Pa Ọkàn-àyà Rẹ Mọ́
Pa Ọkàn-àyà Rẹ Mọ́
“Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—ÒWE 4:23.
1, 2. Èé ṣe tó fi yẹ ká pa ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa mọ́?
LẸ́YÌN ìjì líle kan ni ọkùnrin àgbàlagbà kan ní erékùṣù kan ni Caribbean jáde síta látinú ibi tó forí pa mọ́ sí. Bó ṣe ń wo gbogbo nǹkan tó bà jẹ́ láyìíká rẹ̀, ó rí i pé igi ràgàjì kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé òun ti wó. Ẹnu yà á, ó sì ń ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ló dé tó fi wó, nígbà táwọn igi kéékèèké àyíká rẹ̀ kò wó?’ Ìgbà tó lọ wo kùkùté igi náà ló tó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Àṣé gbogbo inú igi tó jọ pé ó dúró dáadáa nílẹ̀ yìí ló ti rà. Ìjì yẹn ló jẹ́ kó hàn pé òkú òòró ni igi náà.
2 Ẹ wo àjálù ńláǹlà tó máa jẹ́ bí olùjọsìn tòótọ́ tó jọ pé ẹsẹ̀ rẹ̀ ranlẹ̀ lójú ọ̀nà ìyè táwọn Kristẹni ń tọ̀, bá lọ yẹsẹ̀ nígbà tí àdánwò ìgbàgbọ́ dé. Òótọ́ kúkú ni Bíbélì sọ nígbà tó wí pé “ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Èyí túmọ̀ sí pé tá ò bá wà lójúfò déédéé, kódà ọkàn-àyà tó dára jù lọ lè kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Níwọ̀n bí kò ti sí ọkàn-àyà aláìpé tó bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́, kò yẹ ká fojú kékeré wo ìmọ̀ràn náà tó sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:23) Fún ìdí yìí, báwo la ṣe lè pa ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa mọ́?
Àyẹ̀wò Déédéé Pọndandan
3, 4. (a) Àwọn ìbéèrè wo la lè béèrè nípa ọkàn-àyà ti ara? (b) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa?
3 Bó o bá lọ bá oníṣègùn pé kí ó yẹ̀ ọ́ wò, kò ní ṣàì yẹ ọkàn-àyà rẹ wò. Ǹjẹ́ ìlera ara rẹ, títí kan ti ọkàn-àyà rẹ fi hàn pé ara rẹ ń rí àwọn èròjà aṣaralóore tó ń fẹ́? Ìwọ̀n ìfúnpá rẹ ńkọ́? Ṣé ọkàn-àyà rẹ ń lù kìkì bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ? Ṣé o ń ṣe eré ìmárale tí ó tó? Ṣé hílàhílo ò ti pọ̀ jù fún ọkàn-àyà rẹ?
4 Bí ọkàn-àyà tara bá ń fẹ́ àyẹ̀wò déédéé, ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wá ńkọ́? Jèhófà ń yẹ̀ ẹ́ wò. (1 Kíróníkà 29:17) Ó sì yẹ kí àwa náà máa yẹ̀ ẹ́ wò. Lọ́nà wo? Nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè bíi: Ǹjẹ́ ọkàn-àyà mi ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ tó nípa dídá kẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sípàdé déédéé? (Sáàmù 1:1, 2; Hébérù 10:24, 25) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà wà nínú ọkàn-àyà mi “bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi,” tó ń sún mi láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? (Jeremáyà 20:9; Mátíù 28:19, 20; Róòmù 1:15, 16) Ǹjẹ́ mo ń fi torí tọrùn ṣe, nípa lílọ́wọ́ sí apá èyíkéyìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nígbà tó bá ṣeé ṣe? (Lúùkù 13:24) Kí làwọn ohun tí mo ń jẹ́ kó wọnú ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ mi? Ṣé àwọn tí ọkàn-àyà wọ́n ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ ló máa ń wù mí láti bá rìn? (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ǹjẹ́ kí a wà lójúfò, ká lè rí ibi tí ọ̀ràn ara wa bá kù sí, ká sì tètè ṣàtúnṣe.
5. Kí ni àǹfààní tí àdánwò ìgbàgbọ́ lè ṣe?
5 Léraléra la máa ń rí àdánwò ìgbàgbọ́. Àdánwò sì máa ń jẹ́ ká mọ ipò tí ọkàn-àyà wa wà. Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí, kí ó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, láti dán ọ wò, kí ó lè mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà rẹ, ní ti bóyá ìwọ yóò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Diutarónómì 8:2) Ǹjẹ́ kì í yà wá lẹ́nu láti rí ìmọ̀lára wa, tàbí ibi tí ọkàn wa máa ń lọ, tàbí bá a ṣe ń hùwà, nígbà tí àwọn ipò tàbí àdánwò kan tí a kò retí tẹ́lẹ̀ bá yọjú? Dájúdájú, àwọn àdánwò tí Jèhófà fàyè gbà lè jẹ́ kí a rí àwọn àléébù wa, kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣàtúnṣe. (Jákọ́bù 1:2-4) Ǹjẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀, ká sì máa gbàdúrà nípa ìgbésẹ̀ tó yẹ ní gbígbé nígbà tí àdánwò bá dé!
Kí Ni Ọ̀rọ̀ Ẹnu Wa Fi Hàn?
6. Kí ni irú àwọn ohun tí a máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lè fi hàn nípa ọkàn-àyà wa?
6 Báwo la ṣe lè mọ ohun tó wà lọ́kàn-àyà wa? Jésù sọ pé: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Ohun tá a sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ló ń fi ohun tí ọkàn-àyà wa ń gbìmọ̀ hàn. Ṣé àwọn nǹkan ìní tara àti rírọ́wọ́ mú nínú ayé la sábà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Tàbí kẹ̀, ṣé àwọn nǹkan tẹ̀mí tàbí àwọn góńgó tẹ̀mí la sábà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Dípò dídi arí-tẹni-mọ̀ọ́-wí, ǹjẹ́ a máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ gbójú fo àṣìṣe àwọn ẹlòmíì? (Òwe 10:11, 12) Ṣé ọ̀rọ̀ ẹni ẹlẹ́ni la máa ń rí sọ ṣáá, àmọ́ tí a kì í sábàá sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí àti ti ìwà rere? Ṣé èyí kì í ṣe àmì pé à ń tojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn?—1 Pétérù 4:15.
7. Nínú ọ̀ràn pípa ọkàn-àyà wa mọ́, ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ohun táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ṣe?
7 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ńlá kan yẹ̀ wò. Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kò lè bá Jósẹ́fù àbúrò wọn “sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.” Kí nìdí? Wọ́n ń jowú rẹ̀ torí pé ọmọlójú bàbá wọn ni. Nígbà tó tún yá, tí Ọlọ́run mú kí Jósẹ́fù lá àwọn àlá kan tó fi hàn pé ó rí ojú rere Jèhófà, wọ́n wá “rí ìdí síwájú sí i láti kórìíra rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:4, 5, 11) Wọ́n ṣìkà, wọ́n ta àbúrò wọn sóko ẹrú. Nígbà tí wọ́n tún fẹ́ bo ìwà ìkà wọn mọ́lẹ̀, wọ́n tan bàbá wọn, wọ́n ní ẹranko ẹhànnà ló pa Jósẹ́fù jẹ. Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kùnà láti pa ọkàn-àyà wọn mọ́ nínú ọ̀ràn yẹn. Bí a bá jẹ́ alárìíwísí, ṣé kì í ṣe àmì pé ìlara tàbí owú ń bẹ nínú ọkàn-àyà wa nìyẹn? Ó yẹ ká máa kíyè sí nǹkan tó ń tẹnu wa jáde, ká sì tètè yọwọ́ nínú ìwà tí kò dáa.
8. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹ ọkàn-àyà wa wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a purọ́?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́,” àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé máa ń ṣèké. (Hébérù 6:18) Onísáàmù náà kédàárò pé: “Òpùrọ́ ni gbogbo ènìyàn.” (Sáàmù 116:11) Kódà àpọ́sítélì Pétérù purọ́ nígbà tó sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta. (Mátíù 26:69-75) Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ yẹra fún irọ́ pípa, torí pé Jèhófà kórìíra “ahọ́n èké.” (Òwe 6:16-19) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a purọ́, á dáa ká fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó fà á. Ṣé torí ìbẹ̀rù èèyàn ni? Ṣé torí kí wọ́n má bàa fìyà jẹ wá ni? Tàbí kẹ̀, ṣé torí ojú táwọn èèyàn á máa fi wò wá ni, tàbí torí ìwà ìmọtara ẹni nìkan pọ́ńbélé ni? Ohun yòówù kó fà á, ó mà yẹ ká ronú lórí ọ̀ràn náà, ká fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gba àṣìṣe wa, ká tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti wá nǹkan ṣe sí ibi tí ọ̀ràn ara wa kù sí yìí! Ó lè jẹ́ “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ” ló máa tóótun jù lọ láti fún wa ní irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.—Jákọ́bù 5:14.
9. Kí ló ṣeé ṣe kí àdúrà wa fi hàn nípa ọkàn-àyà wa?
9 Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀, èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Nítorí ìdí náà pé èyí wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ, tí o kò sì béèrè fún ọlà, ọrọ̀ àti ọlá . . . ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ; ọlà àti ọrọ̀ àti ọlá pẹ̀lú ni èmi yóò fi fún ọ.” (2 Kíróníkà 1:11, 12) Ohun tí Sólómọ́nì béèrè fún, àtohun tí kò béèrè fún, ni Jèhófà fi mọ ohun tó wà lọ́kàn Sólómọ́nì. Kí ni ohun tí à ń bá Ọlọ́run sọ ń fi hàn nípa ọkàn-àyà wa? Ǹjẹ́ àdúrà wa ń fi hàn pé òùngbẹ ìmọ̀ àti ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ń gbẹ wá? (Òwe 2:1-6; Mátíù 5:3) Ǹjẹ́ ire Ìjọba Ọlọ́run ń jẹ wá lọ́kàn? (Mátíù 6:9, 10) Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni gbogbo ohun tí à ń sọ nínú àdúrà wa, tí kì í ṣe àtọkànwá, èyí lè jẹ́ àmì pé ó yẹ ká wá àkókò láti fi ṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 103:2) Gbogbo Kristẹni ló yẹ kó wà lójúfò kí wọ́n lè mọ ohun tí àdúrà wọn fi hàn nípa wọn.
Kí Ni Ìwà Wa Ń Sọ?
10, 11. (a) Ibo ni panṣágà àti àgbèrè ti ń bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni kò ní jẹ́ ká ‘ṣe panṣágà nínú ọkàn-àyà wa’?
10 Wọ́n ní ìwà èèyàn máa ń sọ irú ẹni téèyàn jẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ lọ. Dájúdájú, èéfín nìwà, ó sì ń sọ púpọ̀ nípa irú èèyàn tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Bí àpẹẹrẹ, lórí ọ̀ràn ìwà mímọ́, pípa ọkàn-àyà wa mọ́ kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn yíyẹra fún àgbèrè tàbí panṣágà nìkan. Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè, ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe panṣágà nínú ọkàn-àyà wa pàápàá?
11 Jóòbù baba ńlá ìgbàanì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Kò sí àní-àní pé Jóòbù bìkítà fáwọn ọ̀dọ́bìnrin, kódà ó ṣojú àánú sí wọn nígbà tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin olùpàwàtítọ́mọ́ yìí kò ronú kan níní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí wọn láé. Èé ṣe? Nítorí pé ó ti pinnu pé òun ò ní wo obìnrin kankan láti ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i. Ó sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Ǹjẹ́ kí àwa náà bá ojú tiwa dá irú májẹ̀mú yẹn, ká lè pa ọkàn-àyà wa mọ́.
12. Báwo lo ṣe máa fi Lúùkù 16:10 sílò lórí ọ̀ràn pípa ọkàn-àyà rẹ mọ́?
12 Ọmọ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ ká máa yẹ ìwà wa wò nínú àwọn ohun tá a lè kà sí pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, títí kan ìwà wa nínú kọ̀rọ̀ yàrá wa. (Sáàmù 101:2) Nígbà tá a bá jókòó tá a ń wo tẹlifíṣọ̀n nínú ilé wa, tàbí tá a wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ǹjẹ́ a máa ń rí i dájú pé a ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ”? (Éfésù 5:3, 4) Ìwà ipá tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí tó máa ń wáyé nínú àwọn eré àṣedárayá orí fídíò ńkọ́? Onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.
13. Kí la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún nígbà tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ń tinú ọkàn-àyà wa jáde wá?
13 Jeremáyà kìlọ̀ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Àdàkàdekè tí ọkàn-àyà ń ṣe yìí máa ń hàn nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre lẹ́yìn tá a ti ṣe ohun tí kò tọ́, tàbí tá a ń fojú pa àṣìṣe wa rẹ́, tàbí tá a ń fojú kékeré wo àléébù wa, tàbí tá a ń fọ́nnu nípa àwọn ohun tá a gbé ṣe. Ọkàn-àyà tó gbékútà tún máa ń ṣe àgàbàgebè—ìyẹn ni pé, ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ dídùn tó ń jáde lẹ́nu onítọ̀hún, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ lohun tó ń hù níwà. (Sáàmù 12:2; Òwe 23:7) Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe tan ara wa jẹ bá a ti ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ń tinú ọkàn-àyà wa jáde!
Ṣé Ojú Wa Mú Ọ̀nà Kan?
14, 15. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti ní ojú tó “mú ọ̀nà kan”? (b) Báwo ni jíjẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa ọkàn-àyà wa mọ́?
14 Jésù sọ pé: “Fìtílà ara ni ojú.” Ó wá fi kún un pé: “Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò.” (Mátíù 6:22) Góńgó kan, tàbí ète kan ni ojú tó bá mú ọ̀nà kan máa ń wò, kì í wò rá-rà-rá. Àní sẹ́, ohun tó yẹ ká gbájú mọ́ ni “wíwá ìjọba náà àti òdodo” Ọlọ́run. (Mátíù 6:33) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa bí ojú wa kò bá mú ọ̀nà kan?
15 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn àtijẹ-àtimu yẹ̀ wò. Ara ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ni pé ká máa gbọ́ bùkátà ìdílé wa. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́ bí a bá wá fẹ́ ní oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé, àtàwọn nǹkan míì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tó dára jù lọ, táwọn èèyàn ń lé kiri ńkọ́? Ǹjẹ́ ìyẹn ò ní dẹrù pa ọkàn-àyà àti èrò inú wa, tí ọkàn wa ò fi ní sí nínú ìjọsìn wa mọ́? (Sáàmù 119:113; Róòmù 16:18) Èé ṣe tí a ó fi wá tọrùn bọ ọ̀ràn gbígbọ́ bùkátà débi pé a ò wá ní í mọ̀ ju fífi ojoojúmọ́ ayé gbọ́ ti ìdílé, ti iṣẹ́ ajé, àti ti ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì? Ká rántí ìmọ̀ràn onímìísí tó sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Lúùkù 21:34, 35.
16. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fúnni nípa ojú, èé sì ti ṣe?
16 Ojú jẹ́ ẹ̀yà ara pàtàkì tó ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí èrò inú àti ọkàn-àyà. Ohun tójú bá ń wò lè ní ipa tó lágbára lórí ìrònú, ìmọ̀lára, àti ìṣesí wa. Jésù lo èdè àpèjúwe nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí fífi ojú rí nǹkan ti jẹ́ ìdẹwò tó lágbára, ó ní: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara rẹ ju kí a gbé gbogbo ara rẹ sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Mátíù 5:29) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojú wa máa wo ìwòkuwò. Fún àpẹẹrẹ, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa wo àwọn ohun tó ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìgbónára sókè.
17. Báwo ni fífi Kólósè 3:5 sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ọkàn-àyà wa mọ́?
17 Àmọ́ o, ojú nìkan kọ́ ni ẹ̀yà ara tó ń jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ń lọ. Ó tún yẹ ká kíyè sára nípa àwọn ẹ̀yà ara mìíràn tó máa ń jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí àti ẹ̀yà ara tá a fi ń gbọ́ràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—Kólósè 3:5.
18. Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ ká gbé bí èròkérò bá wọ ọkàn wa?
18 Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí gbára jọ nínú èrò inú wa lọ́hùn-ún. Ńṣe ni fífàyè gba irú èròkérò bẹ́ẹ̀ máa ń fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lágbára, táá sì bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí ọkàn-àyà. “Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14, 15) Ọ̀pọ̀ jẹ́wọ́ pé bí ìdánìkan hùwà ìbálòpọ̀ ṣe sábà ń wáyé nìyẹn. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí kún èrò inú wa! (Fílípì 4:8) Bí èròkérò bá sì ṣèèṣì wá sọ́kàn wa, ńṣe ló yẹ ká tètè mú un kúrò.
‘Fi Ọkàn-Àyà Pípé Sin Jèhófà’
19, 20. Báwo la ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú fífi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà?
19 Nígbà tí ọjọ́ ogbó dé, Dáfídì Ọba sọ fún ọmọ rẹ̀ pé: “Sólómọ́nì ọmọkùnrin mi, mọ Ọlọ́run baba rẹ kí o sì fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn sìn ín; nítorí gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” (1 Kíróníkà 28:9) Sólómọ́nì alára gbàdúrà fún “ọkàn-àyà ìgbọràn.” (1 Àwọn Ọba 3:9) Ṣùgbọ́n, jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ló dojú kọ ìṣòro bí òun ò ṣe ní pàdánù irú ọkàn-àyà tó béèrè fún yìí.
20 Bí àwa yóò bá kẹ́sẹ járí nínú ọ̀ràn yìí, a ò ní fi mọ sórí kìkì níní ọkàn-àyà tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, ṣùgbọ́n a óò tún sapá láti pa á mọ́. Láti lè ṣe èyí, àwọn ìránnilétí inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà nínú ọkàn-àyà wa—kí wọ́n wà ‘nínú rẹ̀.’ (Òwe 4:20-22) A ò tún ní gbàgbé àtimáa yẹ ọkàn-àyà wa wò déédéé, ká máa fi tàdúrà-tàdúrà gbé ohun tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa ń fi hàn yẹ̀ wò. Kí làǹfààní irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ bí a kò bá fi taratara béèrè pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó tá a rí nínú ara wa? Ẹ sì wo bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká kíyè sára nípa ohun tí àwọn agbára ìmòye wa ń mú wọnú èrò wa! Bá a bá ń ṣe èyí, ìdánilójú wà pé “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó pa ọkàn-àyà wa mọ́ ju gbogbo ohun ìpamọ́, ká sì tún pinnu pé a óò máa fi ọkàn-àyà pípé sin Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká pa ọkàn-àyà wa mọ́?
• Báwo ni fífarabalẹ̀ gbé ohun tó ń jáde lẹ́nu wa yẹ̀ wò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ọkàn-àyà wa mọ́?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan”?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí la sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lóde ẹ̀rí, nípàdé, àti nílé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ojú tó bá mú ọ̀nà kan kì í wò rá-rà-rá