Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Jíjẹ́ Adúróṣinṣin Túmọ̀ Sí?

Kí Ni Jíjẹ́ Adúróṣinṣin Túmọ̀ Sí?

Kí Ni Jíjẹ́ Adúróṣinṣin Túmọ̀ Sí?

ÀWỌN ẹ̀ya ìsìn Júù kan tó ń jẹ́ Hasidim láti ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa gbà pé àwọn gan-an ni adúróṣinṣin. Orúkọ wọ́n wá látinú cha·sidhʹ, tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Hébérù ń lò fún “ìdúróṣinṣin.” Wọ́n mú un jáde látinú ọ̀rọ̀ orúkọ náà cheʹsedh, tí wọ́n sábà máa ń tú sí “inú rere onífẹ̀ẹ́,” “ìfẹ́ adúróṣinṣin,” “inú rere,” “ìwà rere,” “àánú.” Gẹ́gẹ́ bí Theological Dictionary of the Old Testament ṣe túmọ̀ rẹ̀, cheʹsedh ń ṣiṣẹ́, ó kóni mọ́ra, ó sì ní ìfaradà, kì í [sì í] ṣe ìwà ẹ̀dá nìkan ló ń tọ́ka sí àmọ́ ó tún ń tọ́ka sí ìgbésẹ̀ ti irú ìwà yìí ń jẹ́ kéèyàn gbé. Ó jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ń gba ẹ̀mí là tàbí tó ń mú kí ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i. Ó jẹ́ dídá sí ọ̀ràn ẹni tí ìyà ń jẹ tàbí tí wàhálà bá. Ó jẹ́ ọ̀nà láti fi ìwà ọ̀rẹ́ hàn.”

Ó hàn gbangba pé, nínú ọ̀pọ̀ èdè, kò sí ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo tó lè fi ìtumọ̀ tó wé mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù yìí hàn ní kíkún báa ṣe lò ó nínú Bíbélì. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tí ìdúróṣinṣin inú Bíbélì túmọ̀ sí kọjá fífi ìṣòtítọ́ dúró lórí ẹ̀jẹ́ ẹni. Ó ní í ṣe pẹ̀lú níní ìfàsí onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú gbígbé ìgbésẹ̀ rere láti ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní. Láti lóye ohun tí ìdúróṣinṣin túmọ̀ sí ní ti gidi, ronú nípa bí Jèhófà ṣe fi hàn sí Ábúráhámù, Mósè, Dáfídì, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àti ìran ènìyàn lápapọ̀.

Jèhófà Fi Ìdúróṣinṣin Hàn

Jèhófà sọ fún Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi jẹ́ apata fún ọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:1; Aísáyà 41:8) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kì í ṣe èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Jèhófà dáàbò bo Ábúráhámù àti agbo ilé rẹ̀, ó sì gbà wọ́n lọ́wọ́ Fáráò àti lọ́wọ́ Ábímélékì. Ó ran Ábúráhámù lọ́wọ́ láti gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọba mẹ́rin tó gbé ogun dìde. Jèhófà dá agbára ìbímọ Ábúráhámù ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún àti ti Sárà ẹni àádọ́rùn-ún ọdún padà, kí Irú Ọmọ ìlérí náà lè tipasẹ̀ wọn wá. Jèhófà máa ń bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ déédéé nípasẹ̀ ìran, àlá, àti àwọn áńgẹ́lì ońṣẹ́ rẹ̀. Àní, Jèhófà fi ìdúróṣinṣin hàn sí Ábúráhámù nígbà tó wà láàyè àti ní ọ̀pọ̀ ọdún gan-an lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni Jèhófà fi pa àwọn ìlérí tó ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì mọ́, láìka ìwàkiwà wọn sí. Àjọṣe àárín Jèhófà àti Ábúráhámù fi ohun tí ìdúróṣinṣin tòótọ́ jẹ́ hàn—ìfẹ́ tó ń súnni gbégbèésẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì, orí 12 sí 25.

Bíbélì sọ pé “Jèhófà . . . bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan yóò ti bá ọmọnìkejì rẹ̀ sọ̀rọ̀.” (Ẹ́kísódù 33:11) Àní sẹ́, Mósè ní àjọṣe kan tó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ju ti wòlíì èyíkéyìí mìíràn tó wà ṣáájú Jésù Kristi. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sí Mósè?

Ẹni ogójì ọdún tó lágbára, tó sì jẹ́ akíkanjú ni Mósè nígbà tó fi ìkùgbù gbé ìgbésẹ̀ láti fọwọ́ ara rẹ̀ gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là. Àmọ́ àkókò kò tíì tó. Ó ní láti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. Ogójì ọdún gbáko ló fi da ẹran ní Mídíánì. (Ìṣe 7:23-30) Àmọ́, Jèhófà kò fi í sílẹ̀. Nígbà tí àkókò tó, a mú Mósè padà wá láti kó Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.

Bákan náà ni Jèhófà ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn sí Dáfídì, olókìkí ọba tó jẹ ṣìkejì ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí Dáfídì ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, Jèhófà sọ fún wòlíì Sámúẹ́lì pé: “Dìde, fòróró yàn án, nítorí pé òun nìyí!” Látìgbà yẹn ni Jèhófà ti ń dáàbò bo Dáfídì bó ṣe ń dàgbà láti di ọba lọ́la lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Jèhófà dá a nídè “kúrò ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún náà àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì náà,” ó sì gbà á lọ́wọ́ Gòláyátì, òmìrán ará Filísínì nì. Ó fún Dáfídì ní ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì, Jèhófà sì dáàbò bo Dáfídì kúrò lọ́wọ́ ọ̀kọ̀ Sọ́ọ̀lù òjòwú, tó kórìíra rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 16:12; 17:37; 18:11; 19:10.

Àmọ́ ṣá o, Dáfídì kì í ṣe ẹni pípé. Àní ó tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó wúwo gan-an. Síbẹ̀, dípò kí Jèhófà pa á tì, ńṣe ló nawọ́ ìfẹ́ adúróṣinṣin rẹ̀ sí Dáfídì tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Léraléra ni Jèhófà gba ẹ̀mí là, tó sì mú kí ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i jálẹ̀ ìgbésí ayé Dáfídì. Ó dá sí ọ̀ràn ẹni tí wàhálà bá. Inú rere onífẹ̀ẹ́ gidi lèyí jẹ́!—2 Sámúẹ́lì 11:1–12:25; 24:1-17.

Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan pẹ̀lú Jèhófà nígbà tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún un, tí wọ́n sì gbà láti pa májẹ̀mú Òfin Mósè mọ́ ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 19:3-8) Nítorí ìdí èyí, a ṣàpèjúwe Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Jèhófà gbé níyàwó. A sọ fún Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà pè ọ́ bí ẹni pé ìwọ jẹ́ aya.” Jèhófà sì sọ fún un pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fi ṣàánú fún ọ.” (Aísáyà 54:6, 8) Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìdúróṣinṣin hàn nínú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ yìí?

Jèhófà lo ìdánúṣe láti pèsè fún àìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti láti fún ìdè àárín òun àtàwọn lókun. Ó dá wọn nídè ní Íjíbítì, ó sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan, ó sì mú wọn wá sí “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8) Ó ń fún wọn ní ìtọ́ni tẹ̀mí déédéé, nípasẹ̀ àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àtàwọn ońṣẹ́. (2 Kíróníkà 17:7-9; Nehemáyà 8:7-9; Jeremáyà 7:25) Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn ọlọ́run mìíràn, Jèhófà tọ́ wọn sọ́nà. Nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, ó dárí jì wọ́n. Ká sọ tòótọ́, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ́ “aya” tó ṣòroó bá lò. Síbẹ̀, Jèhófà kò ta wọ́n nù lójú ẹsẹ̀. Nítorí àwọn ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù, Ó fi ìdúróṣinṣin rọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí gbogbo ète Rẹ̀ fún wọn fi nímùúṣẹ. (Diutarónómì 7:7-9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún àwọn tọkọtaya lóde òní!

Jèhófà tún fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ hàn sí ìran ènìyàn lápapọ̀ ní ti pé ó pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí nínú ìgbésí ayé fún gbogbo ènìyàn, àti olódodo àti aláìṣòdodo. (Mátíù 5:45; Ìṣe 17:25) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó pèsè ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ kí gbogbo ìran ènìyàn lè ní àǹfààní láti bọ́ lọ́wọ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí wọ́n sì gbádùn ìfojúsọ́nà ológo ti ìyè àìnípẹ̀kun pípé nínú Párádísè. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Ẹ̀bùn ìràpadà náà ni ìgbésẹ̀ tó ga jù lọ láti gba ẹ̀mí là àti láti mú kí ìgbésí ayé sunwọ̀n sí i. Ní ti tòótọ́, ó jẹ́ “dídá sí ọ̀ràn ẹni tí ìyà ń jẹ tàbí tí wàhálà bá.”

Gbé Ìgbésẹ̀ Pàtàkì Láti Fi Ẹ̀rí Ìdúróṣinṣin Rẹ Hàn

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mìíràn táa lè lò fún ìdúróṣinṣin ni inú rere onífẹ̀ẹ́, ó tún gbé èrò ṣe-fún-mi-kí-n-ṣe-fún-ọ yọ. Bí a bá fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí ọ, a retí pé kí ìwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ìdúróṣinṣin la fi ń san ìdúróṣinṣin. Òye tí Dáfídì ní nípa ohun tó wé mọ́ cheʹsedh fara hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sọ pé: “Èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ, èmi yóò sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ.” Kí nìdí? “Nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí òótọ́ rẹ.” (Sáàmù 138:2) Níwọ̀n bí Dáfídì ti rí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà gbà, ó dájú pé èyí sún un láti jọ́sìn Rẹ̀, kí ó sì fi ìyìn fún un. Nítorí náà, báa ṣe ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí wa, èyí ha ń sún wa láti ṣe bákan náà bí? Fún àpẹẹrẹ, bí àwọn èèyàn bá mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, ǹjẹ́ àníyàn tóo ní fún orúkọ rẹ̀ ń sún ọ láti gbèjà rẹ̀?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni kan àti aya rẹ̀ nìyẹn, nígbà tí wọ́n lọ síbi ìsìnkú mọ̀lẹ́bí wọn kan tó kú nínú jàǹbá alùpùpù kan. Ààtò ìsìnkú náà kò jẹ mọ ti ẹ̀sìn, wọ́n sì fún àwọn tó wà níbẹ̀ láǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó kú náà. Ọ̀kan lára àwọn tó sọ̀rọ̀ níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ikú gbígbóná tó pa ọ̀dọ́kùnrin yìí nípa sísọ pé, ‘Ọlọ́run nílò rẹ̀ ní ọ̀run ló ṣe mú un lọ.’ Kristẹni arákùnrin wa rí i pé èyí ti kọjá ohun téèyàn kò fi ní sọ̀rọ̀. Bó ṣe lọ síbi tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mú Bíbélì tàbí àkọsílẹ̀ kankan lọ́wọ́. Ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹ rò pé Ọlọ́run Olódùmarè tó jẹ́ aláàánú àti oníyọ̀ọ́nú ní inú dídùn sí irú nǹkan báwọ̀nyí?” Bó ṣe sọ àsọyé oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá tí kò rò tẹ́lẹ̀ nìyẹn, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ láti fi ṣàlàyé ìdí táa fi ń kú, ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti gba ìran ènìyàn lọ́wọ́ ikú, àti ìfojúsọ́nà àgbàyanu ti àjíǹde sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Bó ṣe sọ̀rọ̀ tán ni àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́ fún àkókò gígùn. Arákùnrin náà wá sọ lẹ́yìn náà pé: “Inú mi ò dùn tó báyẹn rí. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún kíkọ́ tí ó fi ọgbọ́n rẹ̀ kọ́ mi, tó sì fún mi láǹfààní láti gbèjà orúkọ mímọ́ rẹ̀.”

Jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà wé mọ́ jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà ń tipasẹ̀ Bíbélì kọ́ wa bí a ó ṣe gbé ìgbé ayé wa. Àwọn òfin àti ìlànà táa kọ sínú rẹ̀ ló dára jù lọ, tó sì ṣàǹfààní jù lọ fún ìgbésí ayé. (Aísáyà 48:17) Má ṣe jẹ́ kí ìyọlẹ́nu látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn tàbí àìlera tìrẹ fúnra rẹ mú ọ yapa kúrò nínú títẹ̀lé àwọn òfin Jèhófà. Dúró ṣinṣin ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run tún kan jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ètò àjọ rẹ̀. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó ti di dandan láti ṣe àwọn ìyípadà àti àtúnṣe sí òye táa ní lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ẹnikẹ́ni tó ń jẹ àjẹyó nípa tẹ̀mí bíi tiwa. (Mátíù 24:45-47) Láìsí àní-àní, Jèhófà ń ti ètò àjọ rẹ̀ tòde òní lẹ́yìn. Ṣé àwa náà kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni? A. H. Macmillan ṣe bẹ́ẹ̀. Kété ṣáájú ikú rẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti rí i bí ètò àjọ Jèhófà ṣe tẹ̀ síwájú látorí ìbẹ̀rẹ̀ kékeré kan, nígbà tí mo ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélógún ní September 1900, dórí ẹgbẹ́ àwọn èèyàn aláyọ̀ jákèjádò ayé tí wọ́n ń fi tìtaratìtara kéde òtítọ́ rẹ̀. . . . Ó dá mi lójú ju ti ìgbàkígbà rí lọ, bí mo ṣe ń rí i pé iṣẹ́ ìsìn mi sí Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ti ń lọ sópin, pé Jèhófà ti darí àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ti fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò gan-an ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Arákùnrin Macmillan fi ìṣòtítọ́ àti ìdúróṣinṣin sìn fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin, kó tó di pé ó kú ní August 26, 1966. Ó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún dídúró ṣinṣin ti ètò àjọ Ọlọ́run táa lè fojú rí.

Láfikún sí jíjẹ́ adúróṣinṣin ti ètò àjọ náà, ṣé a óò jẹ́ adúróṣinṣin sí ara wa? Nígbà táa bá dojú kọ inúnibíni líle koko, ṣé a óò dúró ṣinṣin ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa? Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn arákùnrin wa ní Netherlands fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nípa ìdúróṣinṣin. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Klaas de Vries, láti ìjọ Groningen, ni Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo ti ìjọba Násì fi ìwà òǹrorò fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, wọ́n fi í sínú àhámọ́ àdáwà fún ọjọ́ méjìlá gbáko, wọ́n ń fún un ní kíkì búrẹ́dì àti omi, lẹ́yìn náà wọ́n tún fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Wọ́n na ìbọn sí i, wọ́n ní àwọn máa pa á, wọ́n sì fún un ní ìṣẹ́jú méjì péré láti sọ ibi tí àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú wà, àti láti fún wọn ní àwọn ìsọfúnni mìíràn tó ṣe pàtàkì. Kìkì ohun tí Klaas sọ ni pé: “Ẹ ò ní gbọ́ ohunkóhun lẹ́nu mi mọ́. . . . Mi ò ní di ọ̀dàlẹ̀.” Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sọ pé àwọn máa yìnbọn pa á. Nígbà tó sú Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo, wọ́n jáwọ́, wọ́n sì tún rán Klaas lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mìíràn. Kò da àwọn arákùnrin rẹ̀ rí.

Ṣé ìdúróṣinṣin wa yóò nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ìbátan wa tó sún mọ́ wa jù lọ—ìyẹn ọkọ tàbí aya wa? Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe pa májẹ̀mú tó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá mọ́, ṣé àwa náà dúró ṣinṣin ti ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wa? Yàtọ̀ sí dídúró ti ẹ̀jẹ́ náà ṣinṣin, o tún gbọ́dọ̀ máa lépa àtiní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ. Sapá láti jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ẹ máa lo àkókò pa pọ̀, ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ fàlàlà, láìfi ohunkóhun pa mọ́, ẹ máa ti ara yín lẹ́yìn, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú, ẹ fetí sí ara yín, ẹ rẹ́rìn-ín pa pọ̀, ẹ sọkún pa pọ̀, ẹ ṣeré pa pọ̀, ẹ pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ kí ẹ̀yin méjèèjì lè lé góńgó yín bá, ẹ tẹ́ ara yín lọ́rùn, ẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara yín. Ẹ ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá lè ṣe láti yẹra fún níní ìfẹ́ ìbálòpọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tọ́ láti di ojúlùmọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, o tiẹ̀ lè fi wọ́n ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pàápàá, àmọ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ kò gbọ́dọ̀ kọjá àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kó sí yín láàárín.—Òwe 5:15-20.

Jẹ́ adúróṣinṣin ti àwọn ọ̀rẹ́ tí ẹ jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí àti ìdílé rẹ. Má ṣe gbàgbé wọn bí ọdún ti ń gorí ọdún. Máa kàn sí wọn, kọ lẹ́tà, tẹ̀ wọ́n láago, ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Ipòkípò tóo bá wà, gbìyànjú láti má ṣe já wọn kulẹ̀. Jẹ́ kí inú wọn máa dùn láti sọ pé àwọn mọ̀ ọ́ tàbí pé àwọn bá ọ tan. Jíjẹ́ adúróṣinṣin tì wọ́n yóò jẹ́ kóo pinnu láti ṣe ohun tó tọ́, yóò sì jẹ́ orísun ìṣírí fún ọ.—Ẹ́sítérì 4:6-16.

Bẹ́ẹ̀ ni o, ìdúróṣinṣin tòótọ́ wé mọ́ gbígbé ìgbésẹ̀ tó dára láti pa àjọṣe tó níye lórí mọ́. Ṣe gbogbo ohun tóo bá lè ṣe láti san inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà padà. Fara wé ìdúróṣinṣin Jèhófà nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú ìjọ Kristẹni, pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ, ìdílé rẹ, àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Fi ìdúróṣinṣin kéde ìwà funfun Jèhófà fáwọn aládùúgbò rẹ. Bó ṣe rí gẹ́ẹ́ ni onísáàmù náà ṣe sọ ọ́ pé: “Àwọn ìfihàn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni èmi yóò máa fi ṣe orin kọ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ní ìran dé ìran ni èmi yóò máa fi ẹnu mi sọ ìṣòtítọ́ rẹ di mímọ̀.” (Sáàmù 89:1) Ǹjẹ́ kò yẹ ká sún mọ́ irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀? Ní ti tòótọ́, “inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 100:5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

A. H. Macmillan