Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì

Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì

Ẹ̀mí Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Ló Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Wá sí Gílíádì

ILÉ Ẹ̀KỌ́ Watchtower Bible School of Gilead wà fún dídá àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó ti ya ara wọn sí mímọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè. Àwọn wo ló ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì? Àwọn tó ní ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni ni. (Sáàmù 110:3) Ìyẹn hàn kedere ní September 8, 2001, nígbà tí kíláàsì kọkànléláàádọ́fà kẹ́kọ̀ọ́ yege.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní kíláàsì yẹn ti fínnúfíndọ̀ fi ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́, àti orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀ láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń dán ara wọn wò láti mọ̀ bóyá àwọn á lè ṣe àwọn ìyípadà kan táwọn á fi lè gbé ní àyíká ibòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, Richer àti Nathalie ṣètò ara wọn láti kó lọ sí Bolivia, Todd àti Michelle kó lọ sí Dominican Republic, David àti Monique kó lọ sí orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà láti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ti lọ sìn ní Nicaragua, Ecuador, àti Albania.

Wọ́n gba Christy níyànjú láti kọ́ èdè Spanish nílé ẹ̀kọ́ gíga, èyí tó múra rẹ̀ sílẹ̀ láti lo ọdún méjì ní Ecuador kó tó ṣègbéyàwó. Àwọn mìíràn ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè láwọn orílẹ̀-èdè tiwọn. Láti kojú ìṣòro mìíràn, Saul àti Priscilla fi ẹ̀mí ìmúratán hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára láti mú kí èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n gbọ́ sunwọ̀n sí i kí wọ́n tó wá sí ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Kíákíá ni oṣù márùn-ún tí wọ́n fi gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì kọjá lọ. Ọjọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege dé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì bára wọn láàárín àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́, tí wọ́n ń fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àtàwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére tí ń fúnni níṣìírí.

Alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni Theodore Jaracz, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí di báyìí. Nínú ọ̀rọ̀ tó fi ṣí ayẹyẹ náà, ó tẹnu mọ́ òtítọ́ náà pé gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan, a kò gbàgbé ète tá a fi ń dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Gílíádì lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo ibi táwọn èèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Máàkù 13:10) Gílíádì ń múra àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tóótun sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí lọ́nà gbígbòòrò ju bí wọ́n ṣe ń ṣe é tẹ́lẹ̀, kí wọ́n sì lọ ṣe iṣẹ́ náà láwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn míṣọ́nnárì tá a dá lẹ́kọ̀ọ́. Arákùnrin Jaracz gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nímọ̀ràn láti lo ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà ní Gílíádì dáadáa bí wọ́n ṣe fẹ́ lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn míṣọ́nnárì tó ń sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún tá a yàn wọ́n sí.

Ìmọ̀ràn Tó Bọ́ Sákòókò fún Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege

Àwọn àsọyé bíi mélòó kan tẹ̀ lé e. William Van De Wall, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Ìtara Míṣọ́nnárì—Àmì Kristẹni Tòótọ́.” Ó pe àfiyèsí sí àṣẹ náà láti “sọni di ọmọ ẹ̀yìn,” èyí tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, ó sì gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé: “Ẹ fara wé Jésù, ẹni tó ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ tìtaratìtara.” Láti ran àwọn míṣọ́nnárì tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi ìtara bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn lọ, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ṣeé tẹ̀ lé; ẹ ní ètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jíire, ẹ máà jẹ́ kí ètò Ọlọ́run yà yín lẹ́sẹ̀ kan; kí ẹ má sì gbàgbé ìdí tí ẹ fi wà ní ibi tá a yàn yín sí.”

Ẹni tó sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e ni Guy Pierce, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Mímú ‘Agbára Ìmọnúúrò Yín’ Dàgbà.” (Róòmù 12:1) Ó fún kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà nímọ̀ràn tó gbéṣẹ́, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn láti ronú. Ó sọ pé: “Ẹ máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Jèhófà ń sọ fún yín nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí yóò dáàbò bò yín.” (Òwe 2:11) Arákùnrin Pierce tún gba kíláàsì náà níyànjú pé kí wọ́n má ṣe ní ojú ìwòye apàṣẹwàá, kí èyí má bàa ṣèdíwọ́ fún “agbára ìmọnúúrò” wọn. Dájúdájú, àwọn ìránnilétí tó bọ́ sákòókò wọ̀nyí yóò ran àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì.

Lẹ́yìn ìyẹn ni alága ké sí Lawrence Bowen, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Gílíádì, tó sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Pinnu Láti Má Ṣe Mọ Ohunkóhun.” Ó là á mọ́lẹ̀ pé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ó “pinnu láti má ṣe mọ ohunkóhun . . . àyàfi Jésù Kristi, ẹni tí a . . . kàn mọ́gi.” (1 Kọ́ríńtì 2:2) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́, tó jẹ́ agbára gíga jù lọ ní ọ̀run òun ayé, ló ń ti ìhìn tó wà nínú Bíbélì látòkè délẹ̀ lẹ́yìn: ìyẹn ni ìdáláre ipò ọba Jèhófà nípasẹ̀ Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé kí wọ́n dà bíi Pọ́ọ̀lù àti Tímótì, kí wọ́n sì kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn nípa títẹ̀lé “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera.”—2 Tímótì 1:13.

“Mọyì Àǹfààní Rẹ, Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn ọ̀wọ́ àwọn àsọyé tá a fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Wallace Liverance, ẹni tí ń forúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ohun kan tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí tàbí tí wọ́n ṣiṣẹ́ fún. Arákùnrin Liverance tọ́ka sí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Yíyàn tí Jèhófà yan Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ àpọ́sítélì òun fún àwọn orílẹ̀-èdè kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rẹ̀, tí ì bá fi dà bíi pé Pọ́ọ̀lù ti ṣe ohun tó jẹ́ kó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba iṣẹ́ náà tàbí pé èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni. Kò sinmi lórí pípẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ìrírí téèyàn ti ní. Lójú ẹ̀dá ènìyàn, ó dà bíi pé Bánábà gan-an ló yẹ kí ó yàn. Kò sì sinmi lórí mímọ nǹkan ṣe; ó dájú pé ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu Ápólò ju Pọ́ọ̀lù lọ. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ni.” (Éfésù 3:7, 8) Arákùnrin Liverance rọ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà láti lo ẹ̀bùn wọn, tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní, láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì gba “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni . . . , ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.

Lẹ́yìn èyí, Mark Noumair, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Gílíádì ṣètò ìjíròrò amóríyá pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bíi mélòó kan lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Ìmúrasílẹ̀ Máa Ń Ní Àbájáde Rere.” (Òwe 21:5) Àwọn ìrírí náà fi hàn pé bí òjíṣẹ́ kan bá múra iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, àgàgà tó bá múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀, yóò ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí àwọn èèyàn. Kò ní í wá ohun tó máa sọ tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ yóò máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Arákùnrin Noumair là á mọ́lẹ̀ pé: “Èyí ni àṣírí jíjẹ́ míṣọ́nnárì tó kẹ́sẹ járí.” Èyí jẹ́ látinú ìrírí ti ara rẹ̀ nígbà tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní Áfíríkà.

Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì Jẹ́ Iṣẹ́ Tí Ń Fúnni Láyọ̀

Ralph Walls àti Charles Woody fi ọ̀rọ̀ wá àwọn míṣọ́nnárì kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, táwọn náà wà ní Ibùdó Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Patterson fún àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́, lẹ́nu wò. Ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò náà fi hàn pé ìfẹ́ fún àwọn èèyàn ló ń mú ayọ̀ wá nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Ó fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́, àtàwọn ìdílé wọn àti àwọn ọ̀rẹ́ tó wà láwùjọ lọ́kàn balẹ̀ láti gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn míṣọ́nnárì tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọ̀nyí fúnra wọn, bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé ìdí tí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì fi jẹ́ iṣẹ́ tí ń fúnni láyọ̀.

John E. Barr, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló sọ lájorí àsọyé ọjọ́ náà, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ẹ Kọ Orin Tuntun sí Jèhófà.” (Aísáyà 42:10) Arákùnrin Barr sọ pé ìgbà mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbólóhùn náà “orin tuntun,” fara hàn nínú Bíbélì. Ó béèrè pé, “Kí ni orin tuntun yìí dá lé lórí?” Ó wá dáhùn pé: “Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé a ń kọ orin tuntun nítorí ọ̀nà tuntun tí Jèhófà fẹ́ gbà lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀.” Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti máa bá a lọ ní fífi ohùn wọn kọrin ìyìn nípa Ìjọba Ọlọ́run tí ń ṣẹ́gun nìṣó ní ọwọ́ Mèsáyà Ọba náà, Kristi Jésù. Arákùnrin Barr mẹ́nu kàn án pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà ní Gílíádì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ onírúurú apá tí “orin tuntun” yìí pín sí ju bí wọ́n ṣe mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ lọ. “Ilé ẹ̀kọ́ náà ti ràn yín lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa ‘kọrin’ ìyìn Jèhófà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín níbikíbi tẹ́ ẹ bá lọ; ẹ máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní ibi tá a bá yàn yín sí.”

Lẹ́yìn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, ẹni tó gbẹnu sọ fún kíláàsì náà ka lẹ́tà kan tó fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà ní Gílíádì.

Ǹjẹ́ o lè mú iṣẹ́ ìsìn rẹ fún Ọlọ́run gbòòrò sí i, kí o sì túbọ̀ méso rere jáde? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, yọ̀ǹda ara rẹ bí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege wọ̀nyí ti ṣe. Èyí ni ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tóótun fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ayọ̀ ńláǹlà wà nínú fífínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara ẹni fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Aísáyà 6:8.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 10

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 19

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33.2

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16.8

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.6

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kíláàsì Kọkànléláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Ní ti àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Yeomans, C.; Toukkari, A.; Nuñez, S.; Phillips, J.; Dawkin, M.; Silvestri, P. (2) Morin, N.; Biney, J.; López, M.; Van Hout, M.; Cantú, A.; Szilvassy, F. (3) Williams, M.; Itoh, M.; Van Coillie, S.; Levering, D.; Fuzel, F.; Geissler, S. (4) Yeomans, J.; Moss, M.; Hodgins, M.; Dudding, S.; Briseño, J.; Phillips, M. (5) López, J.; Itoh, T.; Sommerud, S.; Kozza, C.; Fuzel, G.; Moss, D. (6) Williams, D.; Dudding, R.; Geissler, M.; Morin, R.; Biney, S.; Cantú, L. (7) Dawkin, M.; Hodgins, T.; Levering, M.; Silvestri, S.; Van Hout, D.; Briseño, A. (8) Van Coillie, M.; Nuñez, A.; Kozza, B.; Sommerud, J.; Toukkari, S.; Szilvassy, P.