Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

Ìdáláre wo ni Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn nílẹ̀ Jámánì mú kó ṣeé ṣe nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn?

Kóòtù náà fagi lé ẹjọ́ ẹ̀bi tí kóòtù mìíràn dá fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì kéde pé àjọ kan tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin ni wọ́n. Àwọn tó se ìdájọ́ tá a fi dá wa láre náà sọ pé nínú ọ̀rọ̀ òmìnira ìsìn, ẹnì kan lè ‘ṣègbọràn sí ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ sọ’ dípò ohun tí Orílẹ̀-Èdè rẹ̀ pa láṣẹ.—8/15, ojú ìwé 8.

Báwo ni àkókò tí Jóòbù fi jìyà ṣe gùn tó?

Ìwé Jóòbù kò sọ pé ó jìyà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìjìyà Jóòbù àti bó ṣe dópin ti lè gba oṣù díẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máà tó ọdún kan pàápàá.—8/15, ojú ìwé 31.

Èé ṣe tó fi lè dá wa lójú pé Èṣù kì í wulẹ̀ ṣe ẹni ìtàn àròsọ?

Jésù Kristi mọ̀ pé Èṣù wà lóòótọ́. Ẹni gidi kan ló dán Jésù wò, kì í ṣe èrò ibi kan tó ń rò nínú ara rẹ̀ ló dán an wò. (Mátíù 4:1-11; Jòhánù 8:44; 14:30)—9/1, ojú ìwé 5-6.

Òwe 10:15 sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀. Ìparun àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni ipò òṣì wọn.” Báwo lèyí ṣe jẹ́ òótọ́?

Ọrọ̀ lè jẹ́ ààbò nígbà tá a bá dójú kọ àwọn ohun àìdánilójú inú ìgbésí ayé, gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi kan ṣe lè jẹ́ ààbò fún àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ipò òṣì lè ba nǹkan jẹ́ pátápátá nígbà táwọn nǹkan tí a kò retí bá yọjú.—9/15, ojú ìwé 24.

Ọ̀nà wo ni a gbà bẹ̀rẹ̀ “sí pe orúkọ Jèhófà” nígbà ayé Énọ́ṣì? (Jẹ́nẹ́sísì 4:26)

Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ìtàn ẹ̀dá ènìyàn la ti ń lo orúkọ Ọlọ́run; fún ìdí yìí, ohun tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe nígbà ayé Énọ́ṣì kì í ṣe kíké pe orúkọ Jèhófà nínú ìgbàgbọ́. Ó lè jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ Ọlọ́run pe ara wọn tàbí kí wọ́n máa fi pe àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn tí wọ́n sọ pé àwọn ń tipasẹ̀ wọn jọ́sìn Ọlọ́run.—9/15, ojú ìwé 29.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì, kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí” túmọ̀ sí?

Ọ̀rọ̀ náà kò túmọ̀ sí líle koko mọ́ni tàbí ìwà òǹrorò èyíkéyìí. (Òwe 4:13; 22:15) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ìbáwí” dìídì tàn mọ́ fífúnni-nítọ̀ọ́ni, kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, títọ́nisọ́nà àti, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, fífi ìyà tí ó tọ́ àmọ́ tó fìfẹ́ hàn jẹni. Ọ̀nà pàtàkì kan táwọn òbí lè gbà fara wé Jèhófà ni kí wọ́n làkàkà láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé. (Hébérù 12:7-10)—10/1, ojú ìwé 8, 10.

Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ṣe ń fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run làwọn fara mọ́?

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣalágbàwí Ìjọba Ọlọ́run, wọn kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣọ̀tẹ̀, kódà láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí pàápàá. (Títù 3:1) Wọ́n ń kó ipa tó dára bí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí ti ṣe, wọ́n sì ń sapá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú ìwà ọmọlúwàbí gbígbámúṣé tó wà nínú Bíbélì dàgbà, irú bí àìlábòsí, ìwà mímọ́, àti jíjẹ́ òṣìṣẹ́ kára.—10/15, ojú ìwé 6.

Báwo ni omi tí ń fúnni ní ìyè ṣe ń ṣàn láwọn òkè Andes?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ń sapá láti mú òtítọ́ Bíbélì tọ àwọn ènìyàn náà lọ, kódà ní àwọn èdè méjì tí wọ́n ń sọ ládùúgbò náà, ìyẹn èdè Quechua àti Aymara. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé láwọn erékùṣù tó wà ní Adágún Titicaca, títí kan àwọn erékùṣù tí wọ́n kọ́ sórí àwọn pèpéle “líléfòó” tí wọ́n fi àwọn esùsú tó máa ń hù nínú adágún náà ṣe.—10/15, ojú ìwé 8-10.

Kí ni Ọlọ́run pèsè láti tọ́ wa sọ́nà tá a lè fi wé bí kọ̀ǹpútà ṣe ń tọ́ àwọn ọkọ̀ òfuurufú òde òní sọ́nà?

Ọlọ́run ti fi làákàyè láti mọ ìlànà ìwà híhù, ìyẹn ìwà rere jíǹkí ẹ̀dá ènìyàn. Èyí ni ẹ̀rí ọkàn wa. (Róòmù 2:14, 15)—11/1, ojú ìwé 3-4.

Èé ṣe tí ikú Jésù fi níye lórí gan-an?

Nígbà tí ọkùnrin pípé náà Ádámù ṣẹ̀, ó pàdánù ìwàláàyè ara rẹ̀ àti ti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Róòmù 5:12) Gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn rúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìràpadà tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn olóòótọ́ ẹ̀dá ènìyàn láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—11/15, ojú ìwé 5-6.

Àwọn wo ni àwọn Síkítíánì tá a mẹ́nu kàn nínú Kólósè 3:11?

Àwọn Síkítíánì jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó ń kó kiri ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà tí ó tẹ́jú lọ salalu láti nǹkan bí ọdún 700 sí 300 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ewèlè ni wọ́n lórí ẹṣin, jagunjagun sì ni wọ́n pẹ̀lú. Ó ṣeé ṣe kí Kólósè 3:11 máà tọ́ka sí orílẹ̀-èdè kan pàtó, àmọ́ kó tọ́ka sí àwọn tó burú jù lọ nínú àwọn èèyàn tí kò lajú.—11/15, ojú ìwé 24-5.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Òfin Pàtàkì náà jẹ́ ẹ̀kọ́ tó yẹ ká máa fún láfiyèsí déédéé?

Àwọn ẹlẹ́sìn Júù, ẹlẹ́sìn Búdà, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì àtàwọn ẹlẹ́sìn Confucius pàápàá ń gbé ìlànà yìí lárugẹ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bó ti wù kó rí, ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nínú Ìwàásù Lórí Òkè ń béèrè pé kéèyàn gbé ìgbésẹ̀ tó dára, ó sì tún kan àwọn èèyàn níbi gbogbo àti nígbà gbogbo. (Mátíù 7:12)—12/1, ojú ìwé 3.