Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Onípamọ́ra
Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Onípamọ́ra
“Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Ẹ́KÍSÓDÙ 34:6.
1, 2. (a) Àwọn wo ló jàǹfààní ìfaradà Jèhófà láyé ọjọ́un? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìpamọ́ra” túmọ̀ sí?
ÀWỌN èèyàn ọjọ́ Nóà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá Mósè rìn kọjá ní aginjù, àwọn Júù tó wà láyé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé—gbogbo wọn ni ipò wọn yàtọ̀ síra. Àmọ́ gbogbo wọn pátá ló jàǹfààní nínú ànímọ́ rere kan náà tí Jèhófà ní—ànímọ́ náà ni ìpamọ́ra. Ó tiẹ̀ túmọ̀ sí ìwàláàyè àwọn kan pàápàá. Ìpamọ́ra Jèhófà sì lè túmọ̀ sí ìwàláàyè tiwa pẹ̀lú.
2 Kí ni ìpamọ́ra? Ìgbà wo ni Jèhófà ń fi hàn, fún ìdí wo sì ni? “Ìpamọ́ra” ni a ti túmọ̀ sí “fífi sùúrù fara da ìwà àìtọ́ tá a hù síni tàbí ìmúnibínú, pa pọ̀ mọ́ níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìrètí ṣì wà pé àjọṣe tó bà jẹ́ ṣì ń bọ̀ wá dára.” Nítorí náà, ànímọ́ yìí ní ète kan nínú. Ó ń fi ire ẹni tó ń dá wàhálà náà sílẹ̀ sí ipò kìíní. Àmọ́ o, jíjẹ́ onípamọ́ra kò túmọ̀ sí gbígbójú fo ìwà àìtọ́ dá. Nígbà tí ohun tá a tìtorí ẹ̀ ń lo ìfaradà bá ti tẹ̀ wá lọ́wọ́, tàbí nígbà tí kò bá sí ìdí fún fífarada ipò kan mọ́, ìpamọ́ra parí iṣẹ́ rẹ̀ nìyẹn.
3. Kí ni ète ìpamọ́ra Jèhófà, kí sì ni ààlà rẹ̀?
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè ní ìpamọ́ra, síbẹ̀ Jèhófà ni ẹni tó fi àpẹẹrẹ ànímọ́ yìí hàn lọ́nà gíga jù lọ. Láti àwọn ọdún tí ẹ̀ṣẹ̀ ti ba àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn ènìyàn tó ṣẹ̀dá jẹ́ ni Ẹlẹ́dàá wa ti ń fi sùúrù fara dà á, ó sì ti pèsè ọ̀nà tí àwọn ènìyàn tó ronú pìwà dà fi lè mú àjọṣe wọn pẹ̀lú rẹ̀ sunwọ̀n sí i. (2 Pétérù 3:9; 1 Jòhánù 4:10) Àmọ́, nígbà tí ète tó fi ń lo ìpamọ́ra bá ti ní ìmúṣẹ, Ọlọ́run yóò wá gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, nípa mímú ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí wá sópin.—2 Pétérù 3:7.
Ó Bá Àwọn Ànímọ́ Títayọ Ti Ọlọ́run Mu
4. (a) Báwo la ṣe fi èrò tó jẹ mọ́ ìpamọ́ra hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni wòlíì Náhúmù ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà, kí sì ni èyí fi hàn nípa ìpamọ́ra Jèhófà?
4 Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, a fi èrò tó jẹ mọ́ ìpamọ́ra hàn nínú ọ̀rọ̀ Hébérù méjì tó túmọ̀ ní tààràtà sí “gígùn imú,” a sì túmọ̀ rẹ̀ sí “lílọ́ra láti bínú” nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. a Nígbà tí wòlíì Náhúmù ń sọ̀rọ̀ nípa ìpamọ́ra Ọlọ́run, ó ní: “Jèhófà ń lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára, láìsí àní-àní, Jèhófà kì yóò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹni.” (Náhúmù 1:3) Nítorí náà, ìpamọ́ra Jèhófà kì í ṣe àmì àìlera, kì í sì í ṣe èyí tí kò ní ààlà. Òkodoro òtítọ́ náà pé Ọlọ́run Olódùmarè ń lọ́ra láti bínú, tó sì tún ní agbára ńlá fi hàn pé ìpamọ́ra rẹ̀ jẹ́ nítorí ìkóra-ẹni-níjàánu fún ète kan. Ó lágbára láti fìyà jẹni, àmọ́ ó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ yàgò fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lójú ẹsẹ̀, kí ó lè fún ẹlẹ́ṣẹ̀ láǹfààní láti yí padà. (Ìsíkíẹ́lì 18:31, 32) Nítorí ìdí èyí, ìpamọ́ra Jèhófà jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ rẹ̀, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn nínú bó ṣe ń lo agbára rẹ̀.
5. Lọ́nà wo ni ìpamọ́ra Jèhófà fi bá ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu?
5 Ìpamọ́ra Jèhófà tún wà níbàámu pẹ̀lú àìṣègbè àti òdodo rẹ̀. Ó fi ara rẹ̀ han Mósè gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú [“onipamọra,” Bibeli Mimọ] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Mósè kọrin ìyìn sí Jèhófà pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, àánú Jèhófà, ìpamọ́ra rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀, àti ìdúróṣánṣán rẹ̀ ló para pọ̀ ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó bára mu rẹ́gí.
Ìpamọ́ra Jèhófà Ṣáájú Ìkún Omi
6. Kí ni arabaríbí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà jẹ́ onípamọ́ra sí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà?
6 Ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà ní Édẹ́nì ló ba àjọṣe àtàtà tó wà láàárín àwọn àti Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́ jẹ́ pátápátá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8-13, 23, 24) Ìyara-ẹni-nípa yìí kan àwọn àtọmọdọ́mọ wọn, tó jogún ẹ̀ṣẹ̀, àìpé, àti ikú. (Róòmù 5:17-19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ Jèhófà fàyè gbà wọ́n láti bímọ. Nígbà tó ṣe, ó fìfẹ́ pèsè ọ̀nà tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà lè gbà padà bá òun rẹ́. (Jòhánù 3:16, 36) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Mélòómélòó, nígbà náà, níwọ̀n bí a ti polongo wa ní olódodo nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ni a ó tipasẹ̀ rẹ̀ gbà wá là kúrò nínú ìrunú. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé, nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀, mélòómélòó, nísinsìnyí tí a ti mú wa padà rẹ́, ni a ó gbà wá là nípasẹ̀ ìyè rẹ̀.”—Róòmù 5:8-10.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìpamọ́ra hàn ṣáájú Ìkún Omi, kí sì nìdí tí ìparun tó dé bá ìran tó wà ṣáájú Ìkún Omi fi tọ́ sí i?
7 A rí ìpamọ́ra Jèhófà ní ọjọ́ Nóà. Ní ohun tó lé ní ọ̀rúndún kan ṣáájú Ìkún Omi, “Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́, nítorí pé gbogbo ẹlẹ́ran ara ti ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:12) Síbẹ̀, Jèhófà fi ìpamọ́ra rẹ̀ hàn sí ìran ènìyàn fún àkókò díẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀mí mi kò ní fi àkókò tí ó lọ kánrin gbé ìgbésẹ̀ sí ènìyàn nítorí pé ó jẹ́ ẹlẹ́ran ara pẹ̀lú. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́fà ọdún.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:3) Ọgọ́fà ọdún yìí fún Nóà láyè láti ní ìdílé—nígbà tó sì gbọ́ àṣẹ Ọlọ́run—ọgọ́fà ọdún kan náà yìí fún un láyè láti kan áàkì, kí ó sì kìlọ̀ nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀ fún àwọn tí wọ́n jọ ń gbáyé. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Sùúrù [ìyẹn ànímọ́ tó tan mọ́ ìpamọ́ra] Ọlọ́run ń dúró ní àwọn ọjọ́ Nóà, nígbà tí a ń kan ọkọ̀ áàkì lọ́wọ́, nínú èyí tí a gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20) Ní ti tòótọ́, àwọn tí wọn kì í ṣe mẹ́ńbà ìdílé Nóà ‘kò fiyè sí’ ìwàásù rẹ̀. (Mátíù 24:38, 39) Àmọ́ nípa mímú kí Nóà kan ọkọ̀ áàkì, kí ó sì sìn gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo” fún ẹ̀wádún bíi mélòó kan, Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fún àwọn tó gbáyé lọ́jọ́ Nóà láǹfààní tó pọ̀ tó láti ronú pìwà dà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn, kí wọ́n sì yí padà láti sìn Ín. (2 Pétérù 2:5; Hébérù 11:7) Ìparun tó dé bá ìran burúkú yẹn nígbẹ̀yìngbẹ́yín tọ́ sí i gan-an ni.
Ìpamọ́ra Tí Jèhófà Lò fún Ísírẹ́lì Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ
8. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ìpamọ́ra fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
8 Jèhófà lo ìpamọ́ra fún Ísírẹ́lì fún àkókò tó gùn ju ọgọ́fà ọdún lọ. Ṣàṣà ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò dán ìpamọ́ra Ọlọ́run wò débi gẹ́ẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún tí wọ́n fi jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré lẹ́yìn tí a fi iṣẹ́ ìyanu dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, tó fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Olùgbàlà wọn rárá. (Ẹ́kísódù 32:4; Sáàmù 106:21) Láàárín àwọn ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣàròyé nípa oúnjẹ tí Jèhófà fi iṣẹ́ ìyanu pèsè fún wọn nínú aṣálẹ̀, wọ́n kùn sí Mósè àti Áárónì, wọ́n sọ̀rọ̀ lòdì sí Jèhófà, wọ́n sì bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè; kódà wọ́n lọ́wọ́ sí ìjọsìn Báálì. (Númérì 11:4-6; 14:2-4; 21:5; 25:1-3; 1 Kọ́ríńtì 10:6-11) Kò sẹ́ni tó lè dá Jèhófà lẹ́bi bó bá pa àwọn ènìyàn rẹ̀ run pátápátá, ṣùgbọ́n ó lo ìpamọ́ra fún wọn.—Númérì 14:11-21.
9. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ Ọlọ́run onípamọ́ra ní àkókò Àwọn Onídàájọ́ àti nígbà tí wọ́n ń fi àwọn ọba jẹ?
9 Léraléra làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà ní àkókò Àwọn Onídàájọ́. Nígbà tí wọ́n bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì ké pè é fún ìrànlọ́wọ́, á lo ìpamọ́ra nípa gbígbé onídàájọ́ dìde láti dá wọn nídè. (Àwọn Onídàájọ́ 2:17, 18) Ní àkókò gígùn tí àwọn ọba fi jẹ lé wọn lórí, àwọn ọba díẹ̀ kéréje ló fi ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe hàn sí Jèhófà. Kódà lábẹ́ àwọn ọba tó jẹ́ olóòótọ́ pàápàá, àwọn ènìyàn náà máa ń yí ìsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí Jèhófà bá gbé àwọn wòlíì dìde láti kìlọ̀ fún wọn nítorí àìṣòótọ́ wọn, àwọn ènìyàn náà máa ń yàn láti fetí sí àwọn àlùfáà oníwà ìbàjẹ́ àti àwọn wòlíì èké. (Jeremáyà 5:31; 25:4-7) Àní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tòótọ́ ti Jèhófà, wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan lára wọn pàápàá. (2 Kíróníkà 24:20, 21; Ìṣe 7:51, 52) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ń bá a lọ láti máa lo ìpamọ́ra fún wọn.—2 Kíróníkà 36:15.
Ìpamọ́ra Jèhófà Kò Dópin
10. Ìgbà wo ni ìpamọ́ra Jèhófà dé ààlà rẹ̀?
10 Àmọ́ ṣá o, ìtàn fi hàn pé ìpamọ́ra Jèhófà ní ààlà. Ní ọdún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó fàyè gba àwọn ará Ásíríà láti gbàjọba lọ́wọ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, kí wọ́n sì kó àwọn olùgbé ibẹ̀ ní ìgbèkùn. (2 Àwọn Ọba 17:5, 6) Ó sì fàyè gba àwọn ará Bábílónì láti gbógun ti ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà, kí wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run ní 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.—2 Kíróníkà 36:16-19.
11. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ìpamọ́ra, kódà nígbà tó ń mú ìdájọ́ ṣẹ?
11 Àmọ́, Jèhófà kò gbàgbé àtilo ìpamọ́ra, kódà nígbà tó ń mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Ísírẹ́lì àti Júdà. Jèhófà tipasẹ̀ Jeremáyà wòlíì rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò àwọn àyànfẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú lílo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí yín, dájúdájú, èmi yóò fìdí ọ̀rọ̀ rere mi múlẹ̀ fún yín, láti mú yín padà wá sí ibí yìí. Dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ rí mi . . . Èmi yóò sì kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè yín jọ, èmi yóò sì kó yín jọpọ̀ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti láti inú gbogbo ibi tí mo ti fọ́n yín ká sí.”—Jeremáyà 29:10, 14.
12. Báwo ni pípadà tí àwọn ìyókù Júù kan padà sí Júdà ṣe jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún bíbọ̀ Mèsáyà?
12 Ìyókù lára àwọn Júù tá a kó nígbèkùn náà padà sí Júdà ní ti tòótọ́, wọ́n sì dá ìjọsìn Jèhófà padà sínú tẹ́ńpìlì tí wọ́n tún kọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Jèhófà bá ń mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, àwọn ìyókù wọ̀nyí ni yóò dà bí “ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” èyí tí ń mú ìtura àti aásìkí wá. Wọn yóò sì jẹ́ onígboyà àti alágbára bíi “kìnnìún láàárín àwọn ẹranko igbó.” (Míkà 5:7, 8) Gbólóhùn tó kẹ́yìn yìí ti ní láti nímùúṣẹ ní àkókò àwọn Mákábì, nígbà tí àwọn Júù tó wà lábẹ́ ìdílé àwọn Mákábì ń lé àwọn ọ̀tá wọn jáde kúrò ní Ilẹ̀ Ìlérí, tí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì tí wọ́n ti sọ di ẹlẹ́gbin náà yà sí mímọ́. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pa ilẹ̀ àti tẹ́ńpìlì náà mọ́, kí àwọn ìyókù mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ lè kí Ọmọ Ọlọ́run káàbọ̀ nígbà tó bá fara hàn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà.—Dáníẹ́lì 9:25; Lúùkù 1:13-17, 67-79; 3:15, 21, 22.
13. Kódà lẹ́yìn táwọn Júù ti pa Ọmọ rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe ń bá a lọ láti lo ìpamọ́ra fún wọn?
13 Kódà lẹ́yìn táwọn Júù pa Ọmọ rẹ̀, Jèhófà ṣì ń bá a lọ láti lo ìpamọ́ra fún wọn fún ọdún mẹ́ta ààbọ̀, tó fi fún wọn láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti dídi ẹni tá a pè láti di ara irú-ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí. (Dáníẹ́lì 9:27) b Ṣáájú àti lẹ́yìn ọdún 36 Sànmánì Tiwa ni àwọn Júù kan ti dáhùn sí ìpè náà, ó sì rí gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe wá sọ ọ́ lẹ́yìn náà pé, “àṣẹ́kù kékeré ti fara hàn ní ìbámu pẹ̀lú yíyàn nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.”—Róòmù 11:5.
14. (a) Àwọn wo la nawọ́ àǹfààní dídi apá kan irú ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí sí ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe sọ bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà yan àwọn mẹ́ńbà Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣe rí lára òun?
14 Ọdún 36 Sànmánì Tiwa ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a nawọ́ àǹfààní dídi apá kan irú ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí sí àwọn tí kì í ṣe Júù, tí wọn kì í sì í ṣe aláwọ̀ṣe. Ẹnikẹ́ni tó tẹ́wọ́ gbà á ló sì jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìpamọ́ra Jèhófà. (Gálátíà 3:26-29; Éfésù 2:4-7) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fi ìmọrírì hàn fún ọgbọ́n àti ète ìpamọ́ra aláàánú tí Jèhófà lò láti mú kí àpapọ̀ àwọn tá a pè láti jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí pé iye wọn, ó polongo pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!”—Róòmù 11:25, 26, 33; Gálátíà 6:15, 16.
Ìpamọ́ra Nítorí Orúkọ Rẹ̀
15. Kí ni olórí ìdí tí Ọlọ́run fi ń lo ìpamọ́ra, ọ̀ràn wo la sì nílò àkókò láti yanjú?
15 Kí nìdí tí Jèhófà fi ń lo ìpamọ́ra? Ní pàtàkì jù lọ, ó jẹ́ láti gbé orúkọ mímọ́ rẹ̀ lárugẹ àti láti dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. (1 Sámúẹ́lì 12:20-22) Ọ̀ràn tí Sátánì gbé dìde nípa bóyá ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń lo ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀ tọ́ nílò àkókò kó tó lè yanjú pátápátá lójú gbogbo ìṣẹ̀dá. (Jóòbù 1:9-11; 42:2, 5, 6) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ń ni àwọn ènìyàn Jèhófà lára ní Íjíbítì, ó sọ fún Fáráò pé: “Fún ìdí yìí ni mo ṣe mú kí o máa wà nìṣó, nítorí àtifi agbára mi hàn ọ́ àti nítorí kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Ẹ́kísódù 9:16.
16. (a) Báwo ni ìpamọ́ra Jèhófà ṣe mú kó ṣeé ṣe láti ṣètò àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀? (b) Báwo ni orúkọ Jèhófà yóò ṣe di èyí tá a yà sí mímọ́, tí a ó sì dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre?
16 A ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ sí Fáráò nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ipa tí ìpamọ́ra Ọlọ́run ní lórí ṣíṣe orúkọ mímọ́ rẹ̀ lógo. Pọ́ọ̀lù wá kọ̀wé pé: “Wàyí o, bí Ọlọ́run, bí ó tilẹ̀ ní ìfẹ́ láti fi ìrunú rẹ̀ hàn gbangba, kí ó sì sọ agbára rẹ̀ di mímọ̀, bá fi ọ̀pọ̀ ìpamọ́ra fàyè gba àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun, kí ó bàa lè sọ àwọn ọrọ̀ ògo rẹ̀ di mímọ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tí ó pèsè sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ògo, èyíinì ni, àwa, tí ó pè kì í ṣe láti àárín àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, ìyẹn ńkọ́? Ó rí bí ó ti sọ pẹ̀lú nínú Hóséà pé: ‘Àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi ni èmi yóò pè ní “àwọn ènìyàn mi.”’” (Róòmù 9:17, 22-25) Nítorí pé Jèhófà lo ìpamọ́ra, ó ṣeé ṣe fún un láti mú “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 15:14) Lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, tó jẹ́ Orí wọn ni “àwọn ẹni mímọ́” wọ̀nyí ti jẹ́ ajogún Ìjọba tí Jèhófà yóò lò láti sọ orúkọ ńlá Rẹ̀ di mímọ́ àti láti dá ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀ láre.—Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14, 27; Ìṣípayá 4:9-11; 5:9, 10.
Ìpamọ́ra Jèhófà Ń Ṣiṣẹ́ fún Ìgbàlà
17, 18. (a) Nípa ṣíṣe kí ni, la fi lè máa dá Jèhófà lẹ́bi láìmọ̀ nítorí ìpamọ́ra rẹ̀? (b) Irú ojú wo la rọ̀ wá pé ká máa fi wo ìpamọ́ra Jèhófà?
17 Látìgbà tí ìran ènìyàn ti ṣubú yakata sínú ẹ̀ṣẹ̀ títí di ìsinsìnyí ni Jèhófà ti ń fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run onípamọ́ra. Ìpamọ́ra rẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi fi àkókò tí ó tó sílẹ̀ láti kìlọ̀ àti láti kan ọkọ̀ ìgbàlà. Àmọ́ nígbà tí sùúrù rẹ̀ dé ojú ààlà, Ìkún Omi náà dé. Bákan náà ni lónìí, Jèhófà ń fi ìpamọ́ra tó ga hàn, èyí sì ti wà fún ìgbà pípẹ́ ju bí ọ̀pọ̀ ṣe retí lọ. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn kì í ṣe ìdí fún wa láti juwọ́ sílẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀ sí pé a ń dá Ọlọ́run lẹ́bi fún jíjẹ́ tó jẹ́ onípamọ́ra. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Tàbí ìwọ tẹ́ńbẹ́lú ọrọ̀ inú rere àti ìmúmọ́ra àti ìpamọ́ra rẹ̀, nítorí ìwọ kò mọ̀ pé ànímọ́ onínúrere Ọlọ́run ń gbìyànjú láti ṣamọ̀nà rẹ sí ìrònúpìwàdà?”—Róòmù 2:4.
18 Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè mọ bí a ṣe nílò ìpamọ́ra Ọlọ́run tó, kí ó tó lè dá wa lójú pé ó ti kà wá mọ́ àwọn tí yóò rí ìgbàlà. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká “máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà [wa] yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (Fílípì 2:12) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9.
19. Ọ̀nà wo la lè gbà lo àǹfààní ìpamọ́ra Jèhófà?
19 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a kánjú ju Jèhófà. Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pétérù gbà wá, ká sì máa “ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” Ìgbàlà ta ni? Ìgbàlà tiwa ni, àti ti àìmọye àwọn mìíràn tí wọ́n ṣì ní láti gbọ́ “ìhìn rere ìjọba” náà. (2 Pétérù 3:15; Mátíù 24:14) Èyí yóò jẹ́ ká mọrírì bí ìpamọ́ra Jèhófà ti pọ̀ tó, yóò sì sún wa láti máa lo ìpamọ́ra nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ tá a lò fún “imú” tàbí “ihò imú” (ʼaph) la sábà máa ń lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún ìbínú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí bí ẹni tó ń bínú ṣe máa ń mí lákọlákọ tàbí lódìlódì.
b Fún àlàyé síwájú sí i lórí àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, ojú ìwé 191 sí 194, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìpamọ́ra” túmọ̀ sí nínú Bíbélì?
• Báwo ni Jèhófà ṣe lo ìpamọ́ra ṣáájú Ìkún Omi, lẹ́yìn ìgbèkùn Bábílónì àti ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
• Kí làwọn ìdí pàtàkì tó mú kí Jèhófà lo ìpamọ́ra?
• Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìpamọ́ra Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìpamọ́ra Jèhófà ṣáájú Ìkún Omi fún àwọn èèyàn láǹfààní tí ó tó láti ronú pìwà dà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lẹ́yìn ìṣubú Bábílónì, àwọn Júù jàǹfààní látinú ìpamọ́ra Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù ló jàǹfààní ìpamọ́ra Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn Kristẹni òde òní ń lo àǹfààní ìpamọ́ra Jèhófà dáadáa