Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Mo Mọ Ohun Tó Ń Ṣe Mí!”

“Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Mo Mọ Ohun Tó Ń Ṣe Mí!”

“Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Mo Mọ Ohun Tó Ń Ṣe Mí!”

OHUN tí ọkùnrin kan ní Tokyo sọ nìyẹn lẹ́yìn tó ka ìtàn ìgbésí ayé tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti December 1, 2000. Àkòrí àpilẹ̀kọ náà ni “Ẹ Kò Mọ Ohun Tí Ìwàláàyè Yín Yóò Jẹ́ Lọ́la,” èyí tó sọ ìrírí ẹnì kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀, tó ní àrùn tí àwọn oníṣègùn òyìnbó mọ̀ sí àrùn ọpọlọ tí ìsoríkọ́ máa ń fà.

Ọkùnrin ará Tokyo náà sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde pé: “Àwọn àmì àrùn tí wọ́n ṣàpèjúwe síbẹ̀ bá ohun tó ń ṣe mí mu wẹ́kú. Bí mo ṣe kọrí sí ọsibítù tí wọ́n ti ń tọ́jú àrùn ọpọlọ nìyẹn, wọ́n sì sọ fún mi pé àrùn ọpọlọ tí ìsoríkọ́ máa ń fà ló ń yọ mí lẹ́nu. Ó ṣe dókítà tó yẹ̀ mí wò ní kàyéfì gan-an ni. Ó ní, ‘Àwọn tí àìsàn yìí ń ṣe kì í sábà gbà pé àìsàn ń ṣe àwọn.’ Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti mọ àìsàn tó ń ṣe mí kó tó di èyí tí kò ní gbóògùn mọ́.”

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn káàkiri ayé gbà ń jàǹfààní látinú kíka ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan Ilé Ìṣọ́ àti ìwé ìròyìn Jí! tí ó jẹ́ ìkejì rẹ̀. Wọ́n rí i pé àwọn àpilẹ̀kọ náà kún fún ẹ̀kọ́, wọ́n sì ń fini lọ́kàn balẹ̀. A ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde ní ogóje [141] èdè báyìí, a sì ń tẹ Jí! jáde ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [86]. Ìwọ náà yóò gbádùn kíka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé.