Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Náà Gan-an Tí a Ń Pè Ní Jésù

Ẹni Náà Gan-an Tí a Ń Pè Ní Jésù

Ẹni Náà Gan-an Tí a Ń Pè Ní Jésù

LẸ́YÌN táwọn àpọ́sítélì Jésù sọ ohun táwọn èèyàn ń rò nípa rẹ̀ fun un, ó wá bi wọ́n pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Ìdáhùn àpọ́sítélì Pétérù sí ìbéèrè yìí wà nínú Ìhìn Rere Mátíù, tó kà pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” (Mátíù 16:15, 16) Èrò yẹn kan náà làwọn tó kù ní lọ́kàn. Nàtáníẹ́lì, tó wá di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì, sọ fún Jésù pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.” (Jòhánù 1:49) Jésù alára sọ ìjẹ́pàtàkì ipa tí òun kó, ó ní: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Ó tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ Ọlọ́run” nígbà bíi mélòó kan. (Jòhánù 5:24, 25; 11:4) Ó sì fi ẹ̀rí ohun tó sọ yìí hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu, kódà ó jí òkú dìde pàápàá.

Iyèméjì Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Kẹ̀?

Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù ṣeé gbọ́kàn lé? Ṣé wọ́n fi ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an hàn? Olóògbé Frederick F. Bruce, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ṣíṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àti àlàyé lórí Bíbélì ní Yunifásítì Manchester, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Kì í sábàá rọrùn láti fi àwọn àríyànjiyàn inú ìtàn mọ òtítọ́ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ inú àwọn àkọsílẹ̀ àtayébáyé, yálà àwọn tó wà nínú Bíbélì tàbí àwọn tí kò sí nínú Bíbélì. Ó tó láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé yíyẹ nínú bí òǹkọ̀wé kan ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó; bí ìyẹn bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ tán, ẹ̀rí ti wà nílẹ̀ nìyẹn tó ṣeé ṣe kó fi hàn pé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó kọ jẹ́ òtítọ́. . . . A ò lè sọ pé Májẹ̀mú Tuntun jẹ́ ìtàn tí ṣeé gbára lé nítorí pé àwọn Kristẹni gbà á gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtàn ‘mímọ́.’”

Lẹ́yìn tí James R. Edwards, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìsìn ní Jamestown College, North Dakota, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ṣàyẹ̀wò àwọn iyèméjì tí wọ́n ṣe nípa Jésù gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, ó kọ̀wé pé: “A lè fi ìdánilójú sọ pé àwọn ìwé Ìhìn Rere tọ́jú onírúurú ẹ̀rí tó pọ̀ rẹpẹtẹ pa mọ́ lórí ohun tó dìídì jẹ́ òtítọ́ nípa Jésù. . . . Ìdáhùn tó mọ́gbọ́n dání jù lọ sí ìbéèrè tó sọ pé èé ṣe táwọn ìwé Ìhìn Rere fi sọ̀rọ̀ Jésù lọ́nà tí wọ́n gbà sọ ọ́, ni pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé bí wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn gan-an ni Jésù ṣe rí. Àwọn ìwé Ìhìn Rere kún fún òótọ́ pọ́ńbélé nípa èrò táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní nípa rẹ̀, pé ó jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run rán ní ti tòótọ́, tó sì ní agbára láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àti Ìránṣẹ́ Ọlọ́run.” a

Wíwá Jésù Kiri

Àwọn ìwé tí kì í ṣe Bíbélì, àmọ́ tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Jésù Kristi wá ń kọ́? Kí lèrò àwọn èèyàn nípa wọn? Àwọn ìwé tí Tacitus, Suetonius, Josephus, Pliny Kékeré, àtàwọn ògbógi òǹkọ̀wé díẹ̀ mìíràn kọ wà lára ọ̀pọ̀ ìwé ìtàn tó mẹ́nu kan Jésù. Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica (1995) sọ nípa wọn rèé: “Àwọn ìtàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé nígbà àtijọ́, kódà àwọn tí wọ́n jẹ́ alátakò ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá kò ṣiyèméjì nípa ìtàn Jésù, èyí táwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń ṣe awuyewuye nípa rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, láàárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àti ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́.”

Ó ṣeni láàánú pé, níbi táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní ti ń wá “ojúlówó” Jésù tàbí Jésù “inú ìtàn” kiri, ó dà bí ẹni pé wọ́n ti fi ìméfò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, iyèméjì tí kò nídìí àti àbá èrò orí tí kò nítumọ̀ bo irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an mọ́lẹ̀. Lọ́rọ̀ kan, àwọn náà jẹ̀bi ẹ̀sùn èké tí wọ́n ń fi kan àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere pé ìtàn àròsọ ni wọ́n kọ sílẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ ń hára gàgà láti di olókìkí àti láti sọ orúkọ wọn di èyí tí wọ́n fi ń pe àbá èrò orí kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde débi pé wọ́n kùnà láti fi òtítọ́ inú yẹ àwọn ẹ̀rí nípa Jésù wò. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe èyí, irú “Jésù” tó bá èrò inú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mu ni wọ́n hùmọ̀.

Fún àwọn tó dìídì fẹ́ rí i, ẹni náà gan-an tí a ń pè ní Jésù wà nínú Bíbélì. Luke Johnson, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa Májẹ̀mú Tuntun àti orírun ẹ̀sìn Kristẹni ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn ti Candler tó wà ní Yunifásítì Emory, ṣàlàyé pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwádìí tí wọ́n ń ṣe nípa Jésù inú ìtàn ló ti gbójú fo èrò Bíbélì dá. Ó sọ pé ó lè dùn mọ́ni nínú láti ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé àti sànmánì Jésù níbàámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìṣèlú, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ènìyàn àti àṣà ìbílẹ̀. Síbẹ̀, ó fi kún un pé ṣíṣàwárí ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ pè ní Jésù inú ìtàn “kò fi bẹ́ẹ̀ bá èrò Ìwé Mímọ́ mu,” nítorí “ohun tó dá lé ni àpèjúwe ẹni tí Jésù jẹ́,” iṣẹ́ rẹ̀, àti ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí Olùràpadà. Nítorí náà, báwo ni Jésù ṣe rí gan-an, irú iṣẹ́ wo ló sì ń jẹ́?

Ẹni Náà Gan-an Tí A Ń Pè Ní Jésù

Àwọn ìwé Ìhìn Rere—ìyẹn àwọn ìwé mẹ́rin nínú Bíbélì tó sọ ìtàn nípa ìgbésí ayé Jésù—sọ nípa ọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò lọ́nà tó ga. Àánú àti ìyọ́nú sún Jésù láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn tójú wọn fọ́, àtàwọn tí ìpọ́njú mìíràn dé bá. (Mátíù 9:36; 14:14; 20:34) Ikú Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti ìbànújẹ́ tí èyí kó bá àwọn arábìnrin Lásárù mú kí Jésù ‘kérora, kí ó sì da omi lójú.’ (Jòhánù 11:32-36) Ká sọ tòótọ́, àwọn ìwé Ìhìn Rere fi bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù lábẹ́ onírúurú ipò hàn—ó bá ẹnì kan tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ kẹ́dùn, inú rẹ̀ dùn sí àṣeyọrí táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe, ó bínú sí ìwà àìlójú àánú àwọn agbófinrù, inú rẹ̀ sì bà jẹ́ nítorí kíkọ̀ tí Jerúsálẹ́mù kọ Mèsáyà náà sílẹ̀.

Nígbà tí Jésù bá ṣe iṣẹ́ ìyanu, ipa tí ẹni tó ṣe é fún yẹn kó níbẹ̀ ló sábà máa ń tẹnu mọ́, nípa sísọ pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.” (Mátíù 9:22) Ó gbóríyìn fún Nàtáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí “ọmọ Israeli nitõtọ,” nípa sísọ pé: “Ninu ẹniti ẹ̀tan kò si!” (Jòhánù 1:47, Bibeli Mimọ) Nígbà táwọn kan rò pé ẹ̀bùn tí obìnrin kan fún un láti fi ìmọrírì hàn ti pọ̀ jù, Jésù gbèjà rẹ̀, ó sì sọ pé mánigbàgbé ni ìwà ọ̀làwọ́ obìnrin yìí yóò jẹ́. (Mátíù 26:6-13) Jésù jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti adùn-únbárìn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àní “ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.”—Jòhánù 13:1; 15:11-15.

Àwọn ìwé Ìhìn Rere tún fi hàn pé kíá ni Jésù máa ń mọ bí ọkàn ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó bá pàdé ṣe rí. Yálà ìgbà tó ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ létí kànga kan ni o, tàbí ìgbà tó ń bá olùkọ́ ìsìn kan sọ̀rọ̀ nínú ọgbà ni o, tàbí ìgbà tó ń bá apẹja kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá adágún kan ni o, ojú ẹsẹ̀ lọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí Jésù bá ṣe dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ báyìí, wẹ́rẹ́ ni wọ́n máa ń sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún un. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń gún ọkàn wọn ní kẹ́ṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ayé ọjọ́ rẹ̀ kì í fẹ́ sún mọ́ àwọn tó wà nípò àṣẹ, síbẹ̀ ńṣe làwọn èèyàn ń rọ̀gbà yí Jésù ká. Wọ́n máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ Jésù ṣáá ni; ọkàn wọn máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá ti wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ara máa ń tu àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ti wà lọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tó sì ń lo ọmọdé kan gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe pé ó wulẹ̀ ní kí ọmọ náà dúró síwájú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún “fi àwọn apá rẹ̀ yí i ká.” (Máàkù 9:36; 10:13-16) Àní, àwọn ìwé Ìhìn Rere fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí adùn-únbárìn débi pé àwọn èèyàn dúró tì í fún odindi ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n ṣáà lè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ń wọni lọ́kàn.—Mátíù 15:32.

Ẹni pípé tí Jésù jẹ́ kò sọ ọ́ di ẹni tó ń ṣe lámèyítọ́ tàbí kó máa ṣakọ, kó sì wáá jẹ gàba lé orí àwọn aláìpé tí ẹ̀ṣẹ̀ ti dẹrù pa, ìyẹn àwọn tí wọ́n jọ gbé ayé ní àkókò kan náà, tó sì wàásù fún. (Mátíù 9:10-13; 21:31, 32; Lúùkù 7:36-48; 15:1-32; 18:9-14) Jésù kò fagbára múni rí. Kò fi kún ẹrù àwọn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá . . . Èmi yóò sì tù yín lára.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí i gẹ́gẹ́ bí “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà”; àjàgà rẹ̀ jẹ́ ti onínúure, ẹrù rẹ̀ sì fúyẹ́.—Mátíù 11:28-30.

Ìtàn inú ìwé Ìhìn Rere fi ìwà Jésù hàn kedere lọ́nà tá a fi mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ. Kò lè rọrùn fún àwọn ẹni mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti kó ohun tí kò ṣẹlẹ̀ nípa ẹnì kan jọ, kí wọ́n sì sọ bí ẹni náà ṣe rí lọ́nà tó bára mu bẹ́ẹ̀ látòkè délẹ̀ ìtàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ́nà ṣíṣekedere. Bóyá ló fi lè ṣeé ṣe fún àwọn òǹkọ̀wé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ṣàpèjúwe ẹnì kan náà, kí wọ́n sì sọ ohun kan náà nípa rẹ̀ tó bá jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò fìgbà kan wà rí.

Òpìtàn náà, Michael Grant, béèrè ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ kan pé: “Báwo ló ṣe jẹ́ pé látòkè délẹ̀ gbogbo ìwé Ìhìn Rere, láìsí àfi kankan, la ti rí àpèjúwe kedere tí wọ́n ṣe nípa ọkùnrin fífanimọ́ra kan tó ń rìn fàlàlà láàárín onírúurú obìnrin, títí kan èyí tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí oníwàkiwà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìti ẹ̀mí ìgbónára bọ̀ ọ́, tàbí pé kò mọ ohun tó ń ṣe, tàbí pé bóyá ó ń ṣe bí ẹni tí kò dákan mọ̀, tó sì jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló ń pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́?” Ìdáhùn tó mọ́gbọ́n dání ni pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ gbé ayé ní ti tòótọ́, ó sì hùwà lọ́nà tó bá ohun tí Bíbélì wí mu.

Jésù Náà Gan-an àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

Yàtọ̀ sí fífi irú ẹni tí Jésù jẹ́ nígbà tó wà láyé hàn, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó ti wà lọ́run tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run ta àtaré ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan, kí ó lè bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. (Mátíù 1:18) Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó kéde Ìjọba Ọlọ́run pé òun ni ìrètí kan ṣoṣo fún ìran ènìyàn tí wàhálà ti bá, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ.—Mátíù 4:17; 10:5-7; 28:19, 20.

Ní Nísàn 14 (ní nǹkan bí April 1) ọdún 33 Sànmánì Tiwa, wọ́n mú Jésù, wọ́n gbẹ́jọ́ rẹ̀, wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún un, wọ́n sì pa á nítorí ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kan án pé ó fẹ́ dojú ìjọba dé. (Mátíù 26:18-20, 26:48–27:50) Ikú Jésù ló wá jẹ́ ìràpadà, tó gba ìràn ènìyàn tó nígbàgbọ́ là kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà ìyè ayérayé sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Róòmù 3:23, 24; 1 Jòhánù 2:2) Ní Nísàn 16, a jí Jésù dìde, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tó fi gòkè padà sí ọ̀run. (Máàkù 16:1-8; Lúùkù 24:50-53; Ìṣe 1:6-9) Gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà fi jẹ, Jésù tí a jí dìde náà ní ọlá àṣẹ láti mú ète tí Ọlọ́run ní fún aráyé ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. (Aísáyà 9:6, 7; Lúùkù 1:32, 33) Bẹ́ẹ̀ ni o, Bíbélì ka Jésù sí ẹni pàtàkì jù lọ nínú mímú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ.

Ní ọ̀rúndún kìíní, ògìdìgbó àwọn èèyàn ló tẹ́wọ́ gba Jésù nítorí irú ẹni tó jẹ́—ìyẹn Mèsáyà tí a ṣèlérí rẹ̀, tàbí Kristi, tí a rán wá sáyé láti wá dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre, kí ó sì kú gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún aráyé. (Mátíù 20:28; Lúùkù 2:25-32; Jòhánù 17:25, 26; 18:37) Lójú inúnibíni líle koko, bóyá làwọn èèyàn ì bá fi gbà láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ká ní irú ẹni tó jẹ́ kò dá wọn lójú ni. Pẹ̀lú ìgboyà àti ìtara ni wọ́n fi tẹ́wọ́ gba àṣẹ tó pa fún wọn pé kí wọn “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:19.

Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́, tí wọ́n sì jẹ́ olóye ló mọ̀ pé Jésù kì í ṣe ẹni ìtàn àròsọ. Wọ́n tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run, ẹni ti yóò gba ìṣàkóso orí ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tí ń lọ nínú rẹ̀ láìpẹ́. Ọ̀rọ̀ ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí jẹ́ ìròyìn ayọ̀ nítorí pé ó ṣèlérí bíbọ́ lọ́wọ́ àwọn wàhálà ayé. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi hàn pé àwọn gbé Ọba tí Jèhófà ti yàn náà lárugẹ nípa kíkéde “ìhìn rere ìjọba yìí” fún àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 24:14.

Àwọn tó fara mọ́ ètò Ìjọba náà nípasẹ̀ Kristi, Ọmọ Ọlọ́run alààyè, yóò gbádùn ìbùkún ayérayé. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí lè jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú! Inú àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o lè mọ ẹni náà gan-an tí a ń pè ní Jésù.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àyẹ̀wò kíkún lórí àwọn ìtàn inú ìwé Ìhìn Rere, wo orí 5 sí 7 nínú ìwé The Bible—God’s Word or Man’s?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ohun Táwọn Ẹlòmíràn Sọ

“Mo ka Jésù ará Násárétì sí ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ńlá lágbàáyé. . . . Màá sọ fún àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù pé ìgbésí ayé yín kò lè nítumọ̀ láìjẹ́ pé ẹ fara balẹ̀ gbé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù yẹ̀ wò.”—Mohandas K. Gandhi, The Message of Jesus Christ.

“Ẹ̀dá kan tó jẹ́ ojúlówó, tó pé pérépéré, tí kò níwà àgàbàgebè rárá, tó jẹ́ ẹni pípé, tó tún jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, síbẹ̀ tó ga lọ́lá ju gbogbo ẹ̀dá ènìyàn lọ, kò lè jẹ́ ayédèrú tàbí ẹni ìtàn àròsọ. . . . Ẹni tó ga ju Jésù lọ nìkan ló lè hùmọ̀ Jésù.”—Philip Schaff, History of the Christian Church.

“Tó bá jẹ́ pé àwọn gbáàtúù kéréje láti inú ìran kan ṣoṣo ló fúnra wọn hùmọ̀ irú ẹni ńlá bẹ́ẹ̀, ẹni tí ìwà rẹ̀ fani mọ́ra gan-an, tó ní ìlànà ìwà híhù tó ga lọ́lá, tí ẹ̀mí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará tó ní sì wúni lórí jọjọ, ìyẹn ni ì bá jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó ta yọ gbogbo èyí tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.”—Will Durant, Caesar and Christ.

“Ó dà bí ohun tí kò ṣeé ronú kàn pé ẹ̀sìn kan tó kárí ayé bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ ẹnì kan tí kò fìgbà kan wà rí, tá a kàn ń fọkàn yàwòrán rẹ̀, tí kò yàtọ̀ sí àwòrán táwọn ara ìgbàanì hùmọ̀, pàápàá jù lọ tá a bá rántí pé ọ̀pọ̀ ẹni ìtàn ló ti gbìyànjú láti dá ẹ̀sìn sílẹ̀, àmọ́ tí wọn ò kẹ́sẹ járí.”—Gregg Easterbrook, Beside Still Waters.

‘Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn tó jẹ́ ògbógi nípa àwọn ìtàn ìgbàanì, ó dá mi lójú hán-únhán-ún pé ohun yòówù táwọn ìwé Ìhìn Rere ì báà jẹ́, wọ́n kì í ṣe ìtàn àròsọ. Kò sí àjásà nínú àwọn ìtàn wọ̀nyẹn tí à bá fi sọ pé ìtàn àtẹnudẹ́nu ni wọ́n. Apá tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé Jésù ni a kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ rèé, kò sẹ́ni tó fẹ́ kọ ìtàn àròsọ tó máa jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀.’—C. S. Lewis, Mere God in the Dock.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ìwé Ìhìn Rere fi bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù lábẹ́ onírúurú ipò hàn