Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi

Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi

Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi

ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa Nóà rí, ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì kan ọkọ̀ áàkì láti gba ẹ̀mí là nígbà ìkún omi tó kárí ayé? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn àtayébáyé ni, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló mọ ìtàn náà bí ẹní mowó. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ ò wá mọ̀ ni pé ìgbésí ayé Nóà nítumọ̀ fún gbogbo wa.

Èé ṣe tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn? Ǹjẹ́ a rí ohun tí ipò Nóà fi bá tiwa dọ́gba? Tó bá wà, báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ rẹ̀?

Ayé Ọjọ́ Nóà

Ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọdún 2970 ṣááju Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí Nóà—ìyẹn ọdún mẹ́rìndínláàádóje [126] lẹ́yìn ikú Ádámù. Ní ọjọ́ Nóà, ayé kún fún ìwà ipá, èyí tó sì pọ̀ jù lọ nínú àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ló yàn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà àìgbọràn baba ńlá wọn. Nítorí náà, “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 11, 12.

Kì í ṣe ìṣọ̀tẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn nìkan ló bí Jèhófà nínú. Ìtàn ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn. . . . Àwọn Néfílímù sì wà ní ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ wọnnì, àti lẹ́yìn ìyẹn pẹ̀lú, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, tí wọ́n sì bí ọmọkùnrin fún wọn, àwọn ni alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé, àwọn ọkùnrin olókìkí.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:2-4) Tá a bá fi àwọn ẹsẹ wọ̀nyí wéra pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sílẹ̀, a óò rí i pé àwọn áńgẹ́lì tó ṣàìgbọràn la pè ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́.” Àwọn Néfílímù ni àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tí wọ́n bí látinú ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu láàárín àwọn obìnrin ènìyàn àtàwọn áńgẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n sọ ara wọn di ènìyàn.—1 Pétérù 3:19, 20.

“Néfílímù,” tó túmọ̀ sí “Abiniṣubú,” dúró fún àwọn tó ń jẹ́ káwọn ẹlòmíràn ṣubú. Òṣìkà abúmọ́ni ni wọ́n, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn oníṣekúṣe la sì fi wé ìbálòpọ̀ táwọn èèyàn gbé gbòdì ní Sódómù àti Gòmórà. (Júúdà 6, 7) Lápapọ̀, wọ́n dá ìwà ibi tí kò ṣeé fẹnu sọ sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

“Aláìlẹ́bi Láàárín Àwọn Alájọgbáyé Rẹ̀”

Ìwà ibi gbòde kan débi pé Ọlọ́run pinnu àtipa ìran ènìyàn run. Àmọ́, àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Nóà rí ojú rere ní ojú Jèhófà. . . . Nóà jẹ́ olódodo. Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:8, 9) Báwo ló ṣe ṣeé ṣe láti ‘bá Ọlọ́run rìn’ nínú ayé aláìwà bí Ọlọ́run tó yẹ fún ìparun?

Láìsí àní-àní, Nóà kọ́ ohun púpọ̀ lọ́dọ̀ Lámékì, baba rẹ̀, ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́, tó gbé ayé nígbà tí Ádámù ṣì wà láyé. Nígbà tí Lámékì ń sọ ọmọ rẹ̀ ní Nóà (tá a gbà pé ó túmọ̀ sí “Ìsinmi,” tàbí “Ìtùnú”), ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹni yìí ni yóò mú ìtùnú wá fún wa nínú iṣẹ́ wa àti nínú ìrora ọwọ́ wa tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn nímùúṣẹ nígbà tí Ọlọ́run mú ègún tó fi ilẹ̀ gún kúrò.—Jẹ́nẹ́sísì 5:29; 8:21.

Níní àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ yóò jẹ́ ẹni tẹ̀mí, nítorí pé olúkúlùkù ló gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Nóà ‘bá Ọlọ́run rin’ nípa rírìn ní ọ̀nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ohun tí Nóà kọ́ nípa Ọlọ́run sún un láti sìn Ín. Ìgbàgbọ́ Nóà kò yẹ̀ nígbà tó gbọ́ nípa ète Ọlọ́run ‘láti run gbogbo ẹran ara nínú àkúnya omi náà.’—Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 17.

Pẹ̀lú ìdánilójú pé jàǹbá tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí yìí yóò wáyé, Nóà ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà tó sọ pé: “Fi igi ṣe áàkì kan fún ara rẹ láti ara igi olóje. Ìwọ yóò ṣe àwọn ojúlé sínú áàkì náà, kí o sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì bò ó ní inú àti ní òde.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Kíkan ọkọ áàkì náà bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ó rí kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá. Síbẹ̀síbẹ̀, “Nóà . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un.” Àní, “ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:22) Nóà ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn Ṣémù, Hámù, àti Jáfẹ́tì àtàwọn aya wọn. Jèhófà bù kún irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún àwọn ìdílé lónìí!

Kí ni yóò wé mọ́ kíkan áàkì náà? Jèhófà sọ fún Nóà pé kí ó kan ọkọ̀ onígi ràgàjì kan, tó jẹ́ alájà mẹ́ta, tí omi kò lè wọnú rẹ̀, tó gùn ní nǹkan bíi mítà mẹ́tàléláàádóje [133], tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mítà méjìlélógún [22], tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà mẹ́tàlá. (Jẹ́nẹ́sísì 6:15, 16) Irú ọkọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní ṣàì tó onírúurú àwọn ọkọ̀ òkun tá a fi ń kẹ́rù lóde òní.

Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí! Àfàìmọ̀ ni iṣẹ́ náà kò fi ní gba bíbẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún igi lulẹ̀, gbígbé wọn lọ síbi tí wọ́n ti ń kan ọkọ̀ náà, àti gígé wọn sí pákó. Ó túmọ̀ sí pé wọ́n ní láti ṣe àtẹ̀gùn onígi, kí wọ́n fi igi ṣe ìṣó tàbí èèkàn, kí wọ́n sì wá ọ̀dà tí wọ́n máa fi bo ọkọ̀ náà kí omi má bàa wọnú rẹ̀, wọ́n tún nílò àwọn ohun tí wọn óò máa fi kẹ́rù, àtàwọn ohun èlò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ náà wé mọ́ bíbá àwọn oníṣòwò dúnàádúrà àti sísan owó ẹrù àti owó iṣẹ́. Ó dájú pé iṣẹ́ náà yóò gba kéèyàn mọṣẹ́ káfíńtà dáadáa kó lè mọ ibi tí ó tọ́ láti fi pákó kọ̀ọ̀kan sí, kí ọkọ̀ náà lè dúró dáadáa. Kẹ́ ẹ sì tún wò ó o, kíkan ọkọ̀ náà lè gbà tó nǹkan bí àádọ́ta sí ọgọ́ta ọdún kí wọ́n tó parí rẹ̀ o!

Lẹ́yìn ìyẹn, Nóà tún ní láti wá bí òun ṣe máa kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ èèyàn àti ti ẹranko jọ. (Jẹ́nẹ́sísì 6:21) Ó tún ní láti kó àwọn ẹranko jọ, kí ó sì kó wọn lọ sínú áàkì náà. Nóà ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un, ó sì parí iṣẹ́ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22) Ó dájú pé ìbùkún Jèhófà ló mú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.

“Oníwàásù Òdodo”

Yàtọ̀ sí kíkan áàkì, Nóà kìlọ̀, ó sì fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo.” Àmọ́ àwọn ènìyàn náà “kò . . . fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—2 Pétérù 2:5; Mátíù 24:38, 39.

Tá a bá sì tún ronú nípa bí wọn ò ṣe ka nǹkan tẹ̀mí sí láyé ìgbà yẹn, kò ní ṣòro fún wa láti lóye ohun tójú Nóà àti ìdílé rẹ̀ yóò ti rí nígbà táwọn aládùúgbò wọn tí kò fẹ́ gbọ́ bá ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń bú wọn, tí wọ́n sì ń yọ ṣùtì sí wọn. Àwọn èèyàn á tiẹ̀ máa rò pé ńṣe ni orí wọn dà rú. Bó ti wù kó rí, Nóà kẹ́sẹ járí nínú fífún agbo ilé rẹ̀ ní ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn nípa tẹ̀mí, nítorí pé wọn ò fìgbà kan lọ́wọ́ nínú ìwà ipá, ìṣekúṣe àti ìwà ọ̀tẹ̀ tí àwọn aláìwà bí Ọlọ́run tí wọ́n jọ gbé ayé nígbà yẹn ń hù. Nóà dá ayé ìgbà yẹn lẹ́bi nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́.—Hébérù 11:7.

Wọ́n La Ìkún Omi Náà Já

Nígbà tó ku díẹ̀ kí òjò náà bẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kí ó wọ inú áàkì náà. Nígbà tí ìdílé Nóà àtàwọn ẹranko náà wọnú ọkọ̀ tán, “Jèhófà ti ilẹ̀kùn,” ó sì ti àwọn afiniṣẹ̀sín wọ̀nyẹn mọ́ta. Nígbà tí Ìkún Omi náà dé, ó dájú pé àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyẹn bọ́ ẹran ara silẹ̀, wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìparun. Àmọ́, àwọn tó kù ńkọ́? Àní, gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ní òde áàkì náà ló ṣègbé, títí kan àwọn Néfílímù wọ̀nyẹn! Kìkì Nóà àti ìdílé rẹ̀ ló là á já.—Jẹ́nẹ́sísì 7:1-23.

Nóà àti agbo ilé rẹ̀ lo odindi ọdún kan tá a ń fi òṣùpá kà àti ọjọ́ mẹ́wàá gbáko nínú áàkì náà. Ńṣe ni ọwọ́ wọn dí fún iṣẹ́ bí wọ́n ti ń fún àwọn ẹranko lóúnjẹ àti omi, tí wọ́n ń da ìgbẹ́ wọn nù, tí wọ́n sì ń kíyè sí àkókò. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọjọ́ tí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wé mọ́ Ìkún Omi náà ṣẹlẹ̀, ńṣe ló dà bíi kúlẹ̀kúlẹ̀ àkọsílẹ̀ ìrìn àjò ọkọ̀ òkun, èyí tó fi hàn pe òótọ́ pọ́ńbélé ni ìtàn náà.—Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 17, 24; 8:3-14.

Ó dájú pé Nóà ti ní láti máa bá ìdílé rẹ̀ jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí kí wọ́n sì máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ní àkókò tí wọ́n fi wà nínú áàkì yẹn. Ó hàn gbangba pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ ló jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí ṣáájú Ìkún Omi. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tó ṣeé gbára lé tàbí èyí tó wà lákọsílẹ̀ tí wọ́n ní lọ́wọ́ ti ní láti jẹ́ ohun pàtàkì tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò ní àkókò Àkúnya Omi náà.

Ẹ wo bí inú Nóà àti ìdílé rẹ̀ ti ní láti dùn tó nígbà tí wọ́n tún padà fẹsẹ̀ tẹ ilẹ̀ gbígbẹ! Ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pé ó tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún ìdílé rẹ̀ nípa rírú ẹbọ sí Ẹni tó gbà wọ́n là.—Jẹ́nẹ́sísì 8:18-20.

“Gan-an Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ọjọ́ Nóà Ti Rí”

Jésù Kristi sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37) Báwọn Kristẹni òde òní náà ṣe jẹ́ oníwàásù òdodo nìyẹn, tí wọ́n ń rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n ronú pìwà dà. (2 Pétérù 3:5-9) Nítorí ìfiwéra yìí, a lè wá máa ṣe kàyéfì nípa ohun tí Nóà ní láti máa rò lọ́kàn ṣáájú Àkúnya Omi náà. Ǹjẹ́ ó fìgbà kan ronú pé asán ni iṣẹ́ ìwàásù tí òun ń ṣe? Ǹjẹ́ ó máa ń sú u lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Bíbélì kò sọ. Ohun tá a kàn gbọ́ ni pé Nóà ṣègbọràn sí Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ o rí ohun tí ipò Nóà fi bá tiwa mu? Ó ṣègbọràn sí Jèhófà láìfi àtakò àti ìṣòro pè. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pè é ní olódodo. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Nóà kò mọ àkókò pàtó tí Ọlọ́run yóò mú Àkúnya Omi náà dé, àmọ́ wọn mọ̀ pé yóò dé. Ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí Nóà fara da gbogbo ọdún tó fi ṣe iṣẹ́ àṣekára yẹn àti èyí tó fi ṣe ohun tá a lè pè ní iṣẹ́ ìwàásù tí kò méso jáde. Àní, a sọ fún wa pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀; àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí, ó dá ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́.”—Hébérù 11:7.

Báwo ni Nóà ṣe ní irú ìgbàgbọ́ yẹn? Ó dájú pé ó lo àkókò láti ronú lórí gbogbo ohun tó mọ̀ nípa Jèhófà, ó sì jẹ́ kí ìmọ̀ yẹn darí òun. Láìsí àní-àní, Nóà bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ní ti tòótọ́, ó wá mọ Jèhófà débi pé ó ‘bá Ọlọ́run rìn.’ Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, tayọ̀tayọ̀ ni Nóà fi ń lo àkókò pẹ̀lú agbo ilé rẹ̀, tó sì ń fún wọn ní àfiyèsí onífẹ̀ẹ́. Èyí kan bíbójútó ire tẹ̀mí aya rẹ̀, ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àti tàwọn aya ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú.

Bíi ti Nóà, àwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní mọ̀ pé Jèhófà yóò mú ètò àwọn nǹkan tí kò fi ti Ọlọ́run ṣe yìí wá sópin láìpẹ́. A ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí yẹn o, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé tá a bá fara wé ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn “oníwàásù òdodo” yìí, yóò yọrí sí “pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Hébérù 10:36-39.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àtinú gbogbo ẹ̀yà àti èdè làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn ti kó nǹkan bí igba ó lé àádọ́rin [270] ìtàn àtẹnudẹ́nu nípa ìkún omi jọ. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Claus Westermann, sọ pé: “Jákèjádò ayé la ti rí ìtàn ìkún omi. Bíi ti ìtàn ìṣẹ̀dá, ìtàn ìkún omi jẹ́ ara ohun tá a jogún bá. Ó yani lẹ́nu gan-an pé: ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé la ti ń gbọ́ ìtàn nípa ìkún omi ńlá àtayébáyé kan.” Kí ni àlàyé wọn? Alálàyé náà, Enrico Galbiati sọ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń gbọ́ ìtàn nípa ìkún omi látọ̀dọ̀ onírúurú ènìyàn tí ibùgbé wọ́n jìnnà síra gan-an jẹ́ àmì pé òtítọ́ ni irú ìtàn bẹ́ẹ̀.” Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí ohun táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ, ohun tó ṣe pàtàkì jù sáwọn Kristẹni ni mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé Jésù alára sọ̀rọ̀ nípa Ìkún Omi náà gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi kan nínú ìtàn ìran ènìyàn.—Lúùkù 17:26, 27.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn Néfílímù Nínú Ìtàn Ìwáṣẹ̀ Kẹ̀?

Àwọn ìtàn nípa ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu láàárín àwọn ọlọ́run àtàwọn èèyàn—àti ti “àwọn akọni” tàbí “ẹbọra” tí wọ́n bí látinú ìbálòpọ̀ yìí—pọ̀ lọ jàra nínú ìgbàgbọ́ àwọn Gíríìkì, àwọn ará Íjíbítì, àwọn tó ń sọ èdè Ugaritic, àwọn Hurrian, àtàwọn ará Mesopotámíà. Àwọn ọlọ́run inú ìtàn ìwáṣẹ̀ Gíríìkì ní ìrísí ènìyàn, wọ́n sì lẹ́wà gan-an. Wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n sùn, wọ́n ní ìbálòpọ̀, wọ́n ṣaáwọ̀, wọ́n jà, wọ́n súnni dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì fipá báni lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pe ara wọn ní ẹni mímọ́, síbẹ̀ wọ́n ń tanni jẹ, wọ́n sì ń hu ìwà ọ̀daràn. Ní ti àwọn akọni bí Achilles, wọ́n ní bí wọ́n ṣe jẹ́ ará ọ̀run ni wọ́n tún jẹ́ ará ayé, wọ́n sì ní agbára tó ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ, àmọ́ ẹni kíkú ni wọ́n. Nítorí náà, ohun tí Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Néfílímù jẹ́ ká lóye ibi tó ṣeé ṣe kí irú àwọn ìtàn àròsọ bẹ́ẹ̀ ti pilẹ̀.