Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Ǹjẹ́ Ó Ṣì Wà?
Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Ǹjẹ́ Ó Ṣì Wà?
“Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé tí kì í yẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé tó gbópọn nínú oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Àní ó dájú, ó sì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ débi pé onígbàgbọ́ kò kọ̀ láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún un nígbàkigbà.”—MARTIN LUTHER, 1522.
“Ayé ò ṣú já ọ̀ràn ẹ̀sìn mọ́ o, ìgbàgbọ́ àti ìlànà Kristẹni ti ń di ohun àtijọ́ báyìí.”—LUDOVIC KENNEDY, 1999.
OJÚ táwọn èèyàn fi ń wo ọ̀ràn ìgbàgbọ́ yàtọ̀ síra gan-an. Láyé àtijọ́, ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run làwọn èèyàn gbọ́njú bá. Àmọ́ nínú ayé àìdánilójú táa ń gbé lónìí, níbi tí ìyà ti ń jẹ pásapàsa sáwọn èèyàn lára, ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Bíbélì ti ń pòórá.
Ìgbàgbọ́ Tòótọ́
Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ohun tí “ìgbàgbọ́” túmọ̀ sí kò ju ṣíṣe ẹ̀sìn kan tàbí títẹ̀lé ọ̀nà ìjọsìn kan. Àmọ́, tó bá jẹ́ bí Bíbélì ṣe lò ó ni, ohun tí “ìgbàgbọ́” túmọ̀ sí ní ti gidi ni ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá—bẹ́ẹ̀ ni, ìgbẹ́kẹ̀lé àtọkànwá, tó dúró sán-ún nínú Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀. Ó jẹ́ ànímọ́ táa fi ń dá ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi mọ̀.
Nígbà kan, Jésù Kristi sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì gbígbàdúrà, ‘láìjuwọ́ sílẹ̀.’ Ó wá béèrè bóyá ìgbàgbọ́ tòótọ́ máa wà rárá ní ọjọ́ tiwa. Ó ní: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ [yìí] ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” Kí nìdí tó fi gbé irú ìbéèrè yẹn dìde?—Lúùkù 18:1, 8.
Pípàdánù Ìgbàgbọ́
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè jẹ́ kéèyàn pàdánù ìgbàgbọ́ tó ní. Lára rẹ̀ ni àwọn jàǹbá àti hílàhílo tó kún inú ayé àkámarà yìí. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ àlùfáà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Goulder ń ṣe nílùú Manchester, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tí jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú kan ṣẹlẹ̀ nílùú Munich lọ́dún 1958, nínú èyí tí ọ̀pọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United ti ṣòfò ẹ̀mí wọn. Nínú ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n BBC, oníròyìn nì, Joan Bakewell, ṣàlàyé pé nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Goulder “rí báwọn èèyàn ṣe kárí sọ tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a.” Èyí ló mú kó “pàdánù ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run tó ń darí
kádàrá ẹ̀dá.” Goulder sọ èrò rẹ̀ jáde, pé “Bíbélì kì í ṣe . . . ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ṣùgbọ́n ó jẹ́ “ọ̀rọ̀ ènìyàn tí ó kún fún àṣìṣe, bóyá èyí tí Ọlọ́run kàn mí sí àwọn ọ̀rọ̀ mélòó kan nínú rẹ̀.”Ìgbà míì sì rèé, ńṣe ni ìgbàgbọ́ kàn máa ń ṣá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òǹkọ̀wé àti oníròyìn nì, Ludovic Kennedy nìyẹn. Ó sọ pé láti kékeré lòun “ti ń ṣiyèméjì, tí [òun] ń ṣe kámi-kàmì-kámi [nípa Ọlọ́run], àìgbàgbọ́ [òun] sì wá ń pọ̀ sí i.” Ó jọ pé kò sẹ́ni tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ lọ́nà tó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ikú bàbá rẹ̀ lójú òkun ló wá fọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó ti di ahẹrẹpẹ tẹ́lẹ̀ yángá. Àdúrà tí wọ́n máa ń gbà sí Ọlọ́run pé “gbà wá lọ́wọ́ ewu òkun àti lọ́wọ́ ogun ọ̀tá” kò gbà, nítorí pé àwọn ọkọ̀ òkun tí ilẹ̀ Jámánì fi ń jagun gbógun ti ọkọ̀ òkun akérò, tí bàbá rẹ̀ wà nínú rẹ̀, wọ́n sì rún ọkọ̀ akérò náà wómúwómú nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.—All in the Mind—A Farewell to God.
Irú ìrírí bẹ́ẹ̀ kì í ṣe tuntun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Kí lèrò ẹ? Ǹjẹ́ èèyàn ṣì lè ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ayé tó túbọ̀ ń di oníyèmejì yìí? Gbé ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e sọ lórí kókó yìí yẹ̀ wò.