Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìbùkún Jèhófà—Èyíinì Ni Ohun Tí Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀”

“Ìbùkún Jèhófà—Èyíinì Ni Ohun Tí Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀”

“Ìbùkún Jèhófà—Èyíinì Ni Ohun Tí Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀”

GBOGBO wa là ń fẹ́ ìbùkún. Ìbùkún máa ń mú ayọ̀ ẹni kún, ó sì ń fi kún ire tàbí aásìkí ẹni. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé,” gbogbo ojúlówó ìbùkún pípẹ́ títí ló pilẹ̀ ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́. (Jákọ́bù 1:17) Ó ń tú ìbùkún dà sórí gbogbo ènìyàn, títí kan àwọn tí kò mọ̀ ọ́n pàápàá. Jésù sọ nípa Baba rẹ̀ pé: “Ó . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ń fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Diutarónómì 28:1-14; Jóòbù 1:1; 42:12.

Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” (Sáàmù 84:11) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó ń sin Jèhófà ń gbé ìgbésí ayé tó lárinrin, tó sì nítumọ̀. Wọ́n mọ̀ pé “ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Bíbélì tún sọ pé: “Àwọn ẹni tí [Jèhófà] ń bù kún ni àwọn tí yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Òwe 10:22; Sáàmù 37:22, 29) Ìbùkún ńlá nìyẹn á mà jẹ́ o!

Báwo la ṣe lè rí ìbùkún Jèhófà gbà? Lọ́nà kan, a ní láti ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú rẹ̀ dùn. (Diutarónómì 30:16, 19, 20; Míkà 6:8) A rí èyí nínú àpẹẹrẹ àwọn mẹ́ta lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé ọjọ́un.

Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀

Nóà jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó tayọ lọ́lá. Jẹ́nẹ́sísì 6:8 kà pé: “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà.” Kí nìdí? Nítorí pé Nóà ṣègbọràn. Ìtàn náà sọ pé: “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Nóà tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, ó sì ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Ní àkókò kan tí ìwà ipá àti ìwà ìbàjẹ́ inú ayé légbá kan, Nóà “ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9, 22) Nítorí ìdí èyí, Jèhófà ní kí Nóà “kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.” (Hébérù 11:7) Ní ọ̀nà yìí, Nóà àti ìdílé rẹ̀—àti nípasẹ̀ wọn, ìran ènìyàn lápapọ̀—la ìparun ìran yẹn já. Nóà sì kú pẹ̀lú ìrètí àjíǹde sí ìyè ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló rí gbà yìí!

Ábúráhámù náà ní àwọn ànímọ́ tó múnú Jèhófà dùn. Èyí tó gbawájú nínú ànímọ́ wọ̀nyí ni ìgbàgbọ́. (Hébérù 11:8-10) Ábúráhámù fi ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tó ń gbé ní Úrì sílẹ̀, ó tún fi èyí tó gbé ní Háránì lẹ́yìn náà sílẹ̀ nítorí pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Jèhófà pé irú-ọmọ òun yóò di púpọ̀, yóò sì jẹ́ ìbùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè. (Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3) Láìka ọ̀pọ̀ ọdún tá a fi dán an wò sí, ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú èrè wá nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀, Ábúráhámù di baba ńlá fún Ísírẹ́lì, ìyẹn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run, àti ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó di baba ńlá fún Mèsáyà náà. (Róòmù 4:19-21) Láfikún sí i, òun ni “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́,” ó sì wá di ẹni tí a pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Róòmù 4:11; Jákọ́bù 2:23; Gálátíà 3:7, 29) Ẹ ò rí i pé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ gan-an ló gbé yẹn, ẹ sì wo ìbùkún yàbùgà yabuga tó rí gbà!

Tún gbé ọ̀rọ̀ Mósè, ọkùnrin olóòótọ́ nì yẹ̀ wò. Èyí tó tayọ jù lọ nínú àwọn ànímọ́ rẹ̀ ni bó ṣe mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí. Mósè kọ gbogbo ọrọ̀ ilẹ̀ Íjíbítì, ó sì “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Lẹ́yìn tó lo ogójì ọdún nílẹ̀ Mídíánì, ó fi arúgbó ara padà sí Íjíbítì, ó sì ko Fáráò, tó lágbára jù lọ ní àkókò yẹn lójú, láti gba òmìnira fún àwọn èèyàn rẹ̀. (Ẹ́kísódù 7:1-7) Àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́wàá tó jà nígbà yẹn ṣojú rẹ̀, ó rí Òkun Pupa tá a pín níyà, ó sì rí ìparun Fáráò àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Jèhófà tipasẹ̀ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì ní Òfin, ó sì fi í ṣe alárinà májẹ̀mú àárín Òun àti orílẹ̀-èdè tuntun náà. Ogójì ọdún gbáko ni Mósè fi darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nínú aginjù. Ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀ gidi, ó sì gbádùn àgbàyanu ìbùkún iṣẹ́ ìsìn.

Àwọn Ìbùkún Òde Òní

Àwọn ìtàn wọ̀nyí fi hàn pé ìgbésí ayé àwọn tó ń sin Ọlọ́run nítumọ̀ ní tòótọ́. Bí àwọn ènìyàn Jèhófà ṣe ń mú àwọn ànímọ́ bí ìgbọràn, ìgbàgbọ́, àti ìmọrírì fún àwọn nǹkan tẹ̀mí dàgbà ni wọ́n ń rí ìbùkún tó ga lọ́lá gbà.

Báwo la ṣe ń bù kún wa? Tóò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàn tẹ̀mí ń bá ọ̀kẹ́ àìmọye tó wà ní Kirisẹ́ńdọ̀mù fínra, àwa lè máa “tàn yinrin nítorí oore Jèhófà.” (Jeremáyà 31:12) Jèhófà ti tipasẹ̀ Jésù Kristi àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní “ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè.” (Mátíù 7:13, 14; 24:45; Jòhánù 17:3) Ìfararora pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni wa tún jẹ́ ìbùkún mìíràn. Láwọn ìpàdé àti láwọn àkókò mìíràn, wíwà lọ́dọ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀ jẹ́ orísun ayọ̀ ńlá fún wa. (Kólósè 3:8-10; Sáàmù 133:1) Àmọ́, ìbùkún tó ga lọ́lá jù lọ ni àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti títẹ̀lé ìṣísẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀.—Róòmù 5:1, 8; Fílípì 3:8.

Ríronú lórí irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ká rí i bí iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run ṣe níye lórí tó. Bóyá a ronú kan òwe Jésù nípa oníṣòwò arìnrìn-àjò kan tó ń wá àwọn péálì àtàtà. Jésù sọ nípa ọkùnrin yìí pé: “Nígbà tí ó rí péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga, ó jáde lọ, ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́, ó sì rà á.” (Mátíù 13:46) Dájúdájú, ojú tá a fi ń wo àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run nìyẹn, ojú yìí náà la fi ń wo àǹfààní ńlá tá a ní láti sìn ín, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni wa, ìrètí Kristẹni tá a ní, àti gbogbo ìbùkún mìíràn tó tan mọ́ ìgbàgbọ́ wa. Kò sí ohun tó tún lè níye lórí jùyẹn lọ nínú ìgbésí ayé wa.

San Nǹkan Padà fún Jèhófà

Nítorí pé a mọ Jèhófà sí Olùfúnni ní gbogbo ẹ̀bùn rere, ìyẹn ru wá lọ́kàn sókè láti fi ìmọrírì hàn fún àwọn ìbùkún tí a ń rí gbà. Báwo la ṣe lè ṣèyẹn? Ọ̀nà kan ni pé kí a máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá gbádùn àwọn ìbùkún kan náà. (Mátíù 28:19) Ó lé ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] ilẹ̀ tí ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dí lẹ́nu iṣẹ́ ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń lo ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní—ìyẹn àkókò, agbára, àti àwọn ohun ìní ti ara—láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.

Gbé ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbé Glendale, California, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, yẹ̀ wò. Àràárọ̀ ọjọ́ Saturday ni wọ́n máa ń rin ìrìn àjò nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà tàlọ tàbọ̀ láti ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wákàtí díẹ̀ péré ni wọ́n lè lò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò, síbẹ̀ wọn kò rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Èrè ńlá ló jẹ́ láti máa sìn ní irú ìpínlẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ yìí. Tayọ̀tayọ̀ la fi ń ṣe é.” Ó fi kún un pé: “A ní àwọn olùfìfẹ́hàn tó pọ̀ gan-an, kò sì rọrùn fún wa láti máa kàn sí gbogbo wọn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a ń bá àwọn márùn-ún ṣèkẹ́kọ̀ọ́, àwọn mẹ́rin mìíràn sì ti sọ pé ká wá máa bá àwọn náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tí wọ́n nítara ń láyọ̀ láti lo ara wọn lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. Wọ́n ń fi hàn pé àwọn ní irú ẹ̀mí tí Jésù ní, ẹni tó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ káàkiri àgbáyé ló ń kópa nínú irú iṣẹ́ ìsìn aláìmọtara-ẹni-nìkan yìí, àbájáde rẹ̀ sì ni pé ogunlọ́gọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn ló ń fetí sílẹ̀, tí wọ́n sì ń di ọmọ ẹ̀yìn. Níwọ̀n ọdún bíi márùn-ún sẹ́yìn, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùnlélọ́gọ́rin [1,700,000] ènìyàn ló ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Ká lè bójú tó àìní ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ya wọlé yìí, a ní láti máa tẹ àwọn Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì púpọ̀ sí i, a sì ní láti máa kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àtàwọn ibòmíràn tá a ti ń pàdé. Ibo wá ni owó tá a ń lò fún nǹkan wọ̀nyí ti ń wá? Látinú ọrẹ táwọn èèyàn ń fínnúfíndọ̀ ṣe ni gbogbo rẹ̀ ti ń wá.

Nítorí ipò ọrọ̀ ajé tí kò dára láwọn apá ibì kan lágbàáyé, ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń kájú àtijẹ àtimu ìdílé wọn. Ìwé ìròyìn New Scientist tiẹ̀ sọ pé bílíọ̀nù kan àwọn ènìyàn ló ń ná ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára owó tó ń wọlé fún wọn sórí oúnjẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ló sì wà nínú irú ipò yẹn. Láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, kò sí bí wọ́n ṣe lè rówó ra àwọn nǹkan bí àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni tàbí kí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu.

Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ó wu irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí àwọn ẹlòmíràn máa bá wọn gbé ẹrù wọn. Àmọ́, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Nígbà tí Mósè ń rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ohun ìní wọn ṣètọrẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ lórí wọn, ó sọ pé: “Kí ẹ̀bùn ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ní ìwọ̀n ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ èyí tí ó ti fi fún ọ.” (Diutarónómì 16:17) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù rí opó kan tó dá “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” nínú tẹ́ńpìlì, ó yìn ín lójú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó ṣe ohun tó lè ṣe. (Lúùkù 21:2, 3) Bákan náà ni àwọn Kristẹni tí nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ fún ń ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe. Bí ohun tí wọ́n ṣe kò bá sì tó, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tó ní díẹ̀ lọ́wọ́ lè bá wọn ṣe kún un.—2 Kọ́ríńtì 8:13-15.

Nígbà tá a bá ń san nǹkan padà fún Ọlọ́run lọ́nà yẹn, ó ṣe pàtàkì pé ká ní èrò tó dára lọ́kàn. (2 Kọ́ríńtì 8:12) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Nípa fífúnni fàlàlà látọkànwá bẹ́ẹ̀, a ń ṣètìlẹ́yìn fún ìmúgbòòrò ètò àjọ Ọlọ́run tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, a sì tún ń fi kún ayọ̀ tiwa fúnra wa pẹ̀lú.—Ìṣe 20:35.

Kíkópa nínú iṣẹ́ wíwàásù àti ṣíṣe ìtọrẹ àtọkànwá jẹ́ ọ̀nà méjì tá a fi lè fún Jèhófà ní nǹkan nítorí àwọn ìbùkún rẹ̀ lórí wa. Ẹ ò rí i bó ṣe fúnni níṣìírí tó láti mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti fi ìbùkún rẹ̀ jíǹkí ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n lè máà tíì mọ̀ ọ́n báyìí! (2 Pétérù 3:9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo àwọn nǹkan ìní wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kí a lè wá àwọn olóòótọ́ ọkàn rí, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ bí ìgbọràn, ìgbàgbọ́, àti ìmọrírì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò ní ayọ̀ ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’—Sáàmù 34:8.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Àwọn Ọ̀nà Tí Àwọn Kan Yàn Láti Gbà Ṣe

ÌTỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀ ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tí a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Yíká Ayé]Mátíù 24:14,” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, tàbí ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti àgbègbè wọn. O tún lè fi ọrẹ owó tí o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Treasurer’s Office, Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.

ÌṢÈTÒ ỌRẸ TÓ NÍ IPÒ ÀFILÉLẸ̀

A lè fi owó ṣe ìtọrẹ lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún ẹni tó fi tọrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé onítọ̀hún nílò rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Treasurer’s Office ní àdírẹ́sì tí a kọ sókè yìí.

ÌFÚNNI TÍ A WÉWÈÉ

Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ọrẹ tó ní ipò àfilélẹ̀, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tí a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Lára wọn ni:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí ìwéwèé owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ kan sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí kí a mú kí ó ṣeé san fún Society bí ẹni tí ó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báńkì àdúgbò bá béèrè.

Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.

Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ fún Watch Tower Society, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ ṣáájú fífi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di èyí tó o fi tọrẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tí A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tí a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí kí a kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ohun ìní tí a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Àwọn ohun ìní tí a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́, tó jẹ́ pé ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ìfúnni tí a wéwèé” túmọ̀ sí, irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé lọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí ń fẹ́ láti ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nípa oríṣiríṣi ìfúnni tí a wéwèé, Society ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Spanish, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tá a ti rí gbà nípa ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní tí a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni tó wúlò fún ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú. A sì pète rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí ń wéwèé láti fúnni ní ẹ̀bùn àkànṣe nísinsìnyí, tàbí tí ń fẹ́ fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú, kí wọ́n lè yan ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní jù, tí ó sì gbéṣẹ́ jù láti ṣe é, ní ìbámu pẹ̀lú ipò tí ìdílé wọn àti àwọn fúnra wọn wà. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè fún ẹ̀dà kan ní tààràtà láti ẹ̀ka Charitable Planning Office.

Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka Charitable Planning Office, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kí wọ́n sì tún rí àwọn àjẹmọ́nú gbà látinú owó orí tí wọ́n san. A gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ìṣètò wọ̀nyí tó àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka Charitable Planning Office létí, kí a sì fún wọn ní ẹ̀dà àkọsílẹ̀ èyíkéyìí tó bá tan mọ́ ọn. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ìṣètò ìfúnni tí a wéwèé wọ̀nyí, kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tí a tò sísàlẹ̀ yìí tàbí kí o pè wọ́n lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí kí o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

CHARITABLE PLANNING OFFICE

Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

100 Watchtower Drive,

Patterson, New York 12563-9204

Telephone: (845) 306-0707