Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Oògùn Ojú Láti Fi Pa Ojú Rẹ”

“Oògùn Ojú Láti Fi Pa Ojú Rẹ”

“Oògùn Ojú Láti Fi Pa Ojú Rẹ”

ÈYÍ ni egbòogi tí Jésù Kristi dámọ̀ràn pé kí ìjọ Kristẹni tó wà ní Laodíkíà, Éṣíà Kékeré ní ọ̀rúndún kìíní máa lò.

Jésù sọ pé: “Ra . . . oògùn ojú láti fi pa ojú rẹ, kí o bàa lè ríran.” Kì í ṣe àrùn ojú ti ara ló ń sọ, bí kò ṣe ojú fífọ́ nípa tẹ̀mí tó nílò ìtọ́jú. Ẹ̀mí ìlú ńlá tó lọ́rọ̀ tó sì láásìkí táwọn Kristẹni tó wà ní Laodíkíà ń gbé ti nípa lórí wọn gan-an débi pé wọn ò ka ohun tó dìídì jẹ́ àìní wọn nípa tẹ̀mí sí mọ́.

Jésù sọ pé èyí ló sọ ojú wọn di bàìbàì, ó ní: “Ìwọ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀, àwọn mẹ́ńbà ìjọ náà nílò “oògùn ojú” tí ń woni sàn, èyí tó jẹ́ pé kìkì nípa fífara mọ́ ẹ̀kọ́ àti ìbáwí Jésù Kristi nìkan ni wọ́n fi lè rí i gbà. Jésù sọ pé: “Rà . . . lọ́dọ̀ mi.”—Ìṣípayá 3:17, 18.

Bíi ti àwọn ará Laodíkíà yẹn, àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì àti fàájì tó gbòde kan láyìíká ibi tí wọ́n ń gbé má bàa nípa lórí wọn, bóyá láìfura pàápàá. Egbòogi tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ojú ìwòye tó dára nípa tẹ̀mí ló wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣílétí náà pé: ‘Ra . . . oògùn ojú lọ́dọ̀ [Jésù], láti fi pa ojú rẹ, kí o bàa lè ríran.’

Ó yẹ fún àfiyèsí pé rírà ni a máa ra “oògùn ojú” yìí. Ó túmọ̀ sí pé ó máa náni ní nǹkan kan. A gbọ́dọ̀ lo àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti láti ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Onísáàmù sì mú un dá wa lójú pé, Ọ̀rọ̀ yìí “mọ́, ó ń mú kí ojú [tẹ̀mí] mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 19:8.