Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Omi Tí Ń Fúnni Ní Ìyè Ń Ṣàn Láwọn Òkè Andes

Omi Tí Ń Fúnni Ní Ìyè Ń Ṣàn Láwọn Òkè Andes

Omi Tí Ń Fúnni Ní Ìyè Ń Ṣàn Láwọn Òkè Andes

Àwọn Òkè Ńlá Andes la àárín Peru já, ó pín orílẹ̀-èdè náà sí ẹkùn ilẹ̀ etíkun gbígbẹ táútáú ní ìhà ìwọ̀ oòrùn àti igbó kìjikìji, tó sì tún móoru ní ìlà oòrùn. Orí òkè tó tẹ́ rẹrẹ yìí ni ìdá mẹ́ta mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n èèyàn tó wà ní Peru ń gbé. Wọ́n lè wà ní orí àwọn òkè títẹ́jú pẹrẹsẹ àti ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ẹ̀bá òkè ti Andes tàbí kí wọ́n wà ní àwọn ọ̀gbun tó dà bí èyí tí kò nísàlẹ̀ àti ní àwọn àfonífojì ọlọ́ràá tó wà láàárín àwọn òkè tó so kọ́ra yẹn.

BÍ ÀWỌN òkè Andes ṣe rí págunpàgun yẹn kò jẹ́ kó rọrùn fáwọn ẹlòmíràn láti wá síbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dà bíi pé àdádó ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ wà, tí wọn kò sì mọ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ tó ń lọ àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tó ń yọjú láwọn ibòmíràn.

Wọ́n ti tẹ àwọn abúlé kéékèèké dó sẹ́bàá àwọn odò, kí wọ́n lè máa rí omi lò fáwọn irúgbìn àtàwọn agbo ẹranko llamas, alpacas, vicuñas, àtàwọn àgùntàn. Àmọ́ ṣá o, oríṣi omi mìíràn tún wá ń ṣàn ní àwọn òkè ńlá Andes—ìyẹn ni omi tẹ̀mí tí ń tuni lára tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, tí í ṣe “orísun omi ààyè.” (Jeremáyà 2:13) Ọlọ́run ń lo àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó wà láwọn ibùdó tó lé téńté sórí àwọn òkè Andes, kí wọ́n lè jèrè ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀ àti àwọn ète rẹ̀.—Aísáyà 12:3; Jòhánù 17:3.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyí ń sa gbogbo ipá wọn láti mú ìhìn tí ń fúnni ní ìyè látinú Bíbélì lọ sí àwọn ibi tí kò rọrùn láti dé. (1 Tímótì 2:4) Ìhìn tí a gbé karí Bíbélì yìí ń lani lóye, ó sì gbámúṣé. Ó ti sọ àwọn olóòótọ́ ènìyàn tó wà níbẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àwọn àṣà ìbílẹ̀, àti àwọn èrò tó ń mú kí wọ́n bẹ̀rù àwọn òkú, àwọn ẹ̀mí búburú, àtàwọn agbára ìṣẹ̀dá. Ní pàtàkì jù lọ, ìhìn yìí ń fún wọn ní ìrètí ológo ti ìwàláàyè tí kò lópin nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.

Ìsapá Tí Wọ́n Ń Ṣe

Àwọn oníwàásù Ìjọba náà tó ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn àgbègbè àdádó wọ̀nyí ní ọ̀pọ̀ ìyípadà láti ṣe. Kí àwọn tó máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè dénú ọkàn àwọn ènìyàn ibẹ̀, wọ́n ní láti gbọ́ èdè Quechua tàbí Aymara, tó jẹ́ àwọn èdè méjì tí wọ́n ń sọ ládùúgbò náà, dé ìwọ̀n kan.

Kò rọrùn rárá láti dé àwọn abúlé tó wà láwọn òkè Andes. Àwọn ọkọ̀ ojú irin tó dé àwọn àgbègbè yẹn kò pọ̀. Rírí ọkọ̀ débẹ̀ kì í ṣe ohun tó dájú nítorí ojú ọjọ́ tí kò dára àti bí ilẹ̀ náà ṣe rí gbágungbàgun. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí ṣe wá ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n lè fún wọn ní ìhìn Ìjọba náà?

Àwọn onígboyà tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere ti kojú ìpèníjà náà, wọ́n sì ti fi irú ẹ̀mí tí wòlíì Aísáyà ní fèsì pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Wọ́n ti lo ilé alágbèérìn mẹ́ta láti rin ìrìn àjò lọ sí ìhà àríwá, àárín gbùngbùn, àti gúúsù àgbègbè náà. Àwọn aṣáájú ọ̀nà onítara, ìyẹn àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún náà máa ń kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ páálí tí wọ́n kó Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí lọ síbẹ̀, wọ́n sì ti gbin èso òtítọ́ Bíbélì sọ́kàn àwọn ẹni bí ọ̀rẹ́, tí wọ́n níwà ọ̀làwọ́, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ ọkàn tó ń gbé níbẹ̀.

Àwọn kọ́nà kan wà láwọn ọ̀nà orí òkè wọ̀nyí tó ṣòroó gbà kọjá gan-an. Láti rin àwọn kan lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, àwọn ọkọ̀ ní láti máa yíwọ́ síbí sọ́hùn-ún lójú ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ. Ìgbà kan tí wọ́n ń gba irú ọ̀nà tí kò ṣe tààrà bẹ́ẹ̀, míṣọ́nnárì kan tó jókòó sẹ́yìn bọ́ọ̀sì kan yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé, ó sì rí i pé ọ̀kan lára àwọn táyà ẹ̀yìn wà ní bèbè kòtò tó jìn ju igba ó dín mẹ́wàá [190] mítà lọ! Ńṣe ló di ojú rẹ̀ títí bọ́ọ̀sì náà fi gba ibẹ̀ kọjá.

Àwọn ọ̀nà kan kò dáa rárá, wọ́n sì há. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà gbágungbàgun yẹn ni ọkọ̀ àfiṣelé kan ń gbà bọ̀, tó rọra ń da fíríì bọ̀ lójú ọ̀nà híhá kan, nígbà tó pàdé ọkọ̀ akẹ́rù kan tó ń gun òkè bọ̀. Ọkọ̀ àfiṣelé náà ní láti fẹ̀yìn rìn padà sí òkè tó ti ń bọ̀ títí tó fi dé ibì kan tí ọkọ̀ méjèèjì ti rọra kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn.

Síbẹ̀síbẹ̀, àbájáde irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ kọyọyọ. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìsapá wọ̀nyẹn?

“Bíbomirin” Adágún Titicaca

Àfonífojì kan láàárín àwọn Òkè Andes tó fi mítà ọgbọ̀kàndínlógún [3,800] ga ju ìtẹ́jú òkun lọ ni Adágún Titicaca wà, òun ni adágún tó ga jù lọ, tó gba àwọn ọkọ̀ òkun púpọ̀ jù lọ lágbàáyé. Àwọn ṣóńṣó orí òkè tí yìnyín bò, tí àwọn kan nínú wọn ga ju egbèjìlélọ́gbọ̀n [6,400] mítà lọ, ló jẹ́ kí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn odò mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ń ṣàn sínú Adágún Titicaca wà níbẹ̀. Nítorí gíga tí ibẹ̀ yẹn ga, ńṣe ni ibẹ̀ máa ń tutù nini, ó sì di dandan kí àwọn tó jẹ́ àjèjì ní àgbègbè náà máa fara da àìsàn tí wíwà níbi gíga máa ń fà.

Nígbà díẹ̀ sẹ́yìn, àwùjọ àwọn aṣáájú ọ̀nà kan tí wọ́n gbọ́ èdè Quechua àti ti Aymara rìnrìn àjò lọ sí erékùṣù Amantani àti Taquile lórí Adágún Titicaca. Wọ́n mú àwòrán slide kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “A Closer Look at the Churches,” tó tú gbogbo irọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù fó, dání lọ. Inú àwọn ènìyàn náà dùn sí i gan-an ni. Ọkùnrin kan fi tayọ̀tayọ̀ gba àwọn arákùnrin náà, ó sì fún wọn ní yàrá ńlá kan nínú ilé rẹ̀, níbi tí wọ́n lè gbé, kí wọ́n sì máa tibẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọgọ́rùn-ún èèyàn ló wà ní ìpàdé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ní erékùṣù Amantani; ogóje èèyàn ló sì wá sí ti erékùṣù Taquile. Èdè Quechua ni wọ́n lò. Tọkọtaya kan tó ti ń gbé ibi tó jìnnà sí ẹsẹ̀ odò tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Ó tó àkókò wàyí fún ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti rántí wa. A ti ń gbàdúrà pé kẹ́ ẹ wá.”

Yàtọ̀ sáwọn erékùṣù ńláńlá méjì yìí, ìhìn rere náà tún ti dé àwọn kan lára àwọn erékùṣù bí ogójì tó “léfòó” sórí Adágún Titicaca. Àwọn erékùṣù tó léfòó kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, ewéko totora, ìyẹn àwọn esùsú tó máa ń hù sáwọn ibi tí kò jìn púpọ̀ nínú adágún náà ni wọ́n fi ṣe wọ́n. Ewéko totora máa ń yọ láti inú omi, á sì ga sókè lójú omi. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣe erékùṣù kan, àwọn ará ibẹ̀ á tẹ àwọn esùsú tí gbòǹgbò wọn ṣì wa nísàlẹ̀ adágún náà, wọ́n á sì hun wọ́n pa pọ̀ kó lè dà bíi pèpéle. Wọ́n á wá da ẹrẹ̀ kún inú pèpéle náà, wọ́n a sì fi àwọn esùsú mìíràn tí wọ́n gé kún un kí ilẹ̀ pèpéle náà lè lágbára. Àwọn èèyàn máa ń gbénú àwọn ahéré tí wọ́n fi esùsú kọ́ sórí irú pèpéle bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ọkọ̀ òbèlè kan tí wọ́n fi ń wàásù fáwọn èèyàn lórí àwọn erékùṣù Adágún Titicaca. Èèyàn mẹ́rìndínlógún ni ọkọ̀ náà lè gbé. Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí bá gúnlẹ̀ sí àwọn erékùṣù tó léfòó náà tán, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí rìn gba orí pèpéle tí wọ́n fi esùsú ṣe náà láti ojúlé sí ojúlé. Wọ́n sọ pé ó máa ń dà bí ẹni pé ibi tí wọ́n ń gbẹ́sẹ̀ lé ń mì díẹ̀díẹ̀. Àwọn tó bá ń bẹ̀rù ìrìn àjò lójú omi kò lè wá sí irú ibí yìí ṣá o!

Inú onírúurú àwùjọ àti àwọn abúlé tó wà láwọn etídò àtàwọn tó wà níbi ìyawọlẹ̀ omi tó ń ṣàn lọ sínú adágún náà làwọn tó ń sọ èdè Ayamara ń gbé. Ó máa ń rọrùn láti wa ọkọ̀ òbèlè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn wọ̀nyí ju kéèyàn lo ọkọ̀ ilẹ̀. Lápapọ̀, á tó nǹkan bí ogún ọ̀kẹ́ [400,000] èèyàn tó ń gbé láwọn àgbègbè tí irú àwọn ọkọ̀ òbèlè bẹ́ẹ̀ ń mú ìhìn Ìjọba náà dé. Àwọn ọkọ̀ òbèlè náà ṣì máa ríṣẹ́ ṣe gan-an lọ́jọ́ iwájú.

Pípa Òùngbẹ Tẹ̀mí

Abúlé Santa Lucía nítòsí Juliaca, tó wà ní àwọn òkè Andes, ni Flavio ń gbé. Wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì kọ́ ọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere tó ń lọ. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ló sì ti ń bẹ̀rù pé òun á máa joró títí ayé nínú iná àjóòkú. Ó máa ń ṣe é ní kàyéfì bí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ṣe lè finá dá èèyàn lóró títí láé. Nígbà tí Tito, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sí abúlé yẹn, ó dé ọ̀dọ̀ Flavio.

Ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tí Flavio kọ́kọ́ béèrè ni pé, “Ṣe ìsìn yín ń kọ́ni pé a máa ń dá àwọn ènìyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì?” Tito dáhùn pé irú èrò bẹ́ẹ̀ kó Ẹlẹ́dàá nírìíra, ó sì ń mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. Inú Bíbélì ti Flavio fúnra rẹ̀ ni Tito ti fi hàn án pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun rárá àti pé wọ́n ń dúró de àjíǹde sórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Oníwàásù 9:5; Jòhánù 5:28, 29) Ìyàlẹ́nu ńlá lèyí jẹ́ fún Flavio. Ojú ẹsẹ̀ ló tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi di Kristẹni tó ṣe batisí.

Abúlé Kan Tó Fi Ìmọrírì Hàn

Fojú inú wo bínú èèyàn ṣe máa dùn tó láti mú Ìwé Mímọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará abúlé tí wọn ò tíì rí Bíbélì kan rí tàbí láti wàásù fáwọn ará abúlé tí kò tíì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí nípa ìhìn rere tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ rí! Ìrírí táwọn arábìnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní nìyẹn—àwọn ni Rosa, Alicia, àti Cecilia—tí wọ́n wàásù yí ká àwọn abúlé Izcuchaca àti Conayca, tó wà ní òkè tó ga ju egbèjìdínlógún [3,600] mítà lọ ní àárín gbùngbùn Peru.

Nígbà tí wọ́n dé abúlé àkọ́kọ́, kò síbi tí wọ́n máa gbé. Wọ́n bá ọ̀gá ọlọ́pàá àdúgbò náà sọ̀rọ̀, wọ́n sì ṣàlàyé ìdí táwọn fi wá fún un. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó jẹ́ kí wọ́n sun àgọ́ ọlọ́pàá náà mọ́jú. Ọjọ́ kejì làwọn aṣáájú ọ̀nà ọ̀hún rílé tó ṣeé gbé, èyí ló wá di ibi tí wọ́n fi ṣe ibùdó iṣẹ́ wọn.

Kò pẹ́ tí àkókò fi tó fún Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àwọn aṣáájú ọ̀nà náà ti dé gbogbo ilé tó wà lábúlé Izcuchaca, wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ Bíbélì sóde, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Ṣáájú ọjọ́ Ìṣe Ìrántí náà ni wọ́n ti fún àwọn ènìyàn ní ìwé ìkésíni sí ibi ayẹyẹ yìí, wọ́n ṣàlàyé ète ayẹyẹ náà àti ìtumọ̀ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a máa ń lò nígbà tá a bá ń ṣe é. Wọ́n pe àwọn arákùnrin bíi mélòó kan láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà sì sọ àsọyé. Ẹ wo bí ayọ̀ náà ti pọ̀ tó, láti rí àádọ́ta èèyàn tó tinú abúlé kékeré yẹn wá síbi àṣeyẹ àkànṣe yìí! Fún ìgbà àkọ́kọ́ pàá, ó ṣeé ṣe fún wọn láti lóye ohun tí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa túmọ̀ sí gan-an. Ẹ sì wo bí níní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níkàáwọ́ ṣe jọ wọ́n lójú tó!

Bíbọ́ Kúrò Nínú Àjàgà

Ó máa ń múnú ẹni dùn láti mú omi òtítọ́ Bíbélì tí ń tuni lára wá fún àwọn tó wà nígbèkùn ẹ̀sìn èké. Pisac jẹ́ ìlú pàtàkì ní Ilẹ̀ Ọba Inca ìgbàanì. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń gbébẹ̀ lónìí ni wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kọ́. Àlùfáà wọn sọ fún wọn pé kìkì ìgbà tí àlùfáà bá báwọn bẹ̀bẹ̀ nìkan ni wọ́n tó lè lọ sí ọ̀run.

Ó hàn gbangba pé òùngbẹ omi òtítọ́ Bíbélì tí ń tuni lára ń gbẹ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Santiago, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù láti ilé-dé-ilé, ó láǹfààní láti ṣàlàyé fún ọkùnrin kan pé Párádísè orí ilẹ̀ ayé làwọn olódodo yóò gbé. (Sáàmù 37:11) Santiago fi hàn án látinú Bíbélì pé a óò jí àwọn òkú dìde, àti pé a óò fún aráyé nítọ̀ọ́ni ní àwọn ọ̀nà pípé ti Jèhófà kí wọ́n lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. (Aísáyà 11:9) Kátólíìkì olùfọkànsìn ni ọkùnrin náà títí di àkókò yẹn, ó ti bá ẹ̀mí lò, ó sì máa ń mu ọtí lámupara. Ó ti wá ní ìrètí tá a gbé ka Bíbélì báyìí, ó sì ti ní ohun kan tó ń lépa nínú ìgbésí ayé rẹ̀—ìyẹn ni láti gbé nínú Párádísè. Ó jó gbogbo ohun tó fi ń bá ẹ̀mí lò níná, ó sì jáwọ́ nínú mímu ọtí àmupara. Ó kó gbogbo ìdílé rẹ̀ jọ, ó sì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àkókò ti ń lọ, gbogbo mẹ́ńbà ìdílé yẹn ló ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ṣe batisí.

Wọ́n Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò

Àwọn tó ń gbé orí àwọn òkè wọ̀nyẹn ní ẹ̀mí aájò àlejò gan-an ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé mọ́ńbé ni wọ́n ń gbé, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, síbẹ̀ wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n ní ṣàlejò. Kí onílé kan tóó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà gíga tó wà nínú Bíbélì, ó lè fún àlejò kan ní ewé coca tí yóò máa jẹ lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá di Ẹlẹ́rìí tán, ó lè fún un ní ṣúgà ẹ̀kún ṣíbí kan, tó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú ewé coca láwọn ẹkùn-ìpínlẹ̀ tó jẹ́ àdádó.

Arákùnrin kan sọ pé kí míṣọ́nnárì kan tẹ̀ lé òun lọ sí ìpadàbẹ̀wò kan. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe wàhálà gan-an láti gun òkè kan dé ibẹ̀, wọ́n pàtẹ́wọ́ káwọn onílé náà lè mọ̀ pé wọ́n ti dé. Wọ́n wá mú wọn wọ ahéré kan, tó jẹ́ pé ńṣe lèèyàn máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kó tó lè wọlé. Wọ́n rọra rìn gba ẹ̀bá ilẹ̀ eléruku àárín ilé, níbi tí ìyá náà gbẹ́ ihò kan sí, tó tẹ́ bùláńkẹ́ẹ̀tì sí i, tó sì gbé ọmọ rẹ̀ sínú ihò náà. Níwọ̀n bí ọmọ ọwọ́ náà kò ti lè jáde nínú ihò náà, ńṣe ni ọkàn rẹ̀ balẹ̀, tó ń ṣe atata-n-toto ní tirẹ̀, nígbà táwọn àgbàlagbà ń sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀yàyà jíròrò lórí àwọn ìbùkún Ìjọba náà, obìnrin náà gbé ìgò ńlá kan tí ohun mímu tí wọ́n ń ṣe ládùúgbò yẹn wà nínú rẹ̀ jáde. Láìpẹ́, àwọn arákùnrin náà ti ń sọ̀ kalẹ̀ láwọn òkè wọ̀nyẹn láti bẹ àwọn ẹlòmíràn wò.

Ìkórè Tó Lárinrin

Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún àwùjọ àdádó ló wà ní àgbègbè yìí báyìí, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A tún máa ń rán àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Lima lọ síbẹ̀, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti sọ àwùjọ wọ̀nyẹn di ìjọ. Àwọn tó ní ọkàn rere, tí wọ́n ti wà ní ìgbèkùn ìsìn èké àti ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán fún àkókò gígùn ti rí òmìnira nípasẹ̀ ìhìn rere Ìjọba náà báyìí! (Jòhánù 8:32) A ti pa òùngbẹ omi òtítọ́ tó ń gbẹ wọ́n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jíjẹ́rìí láwọn erékùṣù tó “léfòó” ní Adágún Titicaca