Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Ran Ọmọ “Onínàákúnàá” Lọ́wọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Ran Ọmọ “Onínàákúnàá” Lọ́wọ́?

Báwo Lo Ṣe Lè Ran Ọmọ “Onínàákúnàá” Lọ́wọ́?

“Yọ̀, nítorí pé . . . ó sọnù a sì rí i.”—LÚÙKÙ 15:32.

1, 2. (a) Kí làwọn ọ̀dọ́ kan ń ṣe sí òtítọ́ Kristẹni? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn òbí àtàwọn ọmọ tó wà nírú ipò yẹn?

 “MI Ò ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́!” Yóò mà burú jáì létí àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n sì ti sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní ọ̀nà Kristẹni, láti gbọ́ irú ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu ọmọ kan o! Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn á wulẹ̀ “sú lọ” láìsọ èrò inú wọn jáde rárá. (Hébérù 2:1) Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ló dà bí ọmọ onínàákúnàá inú òwe Jésù, tó fi ilé baba rẹ̀ sílẹ̀, tó lọ lo ogún rẹ̀ nílò àpà ní ilẹ̀ jíjìnnàréré.—Lúùkù 15:11-16.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í nírú ìṣòro yìí, ṣùgbọ́n ní ti àwọn tó níṣòro yìí, kò sí ọ̀rọ̀ ìtùnú tó lè mú ẹ̀dùn ọkàn wọn kúrò pátápátá. Ohun tí a kò tún ní gbójú fò dá ni ìbànújẹ́ tí irú ọ̀dọ́ oníwàkiwà náà máa kó bá ara rẹ̀. Nínú lọ́hùn-ún, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lè máa dà á láàmú. Nínú òwe Jésù, “orí” ọmọ onínàákúnàá náà “wálé” níkẹyìn, èyí sì múnú baba rẹ̀ dùn. Báwo ni àwọn òbí àtàwọn mìíràn nínú ìjọ ṣe lè ran àwọn ọmọ onínàákúnàá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ‘orí wọn wálé’?—Lúùkù 15:17.

Ìdí Táwọn Kan Fi Pinnu Àtilọ

3. Kí ni àwọn ìdí kan tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ fi ìjọ Kristẹni sílẹ̀?

3 Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ni wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Jèhófà nínú ìjọ Kristẹni. Èé ṣe táwọn ọ̀dọ́ míì fi wá ń lọ? Wọ́n lérò pé àwọn ń pàdánù ohun kan táwọn lè rí nínú ayé. (2 Tímótì 4:10) Tàbí kẹ̀, wọ́n lè rò pé inú agbo àgùntàn Jèhófà tí ààbò wà ti le koko jù. Ẹ̀rí ọkàn tí ń dáni lẹ́bi, níní ìfẹ́ gbígbóná janjan sí ẹ̀yà kejì, tàbí ìfẹ́ láti bẹ́gbẹ́ mu tún lè mú kí ọ̀dọ́ kan sú lọ kúrò nínú agbo Jèhófà. Ọ̀dọ́ kan lè máà sin Ọlọ́run mọ́ nítorí ohun tó dà bí ìwà àgàbàgebè tó rí lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn Kristẹni mìíràn.

4. Kí ló sábà máa ń jẹ́ ìdí tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ ṣáko lọ?

4 Ẹ̀mí àti ìwà ọ̀tẹ̀ tọ́mọ kan ní sábà máa ń jẹ́ àmì àìlera nípa tẹ̀mí tó ń fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ hàn. (Òwe 15:13; Mátíù 12:34) Ohun yòówù kó jẹ́ ìdí tó mú kí ọ̀dọ́ kan ṣáko lọ, olórí ìṣòro rẹ̀ ni pé kò ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (2 Tímótì 3:7) Dípò fífi ẹ̀mí gbà-jẹ́-n-sinmi jọ́sìn Jèhófà, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé káwọn ọ̀dọ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Kí ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run

5. Kí ni ọ̀dọ́ tó bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣe?

5 Ọmọ ẹ̀yìn nì, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Kí ọ̀dọ́ kan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàgbà. (Sáàmù 34:8) Lákọ̀ọ́kọ́, yóò nílò “wàrà”—ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì. Àmọ́ bí inú rẹ̀ ṣe ń dùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì ń nífẹ̀ẹ́ sí “oúnjẹ líle”—ìyẹn àwọn ìsọfúnni tó jinlẹ̀ nípa tẹ̀mí—kò ní pẹ́ tó fi máa dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. (Hébérù 5:11-14; Sáàmù 1:2) Ọ̀dọ́ kan tó ti kó wọnú ayé pátápátá tẹ́lẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti yí padà? Ó tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un pé kí ó ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà déédéé. Dájúdájú, ó pọndandan láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, báa bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.

6, 7. Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

6 Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí àwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Láìfi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí wọ́n ń ṣe déédéé pè, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba lọ ń bá àwọn ọmọ tó ti ya pòkíì kẹ́gbẹ́. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn, ó sọ pé: “Nígbà tí Baba bá béèrè àwọn ìbéèrè, mo kàn máa ń ka ìdáhùn láìtiẹ̀ gbójú sókè rárá ni.” Dípò wíwulẹ̀ ka ibì kan lọ wuuruwu lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (2 Tímótì 4:2) Kí ọ̀dọ́ kan tó lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́, ó ní láti rí i pé ohun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kan òun. O ò ṣe béèrè àwọn ìbéèrè tí ń fi èrò ẹni hàn, kóo sì jẹ́ kó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde? Gba ọ̀dọ́ náà níyànjú láti fi kókó ẹ̀kọ́ ibi tí ẹ ń kà náà sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. a

7 Láfikún sí i, jẹ́ kí ìjíròrò Ìwé Mímọ́ náà lárinrin. Nígbà tó bá yẹ, sọ pé kí àwọn ọmọ fi àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe eré àwòkẹ́kọ̀ọ́. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fojú inú wo ibi tí ilẹ̀ tí ìtàn náà ti ṣẹlẹ̀ wà àti bí ibẹ̀ ṣe rí. Lílo àwòrán ilẹ̀ àti àwòrán atọ́ka lè ṣèrànwọ́. Dájúdájú, nípa fífi ojú inú wo nǹkan, ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lè di èyí tó lárinrin táa sì ń ṣe lónírúurú ọ̀nà. Yóò dára pẹ̀lú kí àwọn òbí yẹ àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti Jèhófà wò pẹ̀lú. Bí àwọn fúnra wọn ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, wọ́n lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.—Diutarónómì 6:5-7.

8. Báwo ni àdúrà ṣe ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run?

8 Àdúrà tún máa ń ran èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ọmọbìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ọ̀dọ́langba kò mọ èyí tí òun ì bá mú láàárín ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni àti àwọn ọ̀rẹ́ tí ìgbàgbọ́ tiwọn yàtọ̀ sí tirẹ̀. (Jákọ́bù 4:4) Kí ló wá ṣe nípa rẹ̀? Ó jẹ́wọ́ pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ pàá, mo dìídì gbàdúrà sí Jèhófà nípa bọ́ràn náà ṣe rí lọ́kàn mi gan-an.” Ó gbà pé àdúrà òun gbà ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà tó rí ọ̀rẹ́ kan tó ṣeé finú hàn láàárín ìjọ Kristẹni. Nígbà tó wá rí i pé Jèhófà ń ṣe amọ̀nà òun, ó bẹ̀rẹ̀ sí mú àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run dàgbà. Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nípa mímú kí àdúrà táwọn alára ń gbà túbọ̀ jẹ́ àtọkànwá. Nígbà tí ìdílé bá ń gbàdúrà pa pọ̀, àwọn òbí lè sọ gbogbo ìṣòro wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn jáde káwọn ọmọ lè rí àjọṣe tímọ́tímọ́ tí àwọn òbí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà.

Ní Sùúrù Ṣùgbọ́n Má Gba Gbẹ̀rẹ́

9, 10. Àpẹẹrẹ wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nípa bó ṣe jẹ́ onípamọ́ra sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aṣetinú ẹni?

9 Nígbà tí ọ̀dọ́ kan bá bẹ̀rẹ̀ sí sú lọ, ó lè gbìyànjú láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, kó má sì fún àwọn òbí rẹ̀ láyè láti bá a jíròrò ohunkóhun nípa tẹ̀mí. Kí làwọn òbí lè ṣe nínú irú ipò tí kò bára dé bẹ́ẹ̀? Gbé ohun tí Jèhófà ṣe pẹ̀lú Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò. Ó fara da ìwà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ “ọlọ́rùn-líle” fún ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọdún kó tó di pé ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa bá ọ̀nà aṣetinú ẹni wọn lọ. (Ẹ́kísódù 34:9; 2 Kíróníkà 36:17-21; Róòmù 10:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ‘ń dán Jèhófà wò,’ ó ‘ṣàánú’ wọn. “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó . . . mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà, kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde.” (Sáàmù 78:38-42) Ọlọ́run kò ní ẹ̀bi kankan nínú bó ṣe bá wọn lò. Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ ń fara wé Jèhófà, wọ́n sì máa ń mú sùúrù nígbà tí ọmọ náà kò bá tètè mọrírì gbogbo ìsapá tí wọ́n ń ṣe láti ràn án lọ́wọ́.

10 Jíjẹ́ onípamọ́ra tàbí onísùúrù tún túmọ̀ sí kéèyàn má ṣe ronú pé àjọṣe kan tó ti bà jẹ́ ti kọjá àtúnṣe. Jèhófà fi àpẹẹrẹ báa ṣe lè jẹ́ onípamọ́ra lélẹ̀. Ó lo ìdánúṣe nípa rírán àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “léraléra.” Jèhófà “ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé “wọ́n ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 36:15, 16) Ó rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí padà, olúkúlùkù kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀.” (Jeremáyà 25:4, 5) Síbẹ̀, Jèhófà kò fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́. A pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti “yí padà” sí Ọlọ́run àti sí àwọn ọ̀nà rẹ̀.

11. Báwo làwọn òbí ṣe lè ní ìpamọ́ra síbẹ̀ kí wọ́n má gba gbẹ̀rẹ́ nínú bíbá ọmọ kan tó yapa lò?

11 Àwọn òbí lè fara wé Jèhófà nínú jíjẹ́ onípamọ́ra nípa ṣíṣàì fi ìwàǹwára pa ọmọ kan tó ṣáko lọ tì. Láìsọ ìrètí nù, wọ́n lè lo ìdánúṣe láti jẹ́ kí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ tàbí kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní fi ìlànà òdodo báni dọ́rẹ̀ẹ́, síbẹ̀ wọ́n lè máa rọ ọmọ náà “léraléra” pé kó padà sí ọ̀nà òtítọ́.

Nígbà Tí Wọ́n Bá Yọ Ọmọ Aláìtójúúbọ́ Lẹ́gbẹ́

12. Kí ni ojúṣe àwọn òbí nípa ọmọ aláìtójúúbọ́ tó ń gbé lọ́dọ̀ wọn àmọ́ táa yọ kúrò nínú ìjọ?

12 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọmọ aláìtójúúbọ́ kan tó ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lọ dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, tí wọ́n sì wá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ nítorí pé ó kọ̀ láti ronú pìwà dà ńkọ́? Nítorí pé ọmọ náà ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ẹrù iṣẹ́ wọn ṣì ni láti máa fún un nítọ̀ọ́ni, kí wọ́n sì máa bá a wí níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo ni wọ́n ṣe lè máa ṣe èyí?—Òwe 6:20-22; 29:17.

13. Báwo làwọn òbí ṣe lè dé ọkàn ọmọ tó ṣi ẹsẹ̀ gbé?

13 Ó lè ṣeé ṣe—àní ohun tó tiẹ̀ dára jù lọ ni—láti fún un ní irú ìtọ́ni àti ìbáwí bẹ́ẹ̀ lákòókò ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Òbí kan gbọ́dọ̀ wò ré kọjá ẹ̀mí orí kunkun tí ọmọ náà ní, kó sì gbìyànjú láti rí ohun tó wà nínú ọkàn rẹ̀. Báwo ni àìsàn tẹ̀mí tó ń ṣe é ṣe le tó? (Òwe 20:5) Ǹjẹ́ a lè dé ibi tí kò tíì yigbì nínú ọkàn rẹ̀? Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè lò lọ́nà tó gbéṣẹ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn òbí lè ṣe kọjá wíwulẹ̀ sọ fún ọmọ wọn pé kó má ṣe lọ́wọ́ sí ìwà àìtọ́ mọ́. Wọ́n lè gbìyànjú láti bá a wá ọ̀nà tó máa gbà rí ìwòsàn, kí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ títí ó máa fi sàn pátápátá.

14. Kí ni ohun àkọ́kọ́ tí ọ̀dọ́ kan tí ó ṣi ẹsẹ̀ gbé ní láti ṣe láti tún àjọṣe àárín òun àti Jèhófà ṣe, báwo sì ni àwọn òbí ṣe lè ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ yẹn?

14 Ọ̀dọ́ kan tó dẹ́ṣẹ̀ gbọ́dọ̀ tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó gbọ́dọ̀ gbé ni pé kó ‘ronú pìwà dà, kó sì yí padà.’ (Ìṣe 3:19; Aísáyà 55:6, 7) Kí àwọn òbí tó lè ran ọ̀dọ́ tó ń gbé lọ́dọ̀ wọn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, àwọn fúnra wọn gbọ́dọ̀ máa ‘kó ara wọn ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí wọ́n sì máa fún’ ọmọ tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere “ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” (2 Tímótì 2:24-26) Wọ́n ní láti ‘fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà’ ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa túmọ̀ sí “fi ìbáwí tọ́ sọ́nà” la tún lè túmọ̀ sí ‘fún ní ẹ̀rí amúnigbàgbọ́.’ (Ìṣípayá 3:19; Jòhánù 16:8) Nítorí náà, láti fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà wé mọ́ fífi ẹ̀rí tí ó tó hàn láti mú un dá ọmọ náà lójú pé ipa ọ̀nà tí ó ń tọ̀ jẹ́ ti ẹ̀ṣẹ̀. Ká sọ tòótọ́, kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ níbi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn òbí lè dé inú ọkàn rẹ̀, kí wọ́n ta gbogbo ọgbọ́n tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti yí i lérò padà. Wọ́n gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ láti mọ ìdí tó fi ní láti “kórìíra ohun búburú, kí [ó] sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Ó lè padà wá sí ‘agbára ìmòye rẹ̀ tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu kúrò nínú ìdẹkùn Èṣù.’

15. Ipa wo ni àdúrà ń kó nínú títún àjọṣe àárín ẹlẹ́ṣẹ̀ kan àti Jèhófà ṣe?

15 Àdúrà pọndandan téèyàn bá fẹ́ tún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kéèyàn ‘bẹ̀bẹ̀’ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó hàn gbangba pé ẹnì kan tó ti fìgbà kan ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ń dá láìronú pìwà dà. (1 Jòhánù 5:16, 17; Jeremáyà 7:16-20; Hébérù 10:26, 27) Síbẹ̀, àwọn òbí lè bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn ní ọgbọ́n láti kojú ipò náà. (Jákọ́bù 1:5) Bí ọ̀dọ́ kan táa yọ lẹ́gbẹ́ bá fi ẹ̀rí ìrònúpìwàdà hàn, àmọ́ tí kò ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run,” àwọn òbí lè gbàdúrà pé bí Ọlọ́run bá rí ìdí láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ náà jì í, pé kí ìfẹ́ Rẹ̀ di ṣíṣe. (1 Jòhánù 3:21) Ó yẹ kí gbígbọ́ irú àwọn àdúrà wọ̀nyí ran ọ̀dọ́ náà lọ́wọ́ láti rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run aláàánú. bẸ́kísódù 34:6, 7; Jákọ́bù 5:16.

16. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé ọmọ aláìtójúúbọ́ táa yọ lẹ́gbẹ́?

16 Bí a bá yọ ọ̀dọ́ tó ti ṣe ìrìbọmi lẹ́gbẹ́, àwọn mẹ́ńbà ìjọ ní láti “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú” rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 5:11; 2 Jòhánù 10, 11) Èyí lè jẹ́ kí “orí rẹ̀ wálé” ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, kó sì padà wá sínú agbo Ọlọ́run tí ààbò wà. (Lúùkù 15:17) Àmọ́, yálà ó padà wá sínú ètò tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn mẹ́ńbà ìjọ lè máa fún ìdílé ọ̀dọ́ táa yọ lẹ́gbẹ́ náà níṣìírí. Gbogbo wa lè wá ọ̀nà láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” àti “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn sí wọn.—1 Pétérù 3:8, 9.

Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́

17. Kí ni àwọn mẹ́ńbà ìjọ gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti ran ọmọ kan tó ti ṣáko lọ lọ́wọ́?

17 Ọ̀dọ́ tí a kò yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni àmọ́ tó ti di ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa mọ́ ńkọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹ̀yà ara kan bá . . . ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.” (1 Kọ́ríńtì 12:26.) Àwọn mìíràn lè fi ọkàn ìfẹ́ àtàtà hàn sí irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra o, níwọ̀n bí ọ̀dọ́ tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí náà ti lè ní ipa búburú lórí àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. (Gálátíà 5:7-9) Nínú ìjọ kan, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ní èrò rere, tí wọ́n fẹ́ ran àwọn ọ̀dọ́ tí ipò tẹ̀mí wọn ti di ahẹrẹpẹ lọ́wọ́, ń pè wọ́n sí àwọn àpèjẹ láti jùmọ̀ fi ohun èlò kọrin tí gbogbo èèyàn mọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àwọn ọ̀dọ́ náà dùn sí i, wọ́n sì gbádùn irú àkókò bẹ́ẹ̀, àmọ́ ipa tí wọ́n ní lórí ara wọn wá jẹ́ kí wọ́n ṣíwọ́ dídarapọ̀ mọ́ ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Júúdà 22, 23) Kì í ṣe àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí kò jẹ mọ́ nǹkan tẹ̀mí la ó fi ran ọmọ tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí lọ́wọ́, bí kò ṣe ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó lè ràn án lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ fún àwọn nǹkan tẹ̀mí dàgbà. c

18. Báwo la ṣe lè fara wé ìṣarasíhùwà baba ọmọ onínàákúnàá inú òwe Jésù?

18 Nígbà tí ọ̀dọ́ kan tó ti fi ìjọ sílẹ̀ bá padà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tó wá sí àpéjọ kan, ronú nípa irú ìmọ̀lára tó lè ní. Ǹjẹ́ kò yẹ ká ní ẹ̀mí ìkínikáàbọ̀ bíi ti baba ọmọ onínàákúnàá inú òwe Jésù? (Lúùkù 15:18-20, 25-32) Ọ̀dọ́langba kan tó kúrò nínú ìjọ Kristẹni nígbà kan, àmọ́ tó wá wá sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan lẹ́yìn náà sọ pé: “Mo rò pé gbogbo èèyàn ló máa yẹra fún irú èèyàn bíi tèmi, àmọ́ ńṣe làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin sún mọ́ mi tí wọ́n sì kí mi káàbọ̀. Ó mórí mi wú gan-an ni.” Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe batisí lẹ́yìn náà.

Máà Jẹ́ Kó Sú Ọ

19, 20. Èé ṣe tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí tó dára nípa ọmọ onínàákúnàá?

19 Ríran ọmọ “onínàákúnàá” lọ́wọ́ láti jẹ́ kí “orí rẹ̀ wálé” gba sùúrù, ó sì lè jẹ́ ìpèníjà fún àwọn òbí àtàwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n máà jẹ́ kó sú ọ. “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) A ní ìdánilójú láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n sì yè. Àní, ó ti lo ìdánúṣe ní ṣíṣètò láti mú àwọn ẹ̀dá ènìyàn padà bá ara rẹ̀ rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 5:18, 19) Sùúrù rẹ̀ ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn pe orí ara wọn wálé.—Aísáyà 2:2, 3.

20 Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ káwọn òbí lo gbogbo ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti ran àwọn ọmọ onínàákúnàá wọn lọ́wọ́ kí orí wọn lè wálé? Fara wé Jèhófà. Ní ìpamọ́ra bóo ṣe ń gbégbèésẹ̀ rere láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì dáadáa, kí o sì gbìyànjú láti fi àwọn ànímọ́ Jèhófà bí ìfẹ́, àìṣègbè, àti ọgbọ́n hàn, bóo ti ń gbàdúrà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́. Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó jẹ́ olóríkunkun ṣe fara mọ́ ìpè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà pè wọ́n láti padà wá, ọmọ rẹ tó jẹ́ onínàákúnàá pẹ̀lú lè padà sínú agbo Ọlọ́run tí ààbò wà.—Lúùkù 15:6, 7.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìmọ̀ràn síwájú sí i lórí bí a ṣe ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́, wo Ilé Ìṣọ́, July 1, 1999, ojú ìwé 13-17.

b A kò gbọ́dọ̀ gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀ fún ọmọ aláìtójúúbọ́ táa yọ lẹ́gbẹ́ náà ní àwọn ìpàdé ìjọ, nítorí pé àwọn mìíràn lè ṣàìmọ ipò tí ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ náà wà.—Wo Ile-Iṣọ Naa April 15, 1980, ojú ìwé 31.

c Fún àwọn àbá tó ṣe pàtó, wo Jí! June 22, 1972, [Gẹ̀ẹ́sì], ojú ìwé 13 sí 16; September 22, 1996, ojú ìwé 21 sí 23.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló lè jẹ́ olórí ìṣòro tó ń mú káwọn ọ̀dọ́ fi ìjọ sílẹ̀?

• Báwo la ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà?

• Èé ṣe táwọn òbí fi gbọ́dọ̀ ní ìpamọ́ra ṣùgbọ́n tí wọn ò ní gba gbẹ̀rẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń ran ọmọ onínàákúnàá lọ́wọ́?

• Báwo làwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè ran ọ̀dọ́ onínàákúnàá lọ́wọ́ láti padà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì fún mímú àjọṣe tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àdúrà àtọkànwá táwọn òbí ń gbà lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àwọn òbí náà ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Kí ọmọ onínàákúnàá káàbọ̀ nígbà tí ‘orí rẹ̀ bá wálé’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Gbé ìgbésẹ̀ tó dára láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà