Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

GẸ́GẸ́ BÍ RUSSELL KURZEN ṢE SỌ Ọ́

A bí mi ní September 22, 1907, ọdún méje ṣáájú sànmánì mánigbàgbé tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀. Ìdílé wa jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ. Lẹ́yìn tó o bá gbọ́ díẹ̀ lára kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn wa, wàá gbà pé ọlọ́rọ̀ ni wá lóòótọ́.

LÁTI kékeré ni Ìyáàfin Kurzen, tí í ṣe ìyá wa àgbà, ti fẹ́ mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Kó tó di ọ̀dọ́langba ló ti ń lọ sí oríṣiríṣi ṣọ́ọ̀ṣì ní Spiez, ìyẹn ìlú ẹlẹ́wà tá a bí i sí ní Switzerland. Lọ́dún 1887, ìyẹn ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí ìyá wa àgbà ṣe ìgbéyàwó, ìdílé Kurzen wà lára ẹgbàágbèje àwọn èèyàn tó ṣí wá sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Lẹ́yìn tí ìdílé náà fìdí kalẹ̀ sí Ohio, ní nǹkan bí ọdún 1900, ni Ìyá Àgbà rí ìṣúra tó ti ń wá tipẹ́. Ó rí i nínú ìwé Charles Taze Russell náà, The Time Is at Hand, tí a túmọ̀ sí èdè Jámánì. Lẹ́yẹ-ò-sọkà ló rí i pé ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bíbélì ló wà nínú ìwé náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára káká ni Ìyá Àgbà fi lè ka èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó forúkọ sílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bó ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ Bíbélì nìyẹn, tó tún ń kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Bàbá wa àgbà kò fẹ̀ẹ̀kàn nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí bí ìyàwó rẹ̀ ti nífẹ̀ẹ́ sí i.

Lára ọmọ mọ́kànlá tí Ìyá Àgbà Kurzen bí, méjì lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ìyẹn John àti Adolph àbúrò rẹ̀, nìkan ló mọyì ìṣúra tẹ̀mí tí ìyá wọ́n ṣàwárí. John ni bàbá mi, ọdún 1904 ló sì ṣèrìbọmi nílùú St. Louis, ní Ìpínlẹ̀ Missouri, níbi àpéjọpọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn, orúkọ tá a ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kì í ti í ṣe olówó lọ títí, a ṣètò àpéjọpọ̀ náà sígbà Ìpàtẹ Àgbáyé tó wáyé ní St. Louis, kí wọ́n lè lo àǹfààní ẹ̀dínwó owó ọkọ̀ ojú irin. Nígbà tó ṣe, Adolph, àbúrò bàbá mi ṣèrìbọmi ní 1907 nígbà àpéjọpọ̀ kan tó wáyé níbi Ìtàkìtì Omi Niagara, nílùú New York. Bàbá mi àti àbúrò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fìtara wàásù ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn méjèèjì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún (tá a ń pè ní aṣáájú ọ̀nà báyìí).

Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tá a bí mi lọ́dún 1907, ìdílé wa ti di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. (Òwe 10:22) Ọmọ ọwọ́ ṣì ni mí lọ́dún 1908 nígbà tí John àti Ida tí wọ́n jẹ́ òbí mi, gbé mi dání lọ sí àpéjọpọ̀ “On to Victory” tá a ṣe nílùú Put-in-Bay, ní Ìpínlẹ̀ Ohio. Joseph F. Rutherford, tó jẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn àjò nígbà yẹn ni alága àpéjọpọ̀ náà. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn, ó ti kọ́kọ́ wá sílùú Dalton, ní Ohio, tó tiẹ̀ délé wa, tó sì sọ àsọyé fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń bẹ ládùúgbò wa.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi alára ò rántí nǹkan wọ̀nyẹn, àmọ́ mo rántí àpéjọpọ̀ tá a ṣe nílùú Mountain Lake Park, ní Ìpínlẹ̀ Maryland, lọ́dún 1911. Ibẹ̀ lèmi àti Esther àbúrò mi ti pàdé Charles Taze Russell tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé nígbà yẹn.

Ní June 28, 1914, ìyẹn ọjọ́ náà tí ogun bẹ́ sílẹ̀, nígbà tí wọ́n dìtẹ̀ pa Ọmọọba Ferdinand àtìyàwó rẹ̀ nílùú Sarajevo, èmi àti ìdílé mi wà ní àpéjọpọ̀ alálàáfíà nílùú Columbus, Ohio. Láti àwọn ọdún ìjímìjí wọ̀nyẹn ni mo ti ń ní àǹfààní láti wà ní ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà. Nígbà mìíràn, a lè máà ju nǹkan bí ọgọ́rùn-ún. Nígbà mìíràn sì rèé, èrò máa ń pọ̀ lọ súà láwọn pápá ìṣiré kan tó tóbi jù lọ lágbàáyé.

Ibi Pàtàkì Ni Ilé Wa Wà

Láti nǹkan bí ọdún 1908 sí 1918, ilé wa nílùú Dalton—tó wà láàárín ìlú Pittsburgh, ní Ìpínlẹ̀ Pennsylvania àti ìlú Cleveland, ní Ìpínlẹ̀ Ohio—ni ìjọ kékeré ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń ṣe ìpàdé. Ilé wa di ibi tá a ti ń ṣe àwọn tó ti ibòmíràn wá sọ àsọyé lálejò. Wọ́n máa ń so ẹṣin wọn àti kẹ̀kẹ́ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́ àká wa, wọ́n á wá máa sọ àwọn ìrírí amóríyá àtàwọn ohun iyebíye nípa tẹ̀mí fáwọn tó bá kóra jọ. Ẹ wo ọ̀pọ̀ ìṣírí tá a ń rí gbà lákòókò wọ̀nyẹn!

Olùkọ́ ni bàbá mi, ṣùgbọ́n ìdí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó ga jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, ni ọkàn rẹ̀ wà. Ó rí i dájú pé òun kọ́ ìdílé òun nípa Jèhófà. Alaalẹ́ ni ìdílé wa máa ń gbàdúrà pa pọ̀. Nígbà ìrúwé ọdún 1919, bàbá mi ta ẹṣin wa àti kẹ̀kẹ́ tá a máa ń so mọ́ ọn. Ó sì fi dọ́là márùnléláàádọ́sàn-án [175] ra ọkọ̀ kan tí wọ́n ń pè ní 1914 Ford, kí ó bàa lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Lọ́dún 1919 àti 1922, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ló gbé ìdílé wa lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ mánigbàgbé táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú Cedar Point, Ohio.

Ìdílé wa lódindi—Mọ́mì; Dádì; Esther; John àbúrò mi; àti èmi—gbogbo wa la nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Mo ṣì rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí onílé kan bi mí ní ìbéèrè kan tó jẹ mọ́ Bíbélì. Nǹkan bí ọmọ ọdún méje ni mí nígbà yẹn. Ọkùnrin náà béèrè pé: “Ngbọ́ ọmọdé yìí, kí ni Amágẹ́dọ́nì?” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ látọ̀dọ̀ bàbá mi, mo dá a lóhùn látinú Bíbélì.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ní 1931, ìdílé wa lọ sí àpéjọpọ̀ Columbus, Ohio, níbi tí orí wa ti wú nígbà tá a gba orúkọ tuntun náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wú John lórí débi pé ó pinnu pé kí èmi àtòun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. a A bẹ̀rẹ̀, Màmá àti Bàbá àti Esther pẹ̀lú di aṣáájú ọ̀nà. Ẹ wo ìṣúra àtàtà tá a ní—ìdílé tó ń fi ìṣọ̀kan ṣe iṣẹ́ aláyọ̀ ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run! Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa ń dùn ṣìnkìn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ayọ̀ ṣì ń bẹ níwájú.

Ní February 1934, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tá a ń pè ní Bẹ́tẹ́lì) ní Brooklyn, New York. John náà wá bá mi níbẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà. Ńṣe la jọ ń gbénú yàrá kan náà kó tó di pé ó fẹ́ Jessie, aya rẹ̀ ọ̀wọ́n, lọ́dún 1953.

Lẹ́yìn tí èmi àti John lọ sí Bẹ́tẹ́lì, àwọn òbí wa lọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà jákèjádò orílẹ̀-èdè wa, Esther àti George Read ọkọ rẹ̀ sì ń bá wọn lọ. Àwọn òbí wa ò jáwọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà títí tí wọ́n fi parí ìwàláàyè wọn torí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1963. Esther àti ọkọ rẹ̀ ní ìdílé tó dáńgájíá. Fún ìdí yìí, mo ní àwọn ẹbí tí mo fẹ́ràn gidigidi.

Iṣẹ́ Àtàwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Mi ní Bẹ́tẹ́lì

John lo òye iṣẹ́ rẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, ó sì ṣiṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì mìíràn tí wọ́n pawọ́ pọ̀ ṣe àwọn nǹkan bí ẹ̀rọ giramafóònù tó ṣeé gbé rìn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ẹ̀rọ yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láti ilé dé ilé. John tún ṣe àwọn ẹ̀rọ tó máa ń di ìwé ìròyìn, tí á sì lẹ orúkọ mọ́ wọn lára, kó tó di pé a óò wá fi ìwé ìròyìn wọ̀nyí ránṣẹ́ sí àwọn tó forúkọ sílẹ̀ fún wọn.

Ibi tá a ti ń di ìwé pọ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì. A ṣì rí lára àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́ nígbà yẹn tá a jọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé tó ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì di bá a ṣe ń wí yìí. Lára wọn ni Carey Barber àti Robert Hatzfeld. Àwọn míì tí mi ò jẹ́ gbàgbé, àmọ́ tí wọ́n ti kú báyìí, ni Nathan Knorr, Karl Klein, Lyman Swingle, Klaus Jensen, Grant Suiter, George Gangas, Orin Hibbard, John Sioras, Robert Payne, Charles Fekel, Benno Burczyk, àti John Perry. Wọ́n tẹpá mọ́ṣẹ́ láìwẹ̀yìn, láìráhùn, láìretí “ìgbéga” lẹ́nu iṣẹ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn olóòótọ́ Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí la gbé ẹrù iṣẹ́ ńlá lé lọ́wọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, bí ètò àjọ náà ti ń gbòòrò sí i. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ sìn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Mo rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ nínú bíbá àwọn arákùnrin tó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyí ṣiṣẹ́ pọ̀. Nínú iṣẹ́ ti ayé, owó oṣù ni wọ́n ń san fún iṣẹ́ táwọn èèyàn ń ṣe. Èrè tiwọn nìyẹn. Àmọ́ àwọn ìbùkún yàbùgà-yabuga nípa tẹ̀mí lèèyàn ń rí gbà fún sísìn ní Bẹ́tẹ́lì, kìkì àwọn ẹni tẹ̀mí ló sì lè mọyì irú èrè bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 2:6-16.

Nathan Knorr, tó dé Bẹ́tẹ́lì ní 1923 lẹ́ni ọdún méjìdínlógún, ni alábòójútó ẹ̀ka ìtẹ̀wé láwọn ọdún 1930. Ojoojúmọ́ ló máa ń rìn yíká ẹ̀ka ìtẹ̀wé, tí á sì máa kí gbogbo òṣìṣẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan. Àwa tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn mọrírì irú ìfẹ́ tó fi hàn sí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gan-an. Ní 1936, a rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun kan gbà láti Jámánì, àwọn arákùnrin ọ̀dọ́ tó ń to ẹ̀rọ náà sì tò ó tì. Ni Arákùnrin Knorr bá gbé aṣọ iṣẹ́ wọ̀, ó sì bá wọn ṣiṣẹ́ fún ohun tó lé lóṣù kan, títí ẹ̀rọ náà fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Kò sẹ́nikẹ́ni lára wa tó lè ṣiṣẹ́ kára bíi ti Arákùnrin Knorr. Ṣùgbọ́n ó tún máa ń gbádùn eré ìtura. Kódà lẹ́yìn January 1942, tó di alábòójútó iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé, nígbà míì ó ṣì máa ń bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì ti Gílíádì gbá bọ́ọ̀lù tá a ń pè ní baseball ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì tó wà nítòsí South Lansing, ní New York.

Ní April 1950, ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣí lọ sí ibùgbé alájà mẹ́wàá kan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí 124 Columbia Heights, Brooklyn, New York. Yàrá ìjẹun tuntun náà gba gbogbo wa. Láàárín nǹkan bí ọdún mẹ́ta tá a fi kọ́ ilé yìí, kò ṣeé ṣe fún wa láti máa ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ pa pọ̀. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó nígbà tá a tún bẹ̀rẹ̀ sí kà á pa pọ̀! Arákùnrin Knorr ní kí n máa jókòó ti òun nídìí tábìlì tí wọ́n ti ń darí ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, kí n lè máa rán òun létí orúkọ àwọn ẹni tuntun nínú ìdílé wa. Àádọ́ta ọdún ni mo fi jókòó sáyè yìí nígbà ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ àti oúnjẹ àárọ̀. Ìgbà tó wá di August 4, 2000 ni wọ́n ti yàrá ìjẹun náà pa, wọ́n wá ní kí n lọ máa jẹun ní ọ̀kan lára àwọn yàrá ìjẹun tá a tún kọ́, tó jẹ́ ilé Towers Hotel tẹ́lẹ̀ rí.

Fún sáà kan ní àwọn ọdún 1950, ẹ̀rọ Linotype kan ni mo fi ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé, tí mò ń to àwọn ìlà tó máa wà ní ojú ìwé kọ̀ọ̀kan kó tó di pé a ṣe é sórí àwo ìtẹ̀wé. Iṣẹ́ yẹn kì í ṣe iṣẹ́ tí mo nífẹ̀ẹ́ sí rárá. Ṣùgbọ́n William Peterson, tó ń bójú tó àwọn ẹ̀rọ náà, ṣèèyàn gan-an, ó sì jẹ́ kí n gbádùn àkókò tí mo fi wà níbẹ̀. Nígbà tó di ọdún 1960, wọ́n ń fẹ́ àwọn tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti fi ọ̀dà kun ibùgbé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí 107 Columbia Heights. Inú mi dùn láti yọ̀ǹda ara mi fún píparí iṣẹ́ lórí ilé tuntun wọ̀nyí tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa tí ń tóbi sí i yóò máa gbé.

Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí wọ́n yanṣẹ́ kíkí àwọn àlejò káàbọ̀ sí Bẹ́tẹ́lì fún mi láìpẹ́ lẹ́yìn tá a kun ilé tó wà ní 107 Columbia Heights náà tán. Mo ti gbádùn ogójì ọdún tí mo fi wà lẹ́nu iṣẹ́ olùgbàlejò yìí, bí mo ti gbádùn àwọn ọdún yòókù tí mo ti lò ní Bẹ́tẹ́lì. Ì báà jẹ́ àlejò tàbí àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì tuntun ló wọlé wá, inú mi máa ń dùn láti rí ìyọrísí akitiyan tí gbogbo wa jọ ń ṣe kí iṣẹ́ Ìjọba náà lè máa bí sí i.

Àwọn Tí Ń Fara Balẹ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ohun tó mú kí ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa láásìkí nípa tẹ̀mí ni pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé yìí fẹ́ràn Bíbélì. Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé sí Bẹ́tẹ́lì, mo béèrè lọ́wọ́ Arábìnrin Emma Hamilton, tó jẹ́ akàwéṣàtúnṣe, nípa iye ìgbà tí ó ti ka Bíbélì. Ó fèsì pé: “Lẹ́yìn tí mo kà á ní ìgbà márùndínlógójì ni mo ṣíwọ́ kíka iye ìgbà tó jẹ́.” Arákùnrin Anton Koerber, tóun náà jẹ́ akíkanjú Kristẹni, tó sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní àkókò kan náà, sábà máa ń sọ pé: “Máa rí i dájú pé Bíbélì wà ní àrọ́wọ́tó rẹ nígbà gbogbo.”

Lẹ́yìn ikú Arákùnrin Russell ní 1916, Arákùnrin Joseph F. Rutherford wá bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó iṣẹ́ náà. Rutherford jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńgájíá, lọ́yà tún ni, ó sì ti gba ọ̀pọ̀ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ikú Rutherford ní 1942 ni Arákùnrin Knorr rọ́pò rẹ̀, ó sì sapá gidigidi láti di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Níwọ̀n bí yàrá mi kò ti jìnnà sí tirẹ̀, mo máa ń gbọ́ nígbà tó bá ń múra àsọyé rẹ̀ sílẹ̀ léraléra. Nígbà tó ṣe, gbogbo ìsapá yẹn jẹ́ kó di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́.

Ní February 1942, Arákùnrin Knorr gbé ètò kan kalẹ̀ tí yóò ran gbogbo àwa arákùnrin tá a wà ní Bẹ́tẹ́lì lọ́wọ́ láti mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀rọ̀ sísọ wa sunwọ̀n sí i. Ilé ẹ̀kọ́ náà dá lórí ṣíṣèwádìí nípa Bíbélì àti sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, wọ́n máa ń ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àwọn èèyàn inú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ nípa Mósè ni wọ́n kọ́kọ́ yàn fún mi. Ní 1943, irú ilé ẹ̀kọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ nínú gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì wà títí di òní olónìí. Ọ̀ràn níní ìmọ̀ Bíbélì àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko ṣì ṣe pàtàkì ní Bẹ́tẹ́lì.

February 1943 ni kíláàsì àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì ti Gílíádì bẹ̀rẹ̀. Kíláàsì kọkànléláàádọ́fà [111] ló ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán yìí! Ó ti lé lọ́dún méjìdínlọ́gọ́ta tí ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ń bá a bọ̀, ó sì ti kọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje láti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì jákèjádò ayé. Ó yẹ fún àfiyèsí pé ní 1943 nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] kárí ayé. Àmọ́ iye àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà báyìí!

Mo Mọyì Ogún Tẹ̀mí Mi

Ní kété kí wọ́n tó dá ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀, wọ́n ní kí àwa mẹ́ta láti Bẹ́tẹ́lì lọ máa bẹ àwọn ìjọ wò jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. A máa ń lo ọjọ́ kan, tàbí ọjọ́ díẹ̀, tàbí ọ̀sẹ̀ kan pàápàá, ká lè fún ìjọ wọ̀nyí lókun nípa tẹ̀mí. Orúkọ tí wọ́n ń pè wá ni ìránṣẹ́ àwọn ará, orúkọ tá a wá yí padà sí ìránṣẹ́ àyíká, tàbí alábòójútó àyíká níkẹyìn. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n ní kí n padà sílé, kí n lọ máa kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ kan. Mo jẹ́ olùkọ́ alákòókò kíkún fún kíláàsì kejì sí ìkarùn-ún, mo sì delé de ọ̀kan lára àwọn tó jẹ́ olùkọ́ déédéé tó kọ́ kíláàsì kẹrìnlá. Àǹfààní tí mo ní láti ṣàlàyé àwọn ìgbòkègbodò mánigbàgbé tó wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn ètò àjọ Jèhófà lóde òní—ọ̀pọ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí ló kúkú ṣojú mi—jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì ogún tẹ̀mí ṣíṣeyebíye tí mo ní.

Àǹfààní mìíràn tí mo gbádùn jálẹ̀ ọdún wọ̀nyí ni lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn èèyàn Jèhófà. Ní 1963, mo rìnrìn àjò kárí ayé pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn mìíràn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú sí àwọn àpéjọpọ̀ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun.” Àwọn àpéjọpọ̀ mánigbàgbé mìíràn tí mo lọ ni àwọn tá a ṣe nílùú Warsaw, ní Poland, lọ́dún 1989; tìlú Berlin, ní Jámánì, lọ́dún 1990; àti tìlú Moscow, ní Rọ́ṣíà, lọ́dún 1993. Ní àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan, mo láǹfààní láti pàdé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n, tí wọ́n fara da ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún inúnibíni lábẹ́ ìjọba Násì, tàbí ìjọba Kọ́múníìsì, tàbí lábẹ́ àwọn ìjọba méjèèjì. Ìrírí wọ̀nyẹn mà fún ìgbàgbọ́ mi lókun o!

Ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lárinrin ní tòótọ́! Ńṣe làwọn ìbùkún tẹ̀mí kàn ń ya wọlé láìdáwọ́dúró. Láìdàbí dúkìá ti ara, bá a ṣe túbọ̀ ń ṣàjọpín ọrọ̀ ṣíṣeyebíye wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ náà ló túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń gbọ́ táwọn kan ń sọ pé ì bá wu àwọn kó máà jẹ́ pé inú ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti tọ́ wọn dàgbà. Wọ́n ní àwọn ì bá mọyì àwọn òtítọ́ Bíbélì ká ní àwọn ti kọ́kọ́ wà lóde ètò Ọlọ́run.

Ó máa ń bà mí nínú jẹ́ nígbà tí mo bá gbọ́ tí àwọn ọ̀dọ́ ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ohun tí ọ̀rọ̀ wọn túmọ̀ sí ní ti gidi ni pé kì í ṣe fífi ìmọ̀ Jèhófà tọ́ni dàgbà ni ohun tó dára jù lọ. Àmọ́, ronú nípa àwọn àṣàkaṣà àti èròkerò táwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nínú ìgbésí ayé wọn. Gbogbo ìgbà ni mo ń dúpẹ́, tí mo ń tún ọpẹ́ dá, pé àwọn òbí mi tọ́ àwa ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ọ̀nà òdodo. John dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà títí dọjọ́ ikú rẹ̀ ní July 1980, Esther sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ títí dòní.

Gbogbo ìgbà tí mo bá rántí àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tí mo ní láàárín àwọn Kristẹni olóòótọ́, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ni inú mi máa ń dùn ṣìnkìn. Mo ti lò ju ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] tó mìrìngìndìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbéyàwó rí, síbẹ̀ mo ní ọ̀pọ̀ ọmọ tẹ̀mí, àtàwọn ọmọ-ọmọ tẹ̀mí. Inú mi sì máa ń dùn nígbà tí mo bá ń ronú nípa gbogbo àwọn ẹni tuntun ọ̀wọ́n tí mi ò tíì bá pàdé rí nínú ìdílé wa tẹ̀mí kárí ayé, torí pé ẹni bí ẹni, èèyàn bí èèyàn làwọn náà. Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ náà pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un”!—Òwe 10:22.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a March 8, 1932 ni mo ṣèrìbọmi. Tó túmọ̀ sí pé ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n sọ pé ó yẹ kí n wọnú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Láti apá òsì sí ọ̀tún: bàbá mi tó gbé John àbúrò mi lẹ́sẹ̀, Esther, èmi àti màmá mi

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi rèé níbi tí mo ti ń kọ́ kíláàsì kan ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1945

Lókè lápá ọ̀tún: àwa olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì rèé, Eduardo Keller, Fred Franz, èmi àti Albert Schroeder

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Mo ti gbádùn ìgbésí ayé alárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà