Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo

Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo

Oògùn Ajẹ́bíidán Fún Másùnmáwo

“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.”—MÁTÍÙ 11:28.

1, 2. (a) Kí ni Bíbélì sọ, tó lè pẹ̀rọ̀ sí másùnmáwo lílékenkà? (b) Báwo làwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣe gbéṣẹ́ tó?

 KÒ SÍ àní-àní pé tí másùnmáwo bá ti pọ̀ jù, wàhálà ló ń dá sílẹ̀; ó ń fa ìrora ọkàn. Bíbélì fi hàn pé ẹrù ti wọ gbogbo ọmọ aráyé lọ́rùn débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ìtura lójú méjèèjì nínú ayé másùnmáwo tí à ń gbé lónìí. (Róòmù 8:20-22) Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè rí ìtura ńláǹlà kúrò nínú ìrora ọkàn nísinsìnyí. Ìtura yẹn ń wá látinú títẹ̀lé ìmọ̀ràn àti àpẹẹrẹ ọ̀gbẹ́ni kan tó gbé ayé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn. Káfíńtà ni ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn èèyàn ju iṣẹ́ káfíńtà rẹ̀ lọ. Ó sọ̀rọ̀ ìṣírí fáwọn èèyàn, ó ṣaájò wọn, ó ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ó sì tu àwọn tó sorí kọ́ nínú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ta ọ̀pọ̀ èèyàn jí nípa tẹ̀mí. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ másùnmáwo lílékenkà, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti lè bọ́.—Lúùkù 4:16-21; 19:47, 48; Jòhánù 7:46.

2 Ọkùnrin tá a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Jésù ará Násárétì, kò tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ ayé táwọn èèyàn ń lọ kọ́ nílùú Róòmù, Áténì, tàbí Alẹkisáńdíríà ìgbàanì. Síbẹ̀, gbogbo èèyàn ló mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni: ìjọba tí Ọlọ́run yóò fi ṣàkóso ilẹ̀ ayé lọ́nà tó kẹ́sẹ járí. Jésù tún ṣàlàyé àwọn ìlànà ìwà híhù pàtàkì—àwọn ìlànà tó wúlò gan-an lóde òní. Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jésù fi kọ́ni, tí wọ́n sì ń fi í sílò, ń gbádùn àǹfààní ojú ẹsẹ̀, títí kan ìtura kúrò nínú másùnmáwo lílékenkà. Ǹjẹ́ ìwọ náà ò fẹ́ gbádùn èyí?

3. Ìkésíni ọlọ́yàyà wo ni Jésù nawọ́ rẹ̀ sí wa?

3 O ṣì lè máa ṣiyèméjì. ‘Ǹjẹ́ ẹni tó gbé ayé ní ìgbà tó ti pẹ́ sẹ́yìn bẹ́ẹ̀ lè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé mi ìsinsìnyí?’ Á dáa kó o fetí sí ìkésíni ọlọ́yàyà Jésù, pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28-30) Kí ló ní lọ́kàn? Ẹ jẹ́ ká tú iṣu ọ̀rọ̀ yìí désàlẹ̀ ìkòkò, ká sì rí i bí ó ṣe lè fún wa ní ìtura kúrò nínú másùnmáwo tó pàpọ̀jù.

4. Àwọn wo ni Jésù bá sọ̀rọ̀, èé sì ti ṣe tó fi lè nira fún àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ṣe ohun tó ní kí wọ́n ṣe?

4 Jésù bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, ìyẹn àwọn tí ń fi tọkàntara fẹ́ láti ṣe ohun tó bófin mu ṣùgbọ́n ‘tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn’ nítorí pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ti sọ ọ̀ràn ẹ̀sìn di ẹrù ìnira. (Mátíù 23:4) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo nǹkan ni wọ́n ṣòfin fún. Ǹjẹ́ ayé ò ní fẹ́ẹ̀ẹ́ sú ọ, bó bá jẹ́ pé orin “o ò gbọ́dọ̀” ṣe tibí, “o ò gbọ́dọ̀ ṣe” tọ̀hún ni wọ́n ń kọ sí ọ létí lójoojúmọ́? Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Jésù ń tọ́ àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́nà òtítọ́, sọ́nà òdodo àti sọ́nà ìgbésí ayé rere. Dájúdájú, láti lè mọ Ọlọ́run tòótọ́, a ní láti fetí sí Jésù Kristi, torí pé nípasẹ̀ rẹ̀ làwọn èèyàn fi lè mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:9.

Másùnmáwo Ha Ń Dà Ọ́ Láàmú Bí?

5, 6. Báwo ni iṣẹ́ àti owó ọ̀yà ṣe rí nígbà ayé Jésù, bá a bá fi wé tòde òní?

5 Ọ̀rọ̀ yìí lè gba àfiyèsí rẹ nítorí pé wàhálà iṣẹ́ àti ti ìdílé lè ti máa kó ẹ láyà sókè. Tàbí kí ó jẹ́ pé àwọn ẹrù iṣẹ́ mìíràn ń wọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí, o ò yàtọ̀ sí àwọn olóòótọ́ ọkàn tí Jésù bá pàdé, tó sì ràn lọ́wọ́. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn àtijẹ-àtimu yẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ló ń bá ìyẹn yí lóde òní, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lọ́jọ́ Jésù.

6 Nígbà yẹn, wákàtí méjìlá gbáko ni lébìrà fi máa ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́. Iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́fà ni wọ́n ń ṣe lọ́sẹ̀. Owó tí wọ́n ń gbà kì í sì í sábàá ju ẹyọ owó dínárì kan ṣoṣo fún iṣẹ́ àṣeṣúlẹ̀. (Mátíù 20:2-10) Báwo nìyẹn ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú owó tí ìwọ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń gbà? Ó ṣòro láti fi owó ọ̀yà ìgbàanì wé ti òde òní. Ọ̀nà kan tá a lè gbà mọ bí wọ́n ṣe rí síra ni ká fi ohun tí owó lè rà nígbà yẹn wé ohun tó lè rà lóde òní. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé nígbà ayé Jésù, ìṣù búrẹ́dì tá a fi lítà kan ìyẹ̀fun àlìkámà ṣe yóò tó nǹkan bí owó iṣẹ́ wákàtí kan. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn sọ pé ife wáìnì àtàtà lè tó nǹkan bí owó iṣẹ́ wákàtí méjì. Ìsọfúnni yìí lè jẹ́ kí o rí i pé àwọn ará ìgbàanì ń ṣe làálàá àṣekúdórógbó nítorí àtijẹ-àtimu. Wọ́n fẹ́ ìtura, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti fẹ́ ẹ lónìí. Bó bá jẹ́ pé wọ́n gbà ọ́ síṣẹ́ ni, wọ́n lè máa fúngun mọ́ ẹ pé kí o túbọ̀ jára mọ́ṣẹ́. Ọwọ́ wa sábà máa ń dí débi pé a kì í ráyè ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan. Ìwọ náà á rí i pé o ń fẹ́ ìtura.

7. Báwo làwọn èèyàn ṣe dáhùn sí ìhìn Jésù?

7 Ó dájú pé ìkésíni Jésù sí gbogbo àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” kò ní ṣàìwọ ọ̀pọ̀ olùgbọ́ lọ́kàn nígbà yẹn. (Mátíù 4:25; Máàkù 3:7, 8) Sì rántí pé Jésù fi ìlérí náà kún un pé, “Èmi yóò sì tù yín lára.” Ìlérí kan náà wà fún wa lónìí. Ó sì lè mú ìtura wá bá wa bí a bá “ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀” wá lọ́rùn. Ó tún lè mú ìtura bá àwọn èèyàn wa, tí ipò tiwọn ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa.

8. Báwo ni ọ̀ràn ọmọ títọ́ àti ọjọ́ ogbó ṣe ń pa kún másùnmáwo?

8 Àwọn nǹkan míì tún wà tó ń wọ àwọn èèyàn lọ́rùn. Ìṣòro kékeré kọ́ ni ọ̀ràn ọmọ títọ́. Jíjẹ́ ọmọdé pàápàá tún ní ìṣòro tirẹ̀. Àwọn èèyàn púpọ̀ sí i, lọ́mọdé lágbà, ni hílàhílo ń dé bá, tí àìsàn sì ń fìtínà. Bí àwọn èèyàn tilẹ̀ ń pẹ́ láyé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, síbẹ̀ àwọn àgbàlagbà ní àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ tó ń bá wọn fínra, láìfi ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn pè.—Oníwàásù 12:1.

Ṣíṣiṣẹ́ Lábẹ́ Àjàgà Náà

9, 10. Ní ayé ọjọ́un, àmì kí ni àjàgà jẹ́, èé sì ti ṣe tí Jésù fi sọ pé kí àwọn èèyàn gba àjàgà tòun sí ọrùn wọn?

9 Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé nínú ọ̀rọ̀ tá a fà yọ látinú Mátíù 11:28, 29, Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn gbáàtúù ti lè rí i pé abẹ́ àjàgà làwọn ti ń ṣiṣẹ́. Àtayébáyé ni àjàgà ti jẹ́ àmì ìsìnrú. (Jẹ́nẹ́sísì 27:40; Léfítíkù 26:13; Diutarónómì 28:48) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ lébìrà nígbà ayé Jésù ló wà lábẹ́ àjàgà gidi, tí wọ́n ń gbé ẹrù wíwúwo. Bí wọ́n ṣe ṣe àjàgà ló máa pinnu bóyá ó máa rọni lọ́rùn tàbí ó máa dá egbò síni lọ́rùn àti léjìká. Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ káfíńtà, ó ṣeé ṣe kó ti ṣe àjàgà rí, kó sì ti mọ bá a ṣe ń ṣe èyí tó máa ‘rọni lọ́rùn.’ Bóyá ńṣe ló lẹ awọ tàbí aṣọ mọ́ ibi tó ti máa kan ọrùn àti èjìká, kí àjàgà náà lè rọrùn-ún lò.

10 Nígbà tí Jésù sọ pé, “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín,” ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ń fi ara rẹ̀ wé ẹni tí ń ṣe àwọn àjàgà tí wọ́n ṣe dáadáa, tí kò ní dá egbò sí ọrùn àti èjìká òṣìṣẹ́. Abájọ tí Jésù fi kún un pé: “Ẹrù mi sì fúyẹ́.” Èyí fi hàn pé àjàgà tó rọni lọ́rùn ni, iṣẹ́ náà kì í sì í ṣe àṣekúdórógbó. Òótọ́ ni pé pípè tí Jésù ń pe àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n gba àjàgà òun sí ọrùn wọn kò túmọ̀ sí pé wọ́n á rí ìtura ojú ẹsẹ̀ kúrò nínú gbogbo ìnira tó ń bá àwọn èèyàn nígbà yẹn. Síbẹ̀, èròǹgbà tuntun tó gbé dé yóò mú ìtura ńláǹlà wá fún wọn. Àwọn àtúnṣe tí wọ́n bá ṣe nínú bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan yóò mú ìtura wá fún wọn pẹ̀lú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìrètí tó ṣe kedere, tó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ yóò jẹ́ kí másùnmáwo dín kù nínú ìgbésí ayé wọn.

O Lè Rí Ìtura

11. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀ràn bíbọ́ àjàgà kan sílẹ̀ gbé òmíràn ni Jésù ń sọ?

11 Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí pé Jésù kò sọ pé ṣe ni àwọn èèyàn á bọ́ àjàgà kan sílẹ̀ gbé òmíràn. Ilẹ̀ Róòmù ṣì wà lórí àlééfà síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìjọba tòní ti wà lórí àlééfà níbi táwọn Kristẹni ń gbé. Owó orí tí ilẹ̀ Róòmù bù fáwọn èèyàn ní ọ̀rúndún kìíní ṣì wà níbẹ̀ digbí. Àìsàn àti ìṣòro ìṣúnná owó kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ ṣì ń da àwọn èèyàn láàmú. Síbẹ̀, nípa títẹ̀lé ẹ̀kọ́ Jésù wọ́n lè rí ìtura, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti lè rí ìtura lónìí.

12, 13. Kí ni ohun pàtàkì tí Jésù sọ pé yóò mú ìtura wá, ìgbésẹ̀ wo sì ni àwọn kan gbé?

12 Ohun tí àpèjúwe Jésù nípa àjàgà ń tọ́ka sí ní pàtàkì ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kò sí àní-àní pé lájorí iṣẹ́ tí Jésù ṣe ni iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 4:23) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tó sọ pé, “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín,” ó dájú pé èyí yóò wé mọ́ ṣíṣe irú iṣẹ́ tí òun ṣe. Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ti máa ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé ọ̀rọ̀ Jésù mú káwọn olóòótọ́ ọkàn pa iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ tì, kí wọ́n sì mú iṣẹ́ míì ṣe. Rántí bó ṣe pe Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù pé: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, èmi yóò sì mú kí ẹ di apẹja ènìyàn.” (Máàkù 1:16-20) Ó jẹ́ kí àwọn apẹja wọ̀nyẹn mọ bí wọn yóò ṣe láyọ̀ tó, bí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ tí òun fi sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé òun, ìyẹn bí wọ́n bá ń ṣe é lábẹ́ ìdarí òun àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òun.

13 Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yé àwọn kan lára àwọn Júù tó ń fetí sí i, wọ́n sì mú un lò. Ẹ fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́bàá òkun, gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ nínú Lúùkù 5:1-11. Àwọn apẹja mẹ́rin ti fi gbogbo òru ṣe làálàá láìrí ẹja kankan pa. Àfẹ̀ẹ̀kan náà, tí àwọ̀n wọn kún bámú! Kò ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀; iṣẹ́ ọwọ́ Jésù ni. Bí wọ́n ṣe yíjú sí etíkun, wọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó ń hára gàgà láti gbọ́rọ̀ Jésù. Èyí jẹ́ ká mọ ìdí tí Jésù fi sọ fáwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pé: ‘Láti ìsinsìnyí lọ, ẹ óò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.’ Kí wá ni wọ́n ṣe? “Wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.”

14. (a) Báwo la ṣe lè rí ìtura lónìí? (b) Kí ni ìhìn rere tí ń tuni lára tí Jésù kéde?

14 Ìwọ náà lè gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn. Iṣẹ́ kíkọ́ni ní òtítọ́ Bíbélì ṣì ń bá a lọ. Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jésù láti “gba àjàgà [rẹ̀] sọ́rùn” wọn; wọ́n sì ti di “apẹja ènìyàn.” (Mátíù 4:19) Àwọn kan ti sọ iṣẹ́ yìí di iṣẹ́ tí wọ́n ń fi ojoojúmọ́ ṣe; àwọn míì ń sa gbogbo ipá wọn láti máa ṣe é lóòrèkóòrè. Iṣẹ́ náà ń tu gbogbo wọn lára, ó sì ń tipa báyìí dín másùnmáwo kù. Ó jẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ wọn, sísọ ìhìn rere fáwọn èèyàn—ìyẹn “ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Nǹkan ayọ̀ ló máa ń jẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere, àgàgà irú ìhìn rere yìí. Inú Bíbélì ní pàtàkì la ti lè rí ìsọfúnni tí yóò fi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n lè dín másùnmáwo inú ìgbésí ayé wọn kù.—2 Tímótì 3:16, 17.

15. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa ìgbésí ayé?

15 Títí dé àyè kan, kódà àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ti jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Jésù nípa bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbésí ayé wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló lè fi tòótọ́tòótọ́ sọ pé ẹ̀kọ́ Jésù ti mú ìtura bá àwọn, ó sì ti tún ayé àwọn ṣe látòkèdélẹ̀. Ìgbésí ayé tìrẹ náà lè rí bẹ́ẹ̀, tó o bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà ìwà híhù tó wà nínú àkọsílẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àgàgà àwọn ìwé Ìhìn Rere tí Mátíù, Máàkù àti Lúùkù kọ.

Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Rí Ìtura

16, 17. (a) Ibo la ti lè rí lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù fi kọ́ni? (b) Kí ni a ó ṣe bí a bá fẹ́ rí ìtura nípasẹ̀ fífi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sílò?

16 Nígbà ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ àsọyé kan tí òkìkí rẹ̀ ṣì ń kàn kárí ayé títí di òní olónìí. Àsọyé yìí ni wọ́n ń pè ní Ìwàásù Lórí Òkè. Ó wà nínú Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje àti Lúùkù orí kẹfà. Ó jẹ́ àkópọ̀ ọ̀pọ̀ lára ẹ̀kọ́ rẹ̀. O tún lè rí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù láwọn ibòmíràn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ọ̀pọ̀ ohun tó sọ ló yéni yékéyéké, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣòroó fi ṣèwà hù. O ò ṣe fara balẹ̀ ka orí ìwé wọ̀nyẹn, kí o sì ronú lé wọn lórí? Jẹ́ kí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa darí èrò àti ìṣe rẹ.

17 Onírúurú ìsọ̀rí la lè pín àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sí. Ẹ jẹ́ ká kó àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì jọ sójú kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lè wà fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú oṣù, kí o sì pinnu láti máa fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé rẹ. Lọ́nà wo? Tóò, má kàn wò wọ́n gààràgà. Rántí ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso, tó béèrè lọ́wọ́ Jésù Kristi pé: “Nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Nígbà tí Jésù rán an létí àwọn ohun pàtàkì tí Òfin Ọlọ́run là sílẹ̀, ọkùnrin náà fèsì pé gbogbo rẹ̀ lòun ń pa mọ́. Síbẹ̀, ó rí i pé ó ṣì ku àwọn nǹkan kan. Jésù ní kí ó túbọ̀ sapá láti fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò lọ́nà tó gbéṣẹ́, kí ó di ọmọlẹ́yìn gidi. Àmọ́ ọkùnrin yìí kò múra tán láti ṣe gbogbo ìyẹn. (Lúùkù 18:18-23) Nítorí náà, ó yẹ kí ẹni tó bá fẹ́ tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù lónìí rántí pé ìyàtọ̀ wà láàárín wíwulẹ̀ tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Jésù àti mímú wọn lò ní ti gidi, kí onítọ̀hún lè dín másùnmáwo kù.

18. Ṣàlàyé bí àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe lè ṣàǹfààní fún ọ.

18 Bí o ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ṣíṣàyẹ̀wò àti fífi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sílò, wo kókó àkọ́kọ́ nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó tọ́ka sí Mátíù 5:3-9. Ní ti gidi, ẹnikẹ́ni nínú wa lè lo ọ̀pọ̀ àkókò láti ṣe àṣàrò lórí ìmọ̀ràn alárinrin tó wà nínú ẹsẹ wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n tó o bá wo gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, èrò wo lo máa ní nípa irú ẹ̀mí tó yẹ kéèyàn ní? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àpọ̀jù másùnmáwo nínú ìgbésí ayé rẹ, kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́? Báwo ni ayé rẹ ṣe lè sunwọ̀n sí i nípa títúbọ̀ gbájú mọ́ nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn ni pé kó o jẹ́ kí nǹkan tẹ̀mí gbà ọ́ lọ́kàn? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà nínú ìgbésí ayé rẹ tí kò yẹ kó gbà ọ́ lọ́kàn jù, kó o lè túbọ̀ ráyè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí? Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò fi kún ayọ̀ rẹ nísinsìnyí.

19. Kí lo lè ṣe láti jèrè ìmọ̀ àti òye púpọ̀ sí i?

19 Wàyí o, má fi mọ síbẹ̀ yẹn. O ò ṣe jíròrò ẹsẹ wọ̀nyẹn pẹ̀lú ẹlòmíràn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, bóyá ọkọ tàbí aya rẹ, ìbátan rẹ, tàbí ọ̀rẹ́ rẹ? (Òwe 18:24; 20:5) Rántí pé ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso náà béèrè irú ọ̀rọ̀ tí à ń sọ yìí lọ́wọ́ ẹlòmíràn—ìyẹn Jésù. Èsì tó fún un ì bá fi kún ayọ̀ rẹ̀ àti ìrètí rẹ̀ fún ìyè pípẹ́ títí. Olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ tó o fẹ́ bá jíròrò ẹsẹ wọ̀nyẹn kò lè mọ̀ tó Jésù; síbẹ̀, jíjíròrò nípa àwọn ẹ̀kọ́ Jésù yóò ṣe ẹ̀yin méjèèjì láǹfààní. Gbìyànjú láti tètè ṣe é.

20, 21. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ wo lo lè tẹ̀ lé láti fi mọ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, báwo lo sì ṣe lè mọ bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú sí?

20 Tún wo àpótí náà, “Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́.” A ṣètò ẹ̀kọ́ wọ̀nyí lọ́nà tí wàá fi rí ó kéré tán, ẹ̀kọ́ kan, tí wàá máa ronú lé lóòjọ́. O lè kọ́kọ́ lọ ka ohun tí Jésù sọ nínú àwọn ẹsẹ tá a tọ́ka sí. Lẹ́yìn náà, wáá ronú lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ronú jinlẹ̀ lórí bó o ṣe lè fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé rẹ. Bó o bá gbà pé o ti ń fi wọ́n sílò, ronú lórí nǹkan míì tó o tún lè ṣe láti túbọ̀ fi ẹ̀kọ́ Ọlọ́run náà ṣèwà hù. Gbìyànjú láti fi ẹ̀kọ́ yẹn sílò lọ́jọ́ yẹn. Bó bá gbà ẹ́ lákòókò láti lóye rẹ̀ tàbí láti mọ bó o ṣe lè fi í sílò, lo ọjọ́ kan sí i lórí ẹ̀kọ́ yẹn. Ṣùgbọ́n o, rántí pé kò dìgbà tó bá mọ́ ọ lára tán kó o tó kọjá lọ sórí ẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé e. O lè gbé ẹ̀kọ́ mìíràn yẹ̀ wò lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e. Nígbà tí ọ̀sẹ̀ yẹn bá parí, o lè ṣàtúnyẹ̀wò bó o ti kẹ́sẹ járí tó nínú fífi ẹ̀kọ́ mẹ́rin tàbí márùn-ún lára àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣèwà hù. Ní ọ̀sẹ̀ kejì, fi àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn kún un, lójoojúmọ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé o fìdí rẹmi nínú fífi ẹ̀kọ́ kan sílò, má jọ̀gọ̀ nù. Kò sí Kristẹni tí irú ìyẹn kì í ṣẹlẹ̀ sí. (2 Kíróníkà 6:36; Sáàmù 130:3; Oníwàásù 7:20; Jákọ́bù 3:8) Má a bá a lọ ní ọ̀sẹ̀ kẹta àti ọ̀sẹ̀ kẹrin.

21 Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù kan, ó ṣeé ṣe kó o ti kárí gbogbo kókó mọ́kànlélọ́gbọ̀n náà. Tóò, ìyàtọ̀ wo lo máa rí? Ǹjẹ́ o ò ní láyọ̀ sí i, ǹjẹ́ ọkàn rẹ ò sì ní balẹ̀ sí i? Ká tiẹ̀ sọ pé kìkì àtúnṣe bín-ń-tín lo ṣe, wàá rí i pé másùnmáwo tó o máa ń ní á dín kù, tàbí ó kéré tán, wàá lè kojú rẹ̀ nísinsìnyí, wàá sì mọ bí wàá ṣe máa bá a yí. Má gbàgbé pé àwọn kókó púpọ̀ tó wúlò gan-an ṣì wà nínú ẹ̀kọ́ Jésù tí a kò tò sínú àpótí yìí. O ò ṣe wá wọn kàn, kí o sì gbìyànjú láti fi wọ́n sílò?—Fílípì 3:16.

22. Kí ni ó lè jẹ́ àbájáde títẹ̀lé ẹ̀kọ́ Jésù, àmọ́ apá mìíràn wo ló tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

22 Wàá rí i pé àjàgà Jésù rọni lọ́rùn lóòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ọ̀rìn tiẹ̀. Ẹrù títẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fúyẹ́. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún tí àpọ́sítélì Jòhánù, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù ọ̀wọ́n, ti ń gbé àjàgà ọ̀hún, ó sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Ìwọ náà lè gbà pé bó ṣe rí gẹ́ẹ́ nìyẹn. Bó o bá ṣe túbọ̀ ń fi ẹ̀kọ́ Jésù ṣèwà hù, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá túbọ̀ máa rí i pé ohun tó ń mú kí ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ èèyàn kún fún másùnmáwo lónìí kò ní kó hílàhílo bá ọ. Wàá rí i pé o ti rí ìtura ńláǹlà. (Sáàmù 34:8) Àmọ́, nǹkan míì tún wà nípa àjàgà rírọrùn Jésù tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò. Jésù tún sọ pé “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” ni òun. Báwo ni ìyẹn ṣe wé mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù àti fífara wé e? A óò gbé èyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.—Mátíù 11:29.

Kí Ni Èsì Rẹ?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wo ojú Jésù fún ìtura kúrò nínú másùnmáwo lílékenkà?

• Àmì kí ni àjàgà jẹ́, èé sì ti ṣe?

• Kí nìdí tí Jésù fi ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n gba àjàgà tòun sọ́rùn?

• Báwo lo ṣe lè rí ìtura nípa tẹ̀mí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdọọdún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọdún 2002 ni: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Kí ni àwọn nǹkan àtàtà tó o lè rí nínú Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje? Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà, kọ́ni lẹ́bàá òkè kan ní Gálílì ló wà nínú àwọn orí wọ̀nyí. Jọ̀wọ́ ka àwọn ẹsẹ tá a tọ́ka sí nísàlẹ̀ yìí nínú Bíbélì tìrẹ, kí o sì bi ara rẹ láwọn ìbéèrè tó wà níwájú ẹsẹ wọ̀nyẹn.

1. 5:3-9 Kí ni èyí ń sọ fún mi nípa ìṣarasíhùwà mi? Báwo ni mo ṣe lè sapá láti túbọ̀ jẹ́ aláyọ̀? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ bójú tó àwọn àìní mi nípa tẹ̀mí?

2. 5:25, 26 Kí lohun tó sàn ju fífarawé ẹ̀mí aáwọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní?—Lúùkù 12:58, 59.

3. 5:27-30 Kí ni ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ Jésù nípa fífọkànyàwòrán ìṣekúṣe? Báwo ni yíyẹra fún irú ìròkurò bẹ́ẹ̀ ṣe lè fi kún ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn mi?

4. 5:38-42 Kí nìdí tó fi yẹ kí n gbìyànjú láti yàgò fún ẹ̀mí jàgídíjàgan tó gbòde kan lónìí?

5. 5:43-48 Báwo ni mo ṣe máa jàǹfààní nínú títúbọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn tí ǹ bá kà sí ọ̀tá? Báwo ni èyí ṣe lè dín gbúngbùngbún kù tàbí kí ó tilẹ̀ mú un kúrò pátápátá?

6. 6:14, 15 Bí n kì í báá dárí jini nígbà mìíràn, ṣé kì í ṣe ìlara tàbí ìkórìíra ló ń fà á? Àtúnṣe wo ni mo lè ṣe?

7. 6:16-18 Ṣé kì í ṣe bí mo ṣe rí lóde ló ń ká mi lára ju irú èèyàn tí mo jẹ́ nínú lọ́hùn-ún? Kí ló yẹ kó jẹ mí lógún jù?

8. 6:19-32 Kí ló ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí ọ̀ràn owó àti ohun ìní bá ká mi lára jù? Kí ni mo lè máa ronú nípa rẹ̀ tá á jẹ́ kí n lè wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀ràn yìí?

9. 7:1-5 Báwo ló ṣe máa ń rí lára mi nígbà tí mo bá wà ní sàkáání àwọn alárìíwísí àtàwọn tí ń ṣe lámèyítọ́, tó jẹ́ pé àléébù nìkan ni wọ́n máa ń rí? Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí n yẹra fún jíjẹ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀?

10. 7:7-11 Bí ṣíṣàì juwọ́ sílẹ̀ bá jẹ́ ànímọ́ tó dáa nígbà tí mo bá ń tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run, níní ànímọ́ yẹn nínú àwọn apá yòókù nínú ìgbésí ayé mi ńkọ́?—Lúùkù 11:5-13.

11. 7:12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ Òfin Pàtàkì náà, ǹjẹ́ mo ń fi ṣèwà hù déédéé nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?

12. 7:24-27 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ mi lọ̀ràn ara mi wà, báwo ni mo ṣe lè múra sílẹ̀ de ìjì ayé àtàwọn ìgbì wàhálà, nígbà tí wọ́n bá bì lù mí? Kí nìdí tó fi yẹ kí n ronú lórí èyí dáadáa nísinsìnyí?—Lúùkù 6:46-49.

Àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tí mo lè ronú lé lórí:

13. 8:2, 3 Báwo ni mo ṣe lè fi ìyọ́nú hàn sí àwọn tí nǹkan ò ṣẹnuure fún, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe?

14. 9:9-38 Báwo ni mo ti lójú àánú tó, ṣé mo lè túbọ̀ ní ojú àánú sí i?

15. 12:19 Pẹ̀lú ohun tí mo kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù, ǹjẹ́ mo máa ń gbìyànjú láti yẹra fún àríyànjiyàn?

16. 12:20, 21 Rere wo ni mo lè ṣe nípa ṣíṣàì kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ẹlòmíràn, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu mi tàbí nípa ìṣe mi?

17. 12:34-37 Kí ni mo máa ń sọ̀rọ̀ lé lórí ṣáá? Mo mọ̀ pé bí mo bá fún ọsàn, omi ọsàn ló máa jáde, fún ìdí yìí, èé ṣe tó fi yẹ kí n pe àfiyèsí sí ohun tó wà nínú mi, àní lọ́kàn mi?—Máàkù 7:20-23.

18. 15:4-6 Látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ẹ̀kọ́ wo ni mo rí kọ́ nípa fífi tìfẹ́tìfẹ́ ṣaájò àwọn àgbàlagbà?

19. 19:13-15 Kí ló yẹ kí n rí àyè fún?

20. 20:25-28 Èé ṣe tí kò fi dáa kéèyàn máa wá ọ̀nà láti jẹ gàba lórí àwọn ẹlòmíì? Báwo ni mo ṣe lè fara wé Jésù nínú ọ̀ràn yìí?

Àwọn àfikún ìsọfúnni, tí Máàkù kọ sílẹ̀:

21. 4:24, 25 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ronú lórí bí mo ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn?

22. 9:50 Bí ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi bá jẹ́ ti ọmọlúwàbí, èso rere wo ni yóò so?

Paríparí rẹ̀, díẹ̀ rèé lára àwọn ẹ̀kọ́ tí Lúùkù kọ sílẹ̀:

23. 8:11, 14 Bí mo bá jẹ́ kí àníyàn ṣíṣe, ọrọ̀ àti fàájì gbà mí lọ́kàn, kí ló lè yọrí sí?

24. 9:1-6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní agbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá, kí ló fi sí ipò kìíní?

25. 9:52-56 Ṣé mo máa ń yára bínú? Ṣé mo máa ń yàgò fún ẹ̀mí ìforóyaró?

26. 9:62 Ojú wo ló yẹ kí n fi wo ojúṣe mi láti máa sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?

27. 10:29-37 Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé aládùúgbò rere ni mí, pé n kì í ṣe aláìbìkítà?

28. 11:33-36 Àwọn ìyípadà wo ni mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa gbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì?

29. 12:15 Ǹjẹ́ ìwàláàyè ní nǹkan kan í ṣe pẹ̀lú ohun ìní?

30. 14:28-30 Bí mo bá ń gbé àwọn ọ̀ràn yẹ̀ wò dáadáa kí n tó ṣèpinnu, kí ni màá yẹra fún, báwo ló sì ṣe máa ṣe mí láǹfààní?

31. 16:10-12 Kí làwọn àǹfààní tí mo lè rí látinú pípa ìwà títọ́ mọ́?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà lábẹ́ àjàgà Jésù ń tuni lára