O Lè Yẹra fún Àrùn Ọkàn Nípa Tẹ̀mí
O Lè Yẹra fún Àrùn Ọkàn Nípa Tẹ̀mí
Akíkanjú eléré ìdárayá kan, tí òkìkí rẹ̀ kàn kárí ayé, tó sì jọ pé kokooko lara rẹ̀ le, ṣàdédé dìgbò lulẹ̀, ó sì kú fin-ín fin-ín níbi tó ti ń gbára dì fún ìdíje mìíràn. Orúkọ eléré ìdárayá náà ni Sergei Grinkov. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti gba àmì ẹ̀yẹ góòlù nínú eré orí yìnyín tí wọ́n ń ṣe nígbà Òlíńpíìkì. Àmọ́ ìgbà tí ògo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tàn ni ikú òjijì wá dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò—lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n péré. Áà, ikú dóró! Kí ló fa ikú òjijì yìí? Àrùn ọkàn ni. Wọ́n ní kò sẹ́ni tó mọ̀ pé ikú lè gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ sí i báyẹn, torí pé kò sí nǹkan kan tó fi hàn pé ó ní àrùn ọkàn. Ṣùgbọ́n àwọn tó yẹ̀ ẹ́ wò wáá rí i pé ọkàn rẹ̀ tóbi ju bó ṣe yẹ lọ, àti pé àwọn òpó tí ń gbé ẹ̀jẹ̀ jáde látinú ọkàn rẹ̀ ti dí pa.
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé ó lè dà bíi pé púpọ̀ jù lọ àrùn ọkàn tó ń ṣe àwọn èèyàn ṣàdédé ń bẹ̀rẹ̀ lọ́sàn-án kan òru kan ni, àwọn oníṣègùn sọ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ọ̀ràn náà ni pé ńṣe làwọn èèyàn ń dágunlá sí àwọn àmì tí ń kì wọ́n nílọ̀ àtàwọn nǹkan tí ń dá kún àrùn náà, bíi mímí gúlegúle, sísanra jù àti kí igbá àyà máa dun èèyàn. Fún ìdí yìí, bí ikú kò bá tilẹ̀ pa wọ́n nígbà tí àrùn ọkàn bá kọlù wọ́n, olókùnrùn ni ọ̀pọ̀ nínú wọ́n máa ń yà ní ìyókù ìgbésí ayé wọn.
Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó mọ̀ nípa ìṣègùn ń sọ lónìí ni pé téèyàn ò bá fẹ́ ní àrùn ọkàn, ó gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ irú oúnjẹ tó ń jẹ àti irú ìgbésí ayé tó ń gbé, kí ó sì máa lọ ṣe àyẹ̀wò déédéé lọ́dọ̀ dókítà. a Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú fífẹ́ láti ṣe àwọn ìyípadà yíyẹ, kò ní jẹ́ kéèyàn kàgbákò àrùn ọkàn.
Àmọ́, a tún wá ní ọkàn mìíràn tó ń fẹ́ àfiyèsí gidigidi. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ju Òwe 4:23) Tóò, ọkàn ìṣàpẹẹrẹ ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ti gidi. A ní láti wà lójúfò láti lè dáàbò bo ọkàn wa nípa tara. Àmọ́ wíwà lójúfò wa yóò tún légbá kan sí i, bí a óò bá dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn tó lè pa wá nípa tẹ̀mí.
gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Kúlẹ̀kúlẹ̀ Nípa Àrùn Ọkàn Ìṣàpẹẹrẹ
Gẹ́gẹ́ bíi ti àrùn ọkàn nípa tara, ọ̀nà kan téèyàn fi lè rí i dájú pé òun ò kó àrùn ọkàn nípa tẹ̀mí ni láti mọ àwọn ohun tó ń fà á, kéèyàn sì yáa sá fún nǹkan wọ̀nyẹn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó pàtàkì kan yẹ̀ wò tó ń fa àmódi ọkàn—ọkàn ti ara àti ti ìṣàpẹẹrẹ.
Oúnjẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn oúnjẹ bí ìpápánu máa ń dùn lẹ́nu, gbogbo wa la mọ̀ pé ìwọ̀nba ni àǹfààní tí wọ́n ń ṣe fún ara, ìyẹn bó bá tilẹ̀ ń ṣàǹfààní rárá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ohun tí kò lè ṣe ọpọlọ lóore, àmọ́ tó ń dáni lọ́rùn, pọ̀ lọ jàra, wọ́n sì lè sọni di akúrẹtẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ làwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde, tó sì jẹ́ pé ìwà ìṣekúṣe àti oògùn líle, ìwà ipá àti iṣẹ́ awo ló kún inú wọn. Fífi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kún èrò inú ẹni ń kó èèràn ran ọkàn ìṣàpẹẹrẹ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:16, 17.
Àwọn oúnjẹ aṣaralóore, bí èso àti ewébẹ̀, kì í lọ lẹ́nu ẹni tí midinmíìdìn ti mọ́ lára. Bákan náà, oúnjẹ tẹ̀mí tó gbámúṣé, tó ń ṣara lóore, lè máà fi bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́nu ẹni tó ti mọ́ lára láti máa fi àwọn nǹkan ti ayé bọ́ èrò inú àti ọkàn rẹ̀. Ó lè jẹ́ kìkì “wàrà” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lonítọ̀hún ń mu ṣáá. (Hébérù 5:13) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, kò ní kúrò lójú kan nípa tẹ̀mí, kò sì ní tóótun láti tẹ́rí gba ojúṣe rẹ̀ nípa tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Mátíù 24:14; 28:19; Hébérù 10:24, 25) Àwọn kan tó wà nínú ipò yẹn ti jẹ́ kí ọwọ́ wọn rọ nípa tẹ̀mí débi pé wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí aláfẹnujẹ́ lásán!
Ewu mìíràn ni pé ìrísí máa ń tanni jẹ. Ṣíṣe àwọn ojúṣe Kristẹni lọ́nà tí kò dénú lè jẹ́ àmì pé ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ò gbádùn mọ́, pàápàá bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bá ti gbà wá lọ́kàn, tàbí kí ó jẹ́ pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí sá pa mọ́ wo àwọn eré ìnàjú tó dá lórí ìṣekúṣe, ìwà ipá tàbí iṣẹ́ awo. A lè máa rò pé irú ìjẹkújẹ tẹ̀mí wọ̀nyẹn kò lè ba ìdúró wa tẹ̀mí jẹ, ṣùgbọ́n ó lè sọ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ di ahẹrẹpẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí jíjẹ pàrùpárù oúnjẹ ti lè jẹ́ kí ọ̀rá dì sínú òpó ẹ̀jẹ́, kí ó sì Mátíù 5:28) Dájúdájú, ìjẹkújẹ nípa tẹ̀mí lè fa àrùn ọkàn nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, kò mọ síbẹ̀ o.
ba ọkàn wa nípa tara jẹ́. Jésù kìlọ̀ nípa jíjẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọnú ọkàn ẹni. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Eré ìmárale. A kúkú mọ̀ pé fífi ojoojúmọ́ ayé jókòó tẹtẹrẹ sójú kan lè dá kún àrùn ọkàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, jíjókòó tẹtẹrẹ sójú kan nípa tẹ̀mí lè ṣàkóbá fúnni. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè máa nípìn-ín nínú kìkì apá tó rọ̀ ọ́ lọ́rùn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, láìsapá láti di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Tàbí kẹ̀, ó lè máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n kí ó máà múra wọn sílẹ̀, kí ó má sì kópa nínú wọn. Ó lè ṣàìní ohun kan tó ń lépa nípa tẹ̀mí, tàbí kí ó má ka nǹkan tẹ̀mí sí, tàbí kí ó máà ká a lára. Àìsí ìgbòkègbodò nípa tẹ̀mí lè wá paná ìgbàgbọ́ tó ní tẹ́lẹ̀. (Jákọ́bù 2:26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ewu yìí nígbà tó kọ̀wé sáwọn Hébérù tí í ṣe Kristẹni, tó jẹ́ pé àwọn kan lára wọn ò kúrò lójú kan nípa tẹ̀mí. Ṣàkíyèsí bó ṣe kìlọ̀ fún wọn nípa bí èyí ṣe lè jẹ́ kí ọkàn wọn yigbì nípa tẹ̀mí. Ó ní: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè; ṣùgbọ́n ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní ‘Òní,’ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.”—Hébérù 3:12, 13.
Másùnmáwo. Ohun pàtàkì mìíràn tó ń fa àrùn ọkàn ni ìgbà tí másùnmáwo bá pàpọ̀jù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, másùnmáwo, tàbí “àníyàn ìgbésí ayé,” kì í pẹ́ ṣekú pa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, àní ó tiẹ̀ ń múni ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run pátápátá. Jésù fún wa ní ìkìlọ̀ kan tó bọ́ sákòókò, ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.” (Lúùkù 21:34, 35) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, másùnmáwo lè ṣàkóbá fún ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa nígbà tí ìrònú bá dorí wa kodò fún àkókò pípẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀. Dáfídì Ọba mọ ohun tí irú másùnmáwo bẹ́ẹ̀ fojú òun rí nígbà tó sọ pé: “Kò sí àlàáfíà kankan nínú egungun mi ní tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí pé àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá; bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi.”—Sáàmù 38:3, 4.
Dídá ara ẹni lójú jù. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí àrùn ọkàn kọlù ló gbà pé kokooko lara àwọn le, kó tó di pé àrùn ọkàn kọlù wọ́n. Wọn kì í sábàá lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ dókítà, wọ́n tilẹ̀ lè sọ pé ìranù ni. Bákan náà, àwọn kan lè máa fọwọ́ sọ̀yà pé níwọ̀n bí ọjọ́ ti pẹ́ táwọn ti ń bá a bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, mìmì kan ò lè mi àwọn. Wọ́n lè dágunlá sí lílọ fún àyẹ̀wò nípa tẹ̀mí, títí wàhálà á fi dé. Ó ṣe pàtàkì láti rántí ìmọ̀ràn rere tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ṣíṣàì dá ara ẹni lójú jù. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká fi sọ́kàn pé ẹ̀dá aláìpé ni wá, ká sì máa yẹ ara wa wò lóòrèkóòrè.—1 Kọ́ríńtì 10:12; Òwe 28:14.
Kọbi Ara sí Àwọn Àmì Tí Ń Ṣèkìlọ̀
Ó ní ìdí gúnmọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi pe àfiyèsí pàtàkì sí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ. Jeremáyà 17:9, 10 kà pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n? Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà, mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín, àní láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” Ṣùgbọ́n yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń yẹ ọkàn wa wò, ó tún fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣètò láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe àyẹ̀wò pàtàkì yìí.
A ń rí ìránnilétí tó bákòókò mu gbà nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà. (Mátíù 24:45) Fún àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára olórí ọ̀nà tí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ fi lè tàn wá jẹ ni kí a máa bá ayé lá àlá àsán tí wọ́n ń lá. Èyíinì ni àwọn ìfọkànyàwòrán ohun tọ́wọ́ ẹni ò lè tẹ̀, àlá tí kò lè ṣẹ, tó jẹ́ gbígbé ara ẹni gẹṣin aáyán. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè pa wá lára gan-an, àgàgà bí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá jẹ́ èyí tí kò mọ́. Ìyẹn ló fi yẹ ká sá fún irú èrò bẹ́ẹ̀ pátápátá. Bí a bá kórìíra ìwà àìlófin gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe kórìíra rẹ̀, a ò ní máa fọkàn ro ìròkurò.—Hébérù 1:8, 9.
Láfikún sí i, a ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Lóòótọ́, a mọrírì aájò àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ ojúṣe kálukú wa ni láti bójú tó ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Ó kù sọ́wọ́ wa láti “wádìí ohun gbogbo dájú,” kí a sì ‘máa dán ara wa wò bóyá a ṣì wà nínú ìgbàgbọ́.’—1 Tẹsalóníkà 5:21; 2 Kọ́ríńtì 13:5.
Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ
Ìlànà Bíbélì pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú” tún kan ìlera ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. (Gálátíà 6:7) Àwọn àgbákò nípa tẹ̀mí tó máa ń jọ pé òjijì ló dé, sábà máa ń jẹ́ àtúbọ̀tán àwọn ìwà kan téèyàn ti ń hù tipẹ́ ní kọ̀rọ̀, àwọn ìwà tí ń ba ipò tẹ̀mí jẹ́, irú bíi wíwo àwọn nǹkan tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, ṣíṣàníyàn ré kọjá ààlà nípa àwọn nǹkan tara tàbí dídu òkìkí tàbí agbára.
Nítorí náà, láti dáàbò bo ọkàn wa, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ohun tá a ń jẹ nípa tẹ̀mí. Máa fún èrò inú àti ọkàn rẹ lókun nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ọ. Yẹra fún fífi pàrùpárù oúnjẹ bọ́ ọpọlọ rẹ, torí pé irú ìjẹkújẹ tí ń dáni lọ́rùn bẹ́ẹ̀ pọ̀ káàkiri, àmọ́ wọ́n ń sọ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ di líle. Onísáàmù fi àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí, tó tún bá ìmọ̀ ìṣègùn mu, kì wá nílọ̀, ó ní: “Ọkàn-àyà wọn ti di aláìnímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá.”—Sáàmù 119:70.
Bí o bá ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, yọwọ́ pátápátá 1 Kọ́ríńtì 7:29-31) Bí ọkàn rẹ bá sì bẹ̀rẹ̀ sí fà sí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, rántí ọ̀rọ̀ Jóòbù tó sọ pé: “Bí mo bá fi wúrà ṣe ìgbọ́kànlé mi, tàbí tí mo sọ fún wúrà pé, ‘Ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi!’ ìyẹn pẹ̀lú yóò jẹ́ ìṣìnà fún àfiyèsí àwọn adájọ́, nítorí èmi ì bá ti sẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó wà lókè.”—Jóòbù 31:24, 28; Sáàmù 62:10; 1 Tímótì 6:9, 10.
nínú irú ìwàkíwà bẹ́ẹ̀, kó tó di pé ó dí òpójẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ rẹ. Bí òòfà ayé bá bẹ̀rẹ̀ sí fà ọ́ mọ́ra, tó jọ pé fàájì àti ìgbádùn ń ṣàn nínú ayé, rántí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa. Ó kọ̀wé pé: “Èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí . . . àwọn tí ń lo ayé [dà] bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́; nítorí ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (Láti fi hàn pé ewu ńlá ń bẹ nínú kíkọ etí ikún sí ìmọ̀ràn tó wá látinú Bíbélì, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ènìyàn tí a fi ìbáwí tọ́ sọ́nà léraléra, ṣùgbọ́n tí ó mú ọrùn rẹ̀ le, yóò ṣẹ́ lójijì, kì yóò sì ṣeé mú lára dá.” (Òwe 29:1) Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, nípa títọ́jú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa dáadáa, a lè ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí àwọn tí kò walé ayé máyà ní. Irú ìgbésí ayé yìí ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ń rọ̀ wá pé ká máa gbé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lábẹ́ ìmísí, pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí a kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:6-8.
Ó dájú pé fífi ìfọkànsin Ọlọ́run tọ́ ara wa yóò jẹ́ ká ní ọkàn ìṣàpẹẹrẹ tó lera. Nípa ṣíṣọ́ ohun tí à ń jẹ nípa tẹ̀mí, a ò ní jẹ́ kí èyíkéyìí nínú ọ̀nà àti èrò apanirun ti ayé yìí pa ìdúró wa nípa tẹ̀mí lára. Boríborí rẹ̀, nípa títẹ́wọ́gba àwọn ìpèsè tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ ètò rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa yẹ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa wò déédéé. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká kàgbákò àrùn ọkàn nípa tẹ̀mí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, jọ̀wọ́ wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìkọlù Àrùn Ọkàn-àyà—Kí Ni A Lè Ṣe?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti December 8, 1996, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
JÍJẸ ÌJẸKÚJẸ NÍPA TẸ̀MÍ LÈ SỌ ỌKÀN ÌṢÀPẸẸRẸ DI OLÓKÙNRÙN, GẸ́GẸ́ BÍ PÀRÙPÁRÙ OÚNJẸ ṢE LÈ LỌ DÍ ÒPÓJẸ̀, KÍ Ó SÌ BA ỌKÀN TI ARA JẸ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
JÍJÓKÒÓ TẸTẸRẸ SÓJÚ KAN NÍPA TẸ̀MÍ LÈ ṢÀKÓBÁ FÚN WA
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“ÀWỌN ÀNÍYÀN ÌGBÉSÍ AYÉ” KÌ Í PẸ́ ṢEKÚ PA ỌKÀN ÌṢÀPẸẸRẸ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ṣíṣàì kọbi ara sí ìlera wa nípa tẹ̀mí lè yọrí sí ọ̀pọ̀ ìrora
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jíjẹ́ kí àwọn àṣà tẹ̀mí tó dáa mọ́ wa lára ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Fọ́tò AP/David Longstreath