Ní Ọkàn-àyà Tó Tẹ́ Jèhófà Lọ́rùn
Ní Ọkàn-àyà Tó Tẹ́ Jèhófà Lọ́rùn
“Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.”—SÁÀMÙ 51:10.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ọkàn-àyà wa?
Ó SÍGBỌNLẸ̀, ó sì rẹwà lọ́kùnrin. Bí wòlíì Sámúẹ́lì ṣe rí i báyìí, kò wò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó parí èrò sí pé ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí Jésè yìí ni ọba tí Ọlọ́run yàn lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé: “Má wo ìrísí [ọmọkùnrin náà] àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. . . . Ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” Dáfídì, ọmọkùnrin tó jẹ́ àbíkẹ́yìn Jésè ni Jèhófà yàn—òun lẹni “tí ó tẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ lọ́rùn.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
2 Olùmọ-ọkàn ni Ọlọ́run, ó sì sọ lẹ́yìn ìgbà yẹn pé: “Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín, àní láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” (Jeremáyà 17:10) Ní tòótọ́, “Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 17:3) Ṣùgbọ́n kí ni ọkàn tó wà nínú èèyàn tí Jèhófà ń yẹ̀ wò? Kí la sì lè ṣe láti ní ọkàn-àyà tó tẹ́ ẹ lọ́rùn?
“Ẹni Ìkọ̀kọ̀ ti Ọkàn-Àyà”
3, 4. Báwo la ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn-àyà,” nínú Bíbélì? Mú àwọn àpẹẹrẹ wá.
3 Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ìgbà la lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn-àyà” nínú Ìwé Mímọ́. A sábà máa ń lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún wòlíì Mósè pé: “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gba ọrẹ fún mi: Ọwọ́ olúkúlùkù ènìyàn tí ọkàn-àyà rẹ̀ ru ú sókè ni kí ẹ ti gba ọrẹ mi.” Àwọn tó fẹ́ ṣe ìtọrẹ sì “wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ sún un ṣiṣẹ́.” (Ẹ́kísódù 25:2; 35:21) Láìsí àní-àní, iṣẹ́ kan tí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ ń ṣe ni pé ó ń súnni ṣe nǹkan—òun ni ipá tó wà nínú lọ́hùn-ún tó ń rọ̀ wá láti gbégbèésẹ̀. Ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa tún máa ń fi ìmí ẹ̀dùn àti ìmọ̀lára wa, àtohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí hàn. Ọkàn-àyà lè kún fún ìbínú tàbí kó kún fún ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́, tàbí ayọ̀. (Sáàmù 27:3; 39:3; Jòhánù 16:22; Róòmù 9:2) Ọkàn-àyà lè kún fún ìgbéraga tàbí ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ó lè kún fún ìfẹ́ tàbí ìkórìíra.—Òwe 16:5; Mátíù 11:29; 1 Pétérù 1:22.
4 Fún ìdí yìí, “ọkàn-àyà” máa ń ní í ṣe pẹ̀lú agbára tí ń súnni ṣe nǹkan tàbí ìmí ẹ̀dùn, ṣùgbọ́n “èrò inú” ní tirẹ̀ sábà máa ń wé mọ́ ọ̀ràn òye. Ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí nìyí nígbà tá a bá lò wọ́n pa pọ̀ lójú kan nínú Ìwé Mímọ́. (Mátíù 22:37; Fílípì 4:7) Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tí ìtumọ̀ ọkàn-àyà àti èrò inú kò yàtọ̀ síra. Fún àpẹẹrẹ, Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí o . . . mú kí ó wá sí ọkàn-àyà rẹ [tàbí, “mú un wá sí èrò inú rẹ,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.” (Diutarónómì 4:39) Jésù sọ fáwọn akọ̀wé tí ń gbèrò ibi sí i pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ro àwọn ohun burúkú nínú ọkàn-àyà yín?” (Mátíù 9:4) “Òye,” “ìmọ̀,” àti “èrò” tún lè wá látinú ọkàn-àyà. (1 Àwọn Ọba 3:12; Òwe 15:14; Máàkù 2:6) Nítorí náà, ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tún wé mọ́ làákàyè wa—ìyẹn ìrònú àti òye wa.
5. Kí ni ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ dúró fún?
5 Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ dúró fún “àárín gbùngbùn, inú lọ́hùn-ún, nítorí náà, ó dúró fún ẹni ti inú lọ́hùn-ún tí à ń rí lóde nípasẹ̀ onírúurú ìṣarasíhùwà rẹ̀, nípasẹ̀ àwọn ohun tí ọkàn rẹ̀ fà sí, àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, ìmí ẹ̀dùn, ìtara, ète, ìrònú rẹ̀, agbára ìmòye, ojú ìwòye, ọgbọ́n rẹ̀, ìmọ̀, òye iṣẹ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti èrò rẹ̀, agbára ìrántí rẹ̀ àti ìmọ̀lára rẹ̀.” Ó dúró fún ẹni tá a jẹ́ gan-an nínú lọ́hùn-ún, “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.” (1 Pétérù 3:4) Ohun tí Jèhófà ń rí, tó sì ń ṣàyẹ̀wò nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì fi gbàdúrà pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sáàmù 51:10) Báwo la ṣe lè ní ọkàn-àyà tí ó mọ́?
“Ẹ Fi Ọkàn-Àyà Yín” sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
6. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Mósè gba Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n pabùdó sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù?
6 Nígbà tí Mósè ń sọ̀rọ̀ ìyànjú fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kóra jọ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, kó tó di pé wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ó sọ pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ láti fi kìlọ̀ fún yín lónìí, kí ẹ̀yin lè máa pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti máa kíyè sí pípa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí mọ́.” (Diutarónómì 32:46) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti “fiyè sí i dáadáa.” (Knox) Àyàfi bí wọ́n bá mọ àwọn àṣẹ Ọlọ́run dunjú ni wọ́n fi lè fi kọ́ àwọn ọmọ wọn.—Diutarónómì 6:6-8.
7. Kí ni ‘fífi ọkàn-àyà wa sí’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé mọ́?
7 Ohun pàtàkì tá a ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ní ọkàn-àyà tí ó mọ́ ni pé kí ó ní ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ àti ète Ọlọ́run. Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a mí sí nìkan la ti lè rí ìmọ̀ yìí. (2 Tímótì 3:16, 17) Àmọ́ o, wíwulẹ̀ rọ́ ìmọ̀ ságbárí kò lè fún wa ní ọkàn-àyà tó wu Jèhófà. Kí ìmọ̀ yẹn tó lè nípa lórí ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, a gbọ́dọ̀ ‘fi ọkàn-àyà wa sí’ ohun tí à ń kọ́, tàbí kí ohun tí à ń kọ́ “wà nínú ọkàn-àyà” wa. (Diutarónómì 32:46, An American Translation) Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Onísáàmù náà Dáfídì ṣàlàyé pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.”—Sáàmù 143:5.
8. Àwọn ìbéèrè wo la lè ronú jinlẹ̀ lé lórí bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́?
8 Ó yẹ kí àwa náà máa fi ẹ̀mí ìmọrírì ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ Jèhófà. Nígbà tá a bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì, ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni èyí kọ́ mi nípa Jèhófà? Ànímọ́ wo ni mo rí i pé Jèhófà gbé yọ níhìn-ín? Kí ni ohun tí mo kà yìí kọ́ mi nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àtohun tí kò fẹ́? Kí ni àbájáde títọ ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú títọ ọ̀nà tó kórìíra? Báwo ni ohun tí mo kà yìí ṣe tan mọ́ ohun tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀?’
9. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò ṣe ṣe pàtàkì tó?
9 Lisa a tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ṣàlàyé bóun ṣe dẹni tó ń fojú pàtàkì wo ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò tó múná dóko, ó ní: “Lẹ́yìn tí mo ṣe batisí lọ́dún 1994, mo jẹ́ onítara nínú òtítọ́ fún nǹkan bí ọdún méjì. Mo ń lọ sí gbogbo ìpàdé Kristẹni. Mo ń lo nǹkan bí ọgbọ̀n sí ogójì wákàtí lóṣooṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, mo sì ń bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi rìn. Àmọ́ mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣáko lọ. Mo tiẹ̀ lọ débi pé mo rú òfin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n mo pe orí mi wálé, mo sì pinnu pé mo fẹ́ tún ayé ara mi ṣe. Mo mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìrònúpìwàdà mi, ó sì gbà mí padà! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ń bi ara mi pé: ‘Kí ló mú mi ṣáko lọ ná?’ Ìdáhùn tó sábà máa ń wá sí mi lọ́kàn ni pé mo pa ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò tó múná dóko tì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé òtítọ́ Bíbélì kò dénú ọkàn-àyà mi nígbà yẹn. Láti ìsinsìnyí lọ, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò yóò máa jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi.” Bí a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà, àti Ọmọ rẹ̀, àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí i, ẹ wo bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká wá àyè fún ríro àròjinlẹ̀!
10. Èé ṣe tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká wáyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò?
10 Nínú ayé tí ọwọ́ ti dí fọ́fọ́ yìí, àtirí àyè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá. Ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni lónìí wà ní bèbè Ilẹ̀ Ìlérí àgbàyanu náà—èyíinì ni ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:13) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amúnitagìrì, bí ìparun “Bábílónì ńlá” àti bí “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” yóò ṣe kọlu àwọn èèyàn Jèhófà, ti sún mọ́lé gírígírí. (Ìṣípayá 17:1, 2, 5, 15-17; Ìsíkíẹ́lì 38:1-4, 14-16; 39:2) Ohun tí ń bẹ níwájú lè dán ìfẹ́ wa fún Jèhófà wò. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kánjúkánjú pé ká ra àkókò tó rọgbọ padà nísinsìnyí, ká sì fi ọkàn-àyà wa sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!—Éfésù 5:15, 16.
‘Múra Ọkàn-Àyà Rẹ Sílẹ̀ Láti Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
11. Báwo la ṣe lè fi ọkàn-àyà wa wé ilẹ̀?
11 A lè fi ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wé ilẹ̀ tá a lè gbin èso òtítọ́ sí. (Mátíù 13:18-23) A sábà máa ń ṣán ilẹ̀ tá a fẹ́ gbin nǹkan sí kí irúgbìn lè dàgbà dáadáa. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a gbọ́dọ̀ palẹ̀ ọkàn-àyà wa mọ́, ìyẹn ni pé ká múra rẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè rọrùn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti wọnú rẹ̀. Ẹ́sírà àlùfáà “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́.” (Ẹ́sírà 7:10) Báwo la ṣe lè múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀?
12. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́?
12 Àdúrà àtọkànwá jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an láti fi múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ nígbà tá a bá fẹ́ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àdúrà la fi ń ṣí àwọn ìpàdé Kristẹni, àdúrà la sì fi ń parí wọn. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa kọ́kọ́ gbàdúrà àtọkànwá ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì máa fi tọkàntọkàn bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ!
13. Tá a bá fẹ́ ní ọkàn-àyà tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, kí ló yẹ ká ṣe?
13 Ó yẹ ká múra ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ sílẹ̀ ká lè pa ẹ̀tanú tì. Àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé Jésù kò fẹ́ láti ṣe èyí. (Mátíù 13:15) Ṣùgbọ́n Màríà, ìyá Jésù, kò dà bíi wọn, ní ti pé àwọn òtítọ́ tó gbọ́ ló gbé ìpinnu rẹ̀ kà “nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Lúùkù 2:19, 51) Ó di olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù. Lìdíà ará Tíátírà fetí sí Pọ́ọ̀lù, ‘Jèhófà sì ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ láti fiyè sí ọ̀rọ̀ náà.’ Òun náà di onígbàgbọ́. (Ìṣe 16:14, 15) Ǹjẹ́ kí a má ṣe wonkoko mọ́ àwọn èrò tara wa tàbí àwọn ìgbàgbọ́ tá a ń gbé gẹ̀gẹ̀ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbà pé “kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́, bí a tilẹ̀ rí olúkúlùkù ènìyàn ní òpùrọ́.”—Róòmù 3:4.
14. Báwo la ṣe lè múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nínú àwọn ìpàdé Kristẹni?
14 Mímúra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ láwọn ìpàdé Kristẹni ṣe pàtàkì gidigidi. Bí ọkàn wa bá pínyà, bí ohun tí wọ́n ń sọ ṣe ń gba etí ọ̀tún wa wọlé ni yóò máa gba tòsì jáde. Ohun tí wọ́n ń sọ kò ní wọ̀ wá lọ́kàn bó bá jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn tàbí ohun tí ọ̀la máa mú wá ló gbà wá lọ́kàn. Bí ohun tí à ń sọ nípàdé bá máa ṣe wá láǹfààní, ó yẹ ká dìídì pinnu pé a fẹ́ fetí sílẹ̀ àti pé a fẹ́ rí ẹ̀kọ́ kọ́. Ẹ sì wo bí ohun tí a ó jàǹfààní yóò ti pọ̀ tó, bá a bá fọkàn sí i pé a fẹ́ lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ àti àlàyé tí à ń ṣe lórí rẹ̀!—Nehemáyà 8:5-8, 12.
15. Báwo ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ń jẹ́ ká ṣe tán láti gbẹ̀kọ́?
15 Gan-an gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti lè túbọ̀ lẹ́tù lójú bí a bá da ìlẹ̀dú sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni níní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, níní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí nǹkan tẹ̀mí, gbígbẹ́kẹ̀lé àti bíbẹ̀rù Ọlọ́run àti níní ìfẹ́ rẹ̀ ṣe lè tún ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa ṣe. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ máa ń sọ ọkàn-àyà dẹ̀rọ̀, ó ń jẹ́ ká ṣe tán láti gbẹ̀kọ́. Jèhófà sọ fún Jòsáyà Ọba Júdà pé: “Nítorí ìdí náà pé ọkàn-àyà rẹ rọ̀ tí ó fi jẹ́ pé o rẹ ara rẹ sílẹ̀ nítorí Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ . . . tí o sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún níwájú mi, èmi, àní èmi, ti gbọ́.” (2 Àwọn Ọba 22:19) Ọkàn-àyà Jòsáyà rọ̀, ó sì gbẹ̀kọ́. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù “tí kò mọ̀wé,” tí wọ́n sì jẹ́ “gbáàtúù” lóye, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tí kò yé “àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye.” (Ìṣe 4:13; Lúùkù 10:21) Ǹjẹ́ ká “rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run wa” bá a ti ń sapá láti ní ọkàn-àyà tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn.—Ẹ́sírà 8:21.
16. Èé ṣe tó fi ń béèrè ìsapá kí oúnjẹ tẹ̀mí tó lè máa dá wa lọ́rùn?
16 Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ànímọ́ àbínibí láti nífẹ̀ẹ́ nǹkan tẹ̀mí, àwọn ìṣòro tá a ń rí látinú ayé burúkú yìí, tàbí àwọn ìwà bí ìmẹ́lẹ́ ṣíṣe, lè máà jẹ́ ká fi ìtara ṣe ojúṣe wa. (Mátíù 4:4) Ó yẹ ká máa hára gàgà láti jẹ oúnjẹ tẹ̀mí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kíkà àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ lè máà gbádùn mọ́ wa nígbà tá a bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, bá a bá tẹra mọ́ ọn, a óò rí i pé ìmọ̀ yóò ‘dùn mọ́ ọkàn wa,’ débi pé a óò máa hára gàgà pé kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tètè dé.—Òwe 2:10, 11.
17. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi yẹ lẹ́ni tá a ń fọkàn tán pátápátá? (b) Báwo la ṣe lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run?
17 Sólómọ́nì Ọba gbà wá níyànjú pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 3:5) Ọkàn-àyà tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ̀ pé gbogbo ohun tí Ó bá béèrè tàbí tó bá pa láṣẹ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló tọ́. (Aísáyà 48:17) Dájúdájú, ó yẹ ká fọkàn tán Jèhófà pátápátá. Awímáyẹhùn ni Jèhófà. (Aísáyà 40:26, 29) Ó ṣe tán, ohun tí orúkọ rẹ̀ gan-an túmọ̀ sí ni “Alèwílèṣe,” èyí sì fini lọ́kàn balẹ̀ pé yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ! “Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 145:17) Àmọ́ o, ká tó lè gbẹ́kẹ̀ lé e, a ní láti “tọ́ ọ wò, kí [a] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere” nípa fífi àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa àti nípa ríronú lórí bí nǹkan wọ̀nyí ṣe ń ṣe wá láǹfààní.—Sáàmù 34:8.
18. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ń jẹ́ ká múra tán láti gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?
18 Sólómọ́nì tún mẹ́nu kan ànímọ́ míì tó ń mú kí ọkàn-àyà wa múra tán láti gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ó ní: “Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yí padà kúrò nínú ohun búburú.” (Òwe 3:7) Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Kìkì bí wọn yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ nígbà gbogbo, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin!” (Diutarónómì 5:29) Dájúdájú, àwọn tó ń bẹ̀rù Ọlọ́run a máa ṣègbọràn sí i. Jèhófà ní agbára “láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀” àti láti fìyà jẹ àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí i. (2 Kíróníkà 16:9) Ǹjẹ́ kí ìbẹ̀rù àìfẹ́ ṣẹ Ọlọ́run máa darí gbogbo ìgbésẹ̀, èrò, àti ìmọ̀lára wa.
‘Fi Gbogbo Ọkàn-Àyà Rẹ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà’
19. Ipa wo ni ìfẹ́ ń kó nínú jíjẹ́ kí ọkàn-àyà wa múra tán láti tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
19 Lékè gbogbo ànímọ́ yòókù, ìfẹ́ ló máa ń mú kí ọkàn-àyà wa gba ìtọ́sọ́nà Jèhófà ní tòótọ́. Ọkàn-àyà tó kún fún ìfẹ́ fún Ọlọ́run máa ń mú kéèyàn hára gàgà láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. (1 Jòhánù 5:3) Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ sí i nípa sísọ ọ́ dàṣà láti máa ronú lórí ìwà rere rẹ̀, nípa bíbá a sọ̀rọ̀ déédéé bí ìgbà tí à ń bá ọ̀rẹ́ kòríkòsùn sọ̀rọ̀, àti nípa fífi ìtara sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì.
20. Báwo la ṣe lè ní ọkàn-àyà tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn?
20 Àkópọ̀ ohun tá a ti kọ́ ni pé: Níní ọkàn-àyà tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn wé mọ́ jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa lórí irú ẹni tí a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, ìyẹn ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó múná dóko nínú Ìwé Mímọ́ àti fífi ẹ̀mí ìmọrírì ṣàṣàrò ṣe kókó. Ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà ṣe èyí ni láti ní ọkàn-àyà tá a ti múra sílẹ̀—ìyẹn ọkàn-àyà tí kò ní ẹ̀tanú, ọkàn-àyà tó kún fún àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká gbẹ̀kọ́! Àní sẹ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ní ọkàn-àyà rere. Àmọ́, kí la lè ṣe láti pa ọkàn-àyà wa mọ́?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí ni ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ tí Jèhófà ń yẹ̀ wò?
• Báwo la ṣe lè ‘fi ọkàn-àyà wa sí’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
• Ọ̀nà wo la lè gbà múra ọkàn-àyà wa sílẹ̀ láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
• Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ yìí, kí lohun tó tọkàn rẹ wá láti ṣe?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Dáfídì fi ẹ̀mí ìmọrírì ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ǹjẹ́ o máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run