Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Ń sa Gbogbo Ipá wa!

A Ń sa Gbogbo Ipá wa!

A Ń sa Gbogbo Ipá wa!

“SA GBOGBO ipá rẹ.” Ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí ẹnì kan tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún míṣọ́nnárì kan nígbà kan rí nìyẹn. Àmọ́, kí nìdí tó fi fún òjíṣẹ́ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní irú ìmọ̀ràn yẹn? Ṣé kì í ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn míṣọ́nnárì ló jẹ́ onífaradà tó ń kojú ìdun, ejò, ooru, àrùn, àti onírúurú ìpọ́njú lójoojúmọ́ ni?

Ní ti gidi, àwọn míṣọ́nnárì ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹ̀dá àrà ọ̀tọ̀, wọ́n jẹ́ Kristẹni ọkùnrin àti obìnrin tí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọ́n ti sún láti lọ sìn ní àwọn ilẹ̀ àjèjì. Wọ́n ń sapá láti sin Jèhófà dé ibi tí agbára wọ́n lè gbé e dé, wọ́n sì ń gba okun látọ̀dọ̀ rẹ̀.—Éfésù 6:10.

Láti túbọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ẹ jẹ́ ká fojú inú wò ó pé a fi odindi ọjọ́ kan ṣèbẹ̀wò sí ilé míṣọ́nnárì kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà.

Ọjọ́ Kan Nínú Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Aago méje àárọ̀ ti fẹ́ lù. A ti dé sí ilé míṣọ́nnárì báyìí, ó sì wá bọ́ sí àkókò àtika ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́. Àwọn míṣọ́nnárì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ló fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí wa káàbọ̀, wọ́n sì ní ká jọ jókòó sídìí tábìlì oúnjẹ àárọ̀. Bí a ṣe dojúlùmọ̀ ara wa tán ni míṣọ́nnárì kan tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún bẹ̀rẹ̀ sí sọ ìrírí pípanilẹ́rìn-ín tó ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́, a fòpin sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa nígbà tí alága ìjíròrò ọjọ́ náà rán àwùjọ aláyọ̀ náà létí pé ó ti tó àkókò láti ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́. Èdè Faransé ni wọ́n máa fi sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé á ò lè sọ èdè yẹn, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ̀rọ̀ fi hàn gbangba pé àwọn míṣọ́nnárì tó wá láti ilẹ̀ àjèjì ò kẹ̀rẹ̀ rárá nínú sísọ èdè náà.

Lẹ́yìn ìjíròrò náà látinú Ìwé Mímọ́, àdúrà àtọkànwá tẹ̀ lé e, ó wá tó àkókò láti jẹ oúnjẹ àárọ̀ wàyí. Bá a ṣe ń gbádùn oúnjẹ lọ ní tiwa, míṣọ́nnárì tó jókòó tì wá rọ̀ wá láti rẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ lé e lórí. A ṣàlàyé pé a ò fẹ́ràn ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ, ṣùgbọ́n ó sọ fún wa pé a óò yí èrò wa padà lẹ́yìn tá a bá tọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ tí wọ́n ń gbìn ládùúgbò yẹn wò. A wá rẹ́ díẹ̀ sórí oúnjẹ wa. Òótọ́ ni ohun tó sọ! Àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ wọ̀nyí mà dùn o—wọ́n dùn bí áásìkiriìmù! Àwọn míṣọ́nnárì náà sì mú un dá wa lójú pé àárọ̀ yìí ni wọ́n jí ṣe búrẹ́dì gbọọrọ-gbọọrọ tí ń bẹ níwájú wa ní ṣọ́ọ̀bù kékeré kan tó wà ní òpópónà tó dojú kọ ilé míṣọ́nnárì náà.

Lẹ́yìn oúnjẹ àárọ̀, a ó lo ọjọ́ náà pẹ̀lú tọkọtaya míṣọ́nnárì kan, tá a ó pe orúkọ wọn ní Ben àti Karen. A ti gbọ́ nípa ìpínlẹ̀ tó ń méso jáde ní orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà yìí, a sì ń hára gàgà láti fìdí ìròyìn tá a gbọ́ múlẹ̀.

Nígbà tá a dé ibi tí wọ́n ti ń wọ bọ́ọ̀sì, a rí i pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ló ń dúró de bọ́ọ̀sì. Ká tó pajú pẹ́, ìjíròrò alárinrin lórí kókó kan nínú Bíbélì ti ń lọ láàárín àwọn míṣọ́nnárì tá a jọ jáde àti obìnrin kan pẹ̀lú ọmọ rẹ̀. Ńṣe la wulẹ̀ dúró síbẹ̀ tá a ń rẹ́rìn-ín músẹ́, nítorí pé a ò gbọ́ èdè Faransé tí wọ́n ń sọ! Bí obìnrin náà ṣe tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! báyìí ni bọ́ọ̀sì dé, gbogbo èèyàn sì ń ṣe wìtìwìtì láti wọnú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà! Bá a ṣe jàjà wọnú bọ́ọ̀sì náà, ńṣe ni àwọn èrò ń tì wá látẹ̀yìn. A sáà ń dù kí a má ṣubú bá a ṣe ń rìn lọ sápá ẹ̀yìn nínú bọ́ọ̀sì náà. Gbàrà tí awakọ̀ náà gbéra la bẹ̀rẹ̀ sí wojú Ọlọ́run pé kó mú wa gúnlẹ̀ láyọ̀ nítorí ìwàkuwà tó ń wà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bọ́ọ̀sì náà á dúró, àwọn èèyàn á tún rọ́ wọlé. Àwa èrò ọkọ̀ á wo ara wa lójú a ó sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Ó wù wá ká lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀!

Bí bọ́ọ̀sì wa ṣe ń dà á lọ yaa ni a ń gba ojú fèrèsé wo ohun tó ń lọ níta. Àwọn obìnrin méjì jọ ń rìn lọ, wọ́n sì ru ẹrù tó wúwo lérí. Ọ̀kan nínú wọ́n ń tún ìṣà omi títóbi tó rù sórí ṣe. Ọkùnrin kan tó ń ṣaájò ajé tẹ́ bùláńkẹ́ẹ̀tì sẹ́bàá ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà kọjá, ó sì to nǹkan ọ̀ṣọ́ díẹ̀ tó fẹ́ tà lé e lórí. Ibi gbogbo la ti rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń rà tàbí tí wọ́n ń ta ohunkóhun tó bá ṣáà ti ṣeé rà tàbí tó ṣeé tà.

Lójijì ni Ben, tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi rí i pé nǹkan kan ń fẹnu gún òun lẹ́sẹ̀. Kí ni nǹkan náà lè jẹ́? Bọ́ọ̀sì náà kún dẹ́nu, àmọ́ nǹkan náà tún fẹnu gún un lẹ́sẹ̀. Ó ṣáà wá bí òun ṣe máa wo ilẹ̀. Pẹ́pẹ́yẹ kan wà nínú àpò kan tí wọ́n gbé sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń yọrí jáde nínú àpò náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fẹnu gún un lẹ́sẹ̀! Ben ṣàlàyé pé ó ní láti jẹ́ pé ẹni tó ni pẹ́pẹ́yẹ náà fẹ́ lọ tà á lọ́jà ni.

Nígbà tá a dé ìpínlẹ̀ wa, inú wa dùn nígbà tá a gbọ́ pé àárín àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà gan-an la ti máa ṣiṣẹ́. Nígbà tá a dé ilé àkọ́kọ́, Ben pàtẹ́wọ́ tó dún dáadáa láti sọ fún onílé náà pé a ti dé. Báwọn èèyàn tó ń gbé ní apá ibẹ̀ yẹn ṣe máa “ń kanlẹ̀kùn” nìyẹn. Ọ̀dọ́kùnrin kan jáde síta, ó sì ṣàlàyé pé ọwọ́ òun dí, àmọ́ ó ní ká padà wá tó bá ṣe díẹ̀ sí i.

Ní ilé kejì, a bá obìnrin kan pàdé tí Ben ò gbọ́ èdè rẹ̀. Ó pe ọmọ rẹ̀ pé kó wá máa túmọ̀ ohun tí Ben fẹ́ sọ fún òun. Nígbà tí Ben parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, obìnrin náà gba ìwé pẹlẹbẹ tó ní àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì nínú, ọmọ rẹ̀ sì ṣèlérí pé òun máa ṣàlàyé rẹ̀ fún un. Ní ilé kẹta, àwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan jókòó síwájú ìta. Ojú ẹsẹ̀ ni méjì nínú wọn dìde lórí ìjókòó wọn kí àwa àlejò lè ríbi jókòó sí. Ìjíròrò alárinrin lórí lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn sì tẹ̀ lé e. A ṣètò láti túbọ̀ jíròrò sí i lọ́sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e. Àkókò wá tó wàyí láti padà sọ́dọ̀ ọ̀dọ́kùnrin tá a rí nílé àkọ́kọ́. Lọ́nà kan ṣáá, ó ti gbọ́ nípa ìjíròrò tá a ní pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tá a bá sọ̀rọ̀ nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún. Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti béèrè nínú Bíbélì, ó sì sọ pé ká wá máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí Ben wo gbogbo bóun ṣe fẹ́ rìn ín, ó gbà pé òun á padà wá ní àkókò kan náà lọ́sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e. Nígbà tá a ń padà bọ̀ sílé míṣọ́nnárì láti wá jẹ oúnjẹ ọ̀sán, Ben àti Karen ṣàlàyé pé àwọn ní láti wéwèé bí àwọn ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, nítorí pé àwọn lè lọ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ ju èyí táwọn máa lè darí lọ.

A yìn wọ́n fún yíyọ̀ tí èdè Faransé yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu. Ben ṣàlàyé pé ọdún kẹfà rèé tí òun àti Karen ti ń sin gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ èdè Faransé sọ dáadáa. Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé kò rọrùn láti kọ́ èdè tuntun, ṣùgbọ́n ìforítì táwọn ní ti so èso rere.

Nígbà tí aago méjìlá ààbọ̀ ọ̀sán lù, gbogbo àwọn míṣọ́nnárì náà ló pé sídìí tábìlì láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Wọ́n sọ fún wa pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń yan míṣọ́nnárì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbọ́ oúnjẹ àárọ̀ àti tọ̀sán, tá sì tún fọ abọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Lónìí, ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì náà ti ṣètò adìyẹ díndín àti ànàmọ́ tó dín lọ́nà ti ilẹ̀ Faransé, pẹ̀lú sàláàdì tí wọ́n fi tòmátì ṣe—obìnrin náà mọ̀ nípa oúnjẹ yìí ẹ jọ̀ọ́!

Kí ni Ben àti Karen wéwèé láti ṣe ní ọ̀sán yẹn? Wọ́n ṣàlàyé pé gbogbo àwọn ará orílẹ̀-èdè yẹn ló máa ń sá fún oòrùn tó máa ń ràn láti aago kan sí mẹ́ta ọ̀sán, nítorí náà, àwọn míṣọ́nnárì máa ń fi lára àkókò yẹn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí wọ́n sùn díẹ̀. Kò yà wá lẹ́nu nígbà tí Karen sọ fún wa pé kì í pẹ́ rárá tí àṣà yìí fi ń mọ́ àwọn míṣọ́nnárì lára!

Lẹ́yìn ìsinmi náà, a padà sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ọkùnrin kan tó fìfẹ́ hàn, tí Ben ti ń gbìyànjú láti kàn sí fún ìgbà bíi mélòó kan kò tún sí nílé, àmọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì jáde wá nígbà tí Ben pàtẹ́wọ́. Wọ́n sọ fún wa pé onílé náà ti sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò Ben, ó sì ti sọ fún wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ gba ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú wa dùn láti fún wọn ní ẹ̀dà kan. Lẹ́yìn náà, a wọ bọ́ọ̀sì lọ sí àgbègbè kan tí Karen ti máa bá obìnrin kan tó jẹ́ olùfìfẹ́hàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí ọkọ̀ tá a wà nínú rẹ̀ ṣe ń gba àwọn títì táwọn èrò kún fọ́fọ́ kọjá ni Karen ń sọ fún wa pé òun bá obìnrin náà pàdé lọ́jọ́ kan táwọn jọ wà nínú ọkọ̀ takisí pẹ̀lú àwọn èrò mìíràn. Karen fún obìnrin náà ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan láti kà bí wọ́n ti ń lọ. Obìnrin náà ka ìwé àṣàrò kúkúrú náà tán, ó tún béèrè fún òmíràn. Ọkàn ìfẹ́ tó fi ka ìyẹn tún ga ju èyí tó fi ka tàkọ́kọ́ lọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ, Karen ṣètò láti bẹ obìnrin náà wò nílé rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Òní ni Karen máa parí ẹ̀kọ́ kárùn-ún nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.

A gbádùn òde ẹ̀rí ọjọ́ yẹn gan-an ni, àmọ́ a ṣì ní àwọn ìbéèrè kan tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àwọn tó gbà wá lálejò mú un dá wa lójú pé nígbà tá a bá padà délé, àwọn á wá nǹkan tá a máa fi panu, àwọn ó sì dáhùn àwọn ìbéèrè wa.

Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Bá A Lọ

Bá a ṣe ń jẹ ẹ̀yìn díndín, búrẹ́dì ilẹ̀ Faransé, àti wàràkàṣì lọ́wọ́ la túbọ̀ ń gbọ́ púpọ̀ sí i nípa ìgbésí ayé míṣọ́nnárì. Ọjọ́ Monday làwọn míṣọ́nnárì sábà máa ń fi sinmi tàbí kí wọ́n fi bójú tó àwọn ọ̀ràn ti ara wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn míṣọ́nnárì ló máa ń fi ọjọ́ yẹn kọ lẹ́tà sí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́. Gbígbúròó ilé ṣe pàtàkì fún wọn gan-an ni, inú àwọn míṣọ́nnárì sì máa ń dùn sí kíkọ lẹ́tà àti rírí lẹ́tà gbà.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ibì kan náà ni àwọn míṣọ́nnárì ń gbé, ó pọndandan pé kí àárín wọ́n gún, kí wọ́n máa bá àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn lo àkókò ìgbádùn pa pọ̀, kí wọ́n sì máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí pa pọ̀. Láti ṣe èyí, yàtọ̀ sí dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, gbogbo ìrọ̀lẹ́ Monday làwọn míṣọ́nnárì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Ben là á mọ́lẹ̀ pé nígbà táwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n wá láti àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ń gbé pa pọ̀, kò sí bí wọn ò ṣe ní í láwọn aáwọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nítorí èrò tó yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n ìpèsè tẹ̀mí tá a ń rí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa gbé ní àlàáfíà àti ní ìṣọ̀kan. Ó tún tẹnu mọ́ ọn pé ohun tó tún ń ranni lọ́wọ́ ni pé kéèyàn máà jọ ara rẹ̀ lójú jù.

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tún ṣe pàtàkì. Kí àwọn míṣọ́nnárì lè ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn la ṣe rán wọn jáde, kì í ṣe pé kí ẹlòmíràn máa ṣiṣẹ́ sìn wọ́n. Àwọn ọ̀rẹ́ wa wọ̀nyí sọ pé ọ̀kan lára ohun tó ṣòro jù lọ láti sọ nínú èdè èyíkéyìí ni “Jọ̀wọ́ máà bínú,” àgàgà nígbà téèyàn bá ń tọrọ àforíjì nítorí ohun kan tó sọ tàbí tó ṣe láìmọ̀ọ́mọ̀. Ben rán wa létí àpẹẹrẹ Ábígẹ́lì tó wà nínú Bíbélì, ẹni tó tọrọ àforíjì nítorí ìwà àìlọ́wọ̀ tí ọkọ rẹ̀ hù tó sì tipa bẹ́ẹ̀ pẹ̀tù sí ohun tí ì bá yọrí sí jàǹbá ńlá. (1 Sámúẹ́lì 25:23-28) “Gbígbé pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà” jẹ́ apá pàtàkì nínú ohun tó ń sọni di míṣọ́nnárì tó dáńgájíá.—2 Kọ́ríńtì 13:11.

Àwọn míṣọ́nnárì náà máa ń pàdé pọ̀ lẹ́ẹ̀kan lóṣù láti jíròrò àwọn ọ̀ràn tó kan ìdílé náà, títí kan àwọn ìyípadà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nínú ètò bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Ẹ̀yìn ìyẹn ni gbogbo wọn yóò wá gbádùn ìpápánu àkànṣe. Èyí dà bí ètò kan—tó gbéṣẹ́—tó sì gbádùn mọ́ni lójú wa.

Bá a ṣe jẹ oúnjẹ alẹ́ tán ni wọ́n mú wa rin ilé míṣọ́nnárì náà ká páápààpá. A ṣàkíyèsí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé náà kì í ṣe ilé mèremère, síbẹ̀ àwọn míṣọ́nnárì náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti jẹ́ kó wà ní mímọ́ tónítóní. Fìríìjì kan wà níbẹ̀, ẹ̀rọ ìfọṣọ kan àti sítóòfù kan tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Karen sọ fún wa pé ẹ̀rọ amúlétutù tún máa ń wà láwọn ilé kan nílẹ̀ olóoru, ní irú ibi táwọn wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà yìí. Ibùgbé tó bójú mu, oúnjẹ aṣaralóore, àti bíbójútó ìlera ara ẹni ló ń mú kí ara àwọn míṣọ́nnárì náà le, tí wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ wọn.

Gbígbájúmọ́ Ohun Tó Dára

Gbogbo nǹkan tá a rí pátá ló wú wa lórí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé àwa náà lè di míṣọ́nnárì báyìí? Báwo la ṣe lè mọ̀? Àwọn tó gbà wá lálejò sọ àwọn nǹkan díẹ̀ tó yẹ ká ronú lé lórí fún wa.

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n sọ fún wa pé kì í ṣe ìfẹ́ láti mọ̀lú lọ ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní. Àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àgbàyanu ìlérí Ọlọ́run ni wọ́n ń wá kiri. Ó kéré tán, àwọn míṣọ́nnárì máa ń lo ogóje wákàtí nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣooṣù, nítorí ìdí èyí, ó pọndandan fún wọn láti fẹ́ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́.

A wá ń ṣe kàyéfì pé, ‘àwọn ejò, aláǹgbá, àti ìdun wá ńkọ́?’ Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ibi tá a ń yan àwọn míṣọ́nnárì sí la ti ń rí wọn, Ben sọ fún wa pé àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í pẹ́ mọ́ àwọn míṣọ́nnárì lára. Ó fi kún un pé gbogbo ibi tá a yan àwọn míṣọ́nnárì sí ló ní ẹwà tirẹ̀, àwọn ohun tó dára nípa ibi tá a yàn wọ́n sí làwọn míṣọ́nnárì sì máa ń wò bí àkókò ti ń lọ. Kì í pẹ́ tí àwọn ipò kan tí wọ́n lè kọ́kọ́ kà sí èyí “tó ṣàjèjì,” fi máa ń di ohun tó mọ́ wọn lára, tí wọ́n a tiẹ̀ tún máa gbádùn rẹ̀ láwọn ìgbà mìíràn pàápàá. Míṣọ́nnárì kan tó ti sìn ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ipò àwọn nǹkan tó sọ ọ́ di dandan fún un pé kó padà sílé, sọ pé ó ṣòro gan-an fún òun láti kúrò ní ibi tá a yan òun sí ju bó ṣe ṣòro fún òun láti fi orílẹ̀-èdè òun sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ibi tó ti ń ṣe míṣọ́nnárì ti di ilé rẹ̀.

Ṣé O Ti Múra Tán?

Àwọn ohun tí Ben àti Karen sọ fún wa gbèrò. Ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o ti ronú nípa sísìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì nílẹ̀ àjèjì rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè tètè lé góńgó yẹn bá ju bí o ti rò lọ. Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tó ń béèrè ni pé kéèyàn fẹ́ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, kó sì máa gbádùn iṣẹ́ ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Rántí pé àwọn míṣọ́nnárì kì í ṣe àràmàǹdà ẹ̀dá, ọkùnrin àti obìnrin bíi tiwa ni wọ́n. Wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣàṣeparí iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì jù lọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ìjíròrò látinú Bíbélì ni wọ́n fi ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Àwọn ohun tá a rí ní Áfíríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ń fúnni láyọ̀ gan-an ni