Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń fi Bí a ó Ṣe Máa Ka Àwọn Ọjọ́ Wa Hàn Wá

Jèhófà Ń fi Bí a ó Ṣe Máa Ka Àwọn Ọjọ́ Wa Hàn Wá

Jèhófà Ń fi Bí a ó Ṣe Máa Ka Àwọn Ọjọ́ Wa Hàn Wá

“Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.”—SÁÀMÙ 90:12.

1. Èé ṣe tó fi bójú mu láti bẹ Jèhófà pé kó fi bí a ó ṣe “máa ka àwọn ọjọ́ wa” hàn wá?

 JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ni Ẹlẹ́dàá wa, Òun ló sì fún wa ní ìyè. (Sáàmù 36:9; Ìṣípayá 4:11) Nítorí náà, òun nìkan ló lè fi ọ̀nà tá a lè gbà lo àwọn ọdún ìgbésí ayé wa lọ́nà ọgbọ́n hàn wá. Abájọ tí onísáàmù náà fi bẹ Ọlọ́run pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” (Sáàmù 90:12) Dájúdájú, á dára ká fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò Sáàmù àádọ́rùn-ún, níbi tá a ti rí ẹ̀bẹ̀ yẹn. Àmọ́ o, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ inú orin tí Ọlọ́run mí sí yìí.

2. (a) Ta ni a sọ pé ó kọ Sáàmù àádọ́rùn-ún, ìgbà wo ló sì jọ pé ó kọ ọ́? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí Sáàmù àádọ́rùn-ún nípa lórí ojú tá a fi ń wo ìgbésí ayé?

2 Àkọlé Sáàmù àádọ́rùn-ún pè é ní “àdúrà Mósè, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́.” Níwọ̀n bí sáàmù yìí ti tẹnu mọ́ kíkúrú tí ẹ̀mí ènìyàn kúrú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ́ nínú oko ẹrú Íjíbítì, láàárín ogójì ọdún tí wọn fi rìn ní aginjù, nígbà tí ikú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn fòpin sí ìran aláìnígbàgbọ́ kan, ni a kọ sáàmù yìí. (Númérì 32:9-13) Bó ti wù kó rí, Sáàmù àádọ́rùn-ún fi hàn pé ìgbésí ayé ẹ̀dá aláìpé kúrú gan-an ni. Fún ìdí yìí, ó ṣe kedere pé ó yẹ ká fọgbọ́n lo àwọn ọjọ́ iyebíye tá a ní.

3. Kí làwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Sáàmù àádọ́rùn-ún?

3 Nínú Sáàmù àádọ́rùn-ún, ẹsẹ kìíní sí ìkẹfà pe Jèhófà ní ibùgbé wa ayérayé. Ẹsẹ keje sí ìkejìlá sọ ohun tó yẹ ká ṣe, ká lè lo àwọn ọdún ìgbésí ayé wa tí kì í dúró pẹ́ lọ́nà tínú Ọlọ́run dùn sí. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ kẹtàlá sí ìkẹtàdínlógún sì ti wí, a ń fẹ́ inú rere onífẹ̀ẹ́ àti ìbùkún Jèhófà lójú méjèèjì. Òótọ́ ni pé sáàmù yìí kò sọ̀rọ̀ ní tààràtà nípa ìrírí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ kí kálukú wa fiyè sí bí sáàmù yìí ṣe fàdúrà gbé ẹ̀mí ìfọkànsìn jáde, ká sì fara wé e. Nítorí náà, á dára kí àwa tá a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run fojú ṣùnnùkùn wo Sáàmù àádọ́rùn-ún.

Jèhófà Jẹ́ “Ibùgbé Gidi” fún Wa

4-6. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa?

4 Onísáàmù náà gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, ó ní: “Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa ní ìran dé ìran. Àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá, tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé àti ilẹ̀ eléso gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run [tàbí, Olú Ọ̀run].”—Sáàmù 90:1, 2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

5 Jèhófà, “Ọlọ́run àìnípẹ̀kun” jẹ́ “ibùgbé gidi,” ìyẹn ni ibi ìsádi tẹ̀mí, fún wa. (Róòmù 16:26) Ọkàn wa balẹ̀ nítorí pé ó máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo láti ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Nítorí pé a gbé gbogbo àníyàn wa lé Baba wa ọ̀run nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ ń ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7; Mátíù 6:9; Jòhánù 14:6, 14.

6 A ń gbádùn ààbò tẹ̀mí nítorí pé Jèhófà jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa nípa tẹ̀mí. Ó tún pèsè ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’—tó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀—gẹ́gẹ́ bí ibi ààbò tẹ̀mí, níbi táwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ ti ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kò séwu fún wa. (Aísáyà 26:20; 32:1, 2; Ìṣe 20:28, 29) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn kan lára wa wá látinú ìdílé tó ti ń sin Ọlọ́run látọjọ́ pípẹ́, àwa fúnra wa sì ti rí i pé ó jẹ́ ‘ibùgbé gidi ní ìran dé ìran.’

7. Lọ́nà wo la gbà “bí” àwọn òkè ńlá, tá a sì mú ilẹ̀ ayé jáde gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú “ìrora ìrọbí”?

7 Jèhófà ti wà kí a tó “bí” àwọn òkè ńlá, tàbí kí a tó mú ilẹ̀ ayé jáde gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú “ìrora ìrọbí.” Tá a bá fi ojú èèyàn wò ó, kékeré kọ́ ni iṣẹ́ dídá ilẹ̀ ayé yìí, pẹ̀lú gbogbo nǹkan fífanimọ́ra tí ń bẹ nínú rẹ̀, àwọn èròjà inú rẹ̀, àtàwọn ètò ìṣiṣẹ́ rẹ̀ dídíjú. Nígbà tí onísáàmù náà sì sọ pé a “bí” àwọn òkè ńlá àti pé a mú ilẹ̀ ayé jáde gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú “ìrora ìrọbí,” ńṣe ló ń fi ìmọrírì ńlá hàn fún iṣẹ́ ribiribi tí Jèhófà ṣe nígbà tó dá nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà ní irú ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì bẹ́ẹ̀ fún iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá?

Jèhófà Kò Fi Wá Sílẹ̀ Rí

8. Kí ni gbólóhùn náà pé Jèhófà ni Ọlọ́run “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin” túmọ̀ sí?

8 Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” “Àkókò tí ó lọ kánrin” lè tọ́ka sí àwọn nǹkan tó lópin, àmọ́ tí a kò mọ àkókò pàtó tó máa dópin. (Ẹ́kísódù 31:16, 17; Hébérù 9:15) Ṣùgbọ́n ní Sáàmù 90:2 àti láwọn ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, “àkókò tí ó lọ kánrin” túmọ̀ sí “ayérayé.” (Oníwàásù 1:4) Àlàyé náà pé Ọlọ́run ti wà láti ayérayé, kọjá ohun tí òye wa lè gbé. Síbẹ̀, Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ní lópin. (Hábákúkù 1:12) Títí ayé ni yóò máa wà, tí yóò sì máa ràn wá lọ́wọ́.

9. Kí ni onísáàmù náà sọ pé ẹgbẹ̀rún ọdún ẹ̀dá ènìyàn jẹ́?

9 Onísáàmù náà sọ lábẹ́ ìmísí pé ẹgbẹ̀rún ọdún lọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ àkókò tó kúrú gan-an lójú Ẹlẹ́dàá, tí í ṣe ẹni ayérayé. Ó kọ̀wé nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ mú kí ẹni kíkú padà di ohun àtẹ̀rẹ́, ìwọ sì wí pé: ‘Ẹ padà lọ, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn.’ Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí kìkì àná nígbà tí ó bá kọjá, àti bí ìṣọ́ kan ní òru.”Sáàmù 90:3, 4.

10. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú kí èèyàn “padà di ohun àtẹ̀rẹ́”?

10 Ẹni kíkú lèèyàn, Ọlọ́run sì mú kó “padà di ohun àtẹ̀rẹ́.” Ìyẹn ni pé èèyàn á padà “sí ekuru,” gẹ́gẹ́ bí erùpẹ̀ lẹ́búlẹ́bú. Lẹ́nu kan, ohun tí Jèhófà ń sọ ni pé: ‘Ẹ padà sínú ekuru tá a fi ṣẹ̀dá yín.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; 3:19) Èyí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀—ì báà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà—torí pé kò sí ẹ̀dá aláìpé kankan ‘tí ó lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà ní ọ̀nà èyíkéyìí, tàbí kí ó fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀, tí yóò fi wà láàyè títí láé.’ (Sáàmù 49:6-9) Ṣùgbọ́n a mà dúpẹ́ o, pé ‘Ọlọ́run fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun’!—Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.

11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àkókò gígùn lójú wa jẹ́ àkókò kúkúrú gan-an lójú Ọlọ́run?

11 Mètúsélà alára, tó lo ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] lókè eèpẹ̀, kò pé ọjọ́ kan ṣoṣo lójú Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 5:27) Lójú Ọlọ́run, àná jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún—wákàtí mẹ́rìnlélógún péré ni—nígbà tó bá kọjá. Onísáàmù náà tún sọ pé lójú Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún ọdún kò yàtọ̀ sí ìṣọ́ òru, èyí tí olùṣọ́ ń ṣe fún wákàtí mẹ́rin ní ibùdó. (Àwọn Onídàájọ́ 7:19) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé àkókò gígún lójú wa jẹ́ àkókò kúkúrú gan-an lójú Jèhófà, Ọlọ́run ayérayé.

12. Báwo ni Ọlọ́run ṣe “gbá” àwọn èèyàn “lọ”?

12 Ẹ̀mí ọmọ aráyé kúrú gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ẹni ayérayé. Onísáàmù náà sọ pé: “Ìwọ ti gbá wọn lọ; wọ́n di oorun lásán-làsàn; ní òwúrọ̀, wọ́n dà bí koríko tútù tí ń yí padà. Ní òwúrọ̀, ó mú ìtànná jáde, yóò sì yí padà; ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dànù dájúdájú.” (Sáàmù 90:5, 6) Mósè rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kú ní aginjù, bíi pé ṣe ni Ọlọ́run fi ìkún omi “gbá wọn lọ.” Àwọn mìíràn túmọ̀ ọ̀rọ̀ sáàmù yìí sí: “Ìwọ gbá àwọn èèyàn lọ nínú oorun ikú.” (New International Version) Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, iye ọjọ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé jẹ́ “oorun lásán-làsàn,” tí kò pẹ́ rárá—tá a lè fi wé oorun tá a sùn mọ́jú ọjọ́ kan ṣoṣo.

13. Báwo la ṣe dà bíi “koríko tútù,” ipa wo ló sì yẹ kí èyí ní lórí ìrònú wa?

13 A ò yàtọ̀ sí ‘koríko tútù tó yọ ìtànná ní òwúrọ̀,’ ṣùgbọ́n tó rọ lálẹ́ lẹ́yìn tí oòrùn fẹjú mọ́ ọn. Àní sẹ́, ìgbésí ayé wa kúrú bíi koríko tó rọ láàárín ọjọ́ kan ṣoṣo. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká fi ohun iyebíye yìí tàfàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nípa bó ṣe yẹ ká lo àwọn ọdún tó ṣẹ́ kù fún wa nínú ètò àwọn nǹkan yìí.

Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti “Ka Àwọn Ọjọ́ Wa”

14, 15. Báwo ni Sáàmù 90:7-9 ṣe ṣẹ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára?

14 Ní ti ohun tí Ọlọ́run ṣe, onísáàmù náà fi kún un pé: “A ti wá sí òpin nínú ìbínú rẹ, ìhónú rẹ sì ti yọ wá lẹ́nu. Ìwọ ti gbé ìṣìnà wa kalẹ̀ sí ọ̀gangan iwájú rẹ, àwọn nǹkan àṣírí wa sí iwájú rẹ tí ó mọ́lẹ̀ yòò. Nítorí pé gbogbo ọjọ́ wa ti ń lọ sí òpin wọn nínú ìbínú kíkan rẹ; àwa ti parí àwọn ọdún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.”Sáàmù 90:7-9.

15 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ “wá sí òpin nínú ìbínú” Ọlọ́run. ‘Ìhónú rẹ̀ yọ wọ́n lẹ́nu,’ tàbí pé ‘ìkannú rẹ̀ kó ìpayà bá wọn.’ (New International Version) A ‘ṣá àwọn kan balẹ̀ nínú aginjù’ nígbà tí Ọlọ́run dá wọn lẹ́jọ́. (1 Kọ́ríńtì 10:5) Jèhófà ‘gbé ìṣìnà wọn kalẹ̀ sí ọ̀gangan iwájú rẹ̀.’ Ó mú kí wọ́n jíhìn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ní gbangba. Àmọ́ “àwọn nǹkan àṣírí,” tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn pàápàá tún ń bẹ ní ‘iwájú rẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ yòò.’ (Òwe 15:3) Níwọ̀n bí ìbínú Ọlọ́run ti ń bẹ lórí wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìronúpìwàdà ‘parí àwọn ọdún wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀mí tiwa náà kò wà pẹ́ ju afẹ́fẹ́ tó ń jáde lẹ́nu wa bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ lásán.

16. Bí àwọn kan bá ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?

16 Bí ẹnikẹ́ni nínú wa bá ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, ó lè máa yọ́ ọ dá fún sáà kan, táwọn èèyàn ò sì ní mọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa ń bẹ ní ‘iwájú Jèhófà tí ó mọ́lẹ̀ yòò,’ ìwà wa yóò sì ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Kí á lè mú àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà padà bọ̀ sípò, a óò gbàdúrà fún ìdáríjì, a óò jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ó sì fi ẹ̀mí ìmọrírì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà. (Òwe 28:13; Jákọ́bù 5:14, 15) Ẹ ò rí i pé ìyẹn dára ju pé ká “parí àwọn ọdún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́,” ká sì wá fi ìrètí wa fún ìyè ayérayé sínú ewu!

17. Kí ni ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí àwọn èèyàn, àwọn ọdún wa sì kún fún kí ni?

17 Onísáàmù náà sọ nípa gígùn ẹ̀mí ènìyàn aláìpé, ó ní: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí àwọn èèyàn kì í sábàá ju àádọ́rin ọdún, nígbà tí Kálébù sì jẹ́ ẹni àrùnlélọ́gọ́rin ọdún, ó sọ pé irú okun tí òun ní kò wọ́pọ̀. Àwọn kan wà tí ọ̀ràn tiwọn yàtọ̀ ṣá o, irú àwọn èèyàn bí Áárónì (123), Mósè (120), àti Jóṣúà (110). (Númérì 33:39; Diutarónómì 34:7; Jóṣúà 14:6, 10, 11; 24:29) Àmọ́ ní ti àwọn tá a forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún ọdún sókè, ìyẹn, ìran àwọn aláìnígbàgbọ́ tó jáde wá láti Íjíbítì, àárín ogójì ọdún ni gbogbo wọ́n kú dà nù. (Númérì 14:29-34) Lóde òní, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí àwọn èèyàn kò tíì kọjá iye tí onísáàmù náà pè é. Àwọn ọdún wa kún fún “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́.” Kíákíá ni ọdún wọ̀nyí á kọjá lọ, “àwa yóò sì fò lọ.”—Jóòbù 14:1, 2.

18, 19. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti “máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n”? (b) Kí ni lílò tí a bá ń lo ọgbọ́n yóò sún wa láti ṣe?

18 Ohun tí onísáàmù náà kọ lórin tẹ̀ lé e ni pé: “Ta ní ń bẹ tí ó mọ okun ìbínú rẹ àti ìbínú kíkan rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìbẹ̀rù rẹ? Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” (Sáàmù 90:11, 12) Kò sẹ́nì kankan lára wa tó mọ bí ìbínú Ọlọ́run ṣe lè gbóná tó tàbí ibi tó lè nasẹ̀ dé ní ti gidi, ó sì yẹ kí èyí jẹ́ ká túbọ̀ bẹ̀rù Jèhófà látọkànwá. Àní sẹ́, ó yẹ kí èyí sún wa láti sọ fún un pé kí ó kọ́ wa bí a ó “ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.”

19 Àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà jẹ́ àdúrà pé kí Jèhófà jọ̀wọ́ kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ bí wọn yóò ṣe máa fojú ribiribi wo ọjọ́ tó kù fún wọn láyé, kí wọ́n sì máa fọgbọ́n lò ó lọ́nà tínú Ọlọ́run dùn sí. Àádọ́rin ọdún tó ṣeé ṣe kéèyàn lò láyé jẹ́ nǹkan bí ẹgbàá mẹ́tàlá dín lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [25,500] ọjọ́. Àmọ́ o, láìka ọjọ́ orí wa sí, ‘a kò mọ ohun tí ìwàláàyè wa lè jẹ́ lọ́la, nítorí ìkùukùu ni wá, tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.’ (Jákọ́bù 4:13-15) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo” wa, a ò lè sọ bá a ṣe máa pẹ́ láyé tó. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún ọgbọ́n láti fi kojú àdánwò, láti fi mọ bó ṣe yẹ ká máa bá àwọn èèyàn lò, àti láti lè máa sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nísinsìnyí—àní lójúmọ́ tó mọ́ yìí! (Oníwàásù 9:11; Jákọ́bù 1:5-8) Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. (Mátíù 24:45-47; 1 Kọ́ríńtì 2:10; 2 Tímótì 3:16, 17) Lílo ọgbọ́n ń jẹ́ ká máa ‘wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́,’ ká sì máa lo àwọn ọjọ́ wa lọ́nà tó ń mú ògo wá fún Jèhófà, tó sì ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Mátíù 6:25-33; Òwe 27:11) A mọ̀ pé fífi tọkàntọkàn sìn ín kò ní mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ó dájú pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá.

Ìbùkún Jèhófà Ń Mú Wa Láyọ̀

20. (a) Lọ́nà wo ni Ọlọ́run gbà ń “kẹ́dùn”? (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe bá wa lò, bí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn lẹ́yìn dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo?

20 Ẹ wò bí yóò ṣe dùn tó, ká ní ó ṣeé ṣe láti máa yọ̀ jálẹ̀ ìyókù ìgbésí ayé wa! Ẹ̀bẹ̀ Mósè nìyẹn, ó ní: “Padà, Jèhófà! Yóò ti pẹ́ tó? Kí o sì kẹ́dùn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ [tàbí, ìfẹ́ adúróṣinṣin] tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí a lè fi ìdùnnú ké jáde, kí a sì lè máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.” (Sáàmù 90:13, 14; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ọlọ́run kì í ṣàṣìṣe. Àmọ́, ó máa ń “kẹ́dùn,” ó sì máa ń yí “padà” kúrò nínú ìbínú rẹ̀ àti kúrò nínú fífi ìyà jẹni, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà bá yí ìwà àti ìṣe wọn padà lẹ́yìn gbígbọ́ ìkìlọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tó fẹ́ gbé. (Diutarónómì 13:17) Fún ìdí yìí, bá a tilẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, ṣùgbọ́n tá a ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà yóò ‘fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ wa lọ́rùn,’ a ó sì láǹfààní láti fi “ìdùnnú ké jáde.” (Sáàmù 32:1-5) Bí a bá sì ń tọ ipa ọ̀nà òdodo, a óò rí ìfẹ́ adúróṣinṣin tí Ọlọ́run ní fún wa, a ó sì lè “máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa”—àní, jálẹ̀ gbogbo ìyókù ìgbésí ayé wa.

21. Kí ló jọ pé Mósè ń bẹ̀bẹ̀ fún nínú ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 90:15, 16?

21 Onísáàmù náà fi taratara gbàdúrà pé: “Mú kí a máa yọ̀ lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ọjọ́ tí ìwọ fi ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́, àwọn ọdún tí a fi rí ìyọnu àjálù. Kí ìgbòkègbodò rẹ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ, kí ọlá ńlá rẹ sì hàn lára àwọn ọmọ wọn.” (Sáàmù 90:15, 16) Ó jọ pé ṣe ni Mósè ń bẹ Ọlọ́run pé kí ó fi ayọ̀ yíyọ̀ bù kún Ísírẹ́lì lọ́nà tí yóò ṣe rẹ́gí tàbí tí yóò wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ọjọ́ tá a fi ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́, àtàwọn ọdún tí àjálù fi dé bá wọn. Ó bẹ̀bẹ̀ pé kí “ìgbòkègbodò” tí Ọlọ́run yóò fi bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hàn sí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, kí ọlá ńlá Rẹ̀ sì hàn lára àwọn ọmọ wọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kò sóhun tó burú nínú gbígbàdúrà pé kí òjò ìbùkún rọ̀ sórí aráyé onígbọràn nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—2 Pétérù 3:13.

22. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 90:17, kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún?

22 Ẹ̀bẹ̀ tá a fi kásẹ̀ Sáàmù àádọ́rùn-ún nílẹ̀ ni pé: “Kí adùn Jèhófà Ọlọ́run wa . . . wà lára wa, kí o sì fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in lára wa. Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ ọwọ́ wa, kí o fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” (Sáàmù 90:17) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé ó tọ́ láti máa gbàdúrà kí Ọlọ́run bù kún ìsapá wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn, inú wa dùn pé “adùn Jèhófà” wà lára wa. (Jòhánù 10:16) Inú wa mà dùn o, pé Ọlọ́run ti “fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” nínú iṣẹ́ pípòkìkí Ìjọba náà àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn!

Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ka Ọjọ́ Wa Nìṣó

23, 24. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ṣíṣàṣàrò lórí Sáàmù àádọ́rùn-ún?

23 Ó yẹ kí ṣíṣe àṣàrò lórí Sáàmù àádọ́rùn-ún túbọ̀ mú ká gbára lé Jèhófà, tó jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa. Nípa ríronú lórí ọ̀rọ̀ tí sáàmù yìí sọ nípa bí ìgbésí ayé ṣe kúrú tó, ó yẹ ká túbọ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì wíwá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nínú kíka ọjọ́ wa. Bí a bá sì tẹra mọ́ wíwá ọgbọ́n tó tọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, tá a sì ń fi ọgbọ́n yẹn sílò, ó dájú pé a óò rí inú rere onífẹ̀ẹ́ àti ìbùkún Jèhófà.

24 Jèhófà yóò máa bá a lọ ní fífi bí a ó ṣe máa ka ọjọ́ wa hàn wá. Bá a bá sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a nìṣó ní kíka ọjọ́ wa títí ayérayé. (Jòhánù 17:3) Àmọ́ o, bí a bá fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi wa. (Júúdà 20, 21) Gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, kókó yìí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún.

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ “ibùgbé gidi” fún wa?

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ṣe tán nígbà gbogbo láti ràn wá lọ́wọ́?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti “ka àwọn ọjọ́ wa”?

• Kí ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti “máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa”?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Jèhófà ni Ọlọ́run, “àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Mètúsélà tó lo ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] lókè eèpẹ̀ kò lo ọjọ́ kan ṣoṣo tán lójú Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Jèhófà ti “fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in”