Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ohun Ìyanu Lọ́tùn-Ún Lósì Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ ERIC ÀTI HAZEL BEVERIDGE ṢE SỌ Ọ́

“Mo dájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún ọ.” Ńṣe lọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń ró kìì lọ́kàn mi bí wọ́n ṣe ń gbé mi lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Strangeways nílùú Manchester, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Oṣù December 1950 nìyẹn ṣẹlẹ̀, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fojú winá ọ̀kan lára àdánwò líle koko jù lọ nínú ìgbésí ayé mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ ni—mo kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.—2 Kọ́ríńtì 10:3-5.

AṢÁÁJÚ Ọ̀NÀ ni mí, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn ì bá sì ti jẹ́ kí wọ́n yọ̀ǹda mi pé kí n má wọṣẹ́ ológun, ṣùgbọ́n òfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò kà wá sí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Bí èmi nìkan ṣoṣo gíro ṣe bá ara mi nínú yàrá kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nìyẹn o. Ọkàn mi wá lọ sọ́dọ̀ bàbá mi. Lọ́nà kan ṣá, òun ló jẹ́ kí n dèrò ẹ̀wọ̀n.

Ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ni bàbá mi, ọmọ àdúgbò Yorkshire ni, kò sì gba gbẹ̀rẹ́. Nítorí ohun tójú rẹ̀ rí lójú ogun àti nítorí iṣẹ́ rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ̀sìn Kátólíìkì sétí rárá. Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930 ló kọ́kọ́ gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí, nígbà tó fẹ́ lọ lé wọn dà nù lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀—ṣùgbọ́n ńṣe ló padà dé tòun ti ìwé wọn lọ́wọ́! Nígbà tó yá, ó forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Consolation (táa ń pè ní Jí! nísinsìnyí). Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń wá fún un níṣìírí lọ́dọọdún pé kó sọ ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn náà dọ̀tun. Nígbà tí mo pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, wọ́n tún wá bá bàbá mi jíròrò, mo sì gbè sẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí. Ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mí nígbà tí mo ṣe batisí ní March 1949, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Lẹ́yìn náà lọ́dún yẹn, mo pàdé John àti Michael Charuk, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó wà fáwọn míṣọ́nnárì, nígbà tí wọ́n ń lọ sí Nàìjíríà. Ẹ̀mí míṣọ́nnárì tí wọ́n ní wú mi lórí gan-an ni. Bóyá ni wọ́n mọ̀ pé àwọn ló gbin ẹ̀mí yẹn sí mi lọ́kàn.

Ìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ọ̀ràn lílọ sí yunifásítì ti ṣí kúrò lọ́kàn mi. Láàárín ọdún kan tí mo filé sílẹ̀, tí mo lọ ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ Aṣọ́bodè ní London, mo rí i pé iṣẹ́ ìjọba kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. Nígbà tí mo fi iṣẹ́ ọ́fíìsì sílẹ̀, ọ̀gbẹ́ni kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀hún sọ pé òun bá mi yọ̀ pé mo jáwọ́ nínú “iṣẹ́ tí kò ní àlùbáríkà.”

Mo dojú kọ àdánwò mìíràn ṣáájú èyí—ìyẹn ni bí mo ṣe máa sọ fún bàbá mi pé mo fẹ́ fiṣẹ́ gidi tí mo rí sílẹ̀, kí n lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Alẹ́ ọjọ́ kan lákòókò tí mo wà lẹ́nu ìsinmi ni mo la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀. Mo ń retí kí bàbá mi tutọ́ sókè kó fojú gbà á. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tó kàn sọ pé: “Tóò, gbogbo rẹ̀ dọwọ́ ẹ; kì í sì í dọwọ́ ẹni ká dà á délẹ̀. Àmọ́ bí nǹkan bá yíwọ́, máà sá wá bá mi o.” Ohun tí mo kọ sínú ìwé àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ́ fún January 1, 1950 ni pé: “Mo sọ fún Dádì pé mo fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ó gbà fún mi. Ẹ̀mí rere tó fi gbà á jẹ́ kí omi bọ́ lójú mi.” Mo kọ̀wé fiṣẹ́ ìjọba sílẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún.

“Ilé Mọ́ńbé” Tó Wà Níbi Táa Yàn Mí Sí

Nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ wàyí tó dán ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run wò. Níbi tí wọ́n yàn fún mi láti lọ ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Lancashire, wọ́n ní “ilé mọ́ńbé” kan wà níbẹ̀ tí wọ́n yọ̀ǹda pé kí èmi àti Lloyd Griffiths, Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi láti Wales, jọ máa gbé. Gbogbo bí mo ṣe ń bọ̀ ni mo ń fojú inú wo ilé mọ́ńbé mèremère náà, títí mo fi dé Bacup, ìlú òjò, tí ojú ọjọ́ ti máa ń dágùdẹ̀. Kò pẹ́ tí ojú mi mọ́ fee, àṣé àjàalẹ̀ ni ilé mọ́ńbé ọ̀hún! Èkúté àti aáyán ló máa ń bá wa ṣeré lóru. Díẹ̀ báyìí ló kù kí n padà sílé. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, mo béèrè fún okun láti kojú ìdánwò yìí. Lójú ẹsẹ̀ ni ara tù mí pẹ̀sẹ̀, mo sì wá tún ọ̀ràn náà rò. Ètò Jèhófà ló yan iṣẹ́ yìí fún mi. Màá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Mo mà dúpẹ́ pé mo fàyà rán ìṣòro náà o, torí pé ká ní mo sá padà ni, bí ìgbésí ayé mi ì bá ṣe yí padà pátápátá nìyẹn!—Aísáyà 26:3, 4.

Kó tó di pé wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n nítorí pé mo kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án ni mo fi wàásù ní Àfonífojì Rossendale níbi tí ìṣẹ́ ti ń ṣẹ́ àwọn èèyàn nígbà yẹn. Lẹ́yìn tí mo ṣe ọ̀sẹ̀ méjì ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Strangeways, wọ́n gbé mi lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Lewes ní etíkun gúúsù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwa Ẹlẹ́rìí márùn-ún la jọ ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀, a sì ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi nínú yàrá ẹ̀wọ̀n kan.

Bàbá mi wá wò mí lẹ́ẹ̀kan. Ó ti ní láti kó ìtìjú bá a gan-an ni—òun tó jẹ́ gbajúmọ̀ ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n, tó wá wo ọmọ rẹ̀ tó ń ṣẹ̀wọ̀n! Ìgbà gbogbo ni n óò máa dúpẹ́ fún ìgbésẹ̀ tó gbé yẹn. Níkẹyìn, wọ́n tú mi sílẹ̀ ní April 1951.

Gbàrà tí wọ́n tú mi sílẹ̀ ní Lewes, mo wọkọ̀ ojú irin lọ sílùú Cardiff, ní Wales, níbi tí bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá pátápátá ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà níbẹ̀. Èmi ni àkọ́bí lára àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin—ọkùnrin mẹ́ta, obìnrin kan. Ó di dandan kí n lọ wá iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ṣe, kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi, kí n sì lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi nìṣó. Mo lọ ń ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n ti ń ta aṣọ, àmọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ló wà ní góńgó ẹ̀mí mi. Àárín àkókò yìí ni màmá wa fi wá sílẹ̀. Ìyẹn gbo Dádì àti àwa ọmọ gan-an, àwa tí ọjọ́ orí wa jẹ́ láti ọdún mẹ́jọ sí mọ́kàndínlógún. Ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ pé àwọn òbí wa kọ ara wọn sílẹ̀.

Ẹni Tó Bá Rí Aya Rere . . .

Àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan wà nínú ìjọ wa. Lára wọn ni arábìnrin kan tó máa ń wá lójoojúmọ́ láti Àfonífojì Rhondda tí wọ́n ti ń wa kùsà. Ó máa ń wá fún iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ àti fún iṣẹ́ ìwàásù. Hazel Green lorúkọ rẹ̀—aṣáájú ọ̀nà tó gbéṣẹ́ ni. Hazel ti pẹ́ nínú òtítọ́ jù mí lọ—láti àwọn ọdún 1920 làwọn òbí rẹ̀ ti ń lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (táa mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí). Ṣùgbọ́n á dáa kó kúkú fẹnu ara rẹ̀ sọ ìtàn tirẹ̀.

“Ọdún 1944, nígbà tí mo ka ìwé pẹlẹbẹ náà Religion Reaps the Whirlwind, ni mo tó fọwọ́ dan-indan-in mú òtítọ́. Màmá mi rọ̀ mí pé kí n lọ sí àpéjọ àyíká nílùú Cardiff. Láìmọ nǹkan kan nípa Bíbélì, mo bá ara mi ní àárín ọjà pẹ̀lú àkọlé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí mo gbé kọ́rùn, táa fi ń polongo àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Mo borí ìṣòro yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn mìíràn ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wa. Mo ṣe batisí ní 1946, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà ní oṣù December ọdún yẹn. Nígbà tó wá di ọdún 1951 ni ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà kan dé sílùú Cardiff, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀wọ̀n dé ni. Eric ni orúkọ rẹ̀.

“A jọ máa ń lọ wàásù ni. A mọwọ́ ara wa gan-an. Góńgó wa nínú ìgbésí ayé bára mu—ó jẹ́ láti máa wá ire Ìjọba Ọlọ́run. Báa ṣe ṣègbéyàwó ní December 1952 nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa méjèèjì la jọ ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, tí owó tó ń wọlé fún wa sì kéré, àwọn nǹkan kòṣeémánìí kò wọ́n wa rí. Nígbà míì, a máa ń ṣàdédé rí ẹ̀bùn gbà látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí tó rà ju ọṣẹ tàbí epo tó nílò lọ—á sì wá lọ bó sákòókò táa nílò rẹ̀! A mọrírì àwọn ẹ̀bùn tó wúlò wọ̀nyí gidigidi. Àmọ́ àwọn ohun ìyanu ńlá ṣì ń bọ̀ lọ́nà.”

Ohun Ìyanu Tó Yí Ìgbésí Ayé Wa Padà

Ní November 1954, èmi àti Hazel gba ohun àgbàyanu tí a kò retí—a rí fọ́ọ̀mù kan gbà láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní London, wọ́n fẹ́ kí n kọ ọ̀rọ̀ sí i, kí wọ́n lè sọ mí di alábòójútó arìnrìn àjò, kí n lọ máa bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó dá wa lójú pé àṣìṣe ni, nítorí náà a kò sọ fún ẹnikẹ́ni nínú ìjọ. Àmọ́ o, mo kọ ọ̀rọ̀ síbi tó yẹ nínú fọ́ọ̀mù náà, mo fi ránṣẹ́ padà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí fojú sọ́nà. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà ni èsì dé, pé “Máa bọ̀ ní London fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́”!

Ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní London, ó yà mí lẹ́nu pé èmi ẹni ọdún mẹ́tàlélógún, wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin títayọ, àwọn tí mo kà sí àràbà nípa tẹ̀mí—àwọn bíi Pryce Hughes, Emlyn Wynes, Ernie Beavor, Ernie Guiver, Bob Gough, Glynn Parr, Stan àti Martin Woodburn, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ti ré kọjá lọ. Àwọn ló fi ìpìlẹ̀ tó dúró sán-ún lélẹ̀ fún ìtara àti ìpàwàtítọ́mọ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní àwọn ọdún 1940 sí àwọn ọdún 1950.

Iṣẹ́ Àyíká Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Kì Í Súni

Ìgbà òtútù ọdún 1954 sí 1955 la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn àjò. Wọ́n yàn wá sí East Anglia, tí í ṣe àgbègbè tó tẹ́ pẹrẹsẹ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí òtútù ti máa ń mú gan-an nítorí ẹ̀fúùfù tó ń wá láti Òkun Àríwá. Ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] péré ni iye àwa Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà yẹn. Àyíká táa kọ́kọ́ bẹ̀ wò kò rọrùn fún wa rárá; bẹ́ẹ̀ náà ni kò rọrùn fáwọn ará táa bẹ̀ wò. Nítorí pé n ò ní ìrírí àti nítorí pé àwa ará Yorkshire máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkó, nígbà míì, mo máa ń ṣẹ àwọn èèyàn. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ti wá rí i pé inú rere ṣe pàtàkì ju jíjẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ àti pé àwọn èèyàn ṣe pàtàkì ju àwọn ọ̀nà ìgbà-ṣe-nǹkan. Mo ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nípa títu àwọn ènìyàn lára, ṣùgbọ́n mo máa ń kùnà nígbà míì.—Mátíù 11:28-30.

Lẹ́yìn oṣù méjìdínlógún ní East Anglia, wọ́n ní ká lọ sìn ní àyíká kan ní àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní Newcastle tó wà lẹ́bàá Odò Tyne àti Northumberland. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ọlọ́yàyà tó ń gbé ní àgbègbè ẹlẹ́wà yẹn. Don Ward, alábòójútó àgbègbè wa, tó wá láti ìlú Seattle, ní Washington, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Kíláàsì ogún ní Gílíádì ló ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde. Tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo kàn máa ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu bí ẹni tí nǹkan ń jó lẹ́nu. Òun ló wá kọ́ mi bí a ṣe ń rọra sọ̀rọ̀, àti bí a ṣe ń dánu dúró díẹ̀, òun ló sì kọ́ mi bí a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Ohun Ìyanu Míì Tó Yí Ìgbésí Ayé Wa Padà

Lọ́dún 1958, a gba lẹ́tà kan tó yí ìgbésí ayé wa padà. Wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní South Lansing, New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. A ta ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa kékeré tí wọ́n ń pè ní Austin Seven tí wọ́n ṣe ní 1935, a sì sanwó ọkọ̀ òkun tó máa gbé wa lọ sí New York. A kọ́kọ́ lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York City. A gbabẹ̀ lọ sílùú Peterborough, ní ìpínlẹ̀ Ontario, láti lọ ṣe aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà ká tó forí lé ìhà gúúsù fún Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.

Albert Schroeder, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso báyìí, àti Maxwell Friend àti Jack Redford, tó ti kú báyìí, wà lára àwọn olùkọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ náà. Ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ méjìlélọ́gọ́rin láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá gbé wa ró gan-an. A bẹ̀rẹ̀ sí mọ nǹkan díẹ̀díẹ̀ nípa àṣà ìbílẹ̀ ara wa. Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ká mọ irú ìṣòro tí a óò ní nígbà táa bá ń kọ́ èdè míì. Oṣù márùn-ún ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà gbà, wọ́n sì rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Ọjọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege dé wẹ́rẹ́, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà táa fi kọjá sí New York City, táa ń dúró de ọkọ̀ òkun náà, Queen Elizabeth, tí yóò gbé wa padà sí Yúróòpù.

Iṣẹ́ Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Yàn fún Wa Nílẹ̀ Òkèèrè

Ibo ni wọ́n yàn wá sí? Ilẹ̀ Potogí ni o! A dé sílùú Lisbon ní November 1959. A wá dojú kọ ìdánwò bí a ó ṣe kọ́ èdè àti àṣà ìbílẹ̀ tuntun. Ní 1959, Ẹlẹ́rìí ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́tàlélógójì [643] ló wà lẹ́nu iṣẹ́ náà nílẹ̀ Potogí, tí iye àwọn olùgbé rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án. Ṣùgbọ́n wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, kò sí àkọlé kankan lóde.

Lẹ́yìn tí míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Elsa Piccone kọ́ wa lédè Potogí, èmi àti Hazel bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ìjọ àti àwùjọ tí ń bẹ láyìíká ìlú Lisbon, Faro, Evora, àti Beja wò. Nǹkan wá bẹ̀rẹ̀ sí yí padà nígbà tó di 1961. Mo ń kọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ João Gonçalves Mateus lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó pinnu pé òun máa dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, láìdásí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ogun jíjà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni orílé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá ní kí n yọjú sáwọn, kí n wá sọ tẹnu mi. Ohun ìyanu míì tún dé o! Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n sọ fún wa pé ká fi orílẹ̀-èdè àwọn sílẹ̀ láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ péré! Ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sáwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wa, bíi Eric àti Christina Britten àti Domenick àti Elsa Piccone.

Mo bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n jọ̀ọ́ tún ẹjọ́ wa gbọ́, wọ́n sì jẹ́ ká rí ọ̀gá àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. Ó sọ ìdí tí wọ́n fi ní ká máa lọ fún wa láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, ó sì dárúkọ ẹnì kan—ìyẹn João Gonçalves Mateus—akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi! Ó sọ pé ilẹ̀ Potogí yàtọ̀ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó ní lọ́dọ̀ tàwọn, ẹnì kan ò lè sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò ní jẹ́ kóun wọṣẹ́ ológun. Ó wá di dandan ká fi ilẹ̀ Potogí sílẹ̀. Bí èmi àti João ò ṣe gbúròó ara mọ́ nìyẹn o. Àmọ́ ní ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà, ẹ wo bínú wa ṣe dùn tó láti rí òun àtìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nígbà ìyàsímímọ́ Bẹ́tẹ́lì tuntun ti ilẹ̀ Potogí! Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nílẹ̀ Potogí kò já sásán!—1 Kọ́ríńtì 3:6-9.

Ibo ni wọ́n máa rán wa lọ báyìí o? Ohun ìyanu tún ni! Orílẹ̀-èdè Sípéènì tí ń bẹ nítòsí là ń lọ. Ní February 1962, pẹ̀lú omijé lójú, a wọkọ̀ ojú irin ní Lisbon, a sì forí lé ìlú Madrid.

Kíkọ́ Àṣà Ìbílẹ̀ Mìíràn

Ní Sípéènì, a ní láti kọ́ wíwàásù àti ṣíṣe ìpàdé ní ìdákọ́ńkọ́. Nígbà táa bá ń wàásù, a kì í wọ ilé méjì tó tira wọn. Lẹ́yìn táa bá jẹ́rìí nílé kan, a ó gbọ̀nà àdúgbò míì lọ, ká tó tún wọlé míì. Ìyẹn jẹ́ kó nira fáwọn ọlọ́pàá—tàbí àwọn àlùfáà—láti rí wa mú. Ẹ má gbàgbé o, pé Ìjọba oníkùmọ̀, tí ọ̀pá àṣẹ rẹ̀ wà lọ́wọ́ ìjọ Kátólíìkì, ló wà lórí àlééfà, wọ́n sì ti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ ìwàásù wa. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, a bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ àwọn ará Sípéènì, kí wọ́n má bàa tètè dá wa mọ̀. Èmi ń jẹ́ Pablo, Hazel sì ń jẹ́ Juana.

Lẹ́yìn oṣù mélòó kan nílùú Madrid, wọ́n ní ká lọ máa ṣe iṣẹ́ àyíká nílùú Barcelona. A bẹ ọ̀pọ̀ ìjọ wò nílùú náà, a sábà máa ń lo ọ̀sẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ìbẹ̀wò náà máa ń pẹ́ tóyẹn nítorí pé a gbọ́dọ̀ bẹ àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan wò bí ìgbà táa ń bẹ odindi ìjọ wò, àwùjọ méjì la sábà máa ń bẹ̀ wò láàárín ọ̀sẹ̀ kan.

Ìpèníjà Àìròtẹ́lẹ̀

Ní 1963, wọ́n ní ká wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbègbè ní Sípéènì. Láti lè dé ọ̀dọ̀ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àwọn ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí, tí ń bẹ ní àyíká mẹ́sàn-án tó wà nígbà yẹn, a ní láti rìnrìn àjò jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Igbó kan nítòsí ìlú Seville, àti oko kan nítòsí ìlú Gijon, àti ẹ̀bá àwọn odò tí ń bẹ nítòsí ìlú Madrid, Barcelona, àti Logroño la ti ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àpéjọ àyíká ìdákọ́ńkọ́ tó jẹ́ mánigbàgbé.

Nítorí a-kì-í-bàá-mọ̀, nígbà táa bá ń wàásù láti ilé dé ilé, mo máa ń lọ wo àwọn títì tó wà nítòsí, ká lè mọ ọ̀nà táa lè gbà sá lọ bí wàhálà bá bẹ́. Nígbà kan táa ń wàásù nílùú Madrid, èmi àti Ẹlẹ́rìí kan wà ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì nígbà táa ṣàdédé gbọ́ táwọn kan ń kígbe tòò nísàlẹ̀. Nígbà táa désàlẹ̀, a bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan tó kóra jọ síbẹ̀, wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Kátólíìkì tí wọ́n ń pè ní Hijas de María (Àwọn Ọmọbìnrin Màríà). Wọ́n ń kìlọ̀ fáwọn ará àdúgbò nípa wa. Wọn ò ṣeé bá sọ̀rọ̀, mo sì mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀ ní kíá mọ́sá, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ọwọ́ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá á tẹ̀ wá. Kíá la wábi gbà—lórí eré!

Àwọn ọdún wọ̀nyẹn kò fara rọ rárá ní Sípéènì. A ń gbìyànjú láti fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, títí kan àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe níṣìírí. Wọn ò kọ̀ láti ṣẹ̀wọ̀n, kí wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn, kí wọ́n sáà lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n máa dá ìjọ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa gbé wọn ró.

A tún gbọ́ ìròyìn ìbànújẹ́ ní sáà kan náà yìí. Hazel ṣàlàyé pé: “Màmá mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ kú ní 1964. Ó bà wá nínú jẹ́ gan-an nítorí pé a ò rí i sójú kó tó kú. Ọ̀kan lára ìṣòro tí ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì ń ní nìyí.”

Òmìnira Nígbẹ̀yìngbẹ́yín

Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí wa fún ọ̀pọ̀ ọdún, nígbà tó di July 1970, ìjọba Franco wá gba iṣẹ́ wa láyè lábẹ́ òfin. Inú èmi àti Hazel dùn gan-an nígbà táa ṣí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí àkọ́kọ́ ní Madrid àti èkejì ní Lesseps, nílùú Barcelona. Wọ́n ní àkọlé gàdàgbà, tó máa ń tànmọ́lẹ̀. A fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a ti gbàwé àṣẹ, mìmì kan ò sì lè mì wá mọ́! Ní àkókò táà ń wí yìí, ìyẹn ní 1972, àwa Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ní Sípéènì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000].

Sáà yìí ni mo gbọ́ ìròyìn ayọ̀ láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bàbá mi ti kọ́kọ́ bẹ̀ wá wò ní Sípéènì lọ́dún 1969. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ará Sípéènì ṣe tọ́jú rẹ̀ wú u lórí débi pé nígbà tó padà sílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó wá di 1971, mo gbọ́ pé bàbá mi ti ṣèrìbọmi! Ẹ wo bó ti jẹ́ àkókò alárinrin tó nígbà táa ṣèbẹ̀wò sílé, tí bàbá mi, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni arákùnrin mi, gbàdúrà sórí oúnjẹ táa fẹ́ jẹ. Ó ti lé ní ogún ọdún tí mo ti ń retí ọjọ́ ayọ̀ yìí. Àbúrò mi, Bob àti Iris, ìyàwó rẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí ní 1958. Phillip, ọmọ wọn àti Jean ìyàwó rẹ̀, ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká báyìí ní Sípéènì. Inú wa dùn gidigidi pé wọ́n ń sìn ní orílẹ̀-èdè alárinrin yẹn.

Ohun Ìyanu Tó Dé Kẹ́yìn

Ní February 1980, ọ̀kan lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso wá bẹ Sípéènì wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tó ní òun fẹ́ ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Àṣé ó ń yẹ̀ mí wò ni! Nígbà tó wá di September, wọ́n ní ká máa bọ̀ ní orílé iṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York! Baba ńlá kàyéfì ló jẹ́ fún wa. A tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dùn wá gan-an pé a ó fi àwọn arákùnrin wa ará Sípéènì sílẹ̀. Iye àwọn Ẹlẹ́rìí ti di ẹgbàá mẹ́rìnlélógún [48,000] nígbà yẹn!

Nígbà tí à ń lọ, arákùnrin kan fi aago tó ṣeé tì bọ àpò ta mí lọ́rẹ. Ó kọ ẹsẹ Bíbélì méjì sára rẹ̀—“Lucas 16:10; Lucas 17:10.” Ó ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo máa ń lò jù nìwọ̀nyẹn. Lúùkù 16:10 sọ ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn nǹkan kéékèèké, Lúùkù 17:10 sì sọ pé “ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun” ni wá, fún ìdí yìí kò sídìí fún ṣíṣògo. Mo kúkú mọ̀ pé ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ ni gbogbo ohun táa bá ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Ohun Ìyanu Nípa Ìlera

Ní 1990, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí yọnu. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó di dandan kí wọ́n ki ohun èlò kan tí wọ́n ń pè ní stent bọ̀ ọ́, kí òpó tí ń gbé ẹ̀jẹ̀ jáde láti inú ọkàn má bàa dí pa. Ní àkókò àìlera yìí, Hazel ṣaájò mi lóríṣiríṣi ọ̀nà, òun ló máa ń gbé àwọn àpò àti ẹrù tí mi ò lè gbé. Nígbà tó wá di May 2000, wọ́n fi ẹ̀rọ tí ń mú ọkàn ṣiṣẹ́ dáadáa sínú mi. Ẹ̀rọ yìí mà wúlò o!

Láàárín àádọ́ta ọdún tó ti kọjá, èmi àti Hazel ti rí i pé ọwọ́ Jèhófà kò kúrú, àti pé àkókò tó tọ́ lójú rẹ̀ ni àwọn ète rẹ̀ ń ní ìmúṣẹ, kì í ṣe àkókò tó tọ́ lójú wa. (Aísáyà 59:1; Hábákúkù 2:3) Ọ̀pọ̀ ohun ìyanu tí ń máyọ̀ wá la ti rí nínú ayé wa. A tún ti rí àwọn ohun díẹ̀ tí ń fa ìbànújẹ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ wa dúró nínú gbogbo rẹ̀ pátá. Níhìn-ín ní orílé iṣẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà lágbàáyé, inú wa dùn pé a láǹfààní wíwà nítòsí àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso lójoojúmọ́. Nígbà míì, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé ibí la wà lóòótọ́?’ Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni. (2 Kọ́ríńtì 12:9) Ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní dídáàbò bò wá lọ́wọ́ ètekéte Sátánì, yóò sì máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa kí a lè gbádùn àkókò ìṣàkóso òdodo rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Éfésù 6:11-18; Ìṣípayá 21:1-4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Strangeways, nílùú Manchester, níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀wọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwa rèé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ Austin Seven wa nínú iṣẹ́ àyíká nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àpéjọ ìdákọ́ńkọ́ ní Cercedilla, nílùú Madrid, Sípéènì, lọ́dún 1962

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwa rèé nídìí tábìlì táa ń pàtẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ní Brooklyn