Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìpàdé Di Inú Ìjọba Ọlọ́run”

“Ìpàdé Di Inú Ìjọba Ọlọ́run”

“Ìpàdé Di Inú Ìjọba Ọlọ́run”

“Rupert, Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n! Wọ́n ti dájọ́ ikú fún mi lónìí o. Àmọ́ má ṣọ̀fọ̀ mi o. Mo fẹ́ràn rẹ, mo sì fẹ́ràn gbogbo aráalé. Ìpàdé di inú Ìjọba Ọlọ́run.”

JUNE 8, 1942, ni Franc Drozg kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ ogun Násì yìnbọn pa á. Kí nìdí tí wọ́n fi pa á?

A rí i kà nínú àwọn àkọsílẹ̀ tí ń bẹ nínú Museum of National Liberation nílùú Maribor, lórílẹ̀-èdè Slovenia, pé alágbẹ̀dẹ lẹni ọdún méjìdínlógójì yìí. Ńṣe ló kọ̀ láti wọ ẹgbẹ́ ogun Jámánì tí wọ́n ń pè ní Wehrmannschaft, tí ń bẹ ní Slovenia nígbà tí Jámánì sàga ti orílẹ̀-èdè náà. Ọkùnrin yìí jẹ́ Bibelforscher, èyíinì ni Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn lorúkọ tá a ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè náà nígbà yẹn. Nítorí ohun tó wà nínú ìwé Aísáyà 2:4, ó kọ̀ láti wọ ẹgbẹ́ ogun ìjọba Násì, ó kéde pé ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lòun.—Mátíù 6:33.

Ní ìlú Ptuj níbi tí wọ́n ti bí Franc, àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí ẹni tó ń fi taratara pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọgbọ rárá, ó ń wàásù ìhìn rere náà nìṣó láìfọ̀tápè, títí wọ́n fi mú un ní May 1942.

Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Slovenia ni ìjọba Násì ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí. Franc jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pa nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ohun tó fún un lókun ni ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 14:22) Ó dá a lójú pé ìjọba ọ̀run yẹn yóò dé, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ̀rọ̀ ìdágbére náà pé, “Ìpàdé di inú Ìjọba Ọlọ́run.”

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Franc Drozg: Fọ́tò Archive-Museum of National Liberation Maribor, Slovenia; lẹ́tà: Èyí tó fọwọ́ ara rẹ̀ kọ gan-an wà ní Museum of National Liberation Maribor, Slovenia