Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀
Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
Ó GBA ọdún méjìlá, oṣù mẹ́ta, àti ọjọ́ mọ́kànlá iṣẹ́ àfẹ̀sọ̀ṣe. Àmọ́, ní March 13, 1960, a parí abala tó kẹ́yìn nínú ìtumọ̀ Bíbélì tuntun náà. A pè é ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Ọdún kan lẹ́yìn náà ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìtumọ̀ yìí jáde ní ìdìpọ̀ kan ṣoṣo. Àádọ́ta ọ̀kẹ́ la tẹ̀ jáde lára ẹ̀dà ti 1961 yẹn. Lónìí, iye ẹ̀dà tá a ti tẹ̀ jáde ti lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù, tó mú kí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà Bíbélì tá a pín kiri jù lọ. Àmọ́, kí ló sún àwa Ẹlẹ́rìí láti ṣe ìtumọ̀ yìí?
Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Ìtumọ̀ Bíbélì Tuntun?
Nítorí àtilóye ìhìn inú Ìwé Mímọ́ kí a sì polongo rẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí dára láyè ara wọn, síbẹ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn àti àwọn ìgbàgbọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù sábà máa ń nípa lórí wọn. (Mátíù 15:6) Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá fi rí i pé ó yẹ kí ìtumọ̀ Bíbélì kan wà tó gbé gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ìwé onímìísí ìpilẹ̀ṣẹ̀ yọ lọ́nà tó péye.
Ìgbà àkọ́kọ́ tá a gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe èyí ni October 1946, nígbà tí Nathan H. Knorr, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, dábàá mímú ìtumọ̀ Bíbélì tuntun kan jáde. Ní December 2, 1947, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ìtumọ̀ tó máa bá ohun tó wà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu wẹ́kú, tó máa ní àwọn ìsọfúnni táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ látinú àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ tí wọ́n ṣàwárí lákọ̀tun nínú, tó sì máa lo èdè tó yé àwọn òǹkàwé òde òní dáadáa.
Nígbà tí wọ́n mú apá tí wọ́n kọ́kọ́ parí—ìyẹn Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun— jáde ní 1950, ó wá hàn gbangba pé àwọn atúmọ̀ èdè ti mú àwọn ète wọn ṣẹ. Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lóye tẹ́lẹ̀ wá di ohun tó ṣe kedere sí wọn. Fún àpẹẹrẹ, gbé ẹsẹ tó ń ṣeni ní kàyéfì nínú Mátíù 5:3 yẹ̀ wò, èyí tó sọ pé: “Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmi.” (Bibeli Mimọ) Tó wá di: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” Ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé “Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata. (Bibeli Mimọ) ni a tú sí: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ni sí Olúwa, kí ó di ẹni ègún. Ìwọ Olúwa wa, máa bọ̀!” (1 Kọ́ríńtì 16:22) Ó hàn gbangba pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lani lóye lákọ̀tun.
Ó wú ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lórí. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Alexander Thomson sọ pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ta yọ nínú bó ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a ń lò fún ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Fún Éfésù 5:25 kà pé “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín” dípò sísọ ọ́ ní ṣákálá pé “Ẹyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin.” (Bibeli Mimọ) Thomson sọ nípa Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pé: “Kò jọ pé ẹ̀dà Bíbélì mìíràn wà tó pe àfiyèsí sí apá pàtàkì yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti délẹ̀délẹ̀.”
àpẹẹrẹ:Apá mìíràn tó tún ta yọ nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni pé ó lo Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nínú apá tó jẹ́ ti Hébérù àti èyí tó jẹ́ ti Gíríìkì nínú Ìwé Mímọ́. Níwọ̀n bí orúkọ Ọlọ́run ní èdè Hébérù ti fara hàn ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú apá tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé nìkan, ó ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn olùjọsìn òun máa lo orúkọ òun, kí wọ́n sì mọ irú ẹni tí òun jẹ́. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti ran àìmọye ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti Wà ní Ọ̀pọ̀ Èdè
Àtìgbà tó ti wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti ń wá ọ̀nà láti ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè ìbílẹ̀ wọn—ó sì dára bẹ́ẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tó ti ṣòro fáwọn Ẹlẹ́rìí láti rí àwọn Bíbélì tó jẹ́ ti èdè ìbílẹ̀ wọn rà, nítorí pé àwọn Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì tó ní wọn lọ́wọ́ kì í fẹ́ kí Bíbélì táwọn túmọ̀ dé ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, irú àwọn Bíbélì èdè ìbílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì pa mọ́. Àpẹẹrẹ kan tó gba àfiyèsí ni ti Bíbélì kan ní èdè ìhà gúúsù Yúróòpù tí kò fẹ́ káwọn èèyàn rí ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Bíbélì sọ nípa orúkọ Ọlọ́run, tó wá yí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ̀” padà sí “Kí àwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún ọ.”—Mátíù 6:9.
Ọdún 1961 làwọn atúmọ̀ èdè ti bẹ̀rẹ̀ sí tú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn èdè mìíràn. Ọdún méjì péré lẹ́yìn náà ni wọ́n parí Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun ní àwọn èdè mẹ́fà mìíràn. Lákòókò yẹn, ìdá mẹ́ta nínú ìdá mẹ́rin àwọn Ẹlẹ́rìí kárí ayé ló ní Bíbélì yìí lọ́wọ́ ní èdè tiwọn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò bá jẹ́ kí ẹ̀dà Bíbélì yìí dé ọwọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn.
Ọdún 1989 ni ọ̀rọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí lójú bọ̀, nígbà tá a dá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀ sílẹ̀ ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀ka yẹn gbé ọgbọ́n ìtumọ̀ kan kalẹ̀ tó jẹ́ kó ṣeé ṣe láti fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Lílo ètò yìí ti mú kí ó ṣeé ṣe láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí àwọn èdè bíi mélòó kan láàárín ọdún kan, ká sì túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láàárín ọdún méjì—ìyẹn jẹ́ àkókò tó kéré gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú iye àkókò ti iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì máa ń gbà tẹ́lẹ̀. Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀nà yìí, a ti túmọ̀ ẹ̀dà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n Ìtumọ̀ Ayé Tuntun láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn èdè tí àwọn tó lé ní bílíọ̀nù méjì ènìyàn ń sọ, a sì ti tẹ̀ wọ́n jáde pẹ̀lú. Iṣẹ́ ti ń lọ lọ́wọ́ báyìí lórí àwọn èdè méjìlá mìíràn. Títí di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, a ti tú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì, yálà lódindi tàbí lápá kan, sí èdè mọ́kànlélógójì mìíràn.
Ó ti lé ní àádọ́ta ọdún báyìí látìgbà tá a ti kọ́kọ́ mú apá àkọ́kọ́ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní August 3, 1950, ní Àpéjọpọ̀ Ìbísí Nínú Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York City. Níbi àpéjọpọ̀ yẹn, Nathan H. Knorr rọ àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ẹ gba ìtumọ̀ yìí. Ẹ kà á látìbẹ̀rẹ̀ dópin, ohun tẹ́ ẹ máa gbádùn ni. Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, nítorí pé yóò ràn Kólósè 4:12.
yín lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ pín in fún àwọn ẹlòmíràn.” A rọ̀ yín láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, nítorí pé yóò ràn yín lọ́wọ́ láti ‘dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.’—[Graph/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
“Bá A Ṣe Mú Àwọn Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde”
Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni a ti kọ́kọ́ mú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde, ó sì wà báyìí lódindi tàbí lápá kan ní èdè mọ́kànlélógójì mìíràn
Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì Odindi Bíbélì
1950 1
1960-69 6 5
1970-79 4 2
1980-89 2 2
1990-Di Òní Yìí 29 19