Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni Kristẹni aya ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run kó sì tún tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nígbà tí ọkọ náà bá ń ṣe àwọn ọdún ìsìn?

Yóò gba pé kí ó lo ọgbọ́n àti làákàyè. Àmọ́, ohun tó tọ́ ló ń ṣe bó ṣe ń tiraka láti ṣe ojúṣe rẹ̀ méjèèjì. Jésù gbani nímọ̀ràn nípa ipò kan tó fara jọ ìyẹn, ó ní: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Lóòótọ́, ojúṣe àwọn Kristẹni láti tẹrí bá fún ìjọba, èyí tá a wá mẹ́nu kàn lẹ́yìn náà, ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Róòmù 13:1) Síbẹ̀, ìmọ̀ràn rẹ̀ yìí ṣeé mú lò fún aya kan tó fẹ́ ṣe ojúṣe rẹ̀ sí Ọlọ́run, tó sì tún fẹ́ tẹrí ba lọ́nà tó ba Ìwé Mímọ́ mu fún ọkọ rẹ̀, kódà bí ọkọ náà tilẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́.

Kò sẹ́ni tó mọ Bíbélì dáadáa tó lè sẹ́ bó ṣe tẹnu mọ́ ọn pé ohun tó jẹ́ ojúṣe àkọ́kọ́ fún Kristẹni kan ni láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run Olódùmarè ni gbogbo ìgbà. (Ìṣe 5:29) Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ọ̀pọ̀ ipò, olùjọsìn tòótọ́ kan lè fara mọ́ ohun tí aláìgbàgbọ́ kan tó wà nípò àṣẹ bá béèrè fún tàbí tó pa láṣẹ, tíyẹn ò sì túmọ̀ sí pé ó máa kópa nínú ohun tó lè mú un rú àwọn òfin gíga ti Ọlọ́run.

A rí àpẹẹrẹ tó tọ́ni sọ́nà nínú ọ̀ràn àwọn Hébérù mẹ́ta, tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Dáníẹ́lì orí kẹta. Aláṣẹ tó ga jù wọ́n lọ, ìyẹn Nebukadinésárì, pàṣẹ pé kí àwọn àtàwọn mìíràn pésẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. Níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé ìjọsìn èké ló máa wáyé níbẹ̀, ì bá wu àwọn Hébérù mẹ́ta náà pé káwọn má tiẹ̀ yọjú síbẹ̀ rárá. Bóyá ó ṣeé ṣe fún Dáníẹ́lì láti tọrọ gáfárà, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún àwọn mẹ́ta wọ̀nyí. a Nítorí náà, wọ́n fara mọ́ ohun tí ọba sọ débi pé wọ́n bá wọn pésẹ̀ síbẹ̀, àmọ́ wọn ò bá wọn ṣe ohunkóhun tó lòdì.—Dáníẹ́lì 3:1-18.

Bákan náà, lákòókò ọdún, ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè bẹ Kristẹni aya rẹ̀, tàbí kí ó pa á láṣẹ fún un pé kí ó bá òun ṣe ohun kan tí ì bá wu aya náà láti yẹra fún. Gbé àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò: Ó lè ní kó bá òun se irú oúnjẹ pàtó kan ní ọjọ́ tí òun àtàwọn mìíràn fẹ́ ṣe ọdún náà. Tàbí kó sọ pé kí ìdílé òun (títí kan aya òun) ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí òun kan ní ọjọ́ náà, yálà kí wọ́n lọ jẹun níbẹ̀ tàbí kí wọ́n kàn lọ bá wọn ṣeré. Tàbí ṣáájú ọjọ́ ọdún náà pàápàá, ó lè sọ fún aya rẹ̀ pé tó bá lọ ra nǹkan lọ́jà, ó gbọ́dọ̀ bá òun ra àwọn nǹkan—bí oúnjẹ tí wọ́n fi máa ń ṣe irú ọdún bẹ́ẹ̀, tàbí àwọn ẹ̀bùn tó máa pín fáwọn èèyàn, tàbí bébà tó máa fi di àwọn ẹ̀bùn náà àti káàdì ìkíni-kú-ọdún tó máa fi pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn náà.

Bẹ́ẹ̀ rèé, ńṣe ló yẹ kí Kristẹni aya náà pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sìn èké, àmọ́ àwọn nǹkan tó sọ pé kó bá òun rà wọ̀nyẹn wá ńkọ́? Òun ṣáà ni olórí ìdílé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.” (Kólósè 3:18) Nínú irú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, ǹjẹ́ aya náà lè tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ kó sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run? Ó ní láti pinnu bí ó ṣe máa ṣe ìgbọràn sí ọkọ rẹ̀, láìgbójú fo ìgbọràn tó ṣe pàtàkì ju lọ sí Jèhófà.

Ní àwọn àkókò mìíràn tí kì í ṣe àsìkò ọdún, ọkọ rẹ̀ lè ní kó bá òun se irú oúnjẹ kan, bóyá nítorí pé ó fẹ́ràn oúnjẹ yẹn ni tàbí nítorí pé ó ní àkókò kan pàtó tó máa ń jẹ irú oúnjẹ yẹn. Yóò fẹ́ láti fi ìfẹ́ hàn sí ọkọ rẹ̀ kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ipò orí rẹ̀. Ṣé aya náà lè gbọ́ oúnjẹ ọ̀hún, kódà bó tilẹ̀ ní kó bá òun sè é nígbà ọdún? Àwọn Kristẹni aya kan lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rere, kí wọ́n wulẹ̀ kà á sí ara iṣẹ́ gbígbọ́ oúnjẹ, tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́. Ó dájú pé kò sí Kristẹni tòótọ́ tó máa kà á sí oúnjẹ ọdún, bí ọkọ rẹ̀ tilẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó lè sọ pé kí aya òun bá òun lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí kan ní àwọn àkókò kan nínú oṣù tàbí nínú ọdún. Ǹjẹ́ ó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀, bí ọjọ́ náà tiẹ̀ bọ́ sọ́jọ́ ọdún? Tàbí, ṣé aya náà yóò bá ọkọ rẹ̀ ra àwọn nǹkan tó ní kó bá òun rà wọ̀nyẹn láìsí ohun tó kàn án nípa ohun tí ọkọ òun fẹ́ fi àwọn nǹkan tóun bá a rà náà ṣe?

Láìsí àní-àní, Kristẹni aya ní láti ronú nípa àwọn ẹlòmíràn—ìyẹn ipa tó máa ní lórí wọn. (Fílípì 2:4) Yóò wù ú láti yẹra fún ohun tó lè mú káwọn èèyàn lérò pé ó ń bá wọn ṣe ọdún náà, gẹ́gẹ́ bí ì bá ṣe wu àwọn Hébérù mẹ́ta yẹn káwọn èèyàn máà rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. Nítorí náà, ó lè rọra fọgbọ́n bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, kí ó wò ó bóyá ó lè gba ti òun rò, kó sì fúnra rẹ̀ lọ ṣe àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ọdún náà kí ó lè mú inú aya tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń bọ̀wọ̀ fún un dùn. Ó lè wá rí ọgbọ́n tó wà nínú bí àwọn méjèèjì kò ṣe ní kó ìtìjú bá ara wọn nígbà tí aya náà bá yarí pé òun ò lè lọ́wọ́ nínú ohun tó jẹ́ ti ìsìn èké. Bẹ́ẹ̀ ni o, jíjùmọ̀ fara balẹ̀ jíròrò ọ̀rọ̀ náà ṣáájú àkókò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ojútùú sí ọ̀ràn náà.—Òwe 22:3.

Ní àbárèbábọ̀ rẹ̀, Kristẹni olóòótọ́ gbọ́dọ̀ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò kó sì pinnu ohun tó máa ṣe. Ìgbọràn sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ gba ipò kìíní, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn àwọn Hébérù mẹ́ta náà. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Àmọ́, pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó lè ṣe tí kò ní jẹ́ kó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́ nígbà tí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ nínú ìdílé tàbí láwùjọ bá bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]