Àwọn Èèyàn Mọ Òfin Pàtàkì Náà—Kárí Ayé
Àwọn Èèyàn Mọ Òfin Pàtàkì Náà—Kárí Ayé
“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
ÓTI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí Jésù Kristi ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí Òkè. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn ti sọ, ìwé ò sì lóǹkà tí wọ́n ti kọ lórí gbólóhùn tó sọ wẹ́rẹ́ yẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ti kókìkí òfin yìí, wọ́n lóun ni “olórí ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni,” wọ́n lóun ni “àkópọ̀ ojúṣe Kristẹni sí aládùúgbò rẹ̀,” wọ́n tún sọ pé òun ni “olú òfin ìwà híhù.” Àní níbi táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n dé, Òfin Pàtàkì ni wọ́n ń pè é.
Kì í tún wáá ṣe àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni nìkan làwọn èèyàn tó mọ Òfin Pàtàkì yìí o. Àwọn ẹlẹ́sìn Júù, ẹlẹ́sìn Búdà àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì pàápàá ń gbé ìlànà yìí lárugẹ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí ẹní mowó làwọn ará Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé mọ gbólóhùn kan tó jáde lẹ́nu Confucius, ẹni táwọn ará Ìlà Oòrùn ayé kà sí àgbà amòye àti olùkọ́. Nínú ìwé náà The Analects, tí í ṣe apá kẹta Four Books, ìyẹn ìwé àwọn ẹlẹ́sìn Confucius, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rí ọ̀rọ̀ tó fara pẹ́ Òfin Pàtàkì yìí nínú rẹ̀. Nígbà tí Confucius ń dáhùn ìbéèrè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bi í, ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ pé: “Ohun tí o ò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ, má ṣe é sí wọn.” Nígbà kan tí ọmọléèwé rẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Zigong fọ́nnu pé, “Ohun tí mi ò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí mi, èmi náà kì í fẹ́ ṣe é sí wọn,” olùkọ́ náà fèsì lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀ pé, “Òótọ́ ni, ṣùgbọ́n o ò tíì lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí.”
Béèyàn ṣe ń ka ọ̀rọ̀ yìí, á rí i pé ohun tí Confucius sọ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sóhun tí Jésù sọ lẹ́yìn náà. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbẹ̀ ni pé Òfin Pàtàkì náà tí Jésù gbé kalẹ̀ ń béèrè gbígbé ìgbésẹ̀ pàtó fún ire àwọn ẹlòmíràn. Ká sọ pé àwọn èèyàn ń gbé ìgbésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú gbólóhùn àtàtà tó jáde lẹ́nu Jésù yìí, ká sọ pé wọ́n ń bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, tí ìwà wọn ojoojúmọ́ sì bá ìlànà yìí mu. Ǹjẹ́ o ò rò pé ayé yìí ì bá túbọ̀ dára sí i? Á túbọ̀ dára mọ̀nà.
Yálà ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ tọ́ tàbí kò tọ́, ọ̀nà yòówù kí wọ́n gbà sọ ọ́, ohun tó gbàfiyèsí ni pé láti àtayébáyé ni àwọn èèyàn níbi gbogbo àti ní onírúurú ipò ti gbà pé òfin tó dáa ni Òfin Pàtàkì náà. Ohun tí èyí kàn fi hàn ni pé ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nínú Ìwàásù Lórí Òkè kan àwọn èèyàn nígbà gbogbo, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.
Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Ṣé màá fẹ́ káwọn
èèyàn fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí, kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ mi dù mí, kí wọ́n má sì rẹ́ mi jẹ? Ṣé màá fẹ́ gbé nínú ayé tí kò ti sí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìwà ọ̀daràn àti ogun? Ṣé màá fẹ́ wà nínú ìdílé tí gbogbo mẹ́ńbà rẹ̀ ti ń bìkítà nípa ìmọ̀lára àti ire ẹnì kìíní kejì?’ Ká sòótọ́, ta ló máa sọ pé òun ò fẹ́ nǹkan dáadáa wọ̀nyẹn? Ohun tó kàn ń báni nínú jẹ́ ni pé bóyá la rí ẹni tó ń gbádùn ipò wọ̀nyí lónìí. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, bí ẹní ń gbéra ẹni gẹṣin aáyán ni ríretí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.Wọ́n Ti Rú Òfin Pàtàkì Náà
Kì í ṣòní kì í ṣàná làwọn èèyàn ti ń hùwà ibi séèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìkejì wọn lójú. Lára ìwà ibi wọ̀nyí ni òwò ẹrú ní Áfíríkà, àwọn àgọ́ ìfikúpani ti ìjọba Násì, àṣà fífi agbára mú àwọn ògo wẹẹrẹ ṣiṣẹ́ àti ìwà ìkà pípa odindi ẹ̀yà run ní àwọn ibi púpọ̀. Tá a bá ní ká máa ka gbogbo ìwà láabi táwọn èèyàn ń hù, ilẹ̀ á kún.
Ayé anìkànjọpọ́n layé onímọ̀ ẹ̀rọ tí à ń gbé lónìí. Ṣàṣà làwọn tó ń gba ti ẹlòmíì rò, àfi tí kò bá ní í ná wọn ní nǹkan kan, tí kò sì ní tẹ ohun tí wọ́n pè ní ẹ̀tọ́ tiwọn lójú. (2 Tímótì 3:1-5) Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ya onímọtara-ẹni-nìkan, òǹrorò, aláìlójú àánú àti anìkànjọpọ́n? Kì í ha í ṣe nítorí pé àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti pa Òfin Pàtàkì náà tì, tí wọ́n kà á sí ìlànà tí kò bóde mu mọ́ ni bí? Ó mà ṣe o, nítorí pé àwọn kan tó sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Níbi tí nǹkan sì ń bá a lọ yìí, ńṣe làwọn èèyàn á túbọ̀ máa di anìkànjọpọ́n.
Nítorí náà, àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó, tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni: Kí ni títẹ̀lé Òfin Pàtàkì yìí wé mọ́? Ǹjẹ́ a ṣì rí àwọn tó ń tẹ̀ lé e? Ǹjẹ́ àkókò kan máa wà tí gbogbo aráyé yóò tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì yìí? Tó o bá fẹ́ mọ ìdáhùn tòótọ́ sí ìbéèrè wọ̀nyí, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Confucius àtàwọn mìíràn fi ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí Òfin Pàtàkì náà kọ́ni