́ gba ètò tó ṣe fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣọ̀tẹ̀, wọn sì fẹ́ gba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àní wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì dípò kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pàdánù àǹfààní wíwà láàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. Látìgbà yẹn ni gbogbo aráyé ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 5:12, 14.
Ìṣọ̀tẹ̀ aráyé kò dí ète Ọlọ́run lọ́wọ́. Ọjọ́ ìsinmi rẹ̀ ń bá a nìṣó. Àmọ́ o, Jèhófà ṣe ètò onífẹ̀ẹ́—ìyẹn ìràpadà—nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, kí gbogbo àwọn tó bá fi ìgbàgbọ́ tẹ́wọ́ gbà á lè máa wọ̀nà fún ìtúsílẹ̀ àti ìsinmi kúrò nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 6:23) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ‘sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tiwọn.’ Wọ́n ní láti tẹ́wọ́ gba ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìgbàlà, kí wọ́n má sì gbìyànjú láti lo ọjọ́ ọ̀la wọn bó ṣe wù wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Ádámù àti Éfà ti ṣe. Ó tún yẹ kí wọ́n yàgò fún lílépa iṣẹ́ tó wà fún ìdáláre ara wọn.
Pípa àwọn góńgó onímọtara ẹni nìkan àti afẹ́ ayé tì, láti lè ráyè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń tuni lára, ó sì ń fúnni nísinmi ní ti gidi. Jésù ké sí wa pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìsinmi Ọlọ́run àti béèyàn ṣe lè wọnú rẹ̀ jẹ́ orísun ìṣírí fáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tó ti fàyà rán ọ̀pọ̀ inúnibíni àti ìfiniṣẹ̀sín nítorí ìgbàgbọ́ wọn. (Ìṣe 8:1; 12:1-5) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè jẹ́ orísun ìṣírí fún àwa Kristẹni òde òní. Níwọ̀n bí a ti rí i pé ìlérí Ọlọ́run nípa párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba òdodo rẹ̀ kò ní pẹ́ ní ìmúṣẹ, àwa pẹ̀lú yóò sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tara wa, a ó sì máa sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn.—Mátíù 6:10, 33; 2 Pétérù 3:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìlérí Ọlọ́run nípa párádísè orí ilẹ̀ ayé yóò nímùúṣẹ ní òpin ọjọ́ ìsinmi rẹ̀