Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún péré ni Sarah Jayne nígbà tí wọ́n sọ fún un pé àrùn jẹjẹrẹ wà nínú ilé ẹyin rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún un, ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí le, ó sì gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Àní ọkàn rẹ̀ balẹ̀ débi pé nígbà tó pé ọmọ ogún ọdún, ó ní àfẹ́sọ́nà, ó sì ń múra àtiṣe ìgbéyàwó. Ọdún yẹn ni àrùn jẹjẹrẹ náà tún padà dé, wọ́n sì sọ fún un pé ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré ló kù fún un láti lò láyé. Sarah Jayne kú ní June 2000, nígbà tó kù díẹ̀ kó pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

OHUN tó wú àwọn tó wá kí Sarah Jayne ní ọsibítù lórí ni pé, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú, ó tún ní ìgbàgbọ́ àtọkànwá nínú Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn kò-gbóògùn fẹ́ dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò, ìrètí àjíǹde dá a lójú—ó dá a lójú pé òun ṣì máa rí àwọn ọ̀rẹ́ òun lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 5:28, 29) Ó sọ pé: “Màá rí gbogbo yín nínú ayé tuntun Ọlọ́run.”

Àwọn kan ń bẹnu àtẹ́ lu irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n ní kò yàtọ̀ sí àlá tí kò lè ṣẹ. Ọ̀gbẹ́ni Ludovic Kennedy béèrè pé: “Kí tiẹ̀ ni ẹ̀ ń pè ní ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ná, bí kò ṣe ìgbàgbọ́ àwọn ojo ẹ̀dá pé nígbà tí ìpè ìkẹyìn bá dún, ìgbádùn yóò wá bẹ̀rẹ̀ ní kẹlẹlẹ nínú ọgbà Édẹ́nì ológo kan, níbi tí àwọn àtàwọn tó ti kú tẹ́lẹ̀, àtàwọn tí yóò kú lẹ́yìn wọn yóò ti jùmọ̀ máa hó ìhó ayọ̀?” Àwa náà ní ìbéèrè kan tó tako ti ọ̀gbẹ́ni yìí. Ìbéèrè tiwa ni pé, Èwo ló bọ́gbọ́n mu jù lọ—ṣé ká gbà pé “ìgbésí ayé ọ̀hún kò ju báyìí náà lọ, ká sì máa fìkánjú jayé,” gẹ́gẹ́ bí Kennedy ti dá a lábàá ni, tàbí ká gba Ọlọ́run àti ìlérí rẹ̀ nípa àjíǹde gbọ́? Èyí tó kẹ́yìn yìí ni Sarah Jayne yàn. Báwo ló ṣe ní irú ìgbàgbọ́ yẹn?

‘Ẹ Máa Wá Ọlọ́run . . . Kí Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi’

Kóo tó lè ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹnì kan, o ní láti mọ̀ ọ́n, kóo mọ bó ṣe ń ronú àti ìṣesí rẹ̀. Èyí wé mọ́ ọkàn àti èrò inú. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí táa bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú Ọlọ́run. O ní láti mọ̀ ọ́n, kóo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ àti ìwà rẹ̀, kóo mọ bó ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó nínú gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.—Sáàmù 9:10; 145:1-21.

Àwọn kan rò pé èyí ò ṣeé ṣe. Wọ́n ní Ọlọ́run jìnnà sí wa gan-an, wọ́n ní àdììtú ni—ìyẹn bó bá tilẹ̀ wà rárá. Oníyèmejì kan lè béèrè pé, “Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, bó ṣe rí lọ́kàn àwọn Kristẹni bíi Sarah Jayne, kí ló dé tí kò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwa yòókù?” Àmọ́, ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run jìnnà sí wa, tí a kò sì mọ ibi táa lè wá a sí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn amòye ìlú Áténì, pé “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀” ti pèsè gbogbo ohun táa nílò láti “wá [a] . . . kí [á] sì rí i ní ti gidi.” Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ sọ pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:24-27.

Báwo wá ni o ṣe lè ‘wá Ọlọ́run . . . kí o sì rí i ní ti gidi’? Àwọn kan ti wá a nípa wíwulẹ̀ fara balẹ̀ wo àgbáálá ayé wa. Ṣíṣe èyí nìkan ti tó láti mú un dá ọ̀pọ̀ èèyàn lójú pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́. a (Sáàmù 19:1; Aísáyà 40:26; Ìṣe 14:16, 17) Wọ́n gbà pé òótọ́ lohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé “àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.”—Róòmù 1:20; Sáàmù 104:24.

O Nílò Bíbélì

Ṣùgbọ́n kóo tó lè ní ìgbàgbọ́ gidi nínú Ẹlẹ́dàá, o nílò nǹkan míì tí ó pèsè. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Bíbélì ni—tí í ṣe Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, nínú èyí tí ó ti ṣí ìfẹ́ àti ète rẹ̀ payá. (2 Tímótì 3:16, 17) Àwọn kan lè sọ pé, “Àmọ́ dúró ná o, báwo lèèyàn ṣe lè gba gbogbo ohun tí Bíbélì wí gbọ́, nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ burúkú ló kún ọwọ́ àwọn tó ń gbé Bíbélì?” Òótọ́ ni pé ìtàn Kirisẹ́ńdọ̀mù kún fún àgàbàgebè, ìwà òǹrorò, àti ìwà pálapàla. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ olóye á mọ̀ pé Kirisẹ́ńdọ̀mù kàn ń díbọ́n pé òun ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ni.—Mátíù 15:8.

Bíbélì pàápàá kìlọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò máa sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, àmọ́ tó jẹ́ pé ní ti gidi, wọn yóò “sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú olúwa tí ó rà wọ́n pàápàá.” Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ní tìtorí àwọn wọ̀nyí, ọ̀nà òtítọ́ yóò sì di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” (2 Pétérù 2:1, 2) Jésù Kristi sọ pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ “oníṣẹ́ ìwà àìlófin,” tí iṣẹ́ burúkú wọn yóò fi wọ́n hàn kedere. (Mátíù 7:15-23) Ẹni tó bá kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ nítorí ìwà burúkú Kirisẹ́ńdọ̀mù dà bí ẹni tó ju lẹ́tà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kọ sí i nù, kìkì nítorí pé ẹni tó mú lẹ́tà náà wá kò lórúkọ rere.

Èèyàn ò lè ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ láìsí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Inú Bíbélì nìkan la ti lè rí ohun tí Jèhófà fẹ́. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti ń jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn tipẹ́, bíi, ìdí tó fi fàyè gba ìjìyà àti ìrora, àti ohun tí yóò ṣe nípa nǹkan wọ̀nyí. (Sáàmù 119:105; Róòmù 15:4) Sarah Jayne gbà pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì. (1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Pétérù 1:19-21) Báwo ló ṣe gbà gbọ́? Kì í kàn-án ṣe nítorí pé àwọn òbí rẹ̀ sọ pé kí ó gbà gbọ́, bí kò ṣe nítorí pé ó fi tọkàntọkàn ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì jẹ́ àkànṣe ìwé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 12:2) Fún àpẹẹrẹ, ó kíyè sí agbára tí Bíbélì ń sà nínú ìgbésí ayé àwọn tó rọ̀ mọ́ ìlànà inú rẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìwé bíi The Bible—God’s Word or Man’s?, b ó tún fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí pelemọ tó wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí kíkọ rẹ̀.

“Ìgbàgbọ́ Ń Tẹ̀ Lé Ohun Tí A Gbọ́”

Àmọ́ ṣá o, kò tó láti wulẹ̀ ní Bíbélì lọ́wọ́ tàbí ká tiẹ̀ gbà pé ó ní ìmísí pàápàá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Gbígbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ló ń gbé ìgbàgbọ́ ró, kì í wulẹ̀ ṣe níní Bíbélì lọ́wọ́. Wàá fi hàn pé o ń “gbọ́” ohun tí Ọlọ́run ní í sọ nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kóo sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Àwọn ọmọdé pàápàá lè ṣe èyí. Pọ́ọ̀lù sọ pé “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́.” Ṣé ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé wọ́n ra á níyè? Rárá o! Wọn ò lo agbárí fún Tímótì, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò tàn án jẹ́ rárá. Ńṣe ni wọ́n ‘yí i lérò padà láti gba’ ohun tó gbọ́ àti ohun tó kà gbọ́.—2 Tímótì 1:5; 3:14, 15.

Ọ̀nà kan náà ni a gbà yí Sarah Jayne lérò padà. Bíi ti àwọn ará Bèróà ọ̀rúndún kìíní, ó “gba ọ̀rọ̀ náà [látẹnu àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn olùkọ́ mìíràn] pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú.” Ó dájú pé nígbà tó wà lọ́mọdé, ó gba ohun táwọn òbí rẹ̀ sọ fún un gbọ́. Lẹ́yìn náà, bó ti ń dàgbà, kò kàn gba gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ ọ láìronú lé wọn lórí tàbí láìwádìí. Ó máa “ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

O Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

Ìwọ náà lè ní ìgbàgbọ́ tòótọ́—ìyẹn irú ìgbàgbọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù. Ó sọ pé irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Bóo bá ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, yóò dá ọ lójú hán-ún hán-ún pé gbogbo ìrètí àti ìfojúsọ́nà rẹ, títí kan ìlérí àjíǹde tí Ọlọ́run ṣe, ni yóò ní ìmúṣẹ. Yóò dá ọ lójú pé orí ohun tó dájú la gbé ìrètí wọ̀nyẹn kà, kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Wàá mọ̀ pé ìlérí Jèhófà kò ṣákìí rí. (Jóṣúà 21:45; 23:14; Aísáyà 55:10, 11; Hébérù 6:18) Ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò dá ọ lójú bíi pé ó ti dé. (2 Pétérù 3:13) Wàá fojú ìgbàgbọ́ rí i kedere pé ẹni gidi ni Jèhófà Ọlọ́run, àti Jésù Kristi, àti pé lóòótọ́-lóòótọ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò dé, wàá sì rí i pé gbogbo èyí kì í ṣe gbígbéra ẹni gẹṣin aáyán.

A kò dá ọ̀ràn níní ìgbàgbọ́ tòótọ́ dá ìwọ nìkan. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ó tún pèsè ìjọ Kristẹni kárí ayé, èyí táa yàn láti ran àwọn ọlọ́kàn títọ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. (Jòhánù 17:20; Róòmù 10:14, 15) Tẹ́wọ́ gba gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ yẹn. (Ìṣe 8:30, 31) Níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ sì ti jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí ẹ̀mí yẹn ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tòótọ́.—Gálátíà 5:22.

Má ṣe jẹ́ kí àwọn oníyèméjì tó ń pẹ̀gàn ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. (1 Kọ́ríńtì 1:18-21; 2 Pétérù 3:3, 4) Àní ìgbàgbọ́ tòótọ́ gan-an ni yóò jẹ́ kóo dúró gbọn-in láti dojú kọ irú àtakò bẹ́ẹ̀. (Éfésù 6:16) Sarah Jayne rí i pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ìgbà gbogbo ló sì ń fún àwọn tó wá kí i ní ọsibítù níṣìírí pé kí àwọn náà ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ó máa ń sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ òtítọ́ di tiyín. Ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ sún mọ́ ètò Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí. Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀. Ẹ jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.”—Jákọ́bù 2:17, 26.

Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú rẹ̀ rí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run àti àjíǹde, ó sọ pé: “Kò sí àní-àní pé tọkàntọkàn lo fi gba èyí gbọ́.” Nígbà tí wọ́n bi í pé kí ló jẹ́ kó dá a lójú tó bẹ́ẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, pẹ̀lú gbogbo àdánwò rẹ̀, ó fèsì pé: “Nítorí pé mo nígbàgbọ́ nínú Jèhófà ni. Ọ̀rẹ́ gidi ló jẹ́ fún mi, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi.”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ ìwé yìí jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

“Láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

A gbóríyìn fún àwọn ará Bèróà nítorí pé wọ́n ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́

[Credit Line]

Látinú “Photo-Drama of Creation,” 1914

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Gbígbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì àti ṣíṣègbọràn sí i ló ń gbé ìgbàgbọ́ ró, kì í wulẹ̀ ṣe níní Bíbélì lọ́wọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Màá rí gbogbo yín nínú ayé tuntun Ọlọ́run”