Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dáàbò Bo Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Dáàbò Bo Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Dáàbò Bo Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

OHUN ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni kéèyàn wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tí ìsọfúnni tó wà nínú kọ̀ǹpútà tó ń darí rẹ̀ kò tọ̀nà. Àmọ́ nǹkan á tún wá burú jùyẹn lọ, bó bá jẹ́ pé ńṣe ni ẹnì kan lọ dabarú àwọn ìsọfúnni tó ń tọ́ ọkọ̀ náà sọ́nà, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe lonítọ̀hún lọ dìídì fi ìsọfúnni tí ń ṣini lọ́nà síbẹ̀! Tóò, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ohun tí ẹnì kan ń gbìyànjú láti ṣe sí ẹ̀rí ọkàn rẹ gan-an nìyẹn. Ẹni tá a ń wí yìí kò níṣẹ́ méjì ju pé kó dabarú àwọn ìlànà ìwà rere tó ń tọ́ ẹ sọ́nà. Ohun tó ń wá ni pé kó o forí gbárí pẹ̀lú Ọlọ́run!—Jóòbù 2:2-5; Jòhánù 8:44.

Ta ni onímàdàrú yìí? Bíbélì pè é ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Jagunlabí pitú ọwọ́ rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, ó lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí, ó mú kí Éfà dágunlá sí ohun tó mọ̀ pé ó tọ́, kí ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 16-19) Àtìgbà yẹn ni Sátánì ti wà nídìí gbígbé onírúurú àjọ kalẹ̀, tó jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe kò ju títan àwọn èèyàn lápapọ̀ jẹ, kí ó lè sọ wọ́n di ọ̀tá Ọlọ́run. Èyí tí ẹ̀bi rẹ̀ pọ̀ jù lọ nínú àjọ wọ̀nyí ni ẹ̀sìn èké.—2 Kọ́ríńtì 11:14, 15.

Ẹ̀sìn Èké Ń Pa Ẹ̀rí Ọkàn Kú

Nínú ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì, ohun tá a fi ṣàpẹẹrẹ ẹ̀sìn èké ni aṣẹ́wó kan tá a pè ní Bábílónì Ńlá. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìmọ̀kan ní ti ìwà rere, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n kórìíra, àní kí wọ́n tilẹ̀ hùwà ipá sáwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn. Ìwé Ìṣípayá tilẹ̀ sọ pé ẹ̀sìn èké máa jíhìn níwájú Ọlọ́run fún ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé,” títí kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ń sin Ọlọ́run.—Ìṣípayá 17:1-6; 18:3, 24.

Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ibi tí ẹ̀sìn èké yóò rìn jìnnà dé nínú ọ̀ràn dídabarú ìlànà ìwà rere táwọn kan ń tẹ̀ lé, nígbà tó sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run.” Ẹ ò rí i pé irú àwọn oníwà ipá bẹ́ẹ̀ kò ka ìwà burúkú sí nǹkan kan mọ́! Jésù sọ pé: “Wọn kò mọ Baba tàbí èmi.” (Jòhánù 16:2, 3) Láìpẹ́ sí àkókò tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan ṣekú pa òun alára. Ìwà ọ̀daràn tí wọ́n hù náà kò sì gbún ẹ̀rí ọkàn wọn ní kẹ́sẹ́ rárá. (Jòhánù 11:47-50) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, Jésù sọ pé ìfẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ bá ní láàárín ara wọn làwọn èèyàn ó fi dá wọn mọ̀. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ tiwọn tún gbòòrò jùyẹn lọ, torí pé ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá wọn pàápàá.—Mátíù 5:44-48; Jòhánù 13:35.

Ọ̀nà mìíràn tí ẹ̀sìn èké gbà ń pa ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kú ni nípa gbígbé gbogbo ohun tó bá sáà ti jẹ́ àṣà ìgbàlódé lárugẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ èyí tẹ́lẹ̀, nígbà tó wí pé: “Àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3.

Lóde òní, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń rin àwọn èèyàn létí nípa sísọ pé Ọlọ́run ò bínú sí níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Àwọn mìíràn sọ pé kò sóhun tó burú nínú bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Àní, ọ̀pọ̀ àlùfáà ló ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tá a ń pè ní The Times sọ pé “àlùfáà mẹ́tàlá tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀” ni wọ́n sọ di mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìjọ Áńgílíkà báyìí. Nígbà táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì bá pa ìlànà ìwà rere inú Bíbélì tì, tí ṣọ́ọ̀ṣì sì ń wò wọ́n níran, ìlànà wo làwọn ọmọ ìjọ wá fẹ́ tẹ̀ lé? Abájọ tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ò fi mọ èwo lèwo.

Ẹ ò rí i pé ó sàn láti jẹ́ kí àwọn òtítọ́ tẹ̀mí tó jẹ́ atọ́nà ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni máa ṣamọ̀nà wa! (Sáàmù 43:3; Jòhánù 17:17) Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì kọ́ni pé àwọn àgbèrè tàbí àwọn panṣágà ‘kò ní jogún ìjọba Ọlọ́run.’ (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ó sọ fún wa pé àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó “yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá padà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá . . . ń ṣe ohun ìbàjẹ́” lójú Ọlọ́run. (Róòmù 1:26, 27, 32) Òtítọ́ wọ̀nyí nípa ìwà rere kì í ṣe èyí tí àwọn ẹ̀dá aláìpé hùmọ̀; ìlànà tí Ọlọ́run mí sí ni, kò sì yí wọn padà rí. (Gálátíà 1:8; 2 Tímótì 3:16) Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà míì wà tí Sátánì gbà ń pa ẹ̀rí ọkàn kú.

Ṣọ́ra Nípa Irú Eré Ìnàjú Tí O Yàn

A mọ̀ pé kò dáa kí ẹnì kan jẹ́ kí wọ́n fagbára mú òun hùwà àìdáa. Àmọ́ ó tún wá burú jáì bí èèyàn bá jẹ́ kí wọ́n sọ òun dẹni tí irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń dá lọ́rùn. Ohun tí Sátánì, “olùṣàkóso ayé” yìí, sì ń wá gan-an nìyẹn. Kí ìrònú rẹ̀ tó kún fún ìwà ìbàjẹ́ lè kó èèràn ran èrò inú àti ọkàn àwọn òmùgọ̀ àti aláìfura—àgàgà àwọn ọ̀dọ́ tí ọwọ́ rẹ̀ lè tètè tẹ̀—ó máa ń lo àwọn nǹkan bí ìwé, sinimá, orin, àwọn eré orí kọ̀ǹpútà tí ń kọni lóminú, àtàwọn ibi tí wọ́n ń kó ohun tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Jòhánù 14:30; Éfésù 2:2.

Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Pediatrics sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ [ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà] ń wo nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìwà ipá lọ́dọọdún lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ètò tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọdé ló sì kún fún ìwà ipá jù lọ.” Ìròyìn náà tún sọ pé “àwọn ọ̀dọ́langba ń wo àwọn eré àti àwàdà àti ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ takọtabo tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] lọ́dọọdún.” Ó sọ pé kódà láàárín aago méje sí mọ́kànlá alẹ́, táwọn èèyàn ń ráyè jókòó ti tẹlifíṣọ̀n, “ó máa ń lé ní ìgbà mẹ́jọ tí wọ́n ń gbé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ jáde láàárín wákàtí kan. Èyí jẹ́ ìlọ́po mẹ́rin bó ṣe jẹ́ lọ́dún 1976.” Abájọ tí ìwádìí náà tún fi hàn pé “ọ̀rọ̀ rírùn túbọ̀ ń pọ̀ sí i pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n, Bíbélì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí tó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu, kìlọ̀ pé ńṣe ni fífetí sí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo ń ba ayé àwọn èèyàn jẹ́. Nítorí náà, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí, kí o sì ṣe ara rẹ láǹfààní, á dáa kí o kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 4:23, tó kà pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—Aísáyà 48:17.

Ọ̀pọ̀ orin ìgbàlódé ló ń sọ ẹ̀rí ọkàn dìdàkudà. Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ọsirélíà tá a ń pè ní The Sunday Mail sọ pé olórin kan táwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń gba tiẹ̀ gan-an “fẹ́ ṣe é débi pé kí orin òun máa mú kí ara àwọn èèyàn bù máṣọ.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé “ohun tí àwọn orin rẹ̀ ń gbé lárugẹ ni lílo oògùn olóró, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan àti ìfipábáni-lòpọ̀” àti pé ó “máa ń kọrin nípa pípa ìyàwó rẹ̀, kí ó sì gbé òkú rẹ̀ sọ sínú adágún.” Àwọn ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ míì tí wọ́n sọ pé ó kọ lórin kò tiẹ̀ ṣeé kọ sínú ìwé yìí. Síbẹ̀, orin rẹ̀ ti sọ ọ́ di gbajúgbajà òṣèré. Ǹjẹ́ wàá fẹ́ gbin irú èròkérò tá a mẹ́nu kàn lókè yìí sí èrò inú àti ọkàn rẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orin dídùn ló ń gbé e jáde? A lérò pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí àwọn tó bá ń gbin irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sọ́kàn ń pa ẹ̀rí ọkàn wọn kú ni. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọkàn wọn á di “ọkàn-àyà burúkú,” wọ́n á sì di ọ̀tá Ọlọ́run.—Hébérù 3:12; Mátíù 12:33-35.

Nítorí náà, ṣọ́ra nípa irú eré ìnàjú tí o yàn. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.

Ẹgbẹ́ Tí O Ń Kó Ń Nípa Lórí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Nígbà tí Neil àti Franz wà lọ́mọdé, wọ́n gbádùn ìfararora tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́. a Àmọ́, nígbà tó yá, Neil sọ pé, “Mo bẹ̀rẹ̀ sí kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́.” Ohun àbámọ̀ tó tìdí rẹ̀ yọ ni pé ó di ọ̀daràn, ó sì dèrò ẹ̀wọ̀n. Bákan náà lọ̀ràn Franz rí. Ó kédàárò pé: “Mo rò pé mo lè máa bá àwọn ọ̀dọ́ inú ayé rìn láìkọ́ ìṣe wọn. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Gálátíà 6:7 ti wí, ‘Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.’ Ojú mi já a kí n tó mọ̀ pé mo ti ṣìnà àti pé Jèhófà ló tọ̀nà. Inú ẹ̀wọ̀n gbére ni mo wà báyìí nítorí ìwà ọ̀daràn tí mo hù.”

Kì í ṣe ọ̀sán kan òru kan làwọn bíi Neil àti Franz di ọ̀daràn; irú wọn kì í kọ́kọ́ gbà pé àwọn lè di ọ̀daràn láé. Àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni imú ẹlẹ́dẹ̀ wọn ń wọgbà, bíi kí wọ́n tìdí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ bẹ̀rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Lẹ́yìn náà, wọ́n lè wá bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró, wọ́n á sì máa mu ọtí líle ní ìmukúmu. Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, àwọn kan pe ẹ̀rí ọkàn ní “apá kan àkópọ̀ ìwà wa tí ọtí líle máa ń sọ dìdàkudà.” Tí wọ́n bá ti tọwọ́ bọ irú nǹkan wọ̀nyí, wọn ò jìnnà sí ìwà ọ̀daràn tàbí ìṣekúṣe mọ́.

Ṣé ó yẹ kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ti kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́? Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, máa bá àwọn ọlọgbọ́n tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkànwá rìn. Wọ́n á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún ẹ̀rí ọkàn rẹ lókun, kí ó bàa lè tọ́ ọ sọ́nà tí ó tọ́, kí o lè bọ́ lọ́wọ́ oríṣiríṣi ẹ̀dùn ọkàn. (Òwe 13:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Neil àti Franz ṣì ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, wọ́n ti wá rí i báyìí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀rí ọkàn wọn, tó yẹ kí àwọn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bó ti tọ́ àti bó ti yẹ, àní ẹ̀bùn tó yẹ kí wọ́n fojú ribiribi wò. Láfikún sí i, wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ kára láti ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run wọn. Fi tiwọn ṣe àríkọ́gbọ́n.—Òwe 22:3.

Dáàbò Bo Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Ìgbà tá a bá gbé ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ró nínú Ọlọ́run, tá a sì ń bẹ̀rù rẹ̀ látọkànwá là ń fi hàn pé a fẹ́ dáàbò bo ẹ̀rí ọkàn wa. (Òwe 8:13; 1 Jòhánù 5:3) Bíbélì fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn tí kò bá ní ànímọ́ wọ̀nyí kì í sábàá ní ìlànà ìwà rere tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Sáàmù 14:1 sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ń sọ nínú ọkàn-àyà wọn pé: “Jèhófà kò sí.” Ipa wo ni àìnígbàgbọ́ yìí ní lórí ìwà wọn? Ẹsẹ náà fi kún un pé: “Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun, wọ́n ti hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí nínú ìbálò wọn.”

Àwọn èèyàn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ tọkàntọkàn kì í ní ìrètí gidi pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára. Fún ìdí yìí, wọn kì í ro ti ẹ̀yìnwá ọ̀la. Wọ́n sábà máa ń fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kẹ́ra wọn bà jẹ́. Ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé ni: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó gbájú mọ́ ẹ̀bùn ìyè ayérayé kì í jẹ́ kí afẹ́ ayé gbà wọ́n lọ́kàn. Bíi kọ̀ǹpútà tí ń júwe ọ̀nà ní tààrà ni ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń tọ́ wọn sọ́nà láti máa fi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí Ọlọ́run.—Fílípì 3:8.

Kí ẹ̀rí ọkàn rẹ má bàa pàdánù agbára tó ní àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́ déédéé, ó ń fẹ́ ìtọ́sọ́nà déédéé látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì sọ fún wa pé irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tó sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Fún ìdí yìí, ṣètò àkókò fún kíka Bíbélì lójoojúmọ́. Èyí á fún ọ lókun, á sì fún ọ níṣìírí bó o ṣe ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́ tàbí nígbà tí ìdààmú àti àníyàn bá dé bá ọ. Mọ̀ dájú pé Jèhófà yóò tọ́ ọ sí ọ̀nà ìwà rere àti ọ̀nà tẹ̀mí bó o bá gbára lé e pátápátá. Àní sẹ́, fìwà jọ onísáàmù náà tó kọ̀wé pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”—Sáàmù 16:8; 55:22.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọn padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀sìn èké tí Bíbélì pè ní “Bábílónì Ńlá” ti pa ẹ̀rí ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kú

[Credit Line]

Àlùfáà tí ń súre fún àwọn ọmọ ogun: Fọ́tò U.S. Army

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Wíwo ìwà ipá àti ìṣekúṣe yóò sọ ẹ̀rí ọkàn rẹ dìdàkudà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Rírí ìtọ́sọ́nà gbà déédéé látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò dáàbò bo ẹ̀rí ọkàn rẹ