Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá

Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá

Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá

ÌWÉ ìròyìn Time sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo tó lágbára jù lọ—kì í ṣe ní ẹgbẹ̀rúndún méjì wọ̀nyí nìkan, àmọ́ ní gbogbo ìtàn ìran ènìyàn—ni Jésù ti Násárétì.” Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olóòótọ́ ènìyàn ló jẹ́ pé kì í ṣe bó ṣe tóbi lọ́lá tó nìkan ni wọ́n rí, àmọ́ wọ́n tún rí bó ṣe ń ṣaájò àwọn ẹlòmíràn. Abájọ tí wọ́n fẹ́ fi í jọba. (Jòhánù 6:10, 14, 15) Àmọ́, Jésù kọ̀ láti kópa nínú ìṣèlú, bá a ṣe mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú.

KÓKÓ mẹ́ta, ó kéré tán, ló mú kí Jésù sá fún ìṣèlú: ojú tí Baba rẹ̀ fi wo kéèyàn máa ṣe tinú ara rẹ̀, èyí tó ní ìṣàkóso ènìyàn nínú; mímọ̀ tí Jésù mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá alágbára, tó fara sin wà tí kò ní jẹ́ kí gbogbo akitiyan ènìyàn láti ṣàkóso kẹ́sẹ járí; àti ète Ọlọ́run láti gbé ìjọba ọ̀run tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ayé kalẹ̀. Bá a ṣe ń fojú ṣùnnùkùn wo àwọn kókó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, a óò rí ohun tó fà á tí ìsapá ènìyàn láti tún ayé ṣe fi kùnà. A ó sì rí i bí àṣeyọrí yóò ṣe dé.

Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Lè Ṣàkóso Ara Wọn?

Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó fún wọn ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Àmọ́ abẹ́ àṣẹ gíga ti Ọlọ́run làwọn èèyàn wà. Ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn fi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run nípa ṣíṣàì jẹ èso igi kan, ìyẹn ni “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ó ṣeni láàánú pé Ádámù àti Éfà ṣi òmìnira ìwà híhù tí wọ́n ní lò, wọ́n sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Jíjẹ tí wọ́n jẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà kì í wulẹ̀ ṣe ìwà olè nìkan. Ó jẹ́ ṣíṣọ̀tẹ̀ sí ipò ọba aláṣẹ ti Ọlọ́run. Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tá a ṣe lórí Jẹ́nẹ́sísì 2:17 nínú The New Jerusalem Bible sọ pé, Ádámù àti Éfà sọ ara wọn di “ẹni tí ó ní òmìnira pátápátá, nípasẹ̀ èyí tí ènìyàn kọ̀ láti mọ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá . . . Ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ gbígbéjà ko ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run.”

Nítorí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wé mọ́ ṣíṣe ohun tó bẹ́tọ̀ọ́ mu, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Ádámù àti Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó wù wọ́n, wọ́n sì gbé àwọn ìlànà ti ara wọn nípa ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kalẹ̀. (Sáàmù 147:19, 20; Róòmù 2:14) Ní ti gidi, ìgbà yẹn ni ẹ̀mí ṣíṣe tinú ẹni bẹ̀rẹ̀ láàárín ẹ̀dá ènìyàn. Ṣé ó ti wá kẹ́sẹ járí? Pẹ̀lú ohun tá a ti rí láwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá, a lè sọ pé rárá! Oníwàásù 8:9 sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” Àkọsílẹ̀ bíbani nínú jẹ́ nípa bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń dá ṣàkóso ara wọn ti fi hàn pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú Jeremáyà 10:23 pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Ìtàn ti fi hàn pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn kò lè kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣàkóso ara wọn láìfi ti Ẹlẹ́dàá wọn ṣe.

Jésù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́ẹ́ nìyẹn. Òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìríra lójú Jésù. Ó sọ pé: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi. . . . Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wu [Ọlọ́run].” (Jòhánù 4:34; 8:28, 29) Nítorí náà, níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti sọ pé kí ó tẹ́wọ́ gba ipò ọba lọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, Jésù kò tiẹ̀ ronú nípa títẹ́wọ́gbà á rárá. Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé kò fẹ́ ran àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ri ayọ̀ gíga jù lọ nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti ní ọjọ́ iwájú. Ó tilẹ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ọmọ aráyé. (Mátíù 5:3-11; 7:24-27; Jòhánù 3:16) Àmọ́, Jésù mọ̀ pé “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún,” títí kan àkókò tí Ọlọ́run yàn láti lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lórí ìran ènìyàn. (Oníwàásù 3:1; Mátíù 24:14, 21, 22, 36-39) Àmọ́ o, rántí pé ní Édẹ́nì, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ fara mọ́ ìfẹ́ inú ẹ̀dá ẹ̀mí búburú kan, tó tipasẹ̀ ejò kan tí wọ́n rí sójú sọ̀rọ̀. Èyí mú wa dórí ìdí kejì tí Jésù kò fi lọ́wọ́ sí ìṣèlú.

Aláṣẹ Àìrí Tó Ń Ṣàkóso Ayé

Bíbélì sọ fún wa pé Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” lọ Jésù ní pàṣípààrọ̀ fún ìjọsìn ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. (Mátíù 4:8-10) Lọ́rọ̀ kan, ìṣàkóso ayé á di ti Jésù—àmọ́ ó ní láti ṣe ohun tí Èṣù wí. Jésù kò jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àdánwò yìí. Àmọ́, ṣé àdánwò ni lóòótọ́? Ṣé pé Sátánì lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ohun bàǹtà-banta báyẹn lọni? Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí pé Jésù fúnra rẹ̀ pe Èṣù ni “olùṣàkóso ayé,” àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì pè é ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.”—Jòhánù 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4; Éfésù 6:12.

Dájúdájú, Jésù mọ̀ pé Èṣù kò ní ire àwọn ènìyàn lọ́kàn rárá. Ó pe Sátánì ní “apànìyàn” àti “baba irọ́ àti ti gbogbo ohun tó jẹ́ èké.” (Jòhánù 8:44, The Amplified Bible) Ó hàn gbangba pé, ayé kan tó “wà lábẹ́ agbára” irú ẹ̀mí búburú bẹ́ẹ̀ kò lè láyọ̀ tòótọ́ láé. (1 Jòhánù 5:19) Àmọ́, ọlá àṣẹ yìí kò lè máa jẹ́ ti Èṣù lọ títí láé. Jésù, tó ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára báyìí, kò ní pẹ́ mú Sátánì kúrò, tí yóò sì kápá rẹ̀ pátápátá.—Hébérù 2:14; Ìṣípayá 20:1-3.

Sátánì alára mọ̀ pé àkókò tí òun ní láti lò gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ ayé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Ìdí nìyẹn tó fi ń sa gbogbo ipá rẹ̀, láti sọ ìran ènìyàn dìbàjẹ́ pátápátá, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-5; Júúdà 6) Ìṣípayá 12:12 sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé fi hàn pé a ń gbé ní àkókò tó sún mọ́ òpin “àkókò kúkúrú” tá a ń wí yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ìdáǹdè ti sún mọ́lé báyìí.

Ìjọba Tó Máa Mú Ayọ̀ Wá

Ìdí kẹta tí Jésù kò fi lọ́wọ́ sí ìṣèlú ni pé ó mọ̀ pé ní àkókò kan tí a ti yàn kalẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ ní ọ̀run, èyí tí yóò ṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí. Bíbélì pe ìjọba yìí ní Ìjọba Ọlọ́run, òun sì ni olórí ẹ̀kọ́ Jésù. (Lúùkù 4:43; Ìṣípayá 11:15) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé, nítorí pé abẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ nìkan ni ‘ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ti di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run.’ (Mátíù 6:9, 10) O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Bí Ìjọba yìí bá máa ṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìjọba ènìyàn?’

Ìdáhùn rẹ̀ wà nínú Dáníẹ́lì 2:44, tó kà pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [tó ń ṣàkóso ní òpin ètò ìsinsìnyí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba [ènìyàn] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Èé ṣe tí Ìjọba Ọlọ́run fi ní láti “fọ́” àwọn ìṣàkóso ayé “túútúú”? Nítorí pé àwọn wọ̀nyí ń ṣagbátẹrù ẹ̀mí ìṣetinú ẹni, ẹ̀mí àìnáání Ọlọ́run, tí Sátánì dá sílẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún nínú ọgbà Édẹ́nì. Yàtọ̀ sí pé kò lè ṣe ìran ènìyàn láǹfààní kankan, àwọn tí wọ́n ń ṣagbátẹrù ẹ̀mí yẹn ń múra àtibá Ẹlẹ́dàá fìjà pẹẹ́ta. (Sáàmù 2:6-12; Ìṣípayá 16:14, 16) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ bi ara wa pé, ‘Ṣé a fara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run àbí a lòdì sí i?’

Ipò Ọba Aláṣẹ Ti Ta Ni O Máa Yàn?

Kí Jésù lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa ìṣàkóso, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tó dé. (Mátíù 24:14) Àwọn wo la mọ̀ mọ́ iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé lónìí? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àní sẹ́, ó ti pẹ́ tí ìwé ìròyìn yìí ti máa ń ní àkọlé náà níwájú tó kà pé, “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.” Lónìí, àwọn bíi mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí ló ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ìjọba yẹn ní àwọn ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ. a

Ìbùkún fún Àwọn Ọmọ Abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Jésù máa ń ṣe nǹkan ní ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣáá ni. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé dípò tí ì bá fi yan ọ̀nà tó wù ú, kó sì gbìyànjú láti kọ́wọ́ ti ètò àwọn nǹkan tó wà nígbà yẹn lẹ́yìn tàbí kó gbìyànjú láti tún un ṣe lọ́nà ti ìṣèlú, ó ṣe iṣẹ́ àṣekára láti mú kí ire Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú, èyí tó jẹ́ ojútùú kan ṣoṣo sí ìṣòro ayé. Nítorí ìdúróṣinṣin rẹ̀, a gbé e ka orí ìtẹ́ ológo ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba yẹn gan-an. Èrè ńlá mà lèyí jẹ́ o, fún jíjọ̀wọ́ tí ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún Ọlọ́run!—Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Lóde òní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń fara wé Jésù ní fífi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní, tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ń gbádùn ẹ̀bùn àgbàyanu kan—ìyẹn ni àǹfààní jíjẹ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:33) Lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, a óò gbé wọn dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìṣípayá 21:3, 4) 1 Jòhánù 2:17 sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Nígbà tá a bá gbá Sátánì àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kúrò, tí ilẹ̀ ayé sì di Párádísè kárí ayé tó bọ́ lọ́wọ́ ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó ń fa kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ètò ìṣòwò tó kún fún màkàrúrù, àti ìsìn èké, ẹ ò rí i bí yóò ṣe jẹ́ ayọ̀ ńlá tó láti wà níhìn-ín títí láé!—Sáàmù 37:29; 72:16.

Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run ni ohun náà gan-an tó máa mú ayé tó dìídì jẹ́ aláyọ̀ wá, ó sì bá a mu wẹ́kú pé ìhìn rere là ń pe ọ̀rọ̀ tá a fi ń kéde rẹ̀. Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, o ò ṣe fetí sílẹ̀ sí ìhìn rere yìí nígbà mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún mú un wá sílé rẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣalágbàwí Ìjọba Ọlọ́run, wọn kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣọ̀tẹ̀ sáwọn ìjọba ayé, kódà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí tàbí tí wọ́n ti ń ṣe inúnibíni sí wọn pàápàá. (Títù 3:1) Dípò ìyẹn, wọ́n ń kó ipa tó dára, tó jẹ́ tẹ̀mí, tí kò sì jẹ mọ́ ti ìṣèlú bí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní ti ṣe. Onírúurú àwùjọ táwọn Ẹlẹ́rìí wà ni wọ́n ti ń sapá láti ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú ìwà ọmọlúwàbí gbígbámúṣé tó wà nínú Bíbélì dàgbà, irú bí ìfẹ́ nínú ìdílé, àìlábòsí, ìwà mímọ́, àti jíjẹ́ òṣìṣẹ́ kára. Ní pàtàkì jù lọ, wọ́n ń sapá láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tí wọ́n á sì máa wo Ìjọba Ọlọ́run bí ojúlówó ìrètí fún ìran ènìyàn.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìtàn fi hàn pé ẹ̀dá ènìyàn ò lè kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣàkóso ara wọn láìfi ti Ọlọ́run pè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Sátánì ni alákòóso “ètò àwọn nǹkan” ìsinsìnyí, ìdí nìyẹn tó fi fi “gbogbo ìjọba orí ilẹ̀ ayé” lọ Jésù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù kọ́ni pé lábẹ́ ìṣètò Ìjọba Ọlọ́run, ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ ibi àgbàyanu