Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fara Wé Jèhófà Nígbà Tóo Bá Ń tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ

Fara Wé Jèhófà Nígbà Tóo Bá Ń tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ

Fara Wé Jèhófà Nígbà Tóo Bá Ń tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ

“Kì í ha ṣe gbogbo òbí ní ń tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà bí?”—HÉBÉRÙ 12:7, Contemporary English Version.

1, 2. Èé ṣe táwọn òbí fi níṣòro àtitọ́ àwọn ọmọ wọn lóde òní?

 ÌWÁDÌÍ kan tí wọ́n ṣe ní Japan lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé nǹkan bí ìdajì lára àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn àti pé àwọn òbí máa ń kẹ́ àwọn ọmọ wọn lákẹ̀ẹ́bàjẹ́. Nínú ìwádìí mìíràn tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́rin àwọn tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ tó sọ pé àwọn ò tiẹ̀ mọ béèyàn ṣe ń báwọn ọmọ sọ̀rọ̀. Kì í ṣe Ìlà Oòrùn ayé nìkan ni ìṣòro yìí wà. Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó wà ní Kánádà ló sọ pé kò tiẹ̀ dájú pé àwọn mọ béèyàn ṣe ń jẹ́ òbí tó dáńgájíá.” Ó túbọ̀ ń ṣòro fáwọn òbí níbi gbogbo láti tọ́ àwọn ọmọ wọn.

2 Èé ṣe tó fi ń ṣòro fáwọn òbí láti tọ́ àwọn ọmọ wọn? Ìdí pàtàkì kan ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé àti pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ti wà níhìn-ín. (2 Tímótì 3:1) Láfikún sí i, Bíbélì sọ pé, “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Àwọn ọ̀dọ́ gan-an ló sì máa ń tètè kó sínú akóló Sátánì, tó dà bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù” tó ń fi àwọn tí kò nírìírí ṣèjẹ. (1 Pétérù 5:8) Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ń dojú kọ àwọn òbí Kristẹni tí wọ́n ń tiraka láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti dàgbà di olùjọsìn Jèhófà tó dàgbà dénú, tó lè fìyàtọ̀ sáàárín “ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́”?—Hébérù 5:14.

3. Èé ṣe tí ẹ̀kọ́ àti ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn òbí fi pọndandan ká tó lè tọ́ àwọn ọmọ dàgbà lọ́nà tó kẹ́sẹ járí?

3 Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 13:1; 22:15) Kí irú ìwà òmùgọ̀ bẹ́ẹ̀ lè kúrò lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́, wọ́n nílò ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Àmọ́, àwọn ọ̀dọ́ kì í sábà tẹ́wọ́ gba irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, ńṣe ni wọ́n sábà máa ń kọ ìmọ̀ràn sílẹ̀, láìka ẹni yòówù ó jẹ́, tó fún wọn nímọ̀ràn náà. Nítorí ìdí èyí, àwọn òbí gbọ́dọ̀ kọ́ láti “tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀.” (Òwe 22:6) Nígbà táwọn ọmọ bá fara mọ́ irú ìbáwí bẹ́ẹ̀, ó lè túmọ̀ sí ìyè fún wọn. (Òwe 4:13) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí àwọn òbí mọ ohun tó wé mọ́ títọ́ àwọn ọmọ wọn!

Ìbáwí—Ohun Tó Túmọ̀ Sí

4. Kí ni “ìbáwí” túmọ̀ sí gan-an báa ṣe lò ó nínú Bíbélì?

4 Àwọn òbí kan kì í fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà nítorí ìbẹ̀rù pé wọ́n lè fẹ̀sùn lílekokomọ́ni kàn wọ́n—yálà ẹ̀sùn nína ọmọ ní ìnàkunà, fífi ọ̀rọ̀ gún wọn lára, tàbí bíbà wọ́n lọ́kàn jẹ́. Kò yẹ kíyẹn bà wá lẹ́rù. Ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí,” báa ṣe lò ó nínú Bíbélì kò túmọ̀ sí lílekokomọ́ni tàbí ìwà òǹrorò èyíkéyìí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ìbáwí” dìídì tan mọ́ fífúnni nítọ̀ọ́ni, kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, títọ́ni sọ́nà àti, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, fífi ìyà tí ó tọ́ àmọ́ tó fìfẹ́ hàn jẹni.

5. Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní láti gbé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò yẹ̀ wò?

5 Jèhófà Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ nínú ọ̀ràn pípèsè irú ìbáwí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń fi Jèhófà wé baba kan, ó kọ̀wé pé: “Kì í ha ṣe gbogbo òbí ní ń tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà bí? . . . Àwọn baba tó bí wa máa ń tọ́ wa sọ́nà fún ìgbà díẹ̀, wọ́n sì ń ṣe é lọ́nà tó dára jù lọ lójú wọn. Àmọ́ Ọlọ́run ń tọ́ wa sọ́nà fún àǹfààní ara wa, nítorí pé ó fẹ́ kí a jẹ́ mímọ́.” (Hébérù 12:7-10, Contemporary English Version) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí kí wọ́n lè di mímọ́, tàbí aláìlẹ́gàn. Ó dájú pé a lè kọ́ báa ṣe ń bá àwọn ọmọ wí nípa gbígbé bí Jèhófà ṣe tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ́nà yẹ̀ wò.—Diutarónómì 32:4; Mátíù 7:11; Éfésù 5:1.

Ìfẹ́ Ló Ń Sún Un Ṣe É

6. Kí nìdí tó fi lè ṣòro fáwọn òbí láti fara wé ìfẹ́ Jèhófà?

6 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Nítorí náà, ìfẹ́ ló ń sún Jèhófà dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. (1 Jòhánù 4:8; Òwe 3:11, 12) Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé àtifarawé Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí kò ní ṣòro fáwọn òbí tó ní ìfẹ́ni àdánidá fáwọn ọmọ wọn? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà. Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì jinlẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ “kì í fi gbogbo ìgbà bá ìtẹ̀sí ọkàn ènìyàn mu.” Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní kì í ru bò ó lójú. Ohun tó bá rí i pé ó dára jù lọ fáwọn èèyàn rẹ̀ ló máa ń ṣe.—Aísáyà 30:20; 48:17.

7, 8. (a) Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nínú bó ṣe bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò? (b) Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà nínú ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì?

7 Gbé ìfẹ́ tí Jèhófà fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò yẹ̀ wò. Mósè lo àkàwé kan tó wúni lórí láti ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kékeré náà. Ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ sókè ti í rà bàbà lókè àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀gúnyẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, ti í na àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀ jáde, ti í mú wọn, ti í gbé wọn lọ lórí àwọn ìyẹ́ àfifò rẹ̀, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ń ṣamọ̀nà [Jékọ́bù] nìṣó.” (Diutarónómì 32:9, 11, 12) Nígbà tí ìyá idì bá ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fò, yóò ‘ru ìtẹ́ rẹ̀ sókè,’ yóò bẹ̀rẹ̀ sí gbọn ìyẹ́ apá rẹ̀ pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ kí àwọn ọmọ rẹ̀ lè mọ̀ pé ó ti tó àkókò láti fò. Nígbà tí ọmọ ẹyẹ náà bá wá fò jáde nínú ìtẹ́ náà níkẹyìn, tó sì jẹ́ pé ibi gíga ni ìtẹ́ náà máa ń wà, ìyá ẹyẹ náà á “rà bàbà lókè” ọmọ náà. Bí ó bá jọ pé ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́ náà fẹ́ já lulẹ̀, ìyá ẹyẹ náà yóò tètè fò sábẹ́ rẹ̀, yóò sì gbé e “lórí àwọn ìyẹ́ àfifò rẹ̀.” Ọ̀nà kan náà ni Jèhófà gbà fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì táa ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà. Ó fún àwọn ènìyàn náà ní Òfin Mósè. (Sáàmù 78:5-7) Ọlọ́run wá ń bójú tó orílẹ̀-èdè náà lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó múra tán láti gbà wọ́n nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro.

8 Báwo làwọn Kristẹni òbí ṣe lè fara wé ìfẹ́ Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Diutarónómì 6:4-9) Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ báa ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ń rà bàbà bo àwọn ọmọ wọn, wọ́n ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ìlànà tí wọ́n kọ́ wọn sílò. Bí àwọn ọmọ náà ti ń dàgbà, tí wọ́n sì túbọ̀ ń ní òmìnira ni àwọn òbí tó bìkítà ń múra tán láti “bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,” kí wọ́n sì ‘gbé àwọn ọmọ wọn lórí ìyẹ́ àfifò wọn’ nígbàkigbà tí ewu bá ń bọ̀. Irú ewu wo?

9. Irú ewu wo ní pàtàkì làwọn òbí gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò sí? Ṣàpèjúwe.

9 Jèhófà Ọlọ́run kìlọ̀ ohun tó máa jẹ́ àbájáde kíkó ẹgbẹ́ búburú fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Númérì 25:1-18; Ẹ́sírà 10:10-14) Bíbá àwọn ènìyàn búburú rìn tún jẹ́ ewu wíwọ́pọ̀ lóde òní. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ì bá dára káwọn Kristẹni òbí fara wé Jèhófà lórí kókó yìí. Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lisa bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin kan tí kò fara mọ́ ojú tí ìdílé Lisa fi wo ọ̀ràn nípa ìwà rere àti àwọn nǹkan tẹ̀mí. Lisa sọ pé: “Kíá làwọn òbí mi rí i pé ìṣarasíhùwà mi yí padà, wọ́n sì béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Wọ́n ń tọ́ mi sọ́nà nígbà mìíràn, wọ́n sì ń fìfẹ́ gbà mí níyànjú láwọn ìgbà mìíràn.” Wọ́n pe Lisa jókòó, wọ́n sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ń ṣe é. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti ràn án lọ́wọ́ tó fi lè kojú ohun tí wọ́n rí i pé ó jẹ́ ìṣòro rẹ̀—ìyẹn ni ìfẹ́ láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe. a

Ẹ Máa Bára Yín Sọ̀rọ̀ Déédéé

10. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú bíbá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀?

10 Káwọn òbí tó lè kẹ́sẹ járí nínú títọ́ àwọn ọmọ, wọ́n gbọ́dọ̀ làkàkà láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tó wà nínú ọkàn wa, síbẹ̀ ó gbà wá níyànjú pé ká máa bá òun sọ̀rọ̀. (1 Kíróníkà 28:9) Lẹ́yìn tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin, ó tún yan àwọn ọmọ Léfì láti máa fún wọn nítọ̀ọ́ni, ó sì rán àwọn àlùfáà láti bá wọn fèrò wérò, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Ó tún múra tán láti gbọ́ àdúrà wọn.—2 Kíróníkà 17:7-9; Sáàmù 65:2; Aísáyà 1:1-3, 18-20; Jeremáyà 25:4; Gálátíà 3:22-24.

11. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó dán mọ́rán wà láàárín àwọn àtàwọn ọmọ wọn? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí jẹ́ ẹni tó ń fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀?

11 Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n gbọ́dọ̀ wáyè fún wọn. Yóò tún dára káwọn òbí yẹra fún àwọn kòbákùngbé ọ̀rọ̀ tó ń fini ṣẹ̀sín, irú bíi, “Ṣé ibi tó mọ náà nìyẹn? Ọ̀rọ̀ gidi kan mà ni mo pè é”; “Àṣé ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan tiẹ̀ ni”; “Tóò, kí ni ìwọ náà rò pé ó máa tẹ̀yìn rẹ̀ jáde? Ọmọdé ló ń ṣe ẹ́.” (Òwe 12:18) Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń tiraka láti jẹ́ olùgbọ́ rere, kí wọ́n lè fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti máa sọ tinú wọn jáde. Àwọn òbí tí kì í ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn sí nígbà táwọn ọmọ náà ṣì kéré lè wá rí i pé àwọn ọmọ náà kò ní ka ọ̀rọ̀ tàwọn náà sí nígbà táwọn ọmọ ọ̀hún bá dàgbà. Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń múra tán láti fetí sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń ṣí etí rẹ̀ sílẹ̀ sí àwọn tó ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ yíjú sí i nínú àdúrà.—Sáàmù 91:15; Jeremáyà 29:12; Lúùkù 11:9-13.

12. Àwọn ànímọ́ wo làwọn òbí lè ní tó máa mú kó rọrùn fáwọn ọmọ wọn láti bá wọn sọ̀rọ̀?

12 Tún ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn apá kan nínú ànímọ́ Ọlọ́run ṣe mú kó rọrùn fáwọn ènìyàn rẹ̀ láti bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà. Fún àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nígbà tó bá Bátí-ṣébà ṣèṣekúṣe. Nítorí pé Dáfídì jẹ́ aláìpé, ó tún dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mìíràn nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Síbẹ̀, kì í kùnà láti sọ fún Jèhófà, ó máa ń tọrọ àforíjì, ó sì máa ń gba ìbáwí látọ̀dọ̀ rẹ̀. Láìsí àní-àní, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú Ọlọ́run mú kó rọrùn fún Dáfídì láti yíjú sí Jèhófà. (Sáàmù 103:8) Nípa níní irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, bí ìyọ́nú àti àánú, àwọn òbí lè jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọmọ láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé, kódà nígbà táwọn ọmọ náà bá ṣi ẹsẹ̀ gbé.—Sáàmù 103:13; Málákì 3:17.

Jẹ́ Ẹni Tó Ń Fòye Báni Lò

13. Kí ló wé mọ́ jíjẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò?

13 Nígbà táwọn òbí bá ń gbọ́ ohun táwọn ọmọ wọn ń sọ, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń fòye báni lò, kí wọ́n sì fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” hàn. (Jákọ́bù 3:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò? Ọ̀kan lára ìtumọ̀ táa fún ọ̀rọ̀ tí Gíríìkì lò fún “fífòye báni lò” ni “kéèyàn má rin kinkin mọ́ ohun tí òfin wí.” Nígbà tó jẹ́ pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà ìwà rere àti ìlànà tẹ̀mí, báwo ni wọ́n ṣe lè jẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò?

14. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfòyebánilò hàn nínú bó ṣe bá Lọ́ọ̀tì lò?

14 Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa fífòye báni lò. (Sáàmù 10:17) Nígbà tó ní kí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní ìlú Sódómù táa fẹ́ pa run, Lọ́ọ̀tì “ń lọ́ra ṣáá.” Níkẹyìn, nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé kí ó sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, Lọ́ọ̀tì sọ pé: “Èmi kò lè sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá . . . Jọ̀wọ́, nísinsìnyí, ìlú ńlá yìí [Sóárì] wà nítòsí láti sá lọ síbẹ̀, ó sì jẹ́ ohun kékeré. Jọ̀wọ́, ṣé kí n sá lọ síbẹ̀—kì í ha ṣe ohun kékeré ni?” Báwo ni Jèhófà ṣe rí ohun tó sọ yìí sí? Ó ní: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú, ní ti pé èmi kò ní bi ìlú ńlá náà tí ìwọ ti sọ ṣubú.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:16-21, 30) Jèhófà ṣe tán láti ṣe ohun tí Lọ́ọ̀tì béèrè fún un. Láìsí àní-àní, àwọn òbí gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà tí Jèhófà Ọlọ́run fi lélẹ̀ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n fara mọ́ ohun táwọn ọmọ wọn fẹ́ tí kò bá ṣáà ti tako àwọn ìlànà Bíbélì.

15, 16. Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí lè kọ́ látinú àpèjúwe tó wà nínú Aísáyà 28:24, 25?

15 Jíjẹ́ ẹni tí ń fòye báni lò tún kan mímúra ọkàn àwọn ọmọ sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe tán láti gba ìmọ̀ràn. Lọ́nà àpèjúwe, Aísáyà fi Jèhófà wé àgbẹ̀ kan nígbà tó sọ pé: “Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ha ni atúlẹ̀ máa ń túlẹ̀ kí ó bàa lè fún irúgbìn, tí ó máa ń tú, tí ó sì ń fọ́ ògúlùtu lórí ilẹ̀ rẹ̀ bí? Nígbà tí ó bá ti mú ojú rẹ̀ jọ̀lọ̀, kì í ha ṣe lẹ́yìn ìyẹn ni ó ń tú kúmínì dúdú ká, tí ó sì ń wọ́n kúmínì, kì yóò ha sì gbin àlìkámà, jéró, àti ọkà bálì sí ibi tí a yàn kalẹ̀, àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì gẹ́gẹ́ bí ààlà rẹ̀?”—Aísáyà 28:24, 25.

16 Jèhófà “ń túlẹ̀ kí ó bàa lè fún irúgbìn,” bẹ́ẹ̀ náà ló “ń tú, tí ó sì ń fọ́ ògúlùtu lórí ilẹ̀ rẹ̀.” Ó tipa bẹ́ẹ̀ ń múra ọkàn àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ kó tó bá wọn wí. Nínú títọ́ àwọn ọmọ sọ́nà, báwo làwọn òbí ṣe lè “tú” ọkàn àwọn ọmọ wọn bí ẹní ń túlẹ̀? Baba kan fara wé Jèhófà nígbà tó ń tọ́ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin sọ́nà. Nígbà tí ọmọ rẹ̀ lu ọmọkùnrin kan ládùúgbò wọn, baba náà kọ́kọ́ fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí ọmọ rẹ̀ sọ pé ó mú kí òun ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, bí ẹni pé ó fẹ́ “tú” ọkàn ọmọ rẹ̀ bí ẹní ń túlẹ̀, baba náà wá sọ ìtàn ọmọkùnrin kan tí ẹnì kan tó jẹ́ abúmọ́ni fi ojú rẹ̀ han èèmọ̀. Nígbà tó sọ ìtàn náà tán, àánú ṣe ọmọ náà débi tó fi sọ pé ó yẹ kí wọ́n fìyà jẹ abúmọ́ni ọ̀hún. Irú ‘títú’ bẹ́ẹ̀ múra ọkàn ọmọ náà sílẹ̀, ó sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti rí i pé lílu ọmọkùnrin tí wọ́n jọ jẹ́ aládùúgbò yẹn jẹ́ ìwà abúmọ́ni, kò sì dára.—2 Sámúẹ́lì 12:1-14.

17. Kí ni ẹ̀kọ́ táwọn òbí lè rí kọ́ nípa ìtọ́nisọ́nà nínú Aísáyà 28:26-29?

17 Aísáyà tún fi ìtọ́sọ́nà Jèhófà wé apá mìíràn nínú iṣẹ́ àgbẹ̀—ìyẹn ni ìpakà. Onírúurú ohun èlò ìpakà ni àgbẹ̀ máa ń lò, ó sinmi lórí bí èèpo ọkà náà bá ṣe le tó. Ọ̀pá ni wọ́n fi ń fọ́ kúmínì dúdú tí kò le, ọ̀gọ ni wọ́n sì fi ń fọ́ kúmínì, àmọ́ ohun èlò ìpakà tàbí àgbá kẹ̀kẹ́ la máa ń lò fún ọkà tí èèpo rẹ̀ bá le. Síbẹ̀, kò ní fọ́ ọkà tó le náà ní àfọ́bàjẹ́. Bákan náà, nígbà tí Jèhófà bá fẹ́ mú ohunkóhun tí kò dára kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀, onírúurú ohun èlò ló máa ń lò níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n ṣaláìní àti ipò tí wọ́n wà lákòókò yẹn. Òun kì í ṣe aláìdúrógbẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òǹrorò. (Aísáyà 28:26-29) Àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé ojú lásán làwọn òbí wọn fi ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n á sì gbọ́. Àwọn mìíràn fẹ́ ká máa rán wọn létí, síbẹ̀ àwọn mìíràn kì í gbojú bọ̀rọ̀. Òbí tó jẹ́ afòyebánilò yóò tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà níbàámu pẹ̀lú ohun tí ó tọ́ sí ọmọ kọ̀ọ̀kan.

Jẹ́ Kí Ìjíròrò Ìdílé Gbádùn Mọ́ni

18. Báwo làwọn òbí ṣe lè wá àkókò fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé?

18 Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé àti jíjíròrò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ wà lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti fún àwọn ọmọ rẹ nítọ̀ọ́ni. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé máa ń gbéṣẹ́ jù lọ nígbà tí a bá ń ṣe é déédéé. Bí a bá fi ṣe ọ̀ràn ìgbà tí àyè rẹ̀ bá yọ tàbí ìgbà tó bá kàn sọ sí wa lọ́kàn, ó ṣeé ṣe kí ó di ségesège. Nítorí náà àwọn òbí gbọ́dọ̀ ‘ra àkókò padà’ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. (Éfésù 5:15-17) Yíyan àkókò kan pàtó tí yóò rọrùn fún gbogbo gbòò lè jẹ́ ìpèníjà. Olórí ìdílé kan rí i pé bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà ni àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn tó yàtọ̀ síra túbọ̀ ń jẹ́ kó ṣòro láti kó gbogbo ìdílé pa pọ̀. Síbẹ̀, ìdílé náà máa ń wà pa pọ̀ láwọn alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Baba náà wá ṣètò láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní ọ̀kan lára irú àwọn alẹ́ wọ̀nyẹn. Èyí gbéṣẹ́ gan-an. Àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tí ó ti ṣe batisí báyìí.

19. Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?

19 Àmọ́, wíwulẹ̀ jíròrò àwọn kókó kan látinú Ìwé Mímọ́ lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kò tó. Jèhófà lo àwọn àlùfáà láti kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀. Àwọn àlùfáà wọ̀nyí “làdí” Òfin náà, ‘wọ́n ń fi ìtumọ̀ sí i,’ “wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.” (Nehemáyà 8:8) Baba kan tó kẹ́sẹ járí nínú ríran àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèje lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sábà máa ń wọ yàrá rẹ̀ lọ ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé kí ó lè múra sílẹ̀ láti jẹ́ kí ohun tí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ náà bá àìní ọmọ kọ̀ọ̀kan mu. Ó jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti dàgbà sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa ń dùn gan-an ni. Báa bá ń gbá bọ́ọ̀lù níta nígbà tí wọ́n bá pè wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé náà, kíá la máa ń ju bọ́ọ̀lù sílẹ̀ táa ó sì sáré wọlé láti wá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alẹ́ táa máa ń gbádùn jù lọ láàárín ọ̀sẹ̀.”

20. Kí làwọn ìṣòro tí a ó ṣì gbé yẹ̀ wò, èyí tó ṣeé ṣe ká ní nígbà táa bá ń tọ́ àwọn ọmọ?

20 Onísáàmù náà polongo pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.” (Sáàmù 127:3) Kíkọ́ àwọn ọmọ wa ń gba àkókò àti ìsapá, àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà yíyẹ lè túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn ọmọ wa. Èrè ńlá nìyẹn á mà jẹ́ o! Ǹjẹ́ kí a máa fi tìtaratìtara fara wé Jèhófà nígbà táa bá ń tọ́ àwọn ọmọ wa. Àmọ́ ṣá o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbé ẹrù iṣẹ́ “títọ́ [àwọn ọmọ] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” lé àwọn òbí lọ́wọ́, kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé yóò kẹ́sẹ járí. (Éfésù 6:4) Kódà lábẹ́ àbójútó tó dára jù lọ, ọmọ kan ṣì lè di ọlọ̀tẹ̀, kó má sì sin Jèhófà mọ́. Kí la wá lè ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀? Kókó tí a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e nìyẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìrírí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e lè wá láti àwọn ilẹ̀ tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìrẹ. Gbìyànjú láti fòye mọ àwọn ìlànà tó wé mọ́ ọn, kí o sì lò ó nínú àṣà ìbílẹ̀ tìrẹ.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

• Báwo làwọn òbí ṣe lè fara wé ìfẹ́ Jèhófà táa ṣàpèjúwe nínú Diutarónómì 32:11, 12?

• Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò?

• Kí ni ohun tí gbígbọ́ tí Jèhófà gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Lọ́ọ̀tì fi kọ́ wa?

• Ẹ̀kọ́ nípa bí a ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ sọ́nà wo lo rí kọ́ nínú Aísáyà 28:24-29?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Mósè fi bí Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ wé ọ̀nà tí idì ń gbà kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn òbí gbọ́dọ̀ wá àkókò fún àwọn ọmọ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

“Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alẹ́ táa máa ń gbádùn jù lọ láàárín ọ̀sẹ̀”